ÌTÀN 9
Nóà Kan Ọkọ̀ Áàkì
NÓÀ ní ìyàwó kan àti ọmọkùnrin mẹ́ta. Orúkọ àwọn ọmọ rẹ̀ náà ni Ṣémù, Hámù àti Jáfẹ́tì. Àwọn ọmọ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí sì ní ìyàwó kọ̀ọ̀kan. Nítorí náà, èèyàn mẹ́jọ ló wà nínú ìdílé Nóà.
Ọlọ́run wá mú kí Nóà ṣe nǹkan tó yàtọ̀ pátápátá. Ó sọ fún un pé kó kan ọkọ̀ áàkì ńlá kan. Ọkọ̀ yìí tóbi bí ọkọ̀ ojú omi ńlá, ṣùgbọ́n bí àpótí gígùn ńlá kan ló ṣe rí. Ọlọ́run sọ fún un pé, ‘Kàn án ní olókè mẹ́ta, kó o sì ṣe yàrá sí inú rẹ̀.’ Nóà, ìdílé rẹ̀ àtàwọn ẹranko ni yóò máa gbé inú àwọn yàrá náà, wọn yóò sì tún kó oúnjẹ tí gbogbo wọn yóò máa jẹ síbẹ̀.
Ọlọ́run tún sọ fún Nóà pé kó kan ọkọ̀ yìí lọ́nà tí omi kò fi ní lè wọ inú rẹ̀. Ọlọ́run wí pé: ‘Èmi yóò rán ìkún-omi ńlá láti pa gbogbo ayé run. Gbogbo ẹni tí kò bá sí nínú ọkọ̀ náà yóò kú.’
Nóà àtàwọn ọmọ rẹ̀ ṣe ìgbọràn sí Jèhófà wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kan ọkọ̀ náà. Ṣùgbọ́n ńṣe ni àwọn èèyàn yòókù ń fi wọ́n rẹ́rìn-ín. Wọn ò dẹ́kun àti máa ṣe búburú. Kò sẹ́ni tó gba Nóà gbọ́ nígbà tó sọ ohun tí Ọlọ́run máa ṣe fún wọn.
Ó pẹ́ kí wọ́n tó kan ọkọ̀ náà tán nítorí ó tóbi gan-an. Níkẹyìn, lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, wọ́n parí rẹ̀. Ọlọ́run wá sọ fún Nóà pé kó mú àwọn ẹranko wọ inú ọkọ̀. Ọlọ́run sọ pé kó mú irú àwọn ẹranko kan ní méjì-méjì, akọ àti abo. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún un pé kó mú irú àwọn ẹranko mìíràn ní méje-méje. Ọlọ́run tún sọ fún Nóà pé kó mú gbogbo onírúurú àwọn ẹyẹ wọlé. Nóà ṣe gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti wí gan-an.
Níkẹyìn, Nóà àti ìdílé rẹ̀ pẹ̀lú wọ inú ọkọ̀. Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run ti ilẹ̀kùn. Nóà àti ìdílé rẹ̀ dúró sínú ọkọ̀ lọ́hùn-ún. Jẹ́ ká sọ pé o wà nínú ọkọ̀ náà pẹ̀lú wọn, tẹ́ ẹ̀ ń retí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀. Ṣé lóòótọ́ ni ìkún-omi yóò dé bí Ọlọ́run ti wí?