ÌTÀN 6
Ọmọ Rere Àti Ọmọ Búburú
WO KÉÈNÌ àti Ébẹ́lì. Àwọn méjèèjì ti dàgbà. Iṣẹ́ àgbẹ̀ ni Kéènì ń ṣe. Ó ń gbin ọkà àti èso àti ewébẹ̀.
Ébẹ́lì ti di olùṣọ́ àgùntàn. Ó fẹ́ràn láti máa tọ́jú àwọn àgùntàn kéékèèké. Àwọn àgùntàn náà dàgbà, nítorí náà, kò pẹ́ tí Ébẹ́lì fi ní agbo àgùntàn ńlá táá máa tọ́jú.
Lọ́jọ́ kan Kéènì àti Ébẹ́lì mú ọrẹ wá fún Ọlọ́run. Kéènì mú díẹ̀ nínú àwọn ohun jíjẹ tó gbìn wá. Ébẹ́lì sì mú èyí tó dára jù lọ nínú àwọn àgùntàn rẹ̀ wá. Inú Jèhófà dùn sí Ébẹ́lì àti ọrẹ tó mú wá. Ṣùgbọ́n inú Ọlọ́run kò dùn sí Kéènì àti ọrẹ rẹ̀. Ǹjẹ́ o mọ ìdí?
Kì í wulẹ̀ẹ́ ṣe torí pé ọrẹ Ébẹ́lì dára ju ti Kéènì lọ o. Kàkà bẹ́ẹ̀ ó jẹ́ nítorí pé Ébẹ́lì jẹ́ ẹni rere. Ó fẹ́ràn Jèhófà ó sì fẹ́ràn ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Ṣùgbọ́n èèyàn búburú ni Kéènì; kò fẹ́ràn àbúrò rẹ̀.
Nítorí náà Ọlọ́run sọ fún Kéènì pé kó yí ìwà rẹ̀ padà. Ṣùgbọ́n Kéènì kọ̀ kò gbọ́. Inú rẹ̀ ò dùn torí pé Ọlọ́run fẹ́ràn Ébẹ́lì ju òun lọ. Nítorí náà, lọ́jọ́ kan, Kéènì sọ fún Ébẹ́lì pé, ‘Jẹ́ kí á kọjá lọ sínú pápá.’ Nígbà táwọn méjèèjì jọ wà nínú oko, Kéènì la nǹkan mọ́ Ébẹ́lì àbúrò rẹ̀. Ó là á mọ́ ọn tagbára-tagbára tó bẹ́ẹ̀ tó fi pa á. Ǹjẹ́ o ò rí i pé ohun tí Kéènì ṣe yìí burú jáì?
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ébẹ́lì kú, Ọlọ́run ṣì rántí rẹ̀. Ẹni rere ni Ébẹ́lì, Jèhófà kì í sì í gbàgbé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, ní ọjọ́ kan, Jèhófà Ọlọ́run yóò mú Ébẹ́lì padà bọ̀ sí ìyè. Ní àkókò yẹn, kò tún ní sí ìdí fún Ébẹ́lì láti kú mọ́. Yóò máa wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Ǹjẹ́ inú rẹ kò ní dùn láti tún rí àwọn èèyàn bí Ébẹ́lì?
Àmọ́ o, inú Ọlọ́run kò dùn sáwọn èèyàn bíi Kéènì. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé lẹ́yìn tí Kéènì pa àbúrò rẹ̀, Ọlọ́run fi ìyà jẹ ẹ́ nípa lílé e jìnnà kúrò lọ́dọ̀ àwọn ará ilé rẹ̀ yòókù. Nígbà tí Kéènì ń lọ láti máa gbé ní apá ibòmíràn ní ayé, ó mú ọ̀kan lára àwọn àbúrò rẹ̀ obìnrin dání pẹ̀lú rẹ̀, èyí ló sì di aya rẹ̀.
Nígbà tó ṣe, Kéènì àti aya rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í bímọ. Àwọn ọmọ Ádámù àti Éfà mìíràn ṣe ìgbéyàwó, àwọn pẹ̀lú sì bí àwọn ọmọ. Kò pẹ́ kò jìnnà, èèyàn di púpọ̀ láyé. Jẹ́ ká gbọ́ nípa díẹ̀ nínú wọn.