A Ń fẹ́ Omi Ìyè
NÍ OHUN tó lé lẹ́gbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn, nǹkan ṣẹnuure fún ìlú kan ní Aṣálẹ̀ Arébíà tó ní ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [30,000] èèyàn nínú. Láìka ti ojú ọjọ́ àgbègbè yìí tí kò dára rárá sí, níbi tó jẹ́ pé gbogbo òjò tó ń rọ̀ lọ́dún kan kì í wọ̀n ju àádọ́jọ mìlímítà lọ, àwọn èèyàn ìlú Petra kọ́ bí wọ́n ṣe lè ṣọ́ omi tí kò tó ǹkan lò. Síbẹ̀, Petra di ọlọ́rọ̀ àti aláásìkí.
Àwọn olùgbé Nabataea ní Petra kò ní ẹ̀rọ oníná tó lè fa omi fún wọn. Wọn ò ṣe àwọn adágún omi tó rí gìrìwò. Àmọ́ wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè re omi jọ kí wọ́n sì ṣọ́ ọ lò. Wọ́n fọgbọ́n ṣe àwọn ohun tó lè gba omi dúró, ibi tómi lè gbà kọjá, àtàwọn táǹkì abẹ́lẹ̀ tó ń jẹ́ kí wọ́n lè darí omi tí wọ́n ti fọgbọ́n re jọ láti lọ sínú ìlú wọn kó sì lọ sórí àwọn ilẹ̀ oko wọn kéékèèké. Eku káká ni ẹ̀kán kan fi lè ṣòfò. Ọ̀nà tí wọ́n gbà gbẹ́ àwọn kànga àtàwọn táǹkì abẹ́lẹ̀ wọn dára débi pé, àwọn Lárúbáwá aláṣìíkiri tó ń gbébẹ̀ lóde òní ṣì ń rí wọn lò.
Ọ̀nà ìṣàbójútó omi náà ya ẹnjiníà oníṣẹ́ omi kan lẹ́nu tó fi sọ pé, “ó jẹ́ ohun àgbàyanu ìlú Petra tá ò lè fojú rí. Orí àwọn èèyàn náà pé púpọ̀.” Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn ògbóǹkangí ọmọ ilẹ̀ Ísírẹ́lì ti ń wá ọ̀nà tí wọ́n fi lè rí kọ́ lára ọgbọ́n àkànṣe àwọn ara Nabataea náà, tí wọ́n tún dáko sí Negeb, níbi tó jẹ́ pé eku káká ni òjò tó ń rọ̀ lódindi ọdún kan fi lè kọjá ọgọ́rùn-ún mìlímítà lórí ìwọ̀n. Àwọn onímọ̀ nípa ilẹ̀ ti lọ ṣàyẹ̀wò àṣẹ́kù ẹgbẹẹgbẹ̀rún oko kéékèèké ti àwọn ará Nabataea, tó jẹ́ pé àwọn tó ni wọ́n lo ọgbọ́n tó kàmàmà láti darí òjò tó ń rọ̀ nígbà òtútù lọ sórí wọn.
Àwọn ẹ̀kọ́ táwọn àgbẹ̀ ìpínlẹ̀ Sahel ní Áfíríkà tí ọ̀dá ti hàn léèmọ̀ kọ́ lára àwọn ará Nabataea ti ń ṣe wọ́n láǹfààní báyìí. Bó ti wù kó rí, ọ̀nà tí wọ́n fi ń ṣọ́ omi lò lóde òní náà lè ṣe irú ohun kan náà. Ní Lanzarote, ọ̀kan lára àwọn Erékùṣù Canary, èyí tó fara pẹ́ etíkun Áfíríkà, àwọn àgbẹ̀ ti kọ́ bí wọ́n ṣe lè máa gbin èso àjàrà àti ọ̀pọ̀tọ́ láwọn ibi táa lè sọ pé òjò kì í ti í rọ̀ rárá. Wọ́n á gbìn wọ́n sísàlẹ̀ àwọn ihò róbótó, wọ́n á wá kó eérú látinú òkè ayọnáyèéfín bo iyẹ̀pẹ̀ náà kí wọ́n má bàa gbẹ. Ìyẹn á jẹ́ kí ìrì tó pọ̀ tó ráyè dé ibi gbòǹgbò wọn láti lè mú irè oko tó dára jáde.
