Ìṣètò Ìpèsè Omi London—Apá Tuntun Kan
Láti ọwọ́ aṣojúkọ̀ròyin Jí! ní Britain
LONDON, olú ìlú England, ti ní ọ̀kan lára ìṣètò ìpèsè omi tí ó ga lọ́lá jù lọ lágbàáyé báyìí. Wọ́n parí rẹ̀ ní ọdún méjì ṣáájú àkókò tí a wéwèé fún un ní iye tí ó tó mílíọ̀nù 375 dọ́là. Òye iṣẹ́ tí a rí kọ́ lákòókò tí a ń ṣe é ti di ohun tí a fi ń pawó ní àwọn orílẹ̀-èdè míràn.
Kí ló dé tí irú ìdáwọ́lé gbígbówólórí bẹ́ẹ̀ fi pọn dandan, kí ló sì ti ṣe yọrí?
Tuntún Rọ́pò Ògbólógbòó
Ọdún 1838 ni wọ́n ṣe ọ̀na páìpù omi tí ó pẹ́ jù lọ ní London. Ogójì ọdún lẹ́yìn náà, àwọn ènìyán ṣì ń fi garawa pọnmi láti ẹ̀rọ àdúgbò ní àwọn agbègbè tí kò lọ́rọ̀ ní ìlú ńlá náà. Òǹkọ̀wé kan sọ pé: “Ṣíṣí tí ọkùnrin kan tí ó ní kọ́kọ́rọ́ ẹ̀rọ lọ́wọ́ ń ṣí i ní òwúrọ̀ kùtùkùtù máa ń jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì, . . . nítorí pé tí ọkùnrin tí ó ní kọ́kọ́rọ́ náà bá lọ tán, kò sí ẹni tí ó lè rí ẹ̀kán omi kan pọn títí di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì.”
Àgbà iṣẹ́ ọpọlọ ni àwọn onímọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ tí wọ́n wà lákòókò ìṣàkóso Victoria ṣe láti fa omi yìí sí ilé àwọn ènìyàn, wọ́n na àwọn páìpù omi onírin tí ń gbé omi kiri, wọ́n sì ṣe àwọn ọ̀na páìpù omi tí jíjìnnà wọn sóke títì yàtọ̀ọ̀tọ̀ síra. Bí ó ti wù kí ó rí, láti ìgbà náà, ìtóbi, ìwúwo, àti bí àwọn ọkọ̀ tí ń kọjá ṣe ń mi ilẹ̀ tó lọ́nà púpọ̀ sí i, pa pọ̀ pẹ̀lú agbára púpọ̀ tí a nílò láti tú omi jáde geerege lọ sí ọ̀nà jíjìn—tó 30 kìlómítà nínú àwọn ọ̀ràn kan—ti yọrí sí bíbẹ́ páìpù omi. Èyí yọrí sí ìṣòro ìrinnà nígbà tí a bá ní láti ti àwọn ọ̀nà pa nítorí àtúnṣe àwọn ọ̀na páìpù omi. A fojú díwọ̀n pé ìpín 25 nínú ọgọ́rùn-ún lára gbogbo omi tí a fà láti inú àwọn táǹkì omi ní England ni a ń pàdánù nítorí àbùkù ara àwọn páìpù omi náà.
Ní àfikún sí i, ìwọ̀n omi tí àwọn ènìyan London nílò ti pọ̀ sí i ní 150 ọdún tí ó kọjá—láti lítà 330 mílíọ̀nù sí líta bílíọ̀nù 2 lójoojúmọ́. Àwọn ẹ̀rọ ìfọṣọ, ẹ̀rọ ìfọbọ́, ìfọmọ́tò, àti ti bíbomirin àwọn ọgbà nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ti mú kí ìwọ̀n omi tí a óò pèsé pọ̀ sí i. Àìní láti mú kí ìpèsè omi àárín ìlú sunwọ̀n sí i di kánjúkánjú. Àmọ́ kí ni a lè ṣe?
