BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA Dà
Mo Rò Pé Mò Ń Jayé Orí Mi Ni
ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1982
ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: POLAND
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: MÒ Ń HÙWÀ IPÁ, MÒ Ń LO OÒGÙN OLÓRÓ, MO SÌ Ń WÁ IṢẸ́ TÓ MÁA SỌ MÍ DI ỌLỌ́RỌ̀
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ:
Ìlú kékeré kan lórílẹ̀-èdè Poland ni wọ́n bí mi sí. Ìlú yìí kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sí ààlà ilẹ̀ Jámánì. Àwọn oko àti igbó kìjikìji ló yí wa ká, àmọ́ ọkàn wa balẹ̀. Àwọn òbí mi fẹ́ràn mi gan-an. Wọ́n fẹ́ kí ìgbésí ayé mi dùn, kí n ṣe dáadáa níléèwé kí n sì níṣẹ́ tá á máa mówó gidi wọlé fún mi.
Nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà fún mi nígbà tí mo lọ kọ́ ẹ̀kọ́ òfin ní yunifásítì tó wà nílùú Wrocław. Torí pé ojú àwọn òbí mi kò tó mi mọ́, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kó ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́. Àtilẹ̀ ni mo ti fẹ́ràn eré bọ́ọ̀lù, àmọ́ àwọn tí mo ń bá rìn wá jẹ́ kí n ti àṣejù bọ̀ ọ́. Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù tó wá láti ìlú Warsaw ni mo yàn láàyò, gbogbo òpin ọ̀sẹ̀ ni mo sì máa ń tẹ̀ lé wọn lọ sí ibikíbi tí wọ́n bá ti fẹ́ lọ gbá bọ́ọ̀lù. Tá a bá ti lọ bẹ́yẹn, a máa ń mutí yó, a tún máa ń lo oògùn olóró, a sì máa ń bá àwọn alátìlẹyìn ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù òdìkejì jà láwọn ìgbà míì. Mo wò ó pé èyí ni mo fi ń gbé wàhálà iṣẹ́ ojoojúmọ́ kúrò lọ́kàn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo mọ̀ pé tọwọ́ àwọn ọlọ́pàá bá tẹ̀ mí, mi ò ní lè ṣe iṣẹ́ amòfin mọ́.
Èmi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi tún fẹ́ràn láti máa lọ sí òde ijó. Tá a bá ti lọ, a sábà máa ń ja ìjà ìgboro. Àwọn ọlọ́pàá mú mi láwọn ìgbà mélòó kan, àmọ́ mo máa ń fún wọn ní ẹ̀gúnjẹ kí wọ́n má báa gbé mi lọ sílé ẹjọ́. Gbogbo èrò mi ni pé mò ń jayé orí mi ni. Síbẹ̀ náà, mo mọ̀ lọ́kàn mi lọ́hùn-ún pé ohun tí mò ń ṣe kò dáa. Torí náà, mo máa ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì láwọn ọjọ́ Sunday, kí n lè fi tu ara mi lọ́kàn.
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ:
Lọ́dún 2004, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì wá sílé mi, mo sì gbà wọ́n láyè láti máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí mo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa ohun tí Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ máa ṣe, ẹ̀rí ọkàn mi wá túbọ̀ ń dà mí láàmù. Mo mọ̀ pé ó yẹ kí n dín ọtí mímu kù, kí n sì jáwọ́ nínú lílo oògùn olóró àti ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ tí mò ń kó. Mo tún rí i pé ó yẹ kí n jáwọ́ nínú ìwà jàgídíjàgan. Àmọ́, mi ò ṣe àtúnṣe kankan.