Ojútùú Tí Kò La Ìmọ̀ Iṣẹ́ Ẹ̀rọ Rẹpẹtẹ Lọ
A lè gbọ́ irú àwọn nǹkan tó jọ èyí káàkiri ayé nípa báwọn èèyàn ṣe mú ara wọn bá ipò ojú ọjọ́ gbígbẹ táútáú mu—irú bíi láàárín àwọn èèyàn Bishnoi tó ń gbé ní Aṣálẹ̀ Thar ní Íńdíà; àwọn obìnrin Turkana ní Kẹ́ńyà; àtàwọn Navajo Íńdíà ní Arizona ti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà lọ́hùn-ún. Àwọn ọ̀nà tí wọ́n fi ń re omi òjò pa mọ́, tí wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wúlò gidigidi fún iṣẹ́ ọ̀gbìn ju ojútùú tí ọgbọ́n iṣẹ́ ẹ̀rọ gíga pèsè.
Gbígbẹ́ adágún omi làwọn èèyàn mú níbàádà ní ọ̀rúndún ogún. Wọ́n lo àwọn odò ńláńlá, wọ́n sì ṣàwárí àwọn ọ̀nà ìbomirinlẹ̀ tó hẹ̀rẹ̀ǹtẹ̀. Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kan fojú díwọ̀n rẹ̀ pé, dé àyè kan, wọ́n ti darí ìpín ọgọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún àwọn omi àti odò tó wà láyé síbì kan tàbí síbòmíràn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé irú àwọn ètò bẹ́ẹ̀ mú àǹfààní díẹ̀ wá, àwọn onímọ̀ nípa ohun alààyè àti àyíká tọ́ka sí ìpalára tó ti ṣe fún àyíká, kà má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn tó pàdánù ilé wọn.
Láfikún sí i, láìka ti èrò rere tí wọ́n ní sí, eku káká làwọn àǹfààní tí ètò yìí ní fi lè dé ọ̀dọ̀ àwọn àgbẹ̀ tó nílò omi ọ̀hún lójú méjèèjì. Nígbà tí Rajiv Gandhi tó jẹ́ Olórí Ìjọba nígbà kan ń sọ nípa ètò ìbomirinlẹ̀ ní ilẹ̀ Íńdíà, ó sọ pé: “Fún ọdún mẹ́rìndínlógún la fi gbọ́n owó dànù. Àwọn èèyàn kò rí èrè kankan níbẹ̀, kò sí ètò fún ìbomirinlẹ̀, kò sómi, irè oko wọn kò torí ẹ̀ pọ̀ sí i, wọn ò rí ìrànlọ́wọ́ kankan gbà nínú ìgbésí ayé wọn ojoojúmọ́.”
Àmọ́ táa bá ni ká sọ nípa ti ojútùú tí kò la ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ rẹpẹtẹ lọ, ẹ̀rí wà pé ó wúlò gan an ni bẹ́ẹ̀ ni kò sì fi bẹ́ẹ̀ ṣèpalára fún àyíká. Àwọn adágún omi kéékèèké àti ìsédò táwọn ará àdúgbò ṣe ti kẹ́sẹ járí lọ́pọ̀lọpọ̀ ní China, níbi tó jẹ́ pé mílíọ̀nù mẹ́fà irú ẹ̀ ni wọ́n ti ṣe. Ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì, àwọn èèyàn ti rí i pé nípa wíwá ọgbọ́n díẹ̀ ta, àwọn lè lo omi kan fún fífọ nǹkan, kí àwọn tún lò ó fún ṣíṣe ìmọ́tótó, lẹ́yìn náà káwọn sì tún lo omi kan náà fún ìbomirinlẹ̀.