Wíwéwèé Ìdáwọ́lé Ńlá
Láti pààrọ̀ àwọn ògbólógbòó páìpù náà nípa nínà àwọn tí wọ́n túbọ̀ lágbára sábẹ títì kan náà kò ṣeé ṣe. Iye tí yóò náni fẹ́rẹ̀ẹ́ léni sá gan-an bí àwọn ará London kò ti lè fara mọ́ àìrọgbọ tí yóò mú wá. Nípa bẹ́ẹ̀, ní ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìdáwọ́lé Lílànà Páìpù Omi Roboto ti Thames. Yóò mú kí ìpèsè omi ní London pọ̀ sí i gan-an. Iṣẹ́ ìdáwọ́lé náà jẹ́ ọ̀na páìpù omi, tàbí ọ̀nà abẹ́lẹ̀ oníkìlómítà 80, mítà 2.5 ní fífẹ̀, tí a rì mọ́lẹ̀ ní ìwọ̀n jíjìn tí ó jẹ́ 40 mítà lábẹ́ ìlú ńlá náà, ó sì lè gbé omi tí ó lé ní bílíọ̀nù 1 lítà lójúmọ́. Irú ọ̀na páìpù omi roboto bẹ́ẹ̀ yóò jẹ́ kí a lè darí ibi tí omi náà yóò gbà láti ìhà méjèèjì, ní mímú kí ó rọrùn láti lè yọ ẹ̀yà èyíkéyìí jáde lára rẹ̀ fún àtúnṣe nígbàkígbà. A óò jẹ́ kí omi láti ibi tí a ti ń fi egbòogi ṣètọ́jú omi máa ṣàn sísàlẹ̀ lọ sínú ọ̀nà abẹ́lẹ̀ jíjìn, lẹ́yìn náà yóò sì fà á ní tààràtà lọ sínú lájorí ìpèsè omi, tàbí àwọn àgbá omi àdúgbò.
Kí ló dé tí ọ̀nà abẹ́lẹ̀ náà, tí ó gùn jù lọ ní Britain, ṣe ní láti jìnlẹ̀ tó bẹ́ẹ̀? Nítorí pé ìgbékalẹ̀ ọkọ̀ ojú irin 12 ní àfikún sí àwọn iṣẹ́ ìpèsè ohun èèlò lọ́nà títóbi wà lábẹ́ ilẹ̀ London, ó sì ṣe kedere pé ihò abẹ́lẹ̀ náà gbọ́dọ̀ kọjá láìfara kan gbogbo wọn. Nígbà tí àwọn onímọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ṣalábàápàde ìpìlẹ̀ ilé jíjindò kan, tí wọn kò rí nínú àyẹ̀wò àkọ́kọ́, láìròtẹ́lẹ̀, wọ́n dá iṣẹ́ dúró fún oṣù mẹ́wàá.
Wọ́n ń ṣètò iṣẹ́ ní ìpele-ìpele. Wọn kò retí àwọn ìṣòro ńlá nígbà tí wọ́n ń gbẹ́ ilẹ̀pa tí ó wọ́pọ̀ lágbègbe London, àmọ́ wọ́n ní láti pa gbígbẹ́ ọ̀nà abẹ́lẹ̀ náà tì fún ohun tí ó lé ní ọdún kan ní ibi tí wọ́n kọ́kọ́ fẹ́ẹ́ gbẹ́ ẹ sí, agbègbè ìha gúúsù Thames ní Tooting Bec. Àwọn tí ń gbẹ́ ọ̀nà abẹ́lẹ̀ náà kó sí inú ìpele iyanrìn tí ó ní omi tí ó ní agbára ìtújáde gíga dọ́ba, tí ó wá bo ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń gbẹ́ ọnà abẹ́lẹ̀ náà mọ́lẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Láti yanjú ìṣòro yìí, àwọn agbaṣẹ́ṣe pinnu láti mú ilẹ̀ náà dì gbandi nípa dída omi oníyọ̀ tí ìwọ̀n ìtutù rẹ̀ jẹ́ ìwọn 28 sísàlẹ òdo lórí òṣùwọn Celsius káàkiri àárín àwọn ihò gbígbẹ́ náà. Nípa gbígbẹ́ ihò jíjìn míràn sítòsí, wọ́n lè gbẹ́ ihò gba àárín yìyín dídì náà láti lè yọ ẹ̀rọ tí ó rì náà jáde, kí wọ́n sì máa bá ilẹ̀ gbígbẹ́ wọn lọ.
