Ṣé o Máa Ń dààmú Nípa Bí Irun Rẹ Ṣe Rí?
BÓYÁ o jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ èèyàn tó máa ń dúró níwájú gíláàsì lójoojúmọ́, tí wọ́n á máa fẹ̀sọ̀ wo bí irun orí wọn ṣe rí. Àtọkùnrin àtobìnrin ni ọ̀rọ̀ irun máa ń jẹ lọ́kàn, ó sì lè máa kó ìdààmú bá wọn nígbà míì.
Mọ̀ Nípa Irun Orí Rẹ
Ǹjẹ́ o tiẹ̀ mọ iye fọ́nrán irun tó wà lórí rẹ? Ó kéré tán, ó tó ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000]. Ọdún méjì sí ọdún mẹ́fà ni fọ́nrán irun kan fi máa ń bá a lọ láti máa hù, kì í hù lọ títí ayé. Lẹ́yìn náà á yọ dà nù, tó bá sì ṣe díẹ̀, fọ́nrán tuntun mìíràn á tún bẹ̀rẹ̀ sí í hù ní ojú ihò yẹn kan náà. Èyí fi hàn pé fọ́nrán irun kan ní ìgbà tó máa hù mọ kó tó yọ dà nù. (Wo àpótí tó wà lójú ewé 25.) Fún ìdí yìí, kódà, béèyàn ò bá tiẹ̀ níṣòro irun, nǹkan bí àádọ́rin sí ọgọ́rùn-ún ló máa ń yọ dà nù fúnra wọn lójoojúmọ́.
Kí ló mú kí àwa èèyàn ní oríṣiríṣi àwọ̀ irun? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia ṣàlàyé pé: “Ohun tó sábà máa ń fa irú àwọ̀ irun tí ẹnì kan ní ni bí èròjà aláwọ̀ ilẹ̀-pa-pọ̀-mọ́-dúdú kan tí wọ́n ń pè ní melanin bá ṣe pọ̀ sí nínú irun, àti bó ṣe dé gbogbo ìdí irun sí.” Inú ara ni èròjà melanin yìí wà, ó sì máa ń fara hàn nínú irun, àwọ̀ ara àti ẹyin ojú. Bí èròjà yìí bá ṣe pọ̀ tó lára, bẹ́ẹ̀ ni irun á ṣe dúdú sí. Bí pípọ̀ tó pọ̀ tẹ́lẹ̀ bá sì ṣe ń dín kù sí i, bẹ́ẹ̀ ni irun á bẹ̀rẹ̀ sí í yí padà láti àwọ̀ dúdú sí àwọ̀ ilẹ̀, àwọ̀ pupa, tàbí àwọ̀ òféfèé. Bí irun ò bá wá ní èròjà melanin rárá, ńṣe ló máa funfun báláú táá sì máa dán.
Yàtọ̀ fún èéṣí irun, ohun tó tún máa ń kó ìdààmú bá ọ̀pọ̀ èèyàn ni kí irun máa re tàbí kí irun máa hu ewú.
Ṣé O Ní Ewú Lórí?
Ojú ẹni tó ti ń darúgbó ni wọ́n sábà máa ń fi wo ẹni tó bá léwú lórí. Wọ́n sì máa ń ka irun funfun sí ohun táwọn tó bá ti dàgbà máa ń ní. Lóòótọ́, béèyàn bá ṣe ń dàgbà sí i ni irun funfun á máa pọ̀ sí i lórí ẹ̀. Àmọ́ ṣá o, yàtọ̀ sí dídi àgbàlagbà, a gbọ́ pé àwọn nǹkan mìíràn tún máa ń fà á, irú bíi kéèyàn máa ṣọ́ oúnjẹ jẹ kọjá ààlà. Tọkùnrin tobìnrin ló máa ń ní ewú lórí, kò sì kan ọ̀ràn pé irú àwọ̀ irun kan léèyàn ti ní tẹ́lẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè tètè fara hàn lórí àwọn tí irun wọn dúdú gan-an.
