Wíwo Ayé
Àrùn Herpes Ẹ̀yà Ìbímọ Ń Pọ̀ Sí I
Ìròyìn kan láti ọ̀dọ̀ àjọ akóròyìnjọ Associated Press sọ pé: “Láìka bí a ti tẹnu mọ́ ìbálòpọ̀ tí kò léwu tó láti dènà àrùn AIDS sí, àrùn herpes ẹ̀yà ìbímọ ti pọ̀ sí i ní ìlọ́po márùn-ún láti apá ìparí àwọn ọdún 1970 láàárín àwọn ọ̀dọ́langba aláwọ̀ funfun” ní United States. Bí ó ti wù kí ó rí, a ṣàkíyèsí pé àwọn àrùn mìíràn tí ìbálòpọ̀ ń ta látaré, bí àtọ̀sí, dín kù láàárín àkókò náà. Kí ló fa pípọ̀ tí àrùn herpes ń pọ̀ sí i? Lára àwọn ìdí rẹ̀ ni pé iye àwọn tí ń ní ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó ń pọ̀ sí i, àwọn kan sì ń bá ọ̀pọ̀ ènìyàn ṣèṣekúṣe. Ní báyìí, a fojú bù ú pé mílíọ̀nù 45 ará Amẹ́ríkà ló ní fáírọ́ọ̀sì àrùn herpes, ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn kò sì mọ̀. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, fáírọ́ọ̀sì náà ń fa ọgbẹ́ tàbí ara yíyún ní àwọn àgbègbè ẹ̀yà ìbímọ, ó sì ń fà á ní ìdí tàbí itan lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.
Ṣọ́ọ̀ṣì Ilẹ̀ England Ń Joro
Àwọn aláṣẹ Ṣọ́ọ̀ṣì Ilẹ̀ England fojú díwọ̀n rẹ̀ pé àwọn tí ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì lọ́jọọjọ́ Sunday jẹ́ àádọ́ta ọ̀kẹ́. Ní ti ara wọn, àwọn àlùfáà kan jẹ́wọ́ pé ó ṣeé ṣe kí àwọn tí ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì àwọn fi ìpín 25 nínú ọgọ́rùn-ún dín sí iye yẹn. Bí ó ti wù kí ó rí, ìwádìí kan tí a ṣe ní ìlànà sáyẹ́ǹsì, fi hàn pé, àwọn ojúlówó ọmọ ìjọ, àwọn tí ń gba Ara Olúwa, dín kù sí iye tí kò tó ìlàjì mílíọ̀nù fún ìgbà kìíní. Èé ṣe tí àwọn àlùfáà fi máa ń múra tán láti bù kún iye àwọn tí ń wá sí ṣọ́ọ̀ṣì wọn bẹ́ẹ̀? Ní pàtàkì, ó jẹ́ láti dáàbò bo ṣọ́ọ̀ṣì wọn, kí a má bàa tì wọ́n pa. Bí ìyẹn bá ṣẹlẹ̀, a óò pa àwọn ẹ̀ka ṣọ́ọ̀ṣì pọ̀, a kò sì ní nílò ọ̀pọ̀ àlùfáà. Ìwé agbéròyìnjáde The Sunday Times ti London ròyìn pé, àlùfáà ẹ̀ka ṣọ́ọ̀ṣì kan lóòótọ́ inú tó bẹ́ẹ̀ tó fi wí pé: “Mo ní ìtẹ̀sí láti bù kún iye náà. Ó ń jáni kulẹ̀ nígbà tí àwọn tó wá kò bá tó nǹkan, nítorí náà, mo máa ń dá inú ara mi dùn tí mo bá ṣàkọsílẹ̀ pé àwọn tó wá jù bẹ́ẹ̀ lọ ní gidi.”
