MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
A Dúpẹ́ Lọ́wọ́ Jèhófà Torí Ìfẹ́ Tẹ́ Ẹ̀ Ń Fi Hàn
Nǹkan ò rọrùn fáwọn ará tó wà ní Tẹsalóníkà, síbẹ̀ wọ́n ń fìfẹ́ hàn síra wọn. (2Tẹ 1:3, 4) Lónìí, àwa èèyàn Jèhófà náà ń fìfẹ́ hàn síra wa kárí ayé. Abala tá a pè ní “Bá A Ṣe Ń Ná Owó Tẹ́ Ẹ Fi Ń Ṣètọrẹ” lórí ìkànnì jw.org á jẹ́ kẹ́ ẹ mọ bá a ṣe ń lo owó tẹ́ ẹ fi ń ṣètọrẹ láti ṣèrànwọ́ fáwọn ará tó wà nínú ìṣòro. A mọyì ẹ̀mí ọ̀làwọ́ yín àti ìfẹ́ tẹ́ ẹ̀ ń fi hàn.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ À Ń “DÚPẸ́ LỌ́WỌ́ ỌLỌ́RUN NÍGBÀ GBOGBO NÍTORÍ YÍN,” KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
• Àwọn nǹkan wo ni ètò Ọlọ́run ń fi ọrẹ wa ṣe?
• Ọ̀nà wo ló dáa jù láti ṣètìlẹyìn fáwọn ará wa tó jẹ́ aláìní?—Tún wo àpilẹ̀kọ náà “Ohun Tó Ṣẹ́ Kù Níbì Kan Ń Dí Àìtó Àwọn Míì” lórí ìkànnì jw.org