Ìkórè Yìí Mà Pọ̀ O!
JÉSÙ sọ tẹ́lẹ̀ pé tó bá di àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn ọmọlẹ́yìn òun máa ṣe iṣẹ́ ìkórè tó pọ̀ gan-an. (Mát. 9:37; 24:14) Ká lè rí bí àsọtẹ́lẹ̀ Jésù yìí ṣe ń ṣẹ, ẹ jẹ́ ká jọ dé àgbègbè kan tó ń jẹ́ Transcarpathia, lórílẹ̀-èdè Ukraine. Ní ìlú mẹ́ta péré lágbègbè yẹn, àádọ́ta [50] ìjọ ló wà ńbẹ̀, àwọn akéde tó sì lé ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún àti ọgọ́rùn-ún mẹ́rin [5,400] ló wà láwọn ìjọ yìí.a Ká lè mọ bí àwọn ará ṣe pọ̀ tó láwọn ìlú yìí, tá a bá kó èèyàn mẹ́rin jọ, ọ̀kan lára wọn máa jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà!
Irú àwọn èèyàn wo làwọn tó wà lágbègbè yẹn? Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Vasile sọ pé: “Àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ Bíbélì gan-an níbí, wọn ò fẹ́ kéèyàn máa fọwọ́ ọlá gbá ẹlòmíì lójú, àwọn ìdílé wọn máa ń ṣera wọn lọ́kan, wọ́n sì máa ń ran ara wọn lọ́wọ́.” Ó tún fi kún un pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ohun tá a gbà gbọ́ ni wọ́n fara mọ́, síbẹ̀, tá a bá fi ohun kan hàn wọ́n látinú Bíbélì, wọ́n máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sílẹ̀.”
Àwọn ará pọ̀ gan-an lágbègbè yẹn, kò sì rọrùn láti wàásù torí pé iye èèyàn tí akéde kan máa wàásù fún ò pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ìjọ kan ní akéde mẹ́rìnléláàádóje [134], àmọ́ àwọn ilé tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn ò ju àádọ́ta [50] lọ! Ọgbọ́n wo làwọn ará ń dá sí i?
Ọ̀pọ̀ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló ń náwó nára kí wọ́n lè lọ wàásù níbi tí àìní wà. Arákùnrin Ionash tó ti pé ẹni àádọ́rùn-ún [90] ọdún sọ pé: “Ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ wa, iye ilé tí akéde kan máa wàásù dé ò lè ju méjì lọ. Kó tó di pé àìlera mi bẹ̀rẹ̀, mo máa ń wàásù lábúlé wa, mo tún máa ń rìnrìn-àjò nǹkan bí ọgọ́jọ [160] kìlómítà láti lọ wàásù níbi tí àìní gbé pọ̀, èdè Hungarian ni mo sì fi ń wàásù níbẹ̀.” Ó gba ìsapá káwọn akéde tó lè lọ wàásù láwọn àgbègbè míì. Arákùnrin Ionash sọ pé: “Aago mẹ́rin ni mo máa ń jí láàárọ̀ kí n lè rí ọkọ̀ ojú irin wọ̀, mo sì máa wàásù títí di aago mẹ́fà ìrọ̀lẹ́ nígbà tí ọkọ̀ ojú irin bá ń pa dà sí àdúgbò mi. Nǹkan bí ẹ̀ẹ̀mejì sí ẹ̀ẹ̀mẹta ni mo máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́sẹ̀.” Ṣé ìsapá rẹ̀ wá sèso rere? Ó ní: “Iṣẹ́ ìwàásù yìí ń fún mi láyọ̀ gan-an ni.” Ó tún fi kún un pé: “Inú mi dùn pé mo láǹfààní láti ran ìdílé kan lọ́wọ́ níbi tí àìní wà, àwọn náà sì ti wà nínú òtítọ́ báyìí.”
Lóòótọ́, kì í ṣe gbogbo àwọn ará tó wà lágbègbè yìí ló lè rìnrìn-àjò ọ̀nà jíjìn láti lọ wàásù. Síbẹ̀ gbogbo wọn, títí kan àwọn àgbàlagbà ló ń sapá kí wọ́n lè wàásù fún gbogbo àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn. Torí bí wọ́n ṣe ń fìtara wàásù, nǹkan bí ìdajì gbogbo àwọn tó ń gbé ìlú mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yẹn ló wá sí Ìrántí Ikú Kristi lọ́dún 2017. Ó ṣe kedere nígbà náà pé, ibi yòówù ká wà, gbogbo wa la ṣì ní ‘púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nínú iṣẹ́ Olúwa.’—1 Kọ́r. 15:58.
a Àwọn ìlú náà ni Hlybokyy Potik, Serednye Vodyane àti Nyzhnya Apsha.