Ojú Ìwòye Bíbélì
Àgbélébùú
Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé lílo àgbélébùú ló máa jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Kristẹni làwọn. Síbẹ̀, kì í ṣe gbogbo èèyàn ló gbà pé ó yẹ kéèyàn máa gbé àgbélébùú kọ́rùn tàbí gbé e kọ́ sára ilé tàbí ṣọ́ọ̀ṣì.
Ṣé orí àgbélébùú ni Jésù kú sí?
OHUN TÁWỌN KAN SỌ
Orí àgbélébùú, ìyẹn igi méjì tí wọ́n gbé dábùú ara wọn ni àwọn ara Róòmù kan Jésù mọ́.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Wọ́n pa Jésù nípa “gbígbé kọ́ sí orí igi.” (Ìṣe 5:30, Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní) Ọ̀rọ̀ méjèèjì tí àwọn tó kọ Bíbélì lò láti ṣàpèjúwe ohun tí wọ́n fi pa Jésù fi hàn pé kì í ṣe igi méjì, bí kò ṣe igi kan ṣoṣo. Gẹ́gẹ́ bí ìwé Crucifixion in Antiquity, ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà stau·rosʹ, túmọ̀ sí “igi kan ṣoṣo. Kì í sì í ṣe ohun kan náà pẹ̀lú ‘àgbélébùú.’ ” Ọ̀rọ̀ náà xyʹlon, tí wọ́n lò nínú Ìṣe 5:30, jẹ́ “òpó igi tó dúró ṣánṣán, orí rẹ̀ làwọn ará Róòmù máa ń kan èèyàn tí wọ́n fẹ́ pa mọ́.”a
Bíbélì tún fi hàn pé ọ̀nà tí wọ́n gbà pa Jésù bá ọ̀kan lára òfin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mu. Òfin náà sọ pé: “Bí ó bá sì wá ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin kan ní ẹ̀ṣẹ̀ tí ó yẹ fún ìdájọ́ ikú, tí a sì fi ikú pa á, tí ìwọ sì ti gbé e kọ́ sórí òpó igi, . . . ohun ègún Ọlọ́run ni ẹni tí a gbé kọ́.” (Diutarónómì 21:22, 23) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó jẹ́ Kristẹni tọ́ka sí òfin yìí nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa Jésù, ó ní ó di “ègún dípò wa, nítorí a kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Ẹni ègún ni olúkúlùkù ènìyàn tí a gbé kọ́ sórí òpó igi [xyʹlon].’ ” (Gálátíà 3:13) Pọ́ọ̀lù tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé orí òpó igi ni Jésù kú sí, ìyẹn igi kan ṣoṣo.
“Ẹni tí wọ́n pa nípa gbígbékọ́ sí orí igi.”—Ìṣe 10:39, Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní.
Ṣé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù lo àgbélébùú láti jọ́sìn Ọlọ́run tàbí kí wọ́n fi ṣe àmì ìdánimọ̀ ẹ̀sìn Kristẹni?
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Kò sí ibì kankan tí Bíbélì ti sọ pé àwọn Kristẹni ìjimìjí lo àgbélébùú gẹ́gẹ́ bí àmì táwọn èèyàn á fi dá wọn mọ̀ bíi Kristẹni. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn ará Róòmù ayé ìgbà yẹn ló ń fi àgbélébùú ṣe àmì òrìṣà wọn. Ní nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún [300] ọdún lẹ́yìn ikú Jésù, Constantine tó jẹ́ Olú Ọba Róòmù bẹ̀rẹ̀ sí í lo àgbélébùú bí àmì àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ẹ̀yìn ìgbà yẹn làwọn oníṣọ́ọ̀ṣì náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í lò ó.
Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn abọ̀rìṣà ló ń lo àgbélébùú nínú ìjọsìn wọn, ṣé ó máa mọ́gbọ́n dání fáwọn ọmọlẹ́yìn Jésù pé kí wọ́n máa lò ó nínú ìjọsìn Ọlọ́run tòótọ́? Rárá o, torí wọ́n mọ̀ pé ọjọ́ pẹ́ tí Ọlọ́run kò ti fọwọ́ sí lílo “ìrísí àpẹẹrẹ èyíkéyìí” àti pé àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ “sá fún ìbọ̀rìṣà.” (Diutarónómì 4:15-19; 1 Kọ́ríńtì 10:14) “Ọlọ́run jẹ́ Ẹ̀mí,” àwa èèyàn kò sì lè rí i. Torí náà, àwọn Kristẹni ìjimìjí kò lo àmì tàbí ìrísí èyíkéyìí kí wọ́n báa lè sún mọ́ Ọlọ́run. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń jọ́sìn Ọlọ́run “ní ẹ̀mí,” ìyẹn ni pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ló ń darí wọn, wọ́n sì ń jọ́sìn rẹ̀ ní “òtítọ́,” ìyẹn ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run bí Ìwé Mímọ́ ṣe sọ.—Jòhánù 4:24.
“Àwọn olùjọsìn tòótọ́ yóò máa jọ́sìn Baba ní ẹ̀mí àti òtítọ́.”—Jòhánù 4:23.
Báwo làwọn Kristẹni tòótọ́ ṣe lè máa fi ọ̀wọ̀ hàn fún Jésù Kristi?
OHUN TÁWỌN KAN SỌ
“Ohun tó bójú mu tó sì tọ́ ni pé ká máa fi ọ̀wọ̀ fún ohun èlò ìgbàlà ká sì máa buyì fún un. . . . Ẹni tó bá ń buyì fún ohun èlò yìí ń buyì fún ẹni tí ohun èlò náà ṣàpẹẹrẹ.”—New Catholic Encyclopedia.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Àwọn Kristẹni mọyì Jésù, torí pé ikú rẹ̀ ló ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún wọn láti rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà, kí wọ́n lè gbàdúrà sí Ọlọ́run kí wọ́n sì rí ìyè ayérayé. (Jòhánù 3:16; Hébérù 10:19-22) Bíbélì ò sọ pé gbígbé àmì Jésù kiri tàbí fífi ẹnu lásán sọ pé àwọn nígbàgbọ́ nínú Jésù ló máa fi hàn pé wọ́n mọyì ẹ̀bùn yìí. Ó ṣetán, “ìgbàgbọ́, bí kò bá ní àwọn iṣẹ́, jẹ́ òkú nínú ara rẹ̀.” (Jákọ́bù 2:17) Àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ fi hàn pé àwọn ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù. Lọ́nà wo?
Bíbélì sọ pé: “Nítorí ìfẹ́ tí Kristi ní sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún wa, nítorí èyí ni ohun tí àwa ti ṣèdájọ́, pé ọkùnrin kan kú fún gbogbo ènìyàn . . . kí àwọn tí ó wà láàyè má ṣe tún wà láàyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tí ó kú fún wọn, tí a sì gbé dìde.” (2 Kọ́ríńtì 5:14, 15) Ìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ tí Kristi fi hàn sí aráyé mú kó di ọ̀ranyàn fún àwọn Kristẹni tòótọ́ láti ṣàtúnṣe ìgbésí ayé wọn, kí wọ́n lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. Wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ bọlá fún Jésù lọ́nà tó nítumọ̀ ju pé kí wọ́n kàn máa gbé àmì ìjọsìn kan kiri lọ.
“Èyí ni ìfẹ́ Baba mi, pé gbogbo ẹni tí ó rí Ọmọ tí ó sì lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ yóò ní ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 6:40.
a Ìwé A Critical Lexicon and Concordance to the English and Greek New Testament, Ẹ̀dà Kọkànlá, látọwọ́ Ethelbert W. Bullinger, ojú ìwé 818 àti 819.