Mímọyì Àwọn Obìnrin àti Iṣẹ́ Wọn
NÍ ẸGBẸ̀Ẹ́DÓGÚN ọdún sẹ́yìn, ọkùnrin kan tí ń jẹ́ Lémúẹ́lì kọ àpèjúwe jíjọjú kan nípa aya tí ó dáńgájíá. A kọ èyí sínú Bíbélì nínú Òwe orí 31. Obìnrin náà, tí òun gbé àwọn ànímọ́ rere rẹ̀ lárugẹ, jẹ́ ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ dí dájúdájú. Ó ń bójú tó ìdílé rẹ̀, ó ń ṣòwò ní ọjà, ó ń ra ilẹ̀, ó sì ń ta ilẹ̀, ó ń hun aṣọ fún agbo ilé rẹ̀, ó sì ń ṣiṣẹ́ lóko.
A kò fojú kéré obìnrin yìí. ‘Àwọn ọmọ rẹ̀ pè é ní alábùkúnfún, ọkọ rẹ̀ sì yìn ín.’ Irú obìnrin bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìṣúra kan. Bíbélì wí pé, “Ó níye lórí púpọ̀ ju rúbì lọ.”—Òwe 31:10-28, New International Version.
Láti àkókò Lémúẹ́lì wá, iṣẹ́ àwọn obìnrin ti túbọ̀ díjú. Lọ́pọ̀ ìgbà, ipa tí wọ́n ń kó ní ọ̀rúndún ogún ń béèrè pé kí wọ́n jẹ́ aya, ìyá, olùtọ́jú, olùkọ́, olùgbọ́bùkátà, àti àgbẹ̀—nígbà kan náà. Àìlóǹkà obìnrin ló ń fi àwọn nǹkan rere du ara wọn nítorí kí àwọn ọmọ wọn lè ní ànító oúnjẹ. Ǹjẹ́ gbogbo àwọn obìnrin wọ̀nyí pẹ̀lú kò yẹ láti gba ìmọrírì àti ìyìn bí?
Àwọn Obìnrin Tí Wọ́n Jẹ́ Olùgbọ́bùkátà
Lónìí, àwọn obìnrin tó pọ̀ ju ti ìgbàkigbà rí lọ ló ní láti máa ṣiṣẹ́ lẹ́yìn òde ilé láti ṣèrànwọ́ láti ṣètìlẹ́yìn fún ìdílé wọn tàbí tó jẹ́ pé àwọn gan-an ni igi lẹ́yìn ọgbà ìdílé náà. Ìwé Women and the World Economic Crisis ṣàkọsílẹ̀ ìròyìn kan tó wí pé: “Iṣẹ́ abẹ́lé nìkan kọ́ ni àwọn obìnrin ń ṣe. Iye àwọn obìnrin tó lè sọ pé àwọn jẹ́ ‘ìyàwó ilé lásán’ kò tó nǹkan níbikíbi lágbàáyé.” Àwọn iṣẹ́ tí kò wuyì ni àwọn obìnrin máa ń ṣe lọ́pọ̀ ìgbà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìwé ìròyìn tàbí àwọn eré orí tẹlifíṣọ̀n lè máa fi àwọn obìnrin hàn bí ọ̀gá apàṣẹwàá ní àwọn ọ́fíìsì jàǹkànjàǹkàn tó gbàfiyèsí, òtítọ́ tó wà níbẹ̀ jẹ́ òdì-kejì gan-an. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn obìnrin lágbàáyé ń fi ọ̀pọ̀ wákàtí ṣe làálàá láti rí àsanpadà ohun ìní tí kò tó nǹkan.
Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ obìnrin ní ń dáko, wọ́n ń gbin irúgbìn, wọ́n ń bójú tó ilẹ̀ oko kéékèèké ti ìdílé, tàbí wọ́n ń bójú tó àwọn ohun ọ̀sìn. Iṣẹ́ yìí—tí ó sábà máa ń pawó tí kò tó nǹkan tàbí tí a kì í sanwó fún rárá—ní ń pèsè oúnjẹ fún ìdajì àwọn olùgbé ayé. Ìwé Women and the Environment sọ pé: “Ní Áfíríkà, àwọn obìnrin ní ń gbin ìpín 70 nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo oúnjẹ tó wà, ní Éṣíà, iye náà wà láàárín ìpín 50 sí 60 nínú ọgọ́rùn-ún, ìpín 30 nínú ọgọ́rùn-ún sì ni ti Látìn Amẹ́ríkà.”
Nígbà tí àwọn obìnrin bá ní iṣẹ́ tí wọ́n ń gbowó lé lórí, nítorí pé wọ́n jẹ́ obìnrin, owó wọn sábà máa ń kéré sí ti àwọn ọkùnrin. Ìyàsọ́tọ̀ yìí máa ń nira láti fara mọ́ fún obìnrin tó bá jẹ́ ìyá, tó jẹ́ òun nìkan ní ń gbọ́ bùkátà ìdílé, ipò kan tí ó túbọ̀ ń wọ́pọ̀ sí i. Ìròyìn kan tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣe fojú díwọ̀n rẹ̀ pé láàárín ìpín 30 sí 50 nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo agbo ilé ní Áfíríkà, ilẹ̀ Carib, àti Látìn Amẹ́ríkà ló gbára lé obìnrin kan bí olùgbọ́bùkátà. Kódà ní àwọn ilẹ̀ tí ó túbọ̀ ti gòkè àgbà, iye àwọn obìnrin tó ti ní láti di olùgbọ́bùkátà ń pọ̀ sí i.
Ipò òṣì ní àrọko ní apá ibi púpọ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà ń mú kí ipò yìí yára pọ̀ sí i. Ọkọ kan tí bíbọ́ ìdílé rẹ̀ ń jẹ́ ìṣòro fún láìdẹwọ́ lè pinnu láti kó lọ sí ìlú ńlá kan nítòsí tàbí sí orílẹ̀-èdè mìíràn, kí ó lè ríṣẹ́. Ó ń fi ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ láti máa bójú tó ìdílé. Bí ó bá rìnnà kore débi tó fi ríṣẹ́, yóò máa fowó ránṣẹ́ sílé. Ṣùgbọ́n láìka èrò rere tó ní sí, èyí kì í sábà máa bá a lọ bẹ́ẹ̀. Ìdílé tó fi sílẹ̀ lè túbọ̀ rì sínú ipò òṣì, kí gbogbo bí nǹkan yóò ṣe dára fún wọn sì wá sinmi lé orí ìyá náà.
Títinú ipò búburú kan bọ́ sínú òmíràn yìí, tí a ṣàpèjúwe lọ́nà yíyẹ bí “sísọ ipò òṣì di obìnrin,” ń já ẹrù ìnira ńláǹlà lé èjìká àràádọ́ta ọ̀kẹ́ obìnrin. Ìwé Women and Health sọ pé: “Ó ṣeé ṣe kí àwọn agbo ilé tí obìnrin ti ń ṣolórí, tí a fojú díwọ̀n pé ó jẹ́ ìlàta gbogbo agbo ilé àgbáyé, jẹ́ òtòṣì ní ìlọ́po ìgbà ju àwọn tí ọkùnrin ti ń ṣolórí lọ, iye irú àwọn agbo ilé bẹ́ẹ̀ sì ń pọ̀ sí i ni.” Àmọ́ bí ó ti ṣòro tó nì, pípèsè oúnjẹ nìkan kọ́ ni ìpèníjà tí àwọn obìnrin ń kojú.
Àwọn Ìyá àti Olùkọ́
Ìyá kan tún ní láti bójú tó ire àwọn ọmọ rẹ̀ ní ti ìmọ̀lára. Ó ń kópa pàtàkì nínú ríran ọmọ lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìfẹ́ àti ìfẹ́ni—àwọn ẹ̀kọ́ tó lè ṣe pàtàkì bí títẹ́ àwọn àìní ti ara rẹ̀ lọ́rùn gẹ́lẹ́. Kí ọmọ kan lè di àgbàlagbà tó dáńgájíá, ó nílò àyíká ọlọ́yàyà, tó láàbò, nígbà tó ń dàgbà. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ipa ti ìyá ṣe kókó.
