Ohun Tí Bíbélì Sọ
Ṣé gbogbo àdúrà ni Ọlọ́run máa ń gbọ́?
Ọlọ́run máa ń tẹ́tí sí àwọn èèyàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè. (Sáàmù 145:18, 19) Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ rọ̀ wá pé ká máa sọ ohunkóhun tó bá ń jẹ wá lọ́kàn fún un. (Fílípì 4:6, 7) Síbẹ̀, àwọn àdúrà kan wà tí inú Ọlọ́run ò dùn sí. Bí àpẹẹrẹ, inú Ọlọ́run ò dùn sí kéèyàn máa gba àdúrà àkọ́sórí.—Ka Mátíù 6:7.
Bákan náà, inú Jèhófà kì í dùn sí àdúrà àwọn tó ń mọ̀ọ́mọ̀ rú òfin rẹ̀. (Òwe 28:9) Bí àpẹẹrẹ, láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, Ọlọ́run kò fetí sí àdúrà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n pààyàn. Èyí jẹ́ ká mọ̀ pé, tí a bá fẹ́ kí Ọlọ́run gbọ́ àdúrà wa àwọn ohun kan wà tí a gbọ́dọ̀ ṣe.—Ka Aísáyà 1:15.
Kí la gbọ́dọ̀ ṣe kí Ọlọ́run tó gbọ́ àdúrà wa?
Bí a kò bá ní ìgbàgbọ́, kò sí bí a ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run. (Jákọ́bù 1:5, 6) Ó gbọ́dọ̀ dá wa lójú pé Ọlọ́run wà àti pé ọ̀rọ̀ wa jẹ ẹ́ lógún. A gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ kí ìgbàgbọ́ wa lè túbọ̀ jinlẹ̀ sí i, torí pé orí àwọn ẹ̀rí àti ìdánilójú tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ìgbàgbọ́ tòótọ́ dá lé.—Ka Hébérù 11:1, 6.
Ó yẹ ká máa gbàdúrà tọkàntọkàn àti pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀. Kódà, Jésù Ọmọ Ọlọ́run rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ nígbà tó ń gbàdúrà. (Lúùkù 22:41, 42) Torí náà, dípò ká máa yan ohun tí a fẹ́ lé Ọlọ́run lọ́wọ́, ṣe ló yẹ ká gbìyànjú láti mọ ohun tí ó fẹ́ ká ṣe, tí a bá sì ń ka Bíbélì la tó lè mọ̀ wọ́n. Èyí á jẹ́ kí àdúrà wa máa bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu.—Ka 1 Jòhánù 5:14.