Ojú Ìwòye Bíbélì
Kí Ni Jíjẹ́ Olórí Ìdílé Túmọ̀ Sí?
GẸ́GẸ́ bí Bíbélì ṣe sọ, “orí obìnrin ni ọkùnrin.” (1 Kọ́ríńtì 11:3; Éfésù 5:23) Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ lára àwọn tó sọ pé àwọn ní ọ̀wọ̀ fún Bíbélì lérò pé kì í ṣe pé ìlànà nípa ipò orí ọkọ yìí ò bágbà mu mọ́ nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún léwu. Tọkọtaya kan ṣàlàyé pé: “Bí àṣejù bá wọ ọ̀nà táwọn èèyàn gbà ń lo ìlànà tó sọ pé káwọn obìnrin ‘fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ tẹrí ba’ [fáwọn ọkọ wọn], ó lè fa fífi ìyà jẹ wọ́n nípa tara, ó sì tún lè kó ẹ̀dùn ọkàn bá wọn.” Ó ṣeni láàánú pé lílo ipò orí lọ́nà tí kò tọ́ wọ́pọ̀, ó sì kárí ayé. Òǹkọ̀wé kan sọ pé: “Wọ́n ti ka lílu aya ẹni sí ohun tó ṣètẹ́wọ́gbà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè, wọ́n sì ti lo orin, òwe, àtàwọn ayẹyẹ ìgbéyàwó láti gbé ìwà yìí tí wọ́n rò pé ó jẹ́ ẹ̀tọ́ àwọn ọkùnrin lárugẹ.”
Àwọn kan sọ pé ìlànà Bíbélì nípa ipò orí ló súnná sáwọn ìwà òkú òǹrorò yìí. Ṣé lóòótọ́ ni ẹ̀kọ́ Bíbélì nípa ipò orí fi hàn pé àwọn obìnrin ò já mọ́ nǹkan kan tó sì wá fọwọ́ sí ìjà tó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ ọ̀ọ̀dẹ̀? Kí ni jíjẹ́ olórí ìdílé túmọ̀ sí gan-an?a
Ipò Orí Ò Túmọ̀ sí Jíjẹ́ Òǹrorò
Ìṣètò onífẹ̀ẹ́ ni ipò orí tí Bíbélì là kalẹ̀, kò sì fi ibì kankan jọ jíjẹ́ òǹrorò. Ìwà àìbọ̀wọ̀ fún òfin Ọlọ́run ló sábà máa ń fà á táwọn ọkùnrin fi máa ń jẹ gàba lé àwọn obìnrin lórí lọ́nà òǹrorò. (Jẹ́nẹ́sísì 3:16) Látinú ọgbà Édẹ́nì làwọn ọkùnrin ò ti yéé ṣi agbára wọn lò, tí wọ́n sì ń fìwà òǹrorò yan àwọn ẹlòmíràn jẹ, tó fi mọ́ àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé.
Àmọ́ ṣá o, ìyẹn ò fìgbà kan rí jẹ́ apá kan ète Ọlọ́run. Jèhófà kórìíra àwọn tó bá ń ṣi ọlá àṣẹ wọn lò. Ó dẹ́bi fáwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì tí wọ́n “ṣe àdàkàdekè” sáwọn aya wọn. (Málákì 2:13-16) Síwájú sí i, Ọlọ́run sọ pé “ọkàn [Òun] kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.” (Sáàmù 11:5) Nítorí náà, kò sí ọ̀nà kankan tí àwọn tó ń lu aya wọn àtàwọn míì tí wọ́n ń fìyà jẹ aya wọn lè gbà fi Bíbélì ti ìwà ipá tí wọ́n ń hù lẹ́yìn.
Kí Ló Wé Mọ́ Lílo Ipò Orí Lọ́nà Yíyẹ?
Ipò orí ni ètò àpilẹ̀ṣe tí Ọlọ́run ń lò láti mú kí gbogbo nǹkan máa lọ létòlétò láyé àti lọ́run. Gbogbo èèyàn pátá ló ní olórí, àyàfi Ọlọ́run nìkan. Kristi ni orí gbogbo ọkùnrin, àwọn òbí ni olórí àwọn ọmọ wọn, gbogbo Kristẹni sì wà lábẹ́ ìtẹríba fáwọn ìjọba. Kódà, Ọlọ́run ni orí Jésù.—Róòmù 13:1; 1 Kọ́ríńtì 11:3; 15:28; Éfésù 6:1.
Títẹríba fún ipò orí ṣe pàtàkì kí àwùjọ èèyàn bàa lè wà létòlétò kí ohun gbogbo sì máa lọ déédéé. Bákan náà, títẹrí ba fún olórí ìdílé ṣe pàtàkì bí ìdílé aláyọ̀ àti alálàáfíà bá ní láti wà. Àìsí ọkọ tàbí bàbá nínú ìdílé ò yí òtítọ́ yìí padà. Nínú irú àwọn ìdílé bẹ́ẹ̀ ìyá ni yóò gba ipò orí. Níbi tí ò bá ti sí ìyá tàbí bàbá, ọmọ tó dàgbà jù lọ tàbí ìbátan mìíràn lè gba ipò orí. Èyí ó wù kó jẹ́, àwọn mẹ́ńbà ìdílé máa ń jàǹfààní bí wọ́n bá fi ọ̀wọ̀ tó yẹ hàn fún ẹni tí ipò orí tọ́ sí.