Nítorí ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, àwọn onímọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ rí ìdí tí wọ́n fi ní láti hùmọ̀ ìgbékalẹ̀ tuntun láti fi kọnkéré tẹ́ inú ọ̀nà abẹ́lẹ̀ náà. Ó tún hàn gbangba pé wọ́n nílò irú ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń gbẹ́ ọ̀nà abẹ́lẹ̀ mìíràn láti kojú irú ilẹ̀ tí kò lágbára bẹ́ẹ̀. Ẹ̀rọ ìmú agbára ìtiǹkanjáde ilẹ̀ wà déédéé tí ó wà ní ilẹ̀ Kánádà ni ìdáhùn náà. Wọ́n ra mẹ́ta, àti gẹ́gẹ́ bí àbáyọrí rẹ̀, gbígbẹ́ kanga náà wáá yára ní ìlọ́po méjì ní kìlómítà 1.5 lóṣù.
Lílo Kọ̀m̀pútà Nínú Iṣẹ́ Náà
Wọ́n wọn igun ìbú àti òró ilẹ̀ láti orí òrùlé ilé kí wọ́n baà lè rí ìhà ibi tí àwọn ihò jíjìn wà, wọ́n sì fi kọ̀m̀pútà ṣàyẹ̀wò àwọn àbáyọrí rẹ̀. Ìlànà yìí dára tó ní ìbẹ̀rẹ̀, ṣùgbọ́n gbàrà tí gbígbẹ́ ọ̀nà abẹ́lẹ̀ bá ti bẹ̀rẹ̀, báwo ni yóò ṣe dáni lójú pé ó gún régé?
Níbí ni ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ìgbàlódé ti gba iwájú nípasẹ̀ Ìgbékalẹ̀ Ìmúwànípò Olódindi (GPS). Ohun èèlò ìwọnlẹ̀ yìí ní ihùmọ̀ agbésọfúnni orí satellite tí a yí sí ojú ẹ̀rọ gbangba òfuurufú GPS kan tí ń yí ilẹ́ ayé po. Ohun èèlò náà lè ṣèfiwéra ìsọfúnni tí ń wá láti ara àwọn satellite bíi mélòó kan tí ń yí po. Gbàrà tí a bá ti fi kọ̀m̀pútà ṣe kòkárí ìwọ̀n náà, ìhà ibi tí gbogbo ihò 21 àti 580 ọ̀nà abẹ́lẹ̀ wà ni yóò fi hàn lórí ipa ilà orí àwọn àwòran àjọ Ordnance Survey. Pẹ̀lú ìsọfúnni oníṣirò yìí lọ́wọ́ àwọn tí ń gbẹ́ ọ̀nà abẹ́lẹ̀ náà, ìtọ́sọ́nà ń ṣe rẹ́gí.
Ìdarí Kọ̀m̀pútà
Láti pèsè ìwọ̀n omi tí mílíọ̀nù mẹ́fà ènìyán nílò kì í ṣe iṣẹ́ rírọrùn. Ó lè máà jẹ́ ìgbà kan pàtó ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ ojoojúmọ́ ni ìwọ̀n omi tí àwọn ènìyán nílò ń pọ̀ sí i. Èyí ń béèrè fún fífojú sí i fún gbogbo wàkàtí 24 lóòjọ́ láti rí i dájú pé ìwọ̀n àti agbára ìtújáde omi kò wọ́n ní gbogbo ìgbà. Báwo ni ìṣekòkárí ṣíṣe pàtàkì yìí ṣe ṣeé ṣe? Nípasẹ̀ ìgbékalẹ̀ ìdarí kọ̀m̀pútà kan tí iye rẹ̀ jẹ́ mílíọ̀nù 5 dọ́là ni.
