Òbí Tó Ń Dá Tọ́mọ Túbọ̀ Ń Pọ̀ Sí I
“Ọ̀pọ̀ òru ni mo máa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run tomijé-tomijé, mọ́jú. Màá máa sọ fún un pé: ‘Mi ò mọ bí mo ṣe máa ṣe é sí lọ́la.’”—GLORIA, ÌYÁ KAN TÓ Ń DÁ TỌ́ ỌMỌ MẸ́TA.
ÀWỌN ìdílé olóbìí kan ti wá di ohun tó ń pọ̀ sí i láwùjọ lónìí.a Bí irú ìdílé tá a mọ̀ tẹ́lẹ̀, ìyẹn ìdílé tó ní ọkọ, aya, àtàwọn ọmọ ṣe ń di èyí tí oríṣi mìíràn ń rọ́pò rẹ̀, làwọn elétò ìkànìyàn àtàwọn onímọ̀ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè lágbàáyé ń béèrè ohun tó fà á.
Simon Duncan àti Rosalind Edwards, tí wọ́n jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá sọ pé, “àwọn ìyípadà tó máa wà fún ìgbà pípẹ́ ti ń ṣẹlẹ̀ nínú ètò ìdílé àti nínú àjọṣe àárín ọkùnrin sí obìnrin.” Kí ló ń fà á? Àwọn alákìíyèsí kan sọ pé, ohun tó ń fà á ni irú ìgbésí ayé táwọn èèyàn yàn láti máa gbé bí ìyípadà ti ń ṣẹlẹ̀ nínú ètò ọrọ̀ ajé, àṣà, àti ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà.
Ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ lára àwọn ìyípadà náà àti irú ìpinnu táwọn èèyàn ń ṣe yẹ̀ wò. Àwọn wàhálà ìgbésí ayé jẹ́ nǹkan pàtàkì kan tó ń nípa lórí ìgbésí ayé àwọn èèyàn. Látìgbà tí wọ́n bá ti jí títí dìgbà tí wọ́n á fi sùn ni ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lóde ń nípa lórí wọn. Láyé òde òní, ìdí Íńtánẹ́ẹ̀tì, iwájú tẹlifíṣọ̀n, orí fóònù, inú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ àti orí lílọ-sókè-sódò làwọn èèyàn ti ń lo ọ̀pọ̀ àkókò tí ìdílé fi máa ń wà pa pọ̀ tẹ́lẹ̀ rí.
Ìṣòro ìṣúnná owó náà tún jẹ́ kókó kan. Àwọn nǹkan amáyédẹrùn ìgbàlódé máa ń náni lówó, èyí ló mú kí àwọn òbí tó ń ṣiṣẹ́ túbọ̀ máa pọ̀ sí i. Ṣíṣí kiri nítorí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ ti mú kí ọ̀pọ̀ nínú ìdílé máa gbé ọ̀nà jíjìn tàbí kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ níbi tó jìnnà síbi táwọn mọ̀lẹ́bí wọn ti lè ṣèrànwọ́. Nígbà míì pàápàá, àwọn èèyàn tiẹ̀ máa ń lọ gbé lọ́nà jíjìn síbi tí ọkọ wọn tàbí aya wọn wà. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àwọn àṣà tó lòde, irú bí sinimá àti eré ìnàjú, tún ti wá dá kún àwọn ìṣòro ọ̀hún, nítorí pé wọ́n sábà máa ń ṣàkóbá fún àwọn ètò tí ń fini lọ́kàn balẹ̀, irú bí ètò ìgbéyàwó àti ètò ìdílé.b
Àwọn Ìyá Anìkàntọ́mọ Òde Òní
Àwọn ìyá anìkàntọ́mọ tòde òní kò mọ sí irú àwọn tá a ti mọ̀ tipẹ́ mọ́ o, ìyẹn àwọn ọ̀dọ́ tí kò ṣègbéyàwó, tó jẹ́ pé ẹlòmíràn ló ń bá wọn gbé bùkátà wọn. Àwọn èèyàn ò tún ka dídi abiyamọ láìṣègbéyàwó sí ohun ìtìjú mọ́, àní àwọn ẹni táwọn èèyàn fi ń ṣe àwòkọ́ṣe tiẹ̀ ti wá sọ ọ́ di nǹkan gidi. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ obìnrin ló jẹ́ ọ̀mọ̀wé gidi tí wọ́n sì lè dá gbé bùkátà ara wọn láìwojú ẹnì kan, nípa bẹ́ẹ̀, ọkọ níní kì í ṣe dandan fún wọn kí wọ́n tó lè rówó fi tọ́mọ.