Ọkọ Pe Ìyàwó Lẹ́jọ́ Pé Ó Ń Mu Sìgá
Ó lé ní 20 ọdún tí Richard Thomas fi bẹ̀bẹ̀, tó sì jírẹ̀ẹ́bẹ̀, nínú ìsapá kan láti jẹ́ ki ìyàwó rẹ̀ ṣíwọ́ sìgá mímu, tí gbogbo rẹ̀ sì já sí pàbó. Nítorí náà, ó pè é lẹ́jọ́. Ọ̀gbẹ́ni Thomas wí pé òun ń fẹ́ kí ìjọba gba òun lọ́wọ́ pípàdánù ìfẹ́ àti ìtìlẹ́yìn àti ìbákẹ́gbẹ́ obìnrin tí òun nífẹ̀ẹ́. Àrùn ọkàn-àyà ti pa ìyá rẹ̀, àrùn ẹ̀gbà ti kọ lu baba rẹ̀ lẹ́yìn náà, tí ó sì ti dá baba náà sórí bẹ́ẹ̀dì láti ọdún méje. Àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì ti jẹ́ fìkanrànkan, ó sì sọ pé òun kò fẹ́ kí ìyàwó òun sọ èròjà nicotine di bárakú. Bí ó ti wù kí ó rí, kí ilé ẹjọ́ tó pàṣẹ kankan, Ọ̀gbẹ́ni Thomas mú ìròyìn ayọ̀ wá. Ó wí pé: “Ìyàwó mi ti gbà láti ṣíwọ́ sìgá mímu.” Aya Thomas lọ sí ibùdó ìwòsàn àwọn àṣà bárakú kan, ó sì jẹ́jẹ̀ẹ́ láti má mu sìgá mọ́ láé. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde The New York Times ṣe sọ, tọkọtaya Thomas fọwọ́ kọ́wọ́ kúrò nílé ẹjọ́ náà ni.
Àwọn Ràkúnmí Inú Igbó Ilẹ̀ Australia
Wọ́n kó àwọn ràkúnmí wọ Australia ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn láti fi ṣiṣẹ́ àgbékalẹ̀ ètò ìbánisọ̀rọ̀ àti ọkọ̀ ojú irin la àgbègbè àrọko àdádó tí ń léni sá ní orílẹ̀-èdè náà já. Nígbà tí a fi àwọn ọkọ̀ akẹ́rù rọ́pò àwọn ẹranko tó lè kojú ipò tí kò bára dé náà, ọ̀pọ̀ lára àwọn olówó wọn tó jẹ́ ará Afghanistan kò pa wọ́n, wọ́n wulẹ̀ dà wọ́n sígbó ni. Àwọn ràkúnmí náà bí sí i ní ilẹ̀ gbígbẹ ti àáríngbùngbùn Australia, a sì lè rí tó 200,000 wọn níbẹ̀ ní báyìí. Ìwé agbéròyìnjáde The Australian sọ pé, nísinsìnyí, àwọn ènìyàn kan gbà gbọ́ pé àwọn ràkúnmí náà lè di búrùjí oníyelórí fún orílẹ̀-èdè náà. Wọ́n ti ta ẹran ràkúnmí lọ́jà wò, wọ́n sì sọ pé ó rọ̀ bí ẹran màlúù, kò sì lọ́ràá tó ẹran màlúù. Àwọn ohun mìíràn tí a mú jáde lára ràkúnmí ni awọ, wàrà, irun ẹran, àti ọ̀rá tí a ń fi ṣe ọṣẹ àti àwọn èròjà ìṣaralóge. Àwọn ènìyàn tún ń béèrè fún ààyè ràkúnmí pẹ̀lú. Gẹ́gẹ́ bí Peter Seidel láti Ilé Iṣẹ́ Ràkúnmí ti Àáríngbùngbùn Australia ṣe wí, “ọ̀pọ̀ ọgbà ẹranko lágbàáyé àti àwọn ọgbà ìtura àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ ló ń fẹ́ ràkúnmí ilẹ̀ Australia nítorí pé àwọn ràkúnmí wa kò lárùn lára.”
Jíjẹ Májèlé Èròjà Arsenic
Ìwé agbéròyìnjáde The Times of India sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù 15 àwọn ará Bangladesh àti 30 mílíọ̀nù àwọn ará Ìwọ̀ Oòrùn Bengal, títí kan Calcutta, tó wà láìláàbò lọ́wọ́ májèlé èròjà arsenic. Ìṣòro náà jẹ́ àbájáde tí a kò retí láti inú ètò kébimápàlú. Nígbà tí wọ́n gbẹ́ àwọn kànga jíjìn láti máa bomi rin ohun ọ̀gbìn, omi náà ń mú àwọn èròjà arsenic tó wà lábẹ́ ilẹ̀ lọ́nà àdánidá wá sókè, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ wọnú àwọn kànga tí a ti ń pọnmi mímu níkẹyìn. Ògbógi nípa àyíká, Willard Chappel, láti Yunifásítì Colorado, U.S.A., bẹ àwọn àgbègbè tí ọ̀ràn kàn náà wò láìpẹ́ yìí, ó sì ṣàpèjúwe ìṣòro náà bí “ọ̀ràn jíjẹ májèlé tó tóbi jù lọ tí ó tíì ṣẹlẹ̀ rí lágbàáyé.” Àwọn ènìyàn tó ti ní ìpalára nínú awọ ara wọn, tó jẹ́ àmì jíjẹ májèlé èròjà arsenic, ti lé ní 200,000. Ishak Ali, òṣìṣẹ́ onípò kan nínú ìjọba ní Bangladesh sọ pé: “Ó jọ pé a tán ìṣòro ebi (nípasẹ̀ ètò kébimápàlú), a sì dá ipò ìnira púpọ̀ sí i sílẹ̀ nínú ìgbésẹ̀ náà.”