Nínú ìwé The Developing Child, Helen Bee kọ̀wé pé: “Òbí ọlọ́yàyà kan ń bìkítà nípa ọmọ, ó ń fi ìfẹ́ni hàn, léraléra tàbí déédéé ló ń fi àìní ọmọ náà sípò kìíní, ó ń fi ìtara ọkàn hàn nínú àwọn ìgbòkègbodò ọmọ náà, ó sì ń hùwà padà lọ́nà onímọ̀lára àti onígbatẹnirò sí àwọn ìmọ̀lára ọmọ náà.” Ó yẹ kí àwọn ọmọ tí wọ́n ti rí irú ìṣe ọlọ́yàyà bẹ́ẹ̀ gbà lọ́dọ̀ ìyá kan tó ń bìkítà fi ìmọrírì wọn hàn.—Òwe 23:22.
Nípa fífi ọmú bọ́ ọmọ, ọ̀pọ̀ ìyá ń pèsè àyíká onífẹ̀ẹ́ni kan fún àwọn ọmọ wọn láti ìgbà ìbí. Ní pàtàkì nínú àwọn agbo ilé tí ó tòṣì, wàrà ìyá kan jẹ́ ẹ̀bùn tí kò ṣeé díye lé, tí ó lè fi fún ọmọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí. (Wo àpótí tó wà ní ojú ìwé 10-11.) Ó dùn mọ́ni pé Bíbélì sọ fún wa pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí ó ní fún àwọn Kristẹni ní Tẹsalóníkà wé ti “abiyamọ” tí “ń ṣìkẹ́ àwọn ọmọ tirẹ̀.”—1 Tẹsalóníkà 2:7, 8.
Láfikún sí bíbọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ àti ṣíṣìkẹ́ wọn, ìyá náà ni ó sábà ń jẹ́ olùkọ́ wọn pàtàkì. Ní títọ́ka sí ipa gbígbòòrò tí àwọn ìyá ń kó nínú kíkọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́, Bíbélì gbani nímọ̀ràn pé: “Fetí sílẹ̀, ọmọ mi, sí ìbáwí baba rẹ, má sì ṣá òfin ìyá rẹ tì.” (Òwe 1:8) Ní pàtàkì, ìyá tàbí ìyá àgbà ló máa ń fi sùúrù kọ́ ọmọ láti sọ̀rọ̀, láti rìn, àti láti ṣe àwọn iṣẹ́ ilé pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ àti àwọn àìlóǹkà nǹkan mìíràn.
A Nílò Ìyọ́nú Gidigidi
Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀bùn títóbijùlọ tí àwọn obìnrin lè fún ìdílé wọn ni ìyọ́nú. Nígbà tí ẹnì kan bá ń ṣàìsàn nínú ìdílé, ìyá máa ń kó ipa olùtọ́jú, nígbà tí ó ṣì ń bójú tó gbogbo ẹrù iṣẹ́ mìíràn tó ní. Ìwé Women and Health wí pé: “Ní tòótọ́, àwọn obìnrin ní ń pèsè ọ̀pọ̀ jù lọ àbójútó ìlera lágbàáyé.”
Ìyọ́nú tí ìyá kan ní tilẹ̀ lè sún un láti má jẹun púpọ̀ kí àwọn ọmọ rẹ̀ má bàa ṣàìríjẹ. Àwọn olùwádìí ti rí i pé àwọn obìnrin kan ń wo oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ bí pé ó pọ̀ tó, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò jẹun kánú. Fífún àwọn ọkọ wọn àti àwọn ọmọ wọn lóúnjẹ púpọ̀ ju tiwọn lọ ti mọ́ wọn lára, ní gbígbà pé níwọ̀n ìgbà tí àwọn bá ṣì ń lè ṣiṣẹ́, àwọn ń jẹun tó.