Kókó pàtàkì tó wà níbẹ̀ ni láti má ṣe ta ko ìlànà ipò orí, àmọ́, ká kúkú kọ́ láti lo ipò orí lọ́nà yíyẹ ká sì fojú tó tọ́ wò ó. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn ọkọ tó jẹ́ Kristẹni níyànjú láti jẹ́ olórí agboolé wọn “bí Kristi pẹ̀lú ti jẹ́ orí ìjọ.” (Éfésù 5:21-23) Pọ́ọ̀lù tipa bẹ́ẹ̀ ṣàlàyé pé ọ̀nà tí Kristi gbà bá ìjọ lò ni àpẹẹrẹ pípé nípa bó ṣe yẹ ká lo ipò orí. Àpẹẹrẹ wo ni Kristi fi lélẹ̀?
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà àti Ọba lọ́la, látọ̀dọ̀ Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni ọlá àṣẹ Jésù ti wá, tí òun fúnra rẹ̀ lọ́gbọ́n nínú tó sì ní ìrírí nípa ìgbésí ayé ju àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ, ó jẹ́ onífẹ̀ẹ́, ọlọ́yàyà àti aláàánú. Kì í ṣe ẹni líle, kìígbọ́-kìígbà, tàbí ẹni tó máa ń rin kinkin mọ́ nǹkan. Kì í fi agbára tó ní ṣakọ, kó wá máa rán olúkúlùkù létí pé òun ni Ọmọ Ọlọ́run. Onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn àyà ni Jésù. Ìdí nìyẹn tí ‘àjàgà rẹ̀ fi jẹ́ ti inú rere ti ẹrù rẹ̀ sì fúyẹ́.’ (Mátíù 11:28-30) Nítorí náà, ẹni tó ṣeé sún mọ́ ni, ó sì máa ń gba tàwọn ẹlòmíràn rò. Kódà, Pọ́ọ̀lù sọ pé Jésù fẹ́ràn ìjọ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi “jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lọ́wọ́ fún un.”—Éfésù 5:25.
Báwo Lèèyàn Ṣe Lè Ṣàfarawé Ipò Orí Jésù?
Báwo làwọn olórí ìdílé ṣe lè ṣàfarawé àwọn ànímọ́ Kristi? Olórí ìdílé tó mọṣẹ́ ẹ̀ níṣẹ́ máa ń ṣàníyàn nípa ire ìdílé rẹ̀ nípa tara àti tẹ̀mí. Ó máa ń sa gbogbo ipá rẹ̀ nípa lílo àkókò tó pọ̀ tó láti ṣe ohun tí wọ́n nílò lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àti lápapọ̀ fún wọn. Ire ìyàwó rẹ̀ àti tàwọn ọmọ ló máa ń jẹ ẹ́ lọ́kàn ju ire ara rẹ̀ lọ.b (1 Kọ́ríńtì 10:24; Fílípì 2:4) Bí ọkọ bá ń fi àwọn ìlànà Bíbélì àtàwọn ẹ̀kọ́ tó fi ń kọ́ni sílò nínú ìgbésí ayé rẹ̀ lójoojúmọ́, aya àtàwọn ọmọ rẹ̀ á bọ̀wọ̀ fún un wọ́n á sì tì í lẹ́yìn. Lábẹ́ ipò orí rẹ̀ tó jẹ́ onífẹ̀ẹ́, ìsápa wọn ò ní máa já sí pàbó bí wọ́n bá ń jùmọ̀ bójú tó ìṣòro èyíkéyìí. Ní títipa báyìí lo ipò orí lọ́nà tó bá Ìwé Mímọ́ mu, ọkọ á dẹni tó ní ìdílé aláyọ̀, ọ̀kan tó ń mú ìyìn àti ògo bá orúkọ Ọlọ́run.
Olórí ìdílé tó bá gbọ́n tún máa ń hùwà ìrẹ̀lẹ̀. Bó bá pọn dandan, kò ní lọ́ tìkọ̀ láti tọrọ àforíjì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè ṣòro fún un láti gbà pé òun jẹ̀bi. Bíbélì sọ pé ìgbàlà wà “nínú ògìdìgbó àwọn agbani-nímọ̀ràn.” (Òwe 24:6) Bẹ́ẹ̀ ni, ìwà ìrẹ̀lẹ̀ á tún sún olórí ìdílé láti tẹ́tí sí ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀ kó sì wádìí èrò wọn nígbà tó bá yẹ kó ṣe bẹ́ẹ̀. Nípa fífarawé Jésù, Kristẹni kan tó jẹ́ olórí ìdílé á rí i dájú pé kì í wulẹ̀ ṣe pé ipò orí òun mú kí ìdílé láyọ̀ kó sì fara rọ nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún ń mú ìyìn àti ògo bá Jèhófà Ọlọ́run, Ẹni tó dá ètò ìdílé sílẹ̀.—Éfésù 3:14, 15.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ipa ti ọkọ tó sì tún jẹ́ bàbá nínú ìdílé la dìídì jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí, àwọn òbí anìkàntọ́mọ àtàwọn ọmọ aláìlóbìí tó di dandan kí wọ́n tọ́jú àwọn àbúrò wọn náà lè jàǹfààní látinú àwọn ìlànà tá a fún àwọn olórí ìdílé.
b Àwọn àbá gbígbéṣẹ́ nípa béèyàn ṣe lè bójú tó ìdílé tìfẹ́tìfẹ́ wà nínú ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Ọkọ kan tó mọ inú rò máa ń gba èrò ìyàwó àti tàwọn ọmọ rẹ̀ rò