Wọ́n lè máa fojú àgbàlagbà wo àwọn kan láìjẹ́ pé wọ́n ti dàgbà nítorí pé wọ́n ní irun funfun lórí, èyí sì lè máa kọ wọ́n lóminú. Ní ìdàkejì ẹ̀wẹ̀, àwọn èèyàn kan wà tí wọ́n ti dàgbà àmọ́ tí wọn ò ní irun funfun lórí, tí wọ́n máa ń ṣàníyàn bí wọ́n ti ń wò ó pé ọjọ́ orí àwọn ti kọjá bí àwọ̀ irun orí àwọn ṣe rí.
Pé irun di funfun kò túmọ̀ sí pé irun ọ̀hún ti kú. Kódà, gbogbo irun tá à ń rí lórí wa yìí ló ti kú. Fọ́nrán irun kọ̀ọ̀kan máa ń ṣẹ́ yọ láti abẹ́ awọ orí. Bulb ni wọ́n máa ń pe èyí tó wà lábẹ́ awọ orí nísàlẹ̀, apá ibẹ̀ nìkan sì ni kò tíì kú. Bulb yìí ló dà bí ilé iṣẹ́ tó ń mú irun jáde. Nígbà tí àwọn sẹ́ẹ̀lì tó ń yára pín sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ nínú bulb bá mú fọ́nrán irun kan jáde, irun náà á gba melanin sára, èyí tí àwọn sẹ́ẹ̀lì tó ń ṣe àwọ̀ máa ń pèsè. Nítorí náà, tí àwọn sẹ́ẹ̀lì tó ń ṣe àwọ̀ náà kò bá mú melanin jáde mọ́, àwọ̀ funfun ni irun náà máa ní.
Kò sẹ́ni tó tíì mọ ìdí tí àwọn sẹ́ẹ̀lì tó ń ṣe àwọ̀ fi máa ń ṣàdéédéé ṣíwọ́ mímú èròjà melanin jáde. Nítorí náà, wọn ò tíì rí oògùn kankan tó lè ṣe é kí ewú má hù lórí. A tún gbọ́ pé, àwọn sẹ́ẹ̀lì tó ń ṣe àwọ̀ tó ti ṣíwọ́ iṣẹ́ tẹ́lẹ̀ tún lè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ padà. Ó dùn mọ́ni pé, ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ló wà nínú Bíbélì tó ní í ṣe pẹ̀lú irun, ọ̀kan lára àwọn àkàwé tí Jésù lò pàápàá sì tọ́ka sí irun funfun. Ó sọ pé: “Ìwọ kò lè sọ irun kan di funfun tàbí dúdú.” (Mátíù 5:36) Ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti mọ̀ pé kò sí ohun tí ọmọ ẹ̀dá lè ṣe kí ewú má hù tàbí láti yí ewú padà di dúdú.
Àwọn kan máa ń gbìyànjú àwọn oògùn tó ṣẹ̀sẹ̀ dóde, irú bíi gbígba abẹ́rẹ́ melanin. Àwọn kan sì máa ń fi dáì sí irun wọn, èyí kì í sì í ṣe àṣà tuntun rárá. Àwọn Gíríìkì àtàwọn ará Róòmù ayé ọjọ́un náà máa ń fi dáì sí irun. Àwọn ará Íjíbítì ìgbàanì máa ń lo ẹ̀jẹ̀ màlúù láti fún irun wọn ní àwọ̀ mìíràn. Ó tiẹ̀ wà lákọọ́lẹ̀ pé Hẹ́rọ́dù Ńlá, tó gbé ayé lákòókò Jésù Kristi, pa irun rẹ̀ tó ti ń hu ewú láró, kí wọ́n má bàa mọ̀ pé ó ti ń dàgbà.