Nígbà mìíràn, ìyọ́nú obìnrin kan ń fara hàn nínú àníyàn tó ní fún àyíká rẹ̀. Àyíká yẹn ṣe pàtàkì fún un, nítorí pé òun náà ń fara gbá a nígbà tí ọ̀dá, ìsọ̀gbẹ́daṣálẹ̀, àti pípa-igbó-run bá ba ilẹ̀ náà jẹ́. Ní ìlú kan ní Íńdíà, àwọn obìnrin bínú nígbà tí wọ́n gbọ́ pé ilé iṣẹ́ agégẹdú kan yóò gé nǹkan bí 2,500 igi lulẹ̀ nínú igbó kan nítòsí. Àwọn obìnrin náà nílò igi wọ̀nyẹn fún oúnjẹ, ìdáná, àti oúnjẹ ẹran. Nígbà tí àwọn agégi náà dé, àwọn obìnrin náà ti wà níbẹ̀, tí wọ́n fọwọ́ sowọ́, tí wọ́n yí àwọn igi náà ká láti dáàbò bò wọ́n. Àwọn obìnrin náà sọ fún àwọn agégi ọ̀hún pé, ‘Ẹ ní láti bẹ́ wa lórí bí ẹ bá fẹ́ bẹ́ àwọn igi náà lulẹ̀. Wọ́n gba igbó náà là.
“Fún Un Lérè Tó Tọ́ sí I”
Ó yẹ kí a bọ̀wọ̀ fún obìnrin kan, kí a sì kà á kún, bí a óò ti ṣe fún iṣẹ́ rẹ̀, ì báà jẹ́ ti olùgbọ́bùkátà, ìyá, olùkọ́, tàbí orísun ìyọ́nú. Ọlọgbọ́n ọkùnrin náà, Lémúẹ́lì, tó sọ̀rọ̀ ìgbóríyìn bẹ́ẹ̀ nípa aya tó dáńgájíá kan, mọyì iṣẹ́ obìnrin kan àti ìmọ̀ràn rẹ̀. Ní gidi, Bíbélì ṣàlàyé pé, ó mú apá púpọ̀ jù lọ nínú ìsọfúnni rẹ̀ wá láti inú ìtọ́ni tí ìyá rẹ̀ fún un. (Òwe 31:1) Ó dá Lémúẹ́lì lójú pé a kò gbọ́dọ̀ fojú kéré aya tàbí ìyá kan tí ń fi tọkàntara ṣiṣẹ́. Ó kọ̀wé pé: “Ẹ fún un lérè tó tọ́ sí i. Àwọn iṣẹ́ rẹ̀ ń mú ìyìn wá fún un.”—Òwe 31:31, NIV.
Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí Lémúẹ́lì ń kọ àwọn èrò wọ̀nyẹn sílẹ̀, wọn kì í ṣe àfihàn èrò ẹ̀dá ènìyàn lásán. A kọ wọ́n sílẹ̀ nínú Bíbélì, tó jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí.” (2 Tímótì 3:16) Àwọn èrò wọ̀nyẹn ṣàfihàn èrò Ọlọ́run Olódùmarè nípa àwọn obìnrin, nítorí pé, Ọlọ́run mí sí àwọn apá wọ̀nyẹn nínú Bíbélì láti tọ́ wa.
Síwájú sí i, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a mí sí sọ pé ó yẹ kí àwọn ọkọ “máa fi ọlá fún [àwọn aya wọn].” (1 Pétérù 3:7) Nínú Éfésù 5:33, a sọ fún ọkọ pé: “Kí olúkúlùkù yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀.” Ní gidi, Éfésù 5:25 sọ pé: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti nífẹ̀ẹ́ ìjọ, tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lọ́wọ́ fún un.” Bẹ́ẹ̀ ni, Kristi fi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ dé ipò tí ó fi múra tán láti kú nítorí tiwọn. Ẹ wo irú àpẹẹrẹ rere, ti àìmọtara-ẹni-nìkan, tí ó fi lélẹ̀ fún àwọn ọkọ! Àwọn ìlànà tí Jésù fi kọ́ni, tí òun náà gbé ní ìbámu pẹ̀lú wọn, sì fi àwọn ìlànà Ọlọ́run tí a kọ sílẹ̀ nínú Bíbélì fún àǹfààní wa hàn.