Àwọn Ìyá Tí Ń Ṣiṣẹ́
Ní 1991, Ẹgbẹ́ Àwọn Òṣìṣẹ́ Obìnrin Orílẹ̀-Èdè fojú bù ú pé “nígbà tí ó bá fi di àwọn ọdún àárín 1990, ìpín 65 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn obìnrin [ará Amẹ́ríkà] tó ní àwọn ọmọ tí kò tíì bẹ̀rẹ̀ sí lọ sílé ẹ̀kọ́, àti ìpín 77 nínú ọgọ́rùn ún àwọn tó ní àwọn ọmọ tó ti ń lọ sílé ẹ̀kọ́ ni yóò wà lẹ́nu iṣẹ́.” Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ wọn ti ṣe rẹ́gí tó? Ìwé agbéròyìnjáde The Washington Post ròyìn pé, gẹ́gẹ́ bí Ilé Iṣẹ́ Ìkànìyàn Ilẹ̀ United States ṣe wí, ìpín 63 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn obìnrin tó ní àwọn ọmọ tí kò tíì pé ọdún márùn-ún ló wà lẹ́nu iṣẹ́ ní 1996. Ìpín 78 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ìyá tó ní àwọn ọmọ tó ti ń lọ sílé ẹ̀kọ́ ló wà lẹ́nu iṣẹ́. Ní Yúróòpù ńkọ́? Àkójọpọ̀ ìsọfúnni láti Ilé Iṣẹ́ Ìsọfúnni Oníṣirò ti Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù fi hàn pé, “ìpíndọ́gba àwọn obìnrin tó wà lẹ́nu iṣẹ́ tó ní àwọn ọmọ ọlọ́dún 5 sí 16” ní àwọn orílẹ̀-èdè Yúróòpù ní 1995 jẹ́, ìpín 69 nínú ọgọ́rùn-ún ní ilẹ̀ Potogí, ìpín 67 ní Austria, ìpín 63 ní ilẹ̀ Faransé, ìpín 63 ní Finland, ìpín 62 ní Belgium, ìpín 59 ní Britain, ìpín 57 ní Germany, ìpín 51 ní Netherlands, ìpín 47 ní Gíríìsì, ìpín 45 ní Luxembourg, ìpín 43 ní Ítálì, ìpín 39 ní Ireland, àti ìpín 36 ní Sípéènì.
Wíwọkogbèsè Ń Wọ́pọ̀
Ìwé ìròyìn Newsweek sọ pé, ní 1996, “mílíọ̀nù 1.2 àwọn ará Amẹ́ríkà, tí irú rẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí, kéde pé àwọn wọko gbèsè, ó fi ìpín 44 nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ ju ti 1994 lọ. Wíwọkogbèsè ti wá wọ́pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí kò tini lójú bí ti tẹ́lẹ̀ mọ́.” Kí ló fa bí wíwọkogbèsè ṣe ń pọ̀ sí i? Ìwé ìròyìn Newsweek sọ pé, ìdí kan ni “bí àwọn ènìyàn ṣe túbọ̀ ń tẹ́wọ́ gba wíwọkogbèsè bí ọ̀nà ìgbésí ayé mìíràn kan tí a yàn ṣáá. Àwọn tí a jẹ ní gbèsè sọ pé ìyípadà tó dé bá ìhùwàsí náà ń yọrí sí àṣìlò: ìwádìí kan sọ pé ìpín 45 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tó kéde pé àwọn ti wọko gbèsè ló lè san ọ̀pọ̀ jù lọ nínú gbèsè wọn padà.” Ṣùgbọ́n dípò kí wọ́n ṣàfihàn ìfẹ́ àtọkànwá láti san gbèsè àti dípò kí ojú tì wọ́n, ọ̀pọ̀ nínú wọn wulẹ̀ ń sọ pé, ‘Mo ní láti tún ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni.’ Àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan àti àwọn ilé iṣẹ́ ìjọba tí ń pọ̀ sí i ń fi ìkéde ìwọkogbèsè tán ìṣòro wọn, àwọn ìpolówó tí àwọn agbẹjọ́rò ń ṣe láti “yanjú àwọn ìṣòro gbèsè rẹ kíákíá àti nírọ̀rùn!!” sì ń nípa lórí wọn. Bí iye àwọn tí ń wọko gbèsè ṣe ń pọ̀ sí i nínú ètò ọrọ̀ ajé tí ń bú rẹ́kẹ, ríronú lórí ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀ bí ọjà bá fọ́ tàbí tí òwò bá dẹnu kọlẹ̀ ń kó jìnnìjìnnì bá àwọn ògbógi.
