MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Máa Lo Àwọn Ìwé Ìròyìn Wa
Látọdún 2018, àwọn ìwé ìròyìn tá à ń fi síta máa ń sọ̀rọ̀ nípa àkòrí kan ní pàtó. Àwọn ìwé ìròyìn yìí wà nínú Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́. Torí náà, a lè lò wọ́n lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. A tún lè mú díẹ̀ dání tá a bá ń rìnrìn-àjò tàbí lọ sọ́jà. A kì í fàwọn ìwé ìròyìn yìí darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ ohun tó wà níbẹ̀ lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Lẹ́yìn tó o bá bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò, ka ẹsẹ Bíbélì kan, kó o sì sọ kókó kan nínú ìwé ìròyìn wa tó máa wọ ẹni náà lọ́kàn. Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ ẹni tó ní ìdílé tàbí ẹni tó ní ẹ̀dùn ọkàn lò ń bá sọ̀rọ̀, o lè sọ pé: “Mo ti ka ìwé ìròyìn kan tó sọ̀rọ̀ lórí kókó yẹn. Ṣé kí n fi hàn yín?” Tó o bá rí i pé ẹni náà nífẹ̀ẹ́ sí i, o lè fún un ní ìwé ìròyìn náà tàbí kó o fi ìlujá ẹ̀ ránṣẹ́ sí i, kódà kó jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tẹ́ ẹ máa ríra nìyẹn. Lóòótọ́, kì í ṣe bá a ṣe máa fún àwọn èèyàn níwèé ló jẹ wá lógún, síbẹ̀ tá a bá lo àwọn ìwé ìròyìn wa, a máa rí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—Iṣe 13:48.
2018
2019
2020
Kí ló máa ń wọ àwọn èèyàn lọ́kàn jù ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín?