Kí Ni Ète Ọlọ́run?
Ọ̀PỌ̀ ènìyàn tó ń ṣe iyèméjì nípa bóyá Ọlọ́run kan tí ó jẹ́ alágbára, tí ó sì nífẹ̀ẹ́ wà ń béèrè pé: Bí Ọlọ́run bá wà, èé ṣe tí ó fàyè gba ọ̀pọ̀ ìjìyà àti ìwà ibi ní gbogbo ìtàn ìran ènìyàn? Èé ṣe tí ó fi fàyè gba ipò ìbànújẹ́ tí ó yí wa ká lónìí? Èé ṣe tí òun kò fi ṣe nǹkan kan láti fòpin sí ogun, ìwà ọ̀daràn, àìṣèdájọ́ òdodo, ipò òṣì, àti àwọn ipò ìnira mìíràn tí ó túbọ̀ ń peléke sí i dé ìwọ̀n tí ń bani lẹ́rù ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè lórí ilẹ̀ ayé?
Àwọn kan ronú pé Ọlọ́run dá àgbáálá ayé, ó fi ènìyàn sórí pílánẹ́ẹ̀tì Ilẹ̀ Ayé, ó wá fi wọ́n sílẹ̀ láti máa bójú tó àwọn àlámọ̀rí wọn fúnra wọn. Ní ìbámu pẹ̀lú èrò yìí, a kò lè dá Ọlọ́run lẹ́bi fún wàhálà àti ìnira tí àwọn ènìyàn fà wá sórí ara wọn nítorí ìwọra tàbí àṣìṣe wọn.
Àmọ́ ṣá o, àwọn mìíràn kò gbà pẹ̀lú irú ìrònú bẹ́ẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, Conyers Herring, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ físíìsì, tí ó jẹ́wọ́ pé òun gba Ọlọ́run gbọ́, sọ pé: “N kò gbà pẹ̀lú èrò pé Ọlọ́run kan gbé ohun ńlá kan tí ń ṣiṣẹ́ bí agogo kalẹ̀ láti ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn, tí ó wá tàdí mẹ́yìn láti ìgbà yẹn tó ń wo bí ìran ènìyàn ṣe ń bá ìṣòro náà jìjàkadì. Ìdí tí n kò fi gba èyí ni pé ìrírí tí mo ti ní nínú iṣẹ́ ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì kò jẹ́ kí n lè gbà gbọ́ pé àgbáálá ayé ní ẹ̀yà àwòkọ́ṣe ‘ohun ńlá kan tí ń ṣiṣẹ́ bí agogo’ tí ó jẹ́ èyí tí ó péye pátápátá. Àwọn àbá èrò orí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì wa . . . yóò máa fi ìgbà gbogbo ṣeé mú sunwọ̀n síwájú àti síwájú sí i ni, ṣùgbọ́n ó dá mi lójú pé wọn ó máa fi ìgbà gbogbo já sí èyí tí ó lábùkù. Mo rò pé, ó bọ́gbọ́n mu jù láti ní ìgbàgbọ́ nínú ipá tí ó wà láàyè tí ó ń mú kí àtúnṣe yìí ṣeé ṣe nígbà gbogbo.”
Ọlọ́run Ní Ète Kan
Ète Ọlọ́run ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ ni pé kí àwọn ènìyàn pípé tí wọ́n jẹ́ olódodo máa gbé inú pílánẹ́ẹ̀tì Ilẹ̀ Ayé. Wòlíì Aísáyà kọ ọ́ pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, Ẹlẹ́dàá ọ̀run, Ẹni tí í ṣe Ọlọ́run tòótọ́, Aṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé àti Olùṣẹ̀dá rẹ̀, Òun tí í ṣe Ẹni tí ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in, ẹni tí kò wulẹ̀ dá a lásán, ẹni tí ó ṣẹ̀dá rẹ̀ àní kí a lè máa gbé inú rẹ̀.”—Aísáyà 45:18.
Dípò kí Ọlọ́run fi ènìyàn kún orí ilẹ̀ ayé nípasẹ̀ ṣíṣẹ̀dá wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, ńṣe ló pète láti fi ẹ̀dá ènìyàn kún orí ilẹ̀ ayé nípasẹ̀ ọmọ bíbí. Nígbà tí Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, èyí kò ba ète rẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ jẹ́, àmọ́, ó ṣokùnfà àtúnṣe àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kan tí ó pọndandan kí ète rẹ̀ fún ìran ènìyàn àti ilẹ̀ ayé lè ní ìmúṣẹ.