Ọ̀nà míì tó tún gbéṣẹ́ ni fífi omi sídìí nǹkan ọ̀gbìn nìkan, èyí kì í jẹ́ kí iyẹ̀pẹ̀ ṣòfò, omi tó sì ń gbà jẹ́ kìkì ìpín márùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún omi tí ọ̀nà ìbomirinlẹ̀ àtayébáyé ń gbà. Fífọgbọ́n lo omi tún ń béèrè fún gbígbin kìkì àwọn ohun tó bá àdúgbò tó gbẹ táútáú mu, irú bíi sorghum tàbí ọkà bàbà, dípò àwọn tó máa nílò ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi bí ìrèké tàbí àgbàdo.
Táwọn tó ń lo omi nílé àti ní iléeṣẹ́ bá lè sapá díẹ̀, àwọn náà lè dín omi tí wọ́n ń lò kù. Fún àpẹẹrẹ, iléeṣẹ́ kan lè lo omi ìwọ̀n lítà kan láti fi ṣe ìwọ̀n bébà kan ká ní ó lè máa ṣàtúnlò omi rẹ̀, ìyẹn á fi ohun tó lé ní ìpín mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún dín omi tó ń lò kù. Ìlú Mẹ́síkò ti yí àwọn ilé ìgbọ̀nsẹ̀ rẹ̀ padà sí èyí tó ń lo kìkì ìdá mẹ́ta omi tí àwọn tó wọ́pọ̀ ń lò. Ìlú yẹn tún ṣonígbọ̀wọ́ ìkéde kan tó ń pe àfiyèsí sí dídín lílò omi kù lọ́nà tó ga.
Ohun Táa Nílò Láti Ṣàṣeyọrí
Káwọn èèyàn ṣàtúnṣe ìṣesí wọn ni ojútùú sí ìṣòro omi àti ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ìṣòrò àyíká. Àwọn èèyàn ní láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ kí wọ́n má sì jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan, kí wọ́n fi àwọn nǹkan kan du ara wọn láwọn ibi tó bá ti yẹ, kí wọ́n sì múra tán láti ṣètọ́jú ilẹ̀ ayé de àwọn tó máa gbébẹ̀ lọ́la. Nígbà tí Sandra Postel ń sọ nípa èyí nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní Last Oasis—Facing Water Scarcity, ó sọ pé: “A nílò ìlànà lórí omi lílò, ìyẹn ohun tó lè tọ́ wa sọ́nà tó tọ́ nínú ṣíṣe àwọn ìpinnu tó lágbára nípa àwọn ohun àdánidá tí a kò mọ̀ dáadáa tí a kò sì lè lóye dáadáa.”
Ó dájú pé “ìlànà lórí omi lílò” yẹn kò mọ sí àdúgbò kan. Àwọn orílẹ̀-èdè, títí kan àwọn tó jẹ́ aládùúgbò gbọ́dọ̀ fọwọ́ sowọ́ pọ̀, níwọ̀n bí àwọn odò kò kúkú ti dá ààlà orílẹ̀-èdè ẹnì kan mọ̀ yàtọ̀ sí ti ẹlòmíràn. Nínú ìròyìn tí Ismail Serageldin kọ, tó pè ní Beating the Water Crisis, ó ní: “Wàhálà nípa omi tó dára àti bó ṣe pọ̀ sí, èyí tí wọ́n ń fojú wò látẹ̀yìnwá bí ọ̀rọ̀ ẹni àìmọ̀rí ì báà kú, gbọ́dọ̀ wá di èyí tí wọ́n ń wò bí ọ̀rọ̀ tó kan gbogbo àgbáyé báyìí.”