Síbẹ̀, kéèyàn máa pa irun láró ní gbogbo ìgbà máa ń náni ní àkókò àti wàhálà, ó sì lè kó àìsàn bá awọ ara àwọn kan tàbí kó máà bá wọn lára mu. Ká tiẹ̀ ní o ti pinnu pé ńṣe ni wàá máa fi dáì pa irun rẹ tó ń yọ funfun, tó bá yá, ó lè sú ọ. Tó bá dìgbà yẹn, ó dájú pé kò sí ohun kankan tí wàá rí ṣe sí àwọn tó bá ṣẹ̀sẹ̀ ń hù. Àmọ́ àǹfààní kan wà tí irun funfun ní o, ó máa ń lẹ́wà gan-an lórí ẹni, ó sì lè fún ọ ní ìyí kan tó ò tíì rírú ẹ̀ rí. Bíbélì sọ pé: “Orí ewú jẹ́ adé ẹwà nígbà tí a bá rí i ní ọ̀nà òdodo.”—Òwe 16:31.
Kí Irun Fẹ́lẹ́ Tàbí Kí Orí Máa Pá
Ìṣòro mìíràn tó tún wọ́pọ̀ nípa irun ni kí irun fẹ́lẹ́ tàbí kí orí máa pá. Ọjọ́ pẹ́ táwọn ìṣòro wọ̀nyí náà ti wà. Ní Íjíbítì ìgbàanì, lára àwọn èròjà tí wọ́n máa ń fi gbógun ti orí pípá ni ọ̀rá kìnnìún, ọ̀rá erinmi, ọ̀rá ọ̀nì, ọ̀rá ológbò, ti ejò àti ti oríṣi pẹ́pẹ́yẹ kan tí ń jẹ́ ògbùgbú. Lónìí, àwọn oògùn tí wọ́n sọ pé ó ń ṣiṣẹ́ fún ìtọ́jú irun àti awọ orí kò lóǹkà lọ́jà, owó táwọn èèyàn sì ń ná lórí àwọn oògùn yìí lọ́dọọdún kọjá sísọ.
Ìgbà tí ìṣòro bá dé sí bí irun ṣe ń hù ni orí pípá máa ń ṣẹlẹ̀. Tí àìsàn bá kọ luni, irú bí àìsàn àìjẹunrekánú, tàbí kára ẹni máa gbóná kọjá ààlà, tàbí tí àrùn kan bá kọ lu awọ ara èèyàn, ìṣòro lè dé sí irun olúwarẹ̀ tó ti máa ń hù dáadáa tẹ́lẹ̀. Oyún àti ìbímọ tún lè ṣèdíwọ́ fún bí irun ṣe ń hù, tí irun orí á máa tu dà nù kó tó tó àkókò tí òmíràn máa hù. Àmọ́ tí àwọn ohun tó ń ṣokùnfà orí pípá bá ti wábi gbà, bí irun ṣe ń re yìí á dáwọ́ dúró, irun á sì tún máa hù bó ṣe yẹ padà.
Ìṣòro mìíràn tó tún máa ń fa kí irun máa tu ni wọ́n ń pè ní alopecia.a Téèyàn bá ní ìṣòro yìí, ọ̀pọ̀ ìgbà ni irun orí onítọ̀hún á máa tu láwọn apá ibì kọ̀ọ̀kan lórí. Ìwádìí ìmọ̀ ìṣègùn tí wọ́n ṣe láìpẹ́ yìí fi hàn pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé tí ètò tó ń dènà àrùn nínú ara kò bá ṣiṣẹ́ dáadáa mọ́ ni ìṣòro alopecia máa ń dé síni.
Èyí tó wọ́pọ̀ jù nínú ìṣòro kí irun orí máa fẹ́lẹ́ sí i ni orí pípá àwọn ọkùnrin. Gẹ́gẹ́ bí orúkọ rẹ̀ ti fi hàn, àwọn ọkùnrin lèyí máa ń ṣẹlẹ̀ sí. Iwájú orí ló ti máa ń bẹ̀rẹ̀, tí ẹsẹẹsẹ irun iwájú á máa re kúrò, tàbí kẹ̀ kí irun àárín orí bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́lẹ́, tí yóò sì máa bá a lọ bẹ́ẹ̀. Irun kò ní í hù dáadáa mọ́ lápá ibí yìí, tó bá sì yá, kò tiẹ̀ wá ní í hù mọ́ rárá. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopædia Britannica ṣàlàyé pé: “Lápá ibi tí orí ti bẹ̀rẹ̀ sí í pá yìí, irun múlọ́múlọ́ tí wọ́n ń pè ní vellus ló máa wá máa hù dípò irun tó gùn tó sì nípọn tó ti máa ń hù níbẹ̀ tẹ́lẹ̀.” Èyí túmọ̀ sí pé, ńṣe ni irun tó ń hù níbẹ̀ á wá máa fẹ́lẹ́ sí i táá sì máa re láìpẹ́ jọjọ, títí èyíkéyìí ò tiẹ̀ fi ní í hù mọ́ rárá. Àpapọ̀ ohun méjì ló ń fa èyí, èkíní, ohun téèyàn ti jogún àti èkejì, èròjà inú ẹ̀jẹ̀ àwọn ọkùnrin.