Fún nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] ọdún tó ti kọjá, Ọlọ́run ti fàyè gba ìran ènìyàn láti máa ṣe ohun tí ó wù wọ́n láìsí ìtọ́sọ́nà tààràtà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá. Ohun tí àwọn òbí wa àkọ́kọ́ yàn fún ara wọn nìyẹn. (Jẹ́nẹ́sísì 3:17-19; Diutarónómì 32:4, 5) Òmìnira kúrò lábẹ́ ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run àti bí àwọn ènìyàn ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso ara wọn láìsí Ọlọ́run ni ó fi àìtóótun ènìyàn láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀ hàn, tí ó tún fi àìtóótun rẹ̀ láti ṣàṣeyọrí ní ṣíṣàkóso ènìyàn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ hàn.
Dájúdájú, Jèhófà ti mọ àbájáde yìí tẹ́lẹ̀. Òun ló mí sí àwọn tí ó kọ Bíbélì láti kọ àbájáde yìí sílẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, wòlíì Jeremáyà kọ ọ́ pé: “Mo mọ̀ dáadáa, Jèhófà, pé ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”—Jeremáyà 10:23.
Sólómọ́nì, ọlọ́gbọ́n náà, sọ̀rọ̀ nípa ìjàǹbá tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí ènìyàn gbìyànjú láti jọba lórí ènìyàn bí tiwọn, bí wọ́n ti ń ṣe fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún. “Gbogbo èyí ni mo ti rí, fífi ọkàn-àyà mi sí gbogbo iṣẹ́ tí a ti ṣe lábẹ́ oòrùn sì wà, ní àkókò tí ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.”—Oníwàásù 8:9.
Bí ó ti wù kí ó rí, ní ìyàtọ̀ pátápátá sí “títàdí mẹ́yìn bí òǹwòran nígbà tí ìran ènìyàn ń bá ìṣòro jìjàkadì,” Ọlọ́run Olódùmarè ní ìdí rere láti jẹ́ kí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún wọ̀nyí kọjá lọ láìdásí ohun ti ọ̀pọ̀ jù lọ ìran ènìyàn ń ṣe ní tààràtà.
Ó Ṣiṣẹ́ fún Ète Rere
Ìtàn ènìyàn fún ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ọdún lè dà bí àkókó tí ó gùn gan an nígbà tí a bá fi wéra pẹ̀lú ìpíndọ́gba iye ọdún tí a ń lò láyé tí ó dín ní ọgọ́rùn-ún ọdún. Àmọ́, ní ìbámu pẹ̀lú ìtòlẹ́sẹẹsẹ àkókò ti Ọlọ́run àti ojú ìwòye rẹ̀ nípa bí àkókò ti ń lọ, àwọn ẹgbẹ̀rún ọdún wọ̀nyí dà bí ọjọ́ mẹ́fà—kò tó ọ̀sẹ̀ kan! Àpọ́sítélì Pétérù ṣàlàyé pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí òtítọ́ kan yìí bọ́ lọ́wọ́ àfiyèsí yín, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, pé ọjọ́ kan lọ́dọ̀ Jèhófà jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ̀rún ọdún àti ẹgbẹ̀rún ọdún gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ kan.”—2 Pétérù 3:8.
Pétérù ń bá a lọ lẹ́yìn náà láti sọ̀rọ̀ lòdì sí fífi ẹ̀sùn àìkaǹkansí tàbí ìfònídónìí-fọ̀ladọ́la èyíkéyìí kan Ọlọ́run, ní fífi kún un pé: “Jèhófà kò fi nǹkan falẹ̀ ní ti ìlérí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn kan ti ka ìfi-nǹkan-falẹ̀ sí, ṣùgbọ́n ó ń mú sùúrù fún yín nítorí pé kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.”—2 Pétérù 3:9.
