Lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣe kìràkìtà torí àtijẹ àtimu lójoojúmọ́, ṣe nìyẹn sì túbọ̀ ń nira torí bí nǹkan ṣe ń dojú rú láyé yìí. Kí nìdí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀?
Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀ níbì kan tàbí tí nǹkan ò rí bó ṣe yẹ kó rí, àwọn nǹkan á gbówó lórí, irú bí owó ilé àti owó oúnjẹ.
Tí nǹkan bá dojú rú nílùú, iṣẹ́ lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn èèyàn tàbí kí owó tó ń wọlé fún wọn dín kù.
Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, ó lè ba ohun ìní àwọn èèyàn jẹ́, kíyẹn sì sọ wọ́n di òtòṣì.
Ohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀
Tó o bá mọ béèyàn ṣe ń ṣọ́wó ná, ìyẹn ò ní jẹ́ kí nǹkan nira jù fún ẹ nígbà ìṣòro.
Fi sọ́kàn pé nǹkan lè yí pa dà nígbàkigbà. Owó tàbí ohun ìní rẹ lè má níyì mọ́ tó bá dọ̀la.
Tẹ́nì kan bá lówó, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ó máa láyọ̀ tàbí pé ìdílé ẹ̀ máa wà níṣọ̀kan.
Ohun Tó O Lè Ṣe Ní Báyìí
Bíbélì sọ pé: “Tí a bá ti ní oúnjẹ àti aṣọ, àwọn nǹkan yìí máa tẹ́ wa lọ́rùn.”—1 Tímótì 6:8.
Tó o bá ní ìtẹ́lọ́rùn, o ò ní máa wá àwọn nǹkan tó kàn wù ẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, inú ẹ á máa dùn ọkàn ẹ á sì balẹ̀ tó o bá ti rí àwọn ohun pàtàkì tó o nílò. Èyí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ gan-an tí nǹkan bá yí pa dà fún ẹ.
Kó o lè ní ìtẹ́lọ́rùn, o máa ní láti ṣe àwọn àtúnṣe pàtàkì kan. Bí àpẹẹrẹ, á dáa kó o máa ṣọ́wó ná, kó o má sì ṣe ju agbára ẹ lọ. Torí tó o bá ń ná ju iye tó ń wọlé fún ẹ, ìyẹn lè mú kí nǹkan nira.