OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ
Orúkọ Ọlọ́run
Àìmọye èèyàn ló máa ń pe Ọlọ́run ní àwọn orúkọ oyè bí Olúwa, Ẹni ayérayé, Álà tàbí Ọlọ́run. Àmọ́ Ọlọ́run ní orúkọ tiẹ̀ gangan. Ṣé ó yẹ kí a máa lò ó?
Kí ni Orúkọ Ọlọ́run?
OHUN TÁWỌN KAN SỌ
Ọ̀pọ̀ àwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni gbà gbọ́ pé Jésù ni orúkọ Ọlọ́run. Àwọn míì gbà pé torí pé Ọlọ́run Olódùmarè kan ṣoṣo ló wà, kò pọn dandan ká lo orúkọ kan pàtó fún un. Síbẹ̀, àwọn míì sọ pé kò tọ̀nà rárá láti lo orúkọ àpèlé kankan fún Ọlọ́run.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Jésù kọ́ ni Ọlọ́run Olódùmarè. Torí náà, Jésù kì í ṣe orúkọ Ọlọ́run. Kódà, Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Baba, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.” (Lúùkù 11:2) Jésù fúnra rẹ̀ gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo.”—Jòhánù 12:28.
Nínú Bíbélì, Ọlọ́run sọ pé: “Èmi ni Jèhófà. Èyí ni orúkọ mi; Èmi kì yóò sì fi ògo mi fún ẹlòmíràn.” (Aísáyà 42:8) Lẹ́tà Hébérù mẹ́rin náà YHWH, tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run la túmọ̀ sí “Jèhófà,” lédè Yorùbá. Orúkọ yẹn fara hàn ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje [7000] ìgbà nínú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù.a Ó fara hàn ju orúkọ oyè bí “Ọlọ́run,” “Olódùmarè,” tàbí “Olúwa” lọ. Kódà, ó tún fara hàn ju àwọn orúkọ míì bí Ábúráhámù, Mósè, tàbí Dáfídì lọ.
Kò síbì kankan nínú Bíbélì tí Jèhófà ti sọ pé ká má ṣe lo orúkọ òun. Ìwé Mímọ́ fi hàn pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lo orúkọ Ọlọ́run fàlàlà. Kódà, wọ́n fi sí ara orúkọ tí wọ́n fún àwọn ọmọ wọn. Àpẹẹrẹ irú rẹ̀ ni Èlíjà tó túmọ̀ sí “Jèhófà ni Ọlọ́run Mi,” òmíràn ni Sekaráyà tí ó túmọ̀ sí “Jèhófà ti Rántí.” Àwọn èèyàn náà kò tijú rárá láti lo orúkọ Ọlọ́run nínú ìjíròrò wọn ojoojúmọ́.—Rúùtù 2:4.
Ọlọ́run fẹ́ ká máa lo orúkọ òun. Bíbélì tiẹ̀ rọ̀ wá pé “Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà, ẹ ké pe orúkọ rẹ̀.” (Sáàmù 105:1) Kódà, Jèhófà máa ń “fiyè sí . . . àwọn tí ń ronú lórí orúkọ rẹ̀.”—Málákì 3:16.
“Kí àwọn ènìyàn lè mọ̀ pé ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”—Sáàmù 83:18.
Kí ni orúkọ Ọlọ́run túmọ̀ sí?
Àwọn ọ̀mọ̀wé kan gbà gbọ́ pé lédè Hébérù, orúkọ náà Jèhófà túmọ̀ sí “Alèwílèṣe.” Èyí fi hàn pé Ọlọ́run lè di ohunkóhun tàbí kó mú kí ìṣẹ̀dá rẹ̀ di ohukóhun kí ohun tó ní lọ́kàn lè ṣẹ. Ẹlẹ́dàá Olódùmarè nìkan ló tọ́ ká máa pè ní orúkọ yìí.
ÀǸFÀÀNÍ TÓ MÁA ṢE FÚN Ẹ
Tó o bá mọ orúkọ Ọlọ́run, á jẹ́ kí èrò tí o ní nípa rẹ̀ yàtọ̀. Wàá túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. Ó ṣe tán, kò ṣeé ṣe láti sún mọ́ ẹni tí èèyàn ò mọ orúkọ rẹ̀. Ti pé Ọlọ́run sọ orúkọ rẹ̀ fún wa fi hàn pé ó fẹ́ ká sún mọ́ òun.—Jákọ́bù 4:8.
Jẹ́ kí ó dá ẹ lójú pé Ọlọ́run máa ṣe ohunkóhun tó bá ní lọ́kàn láti ṣe. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé: “Àwọn tí o mọ orúkọ rẹ yóò sì gbẹ́kẹ̀ lé ọ.” (Sáàmù 9:10) Ìdánilójú rẹ á túbọ̀ lágbára bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Jèhófà tí o sì wá mọ̀ pé orúkọ rẹ̀ so mọ́ àwọn ànímọ́ rẹ̀ bí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, àánú, ìyọ́nú àti ìdájọ́ òdodo. (Ẹ́kísódù 34:5-7) Ó fini lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà máa ń pa ìlérí rẹ̀ mọ́, kò sì ní ṣe ohun tó lòdì sí àwọn ànímọ́ rẹ̀.
Láìsí tàbí ṣùgbọ́n, àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé a mọ orúkọ tí Ọlọ́run Olódùmarè ń jẹ́ gangan. Á jẹ́ ká rí ìbùkún gbà ní báyìí àti lọ́jọ́ iwájú. Ọlọ́run ṣèlérí pé: “Èmi yóò dáàbò bò ó nítorí pé ó ti wá mọ orúkọ mi.”—Sáàmù 91:14.
“Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni yóò yè bọ́.”—Jóẹ́lì 2:32.
a Nínú ọ̀pọ̀ Bíbélì, wọ́n ti yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò, wọ́n sì fi “OLÚWA” èyí tí wọ́n kọ ní lẹ́tà gàdàgbà, rọ́pò rẹ̀. Nínú àwọn Bíbélì míì, ìwọ̀nba àwọn ẹsẹ mélòó kan àti àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé ni wọ́n kọ orúkọ náà sí. Àmọ́ orúkọ náà fara hàn lọ́pọ̀ ìgbà nínú Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.