Nígbà míì, ìṣòro orí pípá àwọn ọkùnrin lè tètè bẹ̀rẹ̀, bóyá nígbà tẹ́nì kan tiẹ̀ ṣì jẹ́ ọ̀dọ́langba, àmọ́ ìgbà tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ jù ni ìgbà tí ọkùnrin bá ti lé lọ́mọ ọgbọ̀n ọdún dáadáa tàbí tó ti lé lógójì ọdún. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọkùnrin ló máa ń pàdánù irun wọn lọ́nà yìí, síbẹ̀ ọ̀nà tó ń gbà ṣẹlẹ̀ yàtọ̀ láti ẹ̀yà kan sí òmíràn àti láti ara ẹnì kan sí òmíràn. Ó wá dunni pé, títí di àkókò yìí, kò tíì sí oògùn kan tààrà tó lè wo ìṣòro yìí sàn. Àwọn kan lè máa fi wíìgì borí tàbí kí wọ́n lọ fún iṣẹ́ abẹ fífi irun àtọwọ́dá sí ibi tí orí ti pá. Àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń ṣètọ́jú ìwọ̀nba irun tó kù láti dín bí irun wọn ṣe ń re kù.
Sísọ pé irun ẹnì kan ń fẹ́lẹ́ sí i kò fi dandan túmọ̀ sí pé ẹni náà ń pàdánù irun rẹ̀. Ohun tá à bá kúkú sọ ni pé, irun ẹni náà ń fẹ́lẹ́ sí i tàbí pé ó ń tín-ín-rín sí i, nípa bẹ́ẹ̀, irun yẹn ò ní nípọn tó ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Báwo ni fọ́nrán irun kan tiẹ̀ ṣe nípọn tó? Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan ti fi hàn, fọ́nrán irun orí àwọn kan máa ń fẹ́lẹ́ gan-an nígbà tí tàwọn mìíràn sì máa ń nípọn tó àádọ́ta sí ọgọ́rùn-ún ìwọ̀n tí a mọ̀ sí máíkírónì látorí ẹnì kan sí ẹlòmíràn.b Béèyàn bá ṣe ń dàgbà sí i ni irun orí rẹ̀ á máa fẹ́lẹ́ sí i. Pé fọ́nrán irun fẹ́lẹ́ tàbí pé kò fẹ́lẹ́ lè jọ bí ohun tí kò tó nǹkan. Àmọ́, jọ̀wọ́ rántí pé nǹkan bí ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000] fọ́nrán irun ló wà lórí. Nítorí náà, bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ìwọ̀nba díẹ̀ ni fọ́nrán irun kọ̀ọ̀kan fi fẹ́lẹ́, èyí á hàn gan-an nígbà tí wọ́n bá pa gbogbo rẹ̀ pọ̀.
Tọ́jú Irun Rẹ
Kíákíá ni irun máa ń hù, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀yà ara tó máa ń yára dàgbà jù lọ nínú ara. Tí wọ́n bá pa gbogbo irun tó ń hù lójúmọ́ pọ̀, ó ju ogún mítà lọ!
