OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ
Iṣẹ́
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti pẹ́ tí wọ́n ti kọ Bíbélì, àwọn ìlànà rẹ̀ ṣì wúlò fún wa lóde òní. Bí ohun tí Bíbélì sọ nípa iṣẹ́ ṣe wúlò láyé àtijọ́, bẹ́ẹ̀ náà làwọn ìlànà yẹn wúlò títí dòní.
Irú ọwọ́ wo ló yẹ ká fi mú iṣẹ́?
OHUN TÁWỌN KAN SỌ
Ọ̀pọ̀ gbà pé kéèyàn tó lè rọ́wọ́ mú lẹ́nu iṣẹ́, ó gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ bí akúra. Èyí ti mú kí àwọn kan tara bọ iṣẹ́ débi tí wọn kò fi ráyè ti ìdílé wọn mọ́, wọn ò sì mójú tó ìlera wọn.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn pé ká fi iṣẹ́ sí àyè rẹ̀. Ó ní ká fara ṣiṣẹ́, ká má sì jẹ́ ọ̀lẹ. (Òwe 6:6-11; 13:4) Síbẹ̀, Bíbélì kò sọ pé ká máa ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbà wá níyànjú pé ká máa wáyè sinmi dáadáa. Oníwàásù 4:6 sọ pé: “Ẹ̀kúnwọ́ kan ìsinmi sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì iṣẹ́ àṣekára àti lílépa ẹ̀fúùfù.” Torí náà, kò yẹ kí iṣẹ́ gbà wá lọ́kàn débi tá a máa fi pa ìdílé wa tì, tí a kò sì ní mójú tó ìlera wa. Òótọ́ kan ni pé, kìràkìtà ò dọlà, ká ṣiṣẹ́ bí ẹrú kò da nǹkan kan fúnni!
“Fún ènìyàn, kò sí ohun tí ó sàn ju pé kí ó máa jẹ kí ó sì máa mu ní tòótọ́, kí ó sì jẹ́ kí ọkàn òun rí ohun rere nítorí iṣẹ́ àṣekára rẹ̀.”—Oníwàásù 2:24.
Irú iṣẹ́ wo ló yẹ ká ṣe?
OHUN TÁWỌN KAN SỌ
Kò síṣẹ́ tí kò dáa tí owó gidi bá ṣáà ti yọ. Torí owó òjijì táwọn kan ń wá, ńṣe ni wọ́n máa ń lu àwọn èèyàn ní jìbìtì tàbí kí wọ́n ṣe àwọn iṣẹ́ míì tí kò bófin mu.
Àwọn kan wà tó jẹ́ pé iṣẹ́ tó bá wù wọ́n nìkan ni wọ́n máa ń fẹ́ ṣe. Tí iṣẹ́ míì bá yọjú yàtọ̀ sí èyí tí wọ́n ní lọ́kàn, wọ́n lè máa ṣakọ pé iṣẹ́ náà bu àwọn kù, kí wọ́n sì kọ̀ ọ́ tàbí kí wọ́n fọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ mú iṣẹ́ ọ̀hún.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Bíbélì dẹ́bi fún lílu jìbìtì tàbí ká máa kó àwọn míì nífà. (Léfítíkù 19:11, 13; Róòmù 13:10) Ṣùgbọ́n, iṣẹ́ gidi máa ń ṣe àwọn míì láǹfààní, ó sì máa ń jẹ́ kéèyàn ní “ẹ̀rí-ọkàn rere.”—1 Pétérù 3:16.
Bíbélì tún sọ olórí ìdí tá a fi ń ṣiṣẹ́, kì í ṣe torí ká lè ṣiṣẹ́ tá a nífẹ̀ẹ́ sí, bí kò ṣe ká lè rówó gbọ́ bùkátà. Kò sóhun tó burú téèyàn bá fẹ́ràn irú iṣẹ́ kan, àmọ́ ká fi sọ́kàn pé torí ká lè bójú tó ara wa àti ìdílé wa lá ṣe ń ṣiṣẹ́. Ó ṣe tán, iṣẹ́ lòògùn ìṣẹ́.
Ká sòótọ́, owó ọjà tó ń wọ́n sí i lójoojúmọ́ lè mú ká máa ṣàníyàn nípa bá a ṣe máa gbọ́ bùkátà. Àmọ́ Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, ó ní: “Bí a bá ti ní ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ, àwa yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí.” (1 Tímótì 6:8) Àmọ́, a kò wá ní tìtorí pé a fẹ́ wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, ká wá máa rùnpà. Síbẹ̀, ó yẹ ká mọ ohun tágbára wá ká, ká sì wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì tó bá dọ̀rọ̀ àwọn nǹkan ìní tá à ń rà.—Lúùkù 12:15.
BÓ ṢE KÀN Ẹ́
Ó yẹ kó o tẹpá mọ́ṣẹ́, kó o sì fọkàn sí ìṣẹ́ rẹ, ó ṣe tán, apá lará ìgúnpá ni iyèkan. Tó bá tiẹ̀ jẹ́ iṣẹ́ tí kò fi bẹ́ẹ̀ jọjú lò ń ṣe tàbí tí o kò fẹ́ràn iṣẹ́ náà, sapá láti di ọ̀jáfáfá lẹ́nu rẹ̀. Tó o bá ń ṣiṣẹ́ kára, wàá láyọ̀ torí ò ń gbé nǹkan gidi ṣe nìyẹn. Tó o bá sì jáfáfá lẹ́nu iṣẹ́, wàá túbọ̀ gbádùn iṣẹ́ náà dáadáa.
Àmọ́ o, má ṣe sọ ara rẹ di ẹrú iṣẹ́. Máa wáyè sinmi, kó o sì máa ṣeré. Tó o bá sinmi lẹ́yìn tó o ti ṣiṣẹ́ dáadáa, ìsinmi náà máa tù ẹ́ lára. Tó o bá ń rówó gbọ́ bùkátà ara rẹ, ọkàn rẹ á balẹ̀, wàá níyì lójú àwọn èèyàn, àwọn ìdílé rẹ sì máa bọ̀wọ̀ fún ẹ.—2 Tẹsalóníkà 3:12.
“Ẹ má ṣàníyàn láé, kí ẹ sì wí pé, ‘Kí ni a ó jẹ?’ tàbí, ‘Kí ni a ó mu?’ tàbí, ‘Kí ni a ó wọ̀?’ . . . Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo nǹkan wọ̀nyí.”—Mátíù 6:31, 32.