Àwọn ìyá kan tó ń dá tọ́mọ, pàápàá àwọn tó jẹ́ àgbà lára àwọn ọmọ tí àwọn òbí wọn ti kọra wọn sílẹ̀, yàn láti dá wà nítorí wọn ò fẹ́ kí ojú àwọn ọmọ tiwọn rí ohun tí ojú àwọn rí, tó jẹ́ pé ńṣe ni òbí wọn kan já wọn jù sílẹ̀. Ohun tó sọ àwọn obìnrin mìíràn di anìkàntọ́mọ ni pé, ńṣe ni ọkùnrin pa wọ́n tì, kì í ṣe pé ó wù wọ́n bẹ́ẹ̀. Ẹgbẹ́ Joseph Rowntree tó wà ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: “Dídátọ́mọ kì í fìgbà gbogbo jẹ́ nítorí ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan tàbí ohun téèyàn mọ̀ọ́mọ̀ ṣe, kò sì túmọ̀ sí pé àwọn ọmọ tó wà nínú irú ìdílé bẹ́ẹ̀ kì í rí ìtọ́jú tàbí pé wọn kì í lẹ́kọ̀ọ́ ilé.”
Síbẹ̀, bí àwọn ìdílé olóbìí kan ṣe túbọ̀ ń pọ̀ sí i jẹ́ ọ̀ràn kan tó ń fẹ́ àmójútó, nítorí pé àwọn òbí náà àtàwọn ọmọ wọn lè máa ní ẹ̀dùn ọkàn àti ìṣòro owó, tàbí kí wọ́n máa pàdánù àwọn àǹfààní kan láwùjọ. Àwọn èèyàn kan tiẹ̀ lè máa wò ó pé kò dájú pé òbí kan ṣoṣo lè dá tọ́mọ káwọn ọmọ ọ̀hún sì yàn, kí wọ́n yanjú. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìṣòro kíkàmàmà tí àwọn òbí tó ń dá tọ́mọ dojú kọ? Báwo ni Kristẹni kan ṣe lè kojú ìṣòro dídá tọ́mọ kó sì ṣe é láṣeyọrí?
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn onímọ̀ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá sọ pé àwọn ìyá tó ń dá tọ́mọ ‘pọ̀ ju àwọn bàbá tó ń dá tọ́mọ lọ fíìfíì.’ Fún ìdí yìí, àwọn ìyá tó ń dá tọ́mọ làwọn àpilẹ̀kọ yìí sọ̀rọ̀ nípa wọn jù. Àmọ́ ṣá o, àwọn ìlànà tá a jíròrò níbẹ̀ kan àwọn bàbá tó ń dá tọ́mọ náà.
b Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa onírúurú ìṣòro táwọn abiyamọ ń kojú, wo àpilẹ̀kọ náà, “Iṣẹ́ Abiyamọ—Ṣé O Lè Ṣe É Láṣeyanjú?” nínú ìtẹ̀jáde Jí! ti April 8, 2002.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]
Àwọn Orúkọ Kan Tí Wọ́n Máa Ń Pe Àwọn Ìyá Tó Ń Dá Tọ́mọ
Kárí ayé, oríṣiríṣi ọ̀nà làwọn èèyàn ń gbà pe àwọn ìyá tó jẹ́ pé àwọn nìkan ló ń dá tọ́mọ. Láwọn orílẹ̀-èdè kan, “ìyá anìkàntọ́mọ” ni wọ́n máa ń pe àwọn ìyá tí kò ṣègbéyàwó rí rárá, nígbà tó sì jẹ́ pé láwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, “màmá ń dá gbé” jẹ́ gbólóhùn kan tí wọ́n máa ń fi ṣàkópọ̀ gbogbo àwọn ìyá tó ń dá tọ́mọ láìgbé lọ́dọ̀ ọkùnrin kankan. Irú àwọn ìyá bẹ́ẹ̀ lè ti kọ ọkọ wọn sílẹ̀, ó lè jẹ́ pé ńṣe ni ọkọ wọn kú, tàbí kó jẹ́ pé wọn ò tiẹ̀ lọ́kọ rí.
Nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí, àwọn ọ̀rọ̀ náà, “òbí tó ń dá tọ́mọ” àti “ìyá tó ń dá tọ́mọ” la lò láti tọ́ka sí òbí tó ń nìkan tọ́ ọmọ láìsí ọkọ tàbí aya.