Àmọ́, gẹ́gẹ́ bí Kofi Annan tó jẹ́ Ọ̀gá Àgbà fún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè náà ti fara mọ́ ọn, láti sọ pé káwọn orílẹ̀-èdè bójú tó ọ̀ràn tó kan gbogbo ayé kì í ṣohun tó rọrùn rárá. Ó sọ pé: “Nínú ayé òde òní tí kì í ṣe tẹnì kan, kò dájú pé ohun tó máa mú kí gbogbo ayé pawọ́ pọ̀ wá nǹkan ṣe tíì dé. Àkókò ti tó báyìí fún wa láti pa èrò pọ̀, kí ‘àwọn orílẹ̀-èdè pawọ́ pọ̀ ṣọ̀kan.’”
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣe pàtàkì pé ká ní omi tó dára tó sì pọ̀ tó, ó dájú pé kì í ṣe ìyẹn nìkan lohun táa nílò táa bá máa gbádùn ìgbésí ayé tó pegedé tó sì jẹ́ aláyọ̀. Àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ gbà pé ohun kan wà tí Ẹni náà tó pèsè àti omi, àti ìwàláàyè fúnra rẹ̀ ń béèrè lọ́wọ́ wọn. (Sáàmù 36:9; 100:3) Dípò tí wọn ì bá sì fi àìronújinlẹ̀ lo ayé àtàwọn ohun tó wà nínú rẹ̀ ní ìlòkulò, ńṣe ló yẹ kí wọ́n “máa bójú tó o,” gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá wa ti pàṣẹ fún àwọn òbí wa àkọ́kọ́ pé kí wọ́n ṣe.—Jẹ́nẹ́sísì 2:8, 15; Sáàmù 115:16.
Omi Tó Jomi Lọ
Níwọ̀n bí omi ti ṣe pàtàkì gan an, kò yani lẹ́nu pé Bíbélì lò ó láti fi ṣe àpẹẹrẹ ohun pàtàkì. Àní, táa bá fẹ́ gbádùn ìgbésí ayé lọ́nà tí Ọlọ́run pète rẹ̀ fún wa, a gbọ́dọ̀ ka ẹni tó jẹ́ orísun omi ìṣàpẹẹrẹ yìí sí. A tún gbọ́dọ̀ kọ́ báa ṣe lè ní irú ẹ̀mí obìnrin ọ̀rúndún kìíní yẹn tó sọ fún Jésù Kristi pé: “Ọ̀gá, fún mi ní omi yìí.” (Jòhánù 4:15) Ìwọ wo ohun tó ṣẹlẹ̀ ná.
Jésù dúró síbi kànga jíjìn kan nítòsí Nablus ti òde òní, ìyẹn kànga kan náà táwọn èèyàn láti ibi gbogbo lágbàáyé máa ń lọ bẹ̀ wò títí dọjọ́ òní. Obìnrin ara Samáríà kan náà tún wá síbẹ̀. Kò sí àní-àní pé, bíi ti ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin ọ̀rúndún kìíní, ìgbà gbogbo ló máa ń lọ sídìí kànga yìí kó lè pọn omi sílé. Àmọ́ Jésù sọ pé òun lè fún un ní “omi ààyè,” ìyẹn omi kan tí orísun rẹ̀ kò lè gbẹ títí ayé.—Jòhánù 4:10, 13, 14.
Kò yani lẹ́nu pé kíá ni ìfẹ́ obìnrin náà ru sókè. Àmọ́ o, ó dájú pé “omi ààyè” tí Jésù ń sọ kì í ṣe omi lásán. Ohun tí Jésù ní lọ́kàn ni àwọn ìpèsè tẹ̀mí tó lè mú àwọn èèyàn wà láàyè títí láé. Síbẹ̀, ìsopọ̀ kan wà láàárín omi lásán àti omi ìṣàpẹẹrẹ, méjèèjì la nílò láti gbádùn ìgbésí ayé ní kíkún.