Síbẹ̀, láìka iṣẹ́ àṣekára tí wọ́n ń ṣe ní ẹ̀ka púpọ̀ sí, ọ̀pọ̀ obìnrin kì í sábà rí oríyìn gbà. Báwo ni wọ́n ṣe lè mú kí ipò wọn sunwọ̀n sí i nínú ìgbésí ayé ìsinsìnyí pàápàá? Bákan náà, ǹjẹ́ ó lè ṣeé ṣe pé kí ìṣarasíhùwà sí wọn yí padà bí? Kí ni ìrètí tí àwọn obìnrin ní fún ọjọ́ ọ̀la?
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10, 11]
Ọ̀nà Mẹ́ta Tí Obìnrin Kan Lè Gbà Mú Ipò Rẹ̀ Sunwọ̀n
Ẹ̀kọ́ ìwé. Nǹkan bí 600 mílíọ̀nù obìnrin tí wọ́n jẹ́ púrúǹtù ló wà lágbàáyé—tí ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn kò láǹfààní láti lọ sílé ẹ̀kọ́ nígbà kankan. Ó lè jẹ́ ìwé díẹ̀ ni ìwọ fúnra rẹ kà, ṣùgbọ́n ìyẹn kò túmọ̀ sí pé o kò lè kọ́ ara rẹ níwèé. Kò rọrùn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ obìnrin ló ti ṣàṣeyọrí. Ìwé Women and Literacy sọ pé: “Àwọn èrèdí tó jẹ́ ti ìsìn lè kópa pàtàkì ní sísún àwọn àgbàlagbà láti kọ́ òye iṣẹ́ ìwé kíkọ àti kíkà.” Ti pé o lè dá Bíbélì kà fúnra rẹ jẹ́ èrè àtàtà kan fún kíkọ́ láti kàwé. Ṣùgbọ́n àwọn àǹfààní mìíràn tún wà.
Kì í ṣe pè ìyá tó kàwé ní àǹfààní sí i ní ti àbójútó ìdílé nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún lè mọ̀ sí i nípa àwọn àṣà ìlera. Ìpínlẹ̀ Kerala ní Íńdíà ṣàgbéyọ àǹfààní kíkàwé lọ́nà àgbàyanu. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àgbègbè yìí kéré sí ìpíndọ́gba ní ti iye owó tí ń wọlé, ìpín 87 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn obìnrin tó wà níbẹ̀ ló kàwé. Lọ́nà tó dùn mọ́ni, bí àwọn ọmọdé ṣe ń kú ní ìpínlẹ̀ kan náà fi ìlọ́po márùn-ún dín sí ti àwọn àgbègbè tó kù ní Íńdíà; ní ìpíndọ́gba, àwọn obìnrin ń fi ọdún 15 pẹ́ láyé sí i; gbogbo ọmọbìnrin ló sì ń lọ sílé ẹ̀kọ́.