Ẹ̀rọ ìfami inú ihò jíjìn kọ̀ọ̀kan ni kọ̀m̀pútà tirẹ̀ ń darí, a sì jẹ́ kí ìnáwó rẹ̀ lọ sílẹ̀ nípa lílo mànàmáná tí kò wọ́n, tí kò sì jẹ́ lákòókò tí a ń lò ó jù. Ìhùmọ̀ ìdarí kọ̀m̀pútà ní Hampton, ní ìhà ìwọ̀ oòrùn London, ń darí àpapọ̀ gbogbo ìsokọ́ra náà. Kọ̀m̀pútà náà ń gba ìsọfúnni láti inú àwọn wáyà awò onífọ́nrán tí a ṣe sí ara àwọn páìpù tí ó wà lára ọ̀nà abẹ́lẹ̀ náà, wọ́n sì tún ń gbé e gba inú gọgọwú àwọn ìgbékalẹ̀ tẹlifíṣọ̀n abẹ́lé.
Ojoojúmọ́, ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, àti oṣooṣù ni a ń yẹ bí omi ṣe dára tó wò. Ìwé agbéròyìnjáde The Times ṣàlàyé pé: “Ọgọ́ta àyẹ̀wò àìgbọdọ̀máṣe ló wà fún 120 èròjà, láti ṣàyẹ̀wo bí omi ṣe dára tó. Wọ́n ní nínú, àyẹ̀wo kúlẹ̀kúlẹ̀ fún àwọn èròjà bíi nitrate, àwọn kẹ́míkà tí kò tó nǹkan, àwọn oògùn apakòkòrò àti àwọn ohun alèyòrò oníkẹ́míkà míràn.” Ọ̀nà ìdáṣiṣẹ́ ẹ̀rọ ni a fi ṣe wíwọ̀n náà, a sì tún fà wọ́n lọ sí orílé iṣẹ́ kọ̀m̀pútà fún ìṣètumọ̀ àti ìgbésẹ̀ bí àìní bá ṣe wà fún un. Àwọn tí ń tọ́ omi wò pẹ̀lú ń ṣe àyẹ̀wò látìgbàdégbà.
Ríronú Ṣáájú
Ìyanu iṣẹ́ ẹ̀rọ ìgbàlódé yìí ń pèsè omi mímu mílíọ̀nù 583 lítà lóòjọ́ fún àwọn ènìyàn tí wọ́n wà káàkiri orí ilẹ̀ London Alágbára tí ó jẹ́ 1,500 kìlómítà níbùú lóròó. Tí ó bá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́, yóò máa pèsè ìpín 50 nínú ọgọ́rùn-ún ìwọ̀n omi tí a nílò ní báyìí, èyí yóò sì mú kí a má lo àwọn orísun ìpèsè míràn lálòjù.
Kódà, èyí kò níí tó. Nítorí náà, a ti ń ṣètò ní báyìí láti fẹ ọ̀na páìpù omi roboto náà ní 60 kìlómítà míràn sí i ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún tí ń bọ̀. Ní tòótọ́, ojútùú tí a fi ọgbọ́n wá sí ìṣòro líle koko kan ni!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Àwòrán abẹ́lẹ̀ London, tí ń fi ọ̀na páìpù omi lábẹ́ àwọn iṣẹ́ ìpèsè míràn lábẹ́lẹ̀ hàn
S
Ọ̀na páìpù omi abẹ́lẹ̀ tuntun àti àwọn ihò jíjìn
Odò Thames
Àwọn ọ̀nà ọkọ̀ ojú irin abẹ́lẹ̀
N
[Credit Line]
A gbé wọn karí fọ́tò: Omi Thames
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń gbẹ́ ọ̀na páìpù omi lábẹ́lẹ̀
[Credit Line]
Fọ́tò: Omi Thames
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Iṣẹ́ gbígbẹ́ ọ̀na páìpù omi abẹ́lẹ̀
[Credit Line]
Fọ́tò: Omi Thames