Ó ju ẹ̀ẹ̀kan lọ tí Ọlọ́run ṣe ọ̀nà àbáyọ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ nígbà tí wọn kò rí omi. Ó pèsè omi lọ́nà ìyanu fún òbítíbitì àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n ń rìn la aṣálẹ̀ Sínáì kọjá lójú ọ̀nà sí Ilẹ̀ Ìlérí. (Ẹ́kísódù 17:1-6; Númérì 20:2-11) Èlíṣà tó jẹ́ wòlíì Ọlọ́run sọ kànga eléèérí kan di mímọ́ ní Jẹ́ríkò. (2 Àwọn Ọba 2:19-22) Nígbà tí àṣẹ́kù àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ronú pìwà dà padà dé láti Bábílónì sí ìlú ìbílẹ̀ wọn, Ọlọ́run ṣamọ̀nà wọn lọ síbi “omi ní aginjù.”—Aísáyà 43:14, 19-21.
Lónìí, omi tó máa wà títí lọ ni ilẹ̀ ayé wa nílò lójú méjèèjì. Níwọ̀n bí Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà Ọlọ́run, ti wá ojútùú sí ìṣòro omi láwọn àkókò tó kọjá, ǹjẹ́ kò tún ní ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ iwájú? Bíbélì jẹ́ kó dá wa lójú pé ó máa ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà tí Ọlọ́run ń sọ bí ipò nǹkan ṣe máa rí lábẹ́ Ìjọba rẹ̀ tó ṣèlérí, ó sọ pé: “Lórí àwọn òkè kéékèèké dídán borokoto, èmi yóò ṣí àwọn odò, àti ní àárín àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ àfonífojì, èmi yóò ṣí àwọn ìsun. Èmi yóò sọ aginjù di adágún omi tí ó kún fún esùsú, èmi yóò sì sọ ilẹ̀ aláìlómi di àwọn orísun omi, . . . kí àwọn ènìyàn lè rí, kí wọ́n sì mọ̀, kí wọ́n sì kọbi ara sí i, kí wọ́n sì ní ìjìnlẹ̀ òye lẹ́ẹ̀kan náà, pé ọwọ́ Jèhófà gan-an ni ó ṣe èyí.”—Aísáyà 41:18, 20.
Bíbélì sọ pé nígbà tí àkókò yẹn bá tó, “ebi kì yóò pa” àwọn èèyàn, “bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ kì yóò gbẹ wọ́n.” (Aísáyà 49:10) A mà dúpẹ́ fún ọ̀nà àbójútó tuntun yìí o fún ilẹ̀ ayé, ọ̀nà àbáyọ tó ṣe sàn-án yóò wà fún wàhálà omi. Ìṣàbójútó yìí, ìyẹn Ìjọba tí Jésù kọ́ wa pé ká máa gbàdúrà fún yóò ṣàkóso “nípasẹ̀ ìdájọ́ òdodo àti nípasẹ̀ òdodo, láti ìsinsìnyí lọ àti títí dé àkókò tí ó lọ kánrin.” (Aísáyà 9:6, 7; Mátíù 6:9, 10) Àbájáde èyí ni pé, àwọn èèyàn káàkiri ayé yóò wá di aládùúgbò ara wọn ní tòótọ́.—Sáàmù 72:5, 7, 8.
Báa bá wá omi ìyè nísinsìnyí, àá lè máa wo iwájú de ọjọ́ náà nígbà tí omi tó tó máa wà fún gbogbo èèyàn.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Òkè: Àwọn ará Petra ọjọ́un mọ ọ̀nà àti ṣọ́ omi lò
Ìsàlẹ̀: Ojú ọ̀nà kan tómi ń gbà ní Nabataea, ní Petra
[Credit Line]
Garo Nalbandian
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Àwọn àgbẹ̀ tó ń gbé ní ọ̀kan lára àwọn Erékùṣù Canary ti kọ́ bí wọ́n ṣe lè gbin nǹkan níbi tí òjò kì í ti í rọ̀ dáadáa
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó ṣèlérí “omi ààyè” fún obìnrin yìí?