Lọ́nà àdánidá, ìyá tó kàwé ń jẹ́ ìṣírí fún ọ̀nà ìkẹ́kọ̀ọ́ àwọn ọmọ rẹ̀—bírà kékeré kọ́. Kíkọ́ àwọn ọmọbìnrin lẹ́kọ̀ọ́ ìwé jẹ́ ìdókòwò gígalọ́lá. Ìwé The State of the World’s Children 1991 láti ọwọ́ Àjọ Àkànlò Owó Ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Ọmọdé (UNICEF) wí pé, kò sí ohunkóhun mìíràn tó lágbára tó bẹ́ẹ̀ láti mú ìlera ìdílé sunwọ̀n sí i, kí ó sì mú ìgbésí ayé àwọn obìnrin fúnra wọn dára sí i. Láìsíyèméjì, òye nípa kíkàwé àti kíkọ̀wé yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti jẹ́ ìyá àti olùpèsè tó sunwọ̀n sí i.a
Ìlera. Gẹ́gẹ́ bí ìyá, ó yẹ kí o bójú tó ara rẹ, ní pàtàkì bí o bá lóyún tàbí bí o bá ń tọ́mọ. Ǹjẹ́ o lè mú kí oúnjẹ rẹ sunwọ̀n sí i? Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá méjì nínú mẹ́ta àwọn aboyún ní Áfíríkà àti ìhà gúúsù òun ìwọ̀ oòrùn Éṣíà tí àyẹ̀wò ilé ìwòsàn fi hàn pé ẹ̀jẹ̀ kò tó lára wọn. Yàtọ̀ sí pé àìtó-ẹ̀jẹ̀ lè tán ọ lókun, ó ń mú kí àwọn ewu tí ń bá ìbímọ rìn pọ̀ sí i, ó sì ń mú kí ó túbọ̀ rọrùn láti ní àrùn ibà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹran tàbí ẹja lè ṣọ̀wọ́n tàbí kí ó wọ́nwó, ẹyin tàbí àwọn èso tàbí ẹ̀fọ́ tó ní èròjà iron nínú dáradára lè wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Má ṣe jẹ́ kí ìgbàgbọ́ nínú ohun asán dí ọ lọ́wọ́ láti jẹ àwọn oúnjẹ aṣaralóore, má sì jẹ́ kí àṣà ìbílẹ̀ àdúgbò fi ìpín tìrẹ nínú oúnjẹ ìdílé dù ọ́.b
Fífi ọmú bọ́ ọmọ ṣàǹfààní fún ìwọ àti ọmọ rẹ. Wàrà ọmú dínwó, ó mọ́ tónítóní, ó sì ṣara lóore ju àfidípò èyíkéyìí lọ. Àjọ UNICEF ṣèṣirò pé àádọ́ta ọ̀kẹ́ ọmọdé tí ń kú lọ́dọọdún ni a ti lè gbà là bí àwọn ìyá bá ń fi ọmú bọ́ ọmọ fún oṣù mẹ́rin sí mẹ́fà àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé àwọn ọmọ náà. Dájúdájú, bí ìyá bá ní àrùn tí ń ranni, tí a mọ̀ pé ọmọ lè kó nípa mímu ọmú rẹ̀, a ní láti lo ọ̀nà ìbọ́ni mìíràn tí kò léwu.
Rí i dájú pé afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ fẹ́ bọ̀ bó ti yẹ bí o bá ń dáná nínú ilé rẹ. Ìwé Women and Health kìlọ̀ pé: “Ó ṣeé ṣe kí fífa èéfín àti àwọn gáàsì ìdáná símú ti jẹ́ ewu ìlera tó burú jù lọ tí a mọ̀ pé àwọn ènìyàn ń ní lẹ́nu iṣẹ́ lónìí.”
Láìka ìdẹwò tó wù kó wà sí, má mu tábà. Àwọn ìpolówó sìgá tí a ń ṣe láìdẹwọ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà ń dájú sọ àwọn obìnrin, ó ń gbìyànjú láti mú kí ó dá wọn lójú pé ìwà ọ̀làjú ni mímu sìgá. Ó dájú pé èyí kì í ṣe òtítọ́. Sìgá mímu ń pa àwọn ọmọ rẹ lára, ó sì lè pa ọ́. A ṣírò rẹ̀ pé ìdá mẹ́rin lára àwọn tí ń mu sìgá ni àṣà ìsọtábà-dibárakú ń pa níkẹyìn. Láfikún sí i, àwọn ògbóǹkangí ń kìlọ̀ pé ṣíṣeéṣe náà pé kí ẹni tó mu sìgá fún ìgbà kìíní sọ tábà di bárakú pọ̀ gan-an.