[Àpótí/Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 4, 5]
DÍDÁNÌKAN TỌ́MỌ—ÀṢÀ TÓ TÚBỌ̀ Ń GBILẸ̀ SÍ I NÍ Ọ̀PỌ̀ ORÍLẸ̀-ÈDÈ
Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà: “Iye àwọn ìyá tó ń dá tọ́mọ lọ sókè láti mílíọ̀nù mẹ́ta sí mílíọ̀nù mẹ́wàá láàárín ọdún 1970 sí ọdún 2000; láàárín àkókò kan náà, iye àwọn bàbá tó ń dá tọ́mọ náà lọ sókè, láti ọ̀kẹ́ mọ́kàndínlógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàáje [393,000] sí mílíọ̀nù méjì.”—Ẹ̀ka Ètò Ìkànìyàn Lórílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà.
Mẹ́síkò: Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn La Jornada ti sọ, àwọn ìyá tí kò tíì pé ọmọ ogún ọdún ló kó ìdá mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo oyún tí wọ́n ń ní lórílẹ̀-èdè yẹn.
Ireland: Iye àwọn ìdílé olóbìí kan ti lọ sókè láti nǹkan bí ìdá mẹ́fà nínú ọgọ́rùn-ún tí wọ́n jẹ́ lọ́dún 1981 sí nǹkan bí ìdá mẹ́jọ nínú ọgọ́rùn-ún lọ́dún 1991. “Ìgbéyàwó tó ń forí ṣánpọ́n ló ṣì jẹ́ olórí ohun tó ń fa dídi ìyá adátọ́mọ.”—Ìwé Single Mothers in an International Context, 1997.
Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì: “Iye àwọn ìdílé tó jẹ́ pé òbí kan ṣoṣo ni wọ́n ní ti ju ìdá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún lọ fún ìgbà àkọ́kọ́, èyí sì fi hàn pé iye àwọn ìyá tí wọn ò ṣègbéyàwó rí ń pọ̀ sí i gan-an, àti pé iye ìkọ̀sílẹ̀ ti ròkè lálá láàárín ọgbọ̀n ọdún tó kọjá.”—Ìwé ìròyìn The Times, ti ìlú London, March 2, 2000.
Ilẹ̀ Faransé: “Láti nǹkan bí ọdún 1977 títí di àkókò yìí, àwọn ìdílé olóbìí kan ti fi ohun tó lé ní ìdá àádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún ròkè sí i.”—Ìwé Single Mothers in an International Context, 1997.
Jámánì: “Iye òbí tó ń dá tọ́mọ ti di ìlọ́po méjì láwọn ẹ̀wádún méjì tó kọjá. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ìyá ló máa ń jẹ́ olórí nínú . . . gbogbo àwọn ìdílé olóbìí kan.”—Ìwé Single Mothers in an International Context, 1997.
Japan: ‘Láti ọdún 1970 sí 1979 ni àwọn ìdílé tó jẹ́ pé ìyá nìkan ni wọ́n ní ti ń pọ̀ sí i.’ Lọ́dún 1997, ìdá mẹ́tàdínlógún nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo ìdílé ló jẹ́ pé àwọn ìyá tó ń dá tọ́mọ ni olórí ibẹ̀.—Ìwé Single Mothers in an International Context, 1997; The World’s Women 2000: Trends and Statistics.
Gíríìsì: “Láti ọdún 1980, iye àwọn òbí tí kò ṣègbéyàwó ní orílẹ̀-èdè wa ti lọ sókè sí nǹkan bí ìdá ọgbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún. Gẹ́gẹ́ bí ìsọfúnni tó wá látọ̀dọ̀ Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù sì ṣe sọ, lọ́dún 1997, ìdá mẹ́ta ó lé díẹ̀ nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọ ni wọ́n bí lórílẹ̀-èdè yìí láìṣègbéyàwó, nígbà tó jẹ́ pé lọ́dún 1980, iye yìí kò ju ìdá kan nínú ọgọ́rùn-ún lọ.”—Ìwé ìròyìn Ta Nea, ti ìlú Áténì, September 4, 1998.
Ọsirélíà: Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ìkan nínú mẹ́rin àwọn ọmọ ló ń gbé pẹ̀lú bàbá nìkan tàbí ìyá nìkan. Èyí sábà máa ń jẹ́ nítorí ìgbéyàwó àwọn òbí náà tó forí ṣánpọ́n tàbí àjọṣe wọn tó dà rú. Wọ́n ti fojú bù ú pé, láàárín ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sígbà tá a wà yìí, ìdílé olóbìí kan ṣoṣo máa lọ sókè láti ìdá ọgbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún sí ìdá mẹ́rìndínláàádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún.—Ẹ̀ka Tó Ń Ṣàkójọ Ìsọfúnni ní Ilẹ̀ Ọsirélíà.