Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Kí ni “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” tí Hébérù 4:12 sọ pé ó “yè, ó sì ń sa agbára”?
Ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ṣáájú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí àtèyí tó sọ lẹ́yìn rẹ̀ fi hàn pé ète Ọlọ́run tá a rí nínú Bíbélì ló ń sọ.
Nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa, a sábà máa ń tọ́ka sí Hébérù 4:12 láti jẹ́ ká mọ̀ pé Bíbélì lágbára láti yí ìgbésí ayé àwọn èèyàn pa dà, ó sì tọ̀nà tá a bá sọ bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, ó yẹ ká ronú nípa ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ ṣáájú ẹsẹ Bíbélì yìí àtèyí tí wọ́n sọ lẹ́yìn rẹ̀. Ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ fáwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni ni pé kí wọ́n máa ṣe ohun tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Wọ́n sì lè mọ ìfẹ́ Ọlọ́run tàbí ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe fún aráyé nínú Ìwé Mímọ́ tó wà nígbà yẹn. Pọ́ọ̀lù sọ àpẹẹrẹ kan, ìyẹn ni bí Ọlọ́run ṣe dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò ní Íjíbítì. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láǹfààní láti wọ ilẹ̀ ìlérí “tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin,” níbi tí wọ́n á ti ní ojúlówó ìsinmi.—Ẹ́kís. 3:8; Diu. 12:9, 10.
Ohun tí Ọlọ́run sọ pé òun fẹ́ ṣe fún wọn nìyẹn. Àmọ́ torí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ya alágídí, wọn ò sì lo ìgbàgbọ́, púpọ̀ lára wọn ò wọnú ìsinmi Ọlọ́run. (Núm. 14:30; Jóṣ. 14:6-10) Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù tún fi kún un pé àǹfààní ṣì wà fún wọn láti wọnú ‘ìsinmi Ọlọ́run.’ (Héb. 3:16-19; 4:1) Ó dájú pé ìlérí yẹn wà lára àwọn ohun tí Ọlọ́run sọ pé òun máa ṣe fáráyé. Bíi tàwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni, ó yẹ káwa náà mọ ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́, ká sì máa gbé ìgbé ayé tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. Pọ́ọ̀lù fi ohun tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 2:2 àti Sáàmù 95:11 gbe ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́yin káwọn èèyàn náà lè mọ̀ pé kì í ṣe èrò tiẹ̀ ló sọ.
Inú wa dùn pé ‘ìlérí kan ṣì wà nílẹ̀ fún wíwọnú ìsinmi Ọlọ́run.’ A nígbàgbọ́ pé òótọ́ lohun tí Bíbélì sọ pé a máa wọnú ìsinmi Ọlọ́run, a sì ń ṣe ohun táá jẹ́ ká wọnú rẹ̀. Kì í ṣe pípa Òfin Mósè mọ́ láá mú kéèyàn rí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe nípa ìsapá wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká máa lo ìgbàgbọ́, ká gbà pé Jèhófà máa ṣe ohun tó ní lọ́kàn fáráyé, ká sì tún máa fayọ̀ gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. Láfikún síyẹn, ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, táwọn náà sì ń kọ́ nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run sọ pé òun máa ṣe fáráyé. Ọ̀pọ̀ lára wọn lo ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, wọ́n yí ìgbésí ayé wọn pa dà, wọ́n sì ṣèrìbọmi. Àwọn ìyípadà tí wọ́n ń ṣe yìí jẹ́ ká rí i dájú pé lóòótọ́ ni “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára.” Awọn ohun tí Ọlọ́run sọ nínú Bíbélì pé òun máa ṣe là ń jẹ́ kó darí ìgbésí ayé wa, wọ́n á sì máa sa agbára lórí wa títí láé.