Má Ṣe Fà Sẹ́yìn
1. Kí ló gba ìgboyà, kí sì nìdí?
1 Ǹjẹ́ ó ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí pé o kò fẹ́ jẹ́rìí níléèwé torí pé ẹ̀rù ń bà ẹ́ pé wọ́n máa fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́? Ohun kan tó dájú ni pé ó gba ìgboyà kó o tó lè jẹ́rìí, ní pàtàkì tó bá jẹ́ pé onítìjú èèyàn ni ẹ́. Àmọ́, kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́?
2. Kí nìdí tí jíjẹ́rìí níléèwé fi gba ọgbọ́n?
2 Lo Ọgbọ́n: Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó yẹ kó o wo iléèwé rẹ gẹ́gẹ́ bí ibì kan tó o ti ní àǹfààní tó pọ̀ dáadáa láti máa jẹ́rìí, ó yẹ kó o fi sọ́kàn pé kò yẹ kó jẹ́ pé gbogbo èèyàn tó o bá ṣáà ti rí ni wàá máa bá sọ ọ̀rọ̀ nípa Bíbélì, bí ìgbà tó ò ń wàásù láti ilé dé ilé. Torí náà, ńṣe ni kó o lo ọgbọ́n láti mọ ìgbà tó yẹ kó o sọ̀rọ̀. (Oníw. 3:1, 7) Ó lè jẹ́ pé iṣẹ́ kan tẹ́ ẹ̀ ń ṣe ní kíláàsì yín tàbí iṣẹ́ àṣetiléwá kan tí wọ́n gbé fún yín ló máa fún ẹ láǹfààní láti sọ ohun tó o gbà gbọ́. Ọmọ iléèwé rẹ kan sì lè fẹ́ mọ ìdí tí o kì í fi í lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò kan. Látìbẹ̀rẹ̀ sáà ẹ̀kọ́ tuntun ni àwọn Kristẹni kan ti jẹ́ kí àwọn olùkọ́ wọn mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni àwọn, tí wọ́n sì fún wọn ní àwọn ìtẹ̀jáde tó ṣàlàyé ohun tá a gbà gbọ́. Ńṣe ni àwọn míì sì máa ń fi àwọn ìtẹ̀jáde kan sórí tábìlì wọn, kí àwọn ọmọléèwé wọn lè rí i kí wọ́n sì bi wọ́n ní ìbéèrè nípa rẹ̀.
3. Báwo lo ṣe lè múra sílẹ̀ láti jẹ́rìí níléèwé?
3 Múra Sílẹ̀: Tó o bá múra sílẹ̀, èyí á jẹ́ kó o túbọ̀ ní ìgboyà. (1 Pét. 3:15) Torí náà, gbìyànjú láti ronú nípa àwọn ìbéèrè táwọn ọmọ iléèwé rẹ lè bi ẹ́, kó o sì ronú nípa bó o ṣe lè dáhùn. (Òwe 15:28) Tó bá ṣeé ṣe, tọ́jú Bíbélì rẹ àti àwọn ìtẹ̀jáde bíi mélòó kan pa mọ́ sí iléèwé, irú bí ìwé Reasoning, Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé, àtàwọn ìtẹ̀jáde tó sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀dá, kó o bàa lè fa ọ̀rọ̀ yọ látinú wọn nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Sọ fún àwọn òbí rẹ pé kí wọ́n jẹ́ kẹ́ ẹ máa ṣe ìdánrawò nígbà Ìjọsìn Ìdílé yín.
4. Kí nìdí tó fi yẹ kó o máa bá a nìṣó láti máa jẹ́rìí níléèwé?
4 Ní Èrò Tó Dára: Má ṣe máa ronú pé ìgbà gbogbo ni àwọn ọmọléèwé rẹ á máa fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́ nígbà tó o bá sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀kọ́ Bíbélì. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kí ìgboyà tó o ní wú àwọn míì lórí, èyí sì lè mú kí wọ́n fetí sílẹ̀. Àmọ́, má ṣe rẹ̀wẹ̀sì bí ẹnì kankan kò bá fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ. Inú Jèhófà á dùn sí ẹ pé o gbìyànjú. (Héb. 13:15, 16) Máa bá a nìṣó láti máa bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ‘máa bá a nìṣó ní fífi àìṣojo sọ̀rọ̀.’ (Ìṣe 4:29; 2 Tím. 1:7, 8) Wo bí inú rẹ á ṣe dùn tó nígbà tí ẹnì kan bá fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ. Onítọ̀hún sì lè wá di ìránṣẹ́ Jèhófà bíi tìẹ nígbà tó bá yá!