Ohun kan ṣẹlẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ kan tó jẹ́ kí n yíwà pa dà. Ó ṣẹlẹ̀ pé mo dojú ìjà kọ èèyàn mẹ́jọ, wọ́n sì lù mí lálùbolẹ̀. Mo rántí pé mo ṣubú gbalaja sójú títì, síbẹ̀ wọn ò yéé lù mí. Ẹ̀mí mi fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́, ni mo bá gbàdúrà pé: “Jèhófà, jọ̀ọ́ dárí jì mí torí pé mi ò fọwọ́ pàtàkì mú Ọ̀rọ̀ rẹ. Tí wọn ò bá pa mí, màá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, màá sì tún ayé mi ṣe.” Mo dúpẹ́ pé mo yè é. Mo sì mú ìlérí mi ṣẹ pé màá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Lọ́dún 2006, mo kó lọ sórílẹ̀-èdè England. Gbogbo ohun tó wà lọ́kàn mi ni pé kí n rí towó ṣe, kí n sì pa dà sórílẹ̀-èdè Poland láti lọ gba oyè kún oyè nínú iṣẹ́ amòfin. Bí mó ṣe ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi lọ, ẹsẹ Bíbélì kan tún ìrònú mi ṣe. Ìyẹn ni ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo ka ohun gbogbo sí àdánù pẹ̀lú ní tìtorí ìníyelórí títayọ lọ́lá ti ìmọ̀ nípa Kristi Jésù Olúwa mi. Ní tìtorí rẹ̀, èmi ti gba àdánù ohun gbogbo, mo sì kà wọ́n sí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ pàǹtírí, kí n lè jèrè Kristi.” (Fílípì 3:8) Amòfin bíi tèmi ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, òun náà sì máa ń hùwà jàgídíjàgan. (Ìṣe 8:3) Síbẹ̀, ó rí i pé òun ṣì lè gbé ìgbésí ayé tó dára, ìyẹn ni pé kó fi ayé rẹ̀ sin Ọlọ́run, kó sì sa gbogbo ipá rẹ̀ láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Nígbà tí mo ronú jinlẹ̀ lórí àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù, ó wá yé mi pé ṣíṣe iṣẹ́ tó máa sọni di olówó àti ìwà jàgídíjàgan kò lè fúnni láyọ̀ tó dénú. Ó dá mi lójú pé èmi náà lè yí pa dà bí Pọ́ọ̀lù ṣe yí pa dà. Torí náà, mo pinnu láti dúró sí orílẹ̀-èdè England, mi ò sì lọ gba oyè kún oyè nínú iṣẹ́ amòfin mọ́.
Bí mo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Jèhófà ni mo túbọ̀ ń sún mọ́ ọn. Nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run máa ń darí ji ẹnikẹ́ni tó bá jáwọ́ nínú ìwàkíwà, ọ̀rọ̀ yẹn wọ̀ mí lọ́kàn gan-an. (Ìṣe 2:38) Mo rí ìdí tí Ọlọ́run fi kórìíra ìwà ipá nígbà tí mo ronú lórí ọ̀rọ̀ inú 1 Jòhánù 4:16, tó sọ pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.”
Ó wù mí láti gbádùn ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
Ìwà àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún wú mi lórí gan-an. Ó ṣe kedere sí mi pé wọ́n ń sapá láti fi ìlànà Bíbélì nípa ìwà tó yẹ kéèyàn máa hù sílò. Ó wù mí láti gbádùn ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Èyí mú kí n sapá gidigidi láti fi àwọn ìwàkíwà ọwọ́ mi sílẹ̀. Mo ṣe ìrìbọmi lọ́dún 2008, mo sì tipa bẹ́ẹ̀ di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ:
Ẹ̀kọ́ Bíbélì ti yí ìgbésí ayé mi pa dà. Mi ò lépa àtidi olówó rẹpẹtẹ mọ́, mo sì ti jáwọ́ nínú ìwà jàgídíjàgan, lílo oògùn olóró, mímú ọtí yó kẹ́ri àti àṣejù nídìí eré bọ́ọ̀lù. Ní báyìí, mo ti di òjíṣẹ́ Ọlọ́run, mo sì gbádùn kíkọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Mo ṣì máa ń gbádùn kí n máa wo bọ́ọ̀lù, àmọ́ mi ò kì í ṣàṣejù nídìí rẹ̀ mọ́.
Mo tún fẹ́ arẹwà obìnrin kan tó ń jẹ́ Esther, a sì jọ ń sin Jèhófà. A mọwọ́ ara wa gan-an. Inú wa sì máa ń dùn bá a ṣe jọ ń kọ́ àwọn tó ń sọ èdè Polish ní northwest England lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ní báyìí, ọkàn mi balẹ̀ ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Ẹ̀rí ọ̀kan kò dà mí láàmú mọ́, mo sì ń gbé ìgbésí ayé tó nítumọ̀.