Ìmọ́tótó. Àpẹẹrẹ tìrẹ àti ìmọ̀ràn rẹ lórí ìmọ́tótó ṣe pàtàkì fún ìlera ìdílé rẹ. Ìwé Facts for Life la àwọn ìgbésẹ̀ ìsàlẹ̀ wọ̀nyí lẹ́sẹẹsẹ fún ojúlówó ìmọ́tótó:
• Fi ọṣẹ àti omi wẹ ọwọ́ rẹ nígbàkigbà tí o bá ṣe ohunkóhun tí ó jẹ mọ́ ìyàgbẹ́ àti kí o tó fọwọ́ kan oúnjẹ. Rí i dájú pé àwọn ọmọ rẹ wẹ ọwọ́ wọn kí wọ́n tó jẹun.
• Máa lo ilé ìgbọ̀nsẹ̀, sì jẹ́ kí ó máa wà ní mímọ́ àti ní bíbò. Bí èyí kò bá ṣeé ṣe, máa lọ yàgbẹ́ níbi tó jìnnà dáadáa sí ilé rẹ, kí o sì bo ìyàgbẹ́ náà mọ́lẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.—Fi wé Diutarónómì 23:12, 13.
• Gbìyànjú láti máa lo omí tí kò lẹ́gbin nínú agbo ilé rẹ. Láti ṣe èyí, máa bo àwọn kànga, kí o sì máa lo àwọn èlò ìpọnmi mímọ́tónítóní.
• Bí kò bá sí omi tí kò lẹ́gbin lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ, máa se omi, kí o sì máa jẹ́ kí ó tutù kí o tó mu ún. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé omi tí a kò sè lè mọ́ bí a bá fojú lásán wò ó, síbẹ̀ ó lè ní ẹ̀gbin nínú.
• Rántí pé àwọn oúnjẹ tí a ko sè lè kó àrùn ranni. A gbọ́dọ̀ fọ àwọn oúnjẹ tí a bá ní láti jẹ ní tútù dáadáa kí a tó jẹ wọ́n, kí a sì jẹ wọ́n lọ́gán, bí ó bá ti lè yá tó. A gbọ́dọ̀ se àwọn oúnjẹ mìíràn jinná dáadáa, ní pàtàkì, ẹran àti ohun abìyẹ́.
• Jẹ́ kí oúnjẹ máa wà ní mímọ́ àti bíbò kí àwọn kòkòrò àti àwọn ẹranko má lè sọ ọ́ dìbàjẹ́.
• Dáná sun àwọn pàǹtírí tí ẹ gbá jáde nílé tàbí kí o bò wọ́n mọ́lẹ̀.c
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣètò kíláàsì mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà lọ́fẹ̀ẹ́ gẹ́gẹ́ bí apá kan ìtòlẹ́sẹẹsẹ ẹ̀kọ́ Bíbélì gbígbòòrò tí wọ́n ń ṣe.
b Ní àwọn ilẹ̀ kan, ìgbàgbọ́ nínú ohun asán kà á léèwọ̀ fún àwọn aboyún láti jẹ ẹja, ẹyin tàbí adìyẹ, nítorí ìbẹ̀rù pé ó lè pa ọmọ tí a kò ì bí náà lára. Nígbà mìíràn, àṣà ìbílẹ̀ béèrè pé ohun tí àwọn àgbàlagbà ọkùnrin àti àwọn ọmọkùnrin bá jẹ kù ni kí obìnrin máa jẹ.
c Wo Jí!, April 8, 1995, ojú ìwé 6 sí 11, fún àlàyé kíkún sí i.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Ọ̀pọ̀ obìnrin ní ìhà Ìwọ̀ Oòrùn ayé ń ṣiṣẹ́ ọ́fíìsì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
Ọ̀pọ̀ obìnrin ló di dandan fún láti máa ṣiṣẹ́ lábẹ́ àwọn ipò tí kò bára dé
[Credit Line]
Godo-Foto
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Àwọn ìyá jẹ́ àwọn olùkọ́ nílé