Àwọn Ọ̀nà Ìpẹja Tí Ń Ṣèparun
Àwọn ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun tí ń ṣòwò ẹja pípa ń náwó sórí àwọn ohun èlò láti fi gbá àwọn ẹja tí iye wọn ń yára dín kù mọ́ fééféé nísàlẹ̀ òkun. Wọ́n máa ń wọ́ ohun èlò ìsàlẹ̀ òkun náà, tí a mọ̀ sí ohun èlò ìpẹja alágbèéká, kiri ìsàlẹ̀ òkun tí ó jìn tó 1,200 mítà láti fi wọ́ àwọn irú ọ̀wọ́ tí a kò kà sí tẹ́lẹ̀ jáde. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Science News ṣe sọ, ìṣòro náà ni pé, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ “ẹran omi tube worm, sponge, anemone, hydrozoan, urchin, àti àwọn olùgbé-inú-ibú mìíràn” ni wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ kó, tí wọ́n sì “ń dà nù bí pàǹtírí.” Pípa wọ́n run ń mú kí àwọn ẹja túbọ̀ máa dín kù sí i. Nítorí pé àwọn ẹran omi wọ̀nyí ní ń pèsè oúnjẹ àti ibùgbé fún àwọn ẹja kéékèèké, Elliott Norse, olùdarí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìdáàbòbò Ohun Alààyè Inú Omi ní Redmond, Washington, U.S.A., sọ pé, pípa ibùgbé inú omi run nípasẹ̀ ọ̀nà ìpẹja yìí ṣeé fi wé “pípa igbó run lórí ilẹ̀.”
Ìwà Rere Àwọn Ọ̀dọ́langba ní Britain
Ìròyìn àìpẹ́ yìí kan fi hàn pé àwọn ètò ìsìn ní Britain ń kùnà láti gbin ìwà àìṣèṣekúṣe sínú ọkàn àwọn ọ̀dọ́langba. Yunifásítì London wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu 3,000 ọ̀dọ́langba lórí “bóyá ó lòdì ní ti ìwà rere fún takọtabo tí kò ṣègbéyàwó, tí wọ́n ti jùmọ̀ ń dọ́rẹ̀ẹ́ fún ọjọ́ gbọọrọ, láti bá ara wọn lò pọ̀.” Bí a ti retí, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo àwọn tí wọ́n ṣàpèjúwe ara wọn bí aláìgbọlọ́rungbọ́ tàbí onígbàgbọ́ Ọlọ́run-kò-ṣeé-mọ̀ ló sọ pé kò lòdì. Bí ó ti wù kí ó rí, ìpín 85.4 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọ ìjọ Roman Kátólíìkì àti ìpín 80 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọ ìjọ Áńgílíkà pẹ̀lú ló sọ pé kò lòdì. Iye náà jọra pẹ̀lú ti ọ̀pọ̀ ìsìn mìíràn, tí a wò gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan—tí ó ní àwọn Mùsùlùmí, Júù, Híńdù, àti àwọn mìíràn nínú. Ìwé agbéròyìnjáde The Times ti London sọ pé, ìwádìí náà “yóò jẹ́ ìsọfúnni tí ń múni sorí kọ́ fún àwọn tó wà nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì náà, tí wọ́n ń gbìyànjú láti gbé ọ̀pá ìdiwọ̀n tó jẹ́ àṣà nípa ìwà àìṣèṣekúṣe lárugẹ.”