Nítorí náà, nígbà tí àwọn ọdún tí a là sílẹ̀ náà bá parí, Ẹlẹ́dàá yóò fi òpin sí àṣìlò pílánẹ́ẹ̀tì wa ẹlẹ́wà. Yóò ti fún ènìyàn ní àkókò tí ó pọ̀ tó láti fi àìtóótun rẹ̀ láti ṣàkóso tàbí láti fòpin sí ogun, ìwà ipá, ipò òṣì, àìsàn, àti àwọn ohun mìíràn tí ń fa ìrora, hàn kedere. Ìrírí yìí yóò wá fi ìdí ohun tí Ọlọ́run tọ́ka sí fún ènìyàn ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ múlẹ̀—pé wọ́n gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà àtọ̀runwá kí wọ́n tó lè ṣàṣeyọrí.—Jẹ́nẹ́sísì 2:15-17.
Ní ìbámu pẹ̀lú ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, a ń gbé ní apá àṣekágbá “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò àwọn nǹkan aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run yìí. (2 Tímótì 3:1-5, 13; Mátíù 24:3-14) Gbígbà tí Ọlọ́run gba ìṣàkóso ènìyàn láyè láìjẹ́ pé wọ́n gbára lé e àti bí ó ṣe fàyè gba ìwà ibi àti ìjìyà ti ń sún mọ́ òpin rẹ̀. (Dáníẹ́lì 2:44) Láìpẹ́, ìpọ́njú ńlá tí ayé yìí kò tíì ní ìrírí rẹ̀ rí yóò dé bá wa, yóò sì parí nínú “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè,” Amágẹ́dọ́nì. (Ìṣípayá 16:14, 16) Ogun tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ darí yìí kò ní ba ilẹ̀ ayé tí ó jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọ́run jẹ́, àmọ́ yóò “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.”—Ìṣípayá 11:18.
Ìjọba Ọlọ́run Ti Ẹgbẹ̀rún Ọdún
Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn olùlàájá ni yóò wà lórí ilẹ̀ ayé nígbà tí Amágẹ́dọ́nì bá jà tán. (Ìṣípayá 7:9-14) Àsọtẹ́lẹ̀ tí ó wà nínú Òwe 2:21, 22 yóò ti ní ìmúṣẹ nígbà yẹn pé: “Àwọn adúróṣánṣán ni àwọn tí yóò máa gbé ilẹ̀ ayé, àwọn aláìlẹ́bi sì ni àwọn tí a óò jẹ́ kí ó ṣẹ́ kù sórí rẹ̀. Ní ti àwọn ẹni burúkú, a óò ké wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé gan-an; àti ní ti àwọn aládàkàdekè, a ó fà wọ́n tu kúrò lórí rẹ̀.”
Ète Ọlọ́run ni pé àkókò àrà ọ̀tọ̀ ẹlẹ́gbẹ̀rún ọdún kan yóò tẹ̀ lé Amágẹ́dọ́nì, ogun òdodo náà. (Ìṣípayá 20:1-3) Èyí yóò para pọ̀ jẹ́ Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Ọmọ Ọlọ́run, Kristi Jésù, tí í ṣe Ọba Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run. (Mátíù 6:10) Lákòókò ìṣàkóso Ìjọba aláyọ̀ yìí lórí ilẹ̀ ayé, ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn tí ó sùn nínú ikú ni a óò jí dìde láti dara pọ̀ mọ́ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn tí ó la Amágẹ́dọ́nì já. (Ìṣe 24:15) A óò mú wọn padà bọ̀ sí ìjẹ́pípé lápapọ̀, lẹ́yìn náà—nígbà òpin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi—ilẹ̀ ayé yóò wá kún fún àwọn ọ̀kùnrin àti obìnrin pípé, tí gbogbo wọ́n jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà. Ète Ọlọ́run yóò ti ní ìmúṣẹ ológo.
Dájúdájú, ète Ọlọ́run ni láti “‘nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.’ Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ sì wí pé: ‘Wò ó! Mo ń sọ ohun gbogbo di tuntun.’” (Ìṣípayá 21:4, 5) Láìsí ìjákulẹ̀, ète yẹn yóò ní ìmúṣẹ láìpẹ́.—Aísáyà 14:24, 27.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Nínú ayé tuntun ti Ọlọ́run, àwọn ènìyàn yóò máa wà láàyè lọ títí láé nínú ayọ̀