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò tíì sí oògùn kankan tó lè mú ohun tó ń fa ewú àti orí pípá kúrò, ọ̀pọ̀ nǹkan la lè ṣe láti tọ́jú irun orí wa. Jíjẹ oúnjẹ aṣaralóore tó pọ̀ tó àti ṣíṣe àwọn ohun táá mú kí ẹ̀jẹ̀ túbọ̀ máa ṣàn dé abẹ́ awọ orí wa ṣe kókó. Fífi ebi para ẹni lọ́nà bíbùáyà tàbí jíjẹ àwọn oúnjẹ tí kò ní láárí lè fa kí ewú tètè máa yọ àti kí irun máa fẹ́lẹ́. Àwọn ògbógi tó mọ̀ nípa irun dámọ̀ràn pé ká máa fọ irun wa déédéé ká sì máa fi nǹkan ra awọ orí wa, ká sì ṣọ́ra, ká má máa fi èékánná họ ọ́. Èyí á jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ máa ṣàn dáadáa dé awọ orí. Lẹ́yìn tó o bá ti fọ irun rẹ tán, rí i dájú pé o ṣàn án, ó mọ́ dáadáa.
Má máa fi gbogbo agbára ya irun rẹ o. Bó bá jẹ́ irun gígùn lo ní, ó sàn kó o má ṣe kọ́kọ́ máa yà á látìsàlẹ̀ wá sókè. Kàkà bẹ́ẹ̀, kọ́kọ́ dì í mú, kó o wá fi kóòmù ya ẹnu rẹ̀ tó ti lọ́ mọ́ra. Lẹ́yìn náà, bẹ̀rẹ̀ láti àárín lọ sí ẹnu irun. Níkẹyìn, wá rọra fi irun rẹ sílẹ̀ kó o sì yà á látìdí lọ sí ẹnu irun.
Tó o bá rí i tí irun funfun ń yọ lórí rẹ tàbí tí irun rẹ ń já gan-an, èyí lè kódààmú bá ọ. Àmọ́, rántí pé irun rẹ kì í kó ìdààmú bá àwọn mìíràn tó bo ṣe máa ń ṣe ìwọ fúnra rẹ. Ọwọ́ rẹ ló wà bóyá kó o fi dáì pa irun rẹ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, bóyá kó o lo àfikún irun kún un tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, tàbí bóyá kó o wá ìtọ́jú mìíràn. Àwọ̀ yòówù kí irun rẹ ní, bóyá irun rẹ sì kéré ni tàbí ó pọ̀, ohun tó ṣe pàtàkì ni pé, jẹ́ kó máa wà ní mímọ́ kó sì bójú mu.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Jí! ti April 22, 1991, ojú ìwé 12.
b Ìdá kan nínú ìdá ẹgbẹ̀rún mìlímítà kan ni máíkírónì kan.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
BÍ IRUN ṢE MÁA Ń HÙ
Irun wá ní ìgbà tó máa ń hù, ìgbà tó máa ń yí padà díẹ̀, àtìgbà tó máa ń kú. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé: “Tó bá ti tó àkókò tí fọ́nrán irun kan máa sinmi, kò ní í hù mọ́. Inú ohun kan tó dà bí àpò ni irun tó ń sinmi yìí máa wà títí tí àkókò tí òmíràn máa hù á fi tó. Ní àkókò yìí, irun ti tẹ́lẹ̀ á yọ dà nù nígbà tí irun tuntun tó ń hù jáde bọ̀ bá tì í jáde kúrò nínú àpò irun náà.” Ní ìgbà èyíkéyìí, ìdá márùnlélọ́gọ́rin sí àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo irun tá a ní ló máa ń fara hàn lórí wa, ìdá mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún nínú ọgọ́rùn-ún á máa sinmi lọ́wọ́, ìdá kan nínú ọgọ́rùn-ún á sì máa yíra padà.
[Àwòrán]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
fọ́nrán irun
ẹṣẹ́ tó máa ń sun epo
ìṣàn ẹ̀jẹ̀
àpò irun
Ìgbà tí irun ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í hù
Ìgbà tó ń hù dáadáa
Ìgbà tó ti ń rẹ̀ ẹ́
Ìgbà tó ń sinmi
Ìgbà tó tún ń hù padà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]