ÌTÀN 13
Ábúráhámù—Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run
Ọ̀KAN lára àwọn ibi táwọn èèyàn ṣí lọ láti máa gbé lẹ́yìn Ìkún-omi ni ìlú Úrì. Ìlú yìí di ìlú ńlá pàtàkì kan tó ní àwọn ilé dáradára. Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́run èké ni àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ ń sìn. Ohun tí wọ́n ṣe ní Bábélì gan-an náà nìyẹn. Àwọn èèyàn tó wà ní Úrì àti Bábélì kò dà bíi Nóà àti Ṣémù ọmọ rẹ̀, tí wọn kò yéé máa sin Jèhófà.
Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé àádọ́ta [350] ọdún lẹ́yìn Ìkún-omi, Nóà kú. Ọdún méjì lẹ́yìn ikú rẹ̀ ni wọ́n sì bí ọkùnrin tó ò ń wò nínú àwòrán yìí. Ẹnì kan tí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ sí gidigidi ni ọkùnrin yìí. Ábúráhámù ni orúkọ rẹ̀. Òun àtàwọn èèyàn rẹ̀ ń gbé ní ìlú Úrì.
Lọ́jọ́ kan Jèhófà sọ fún Ábúráhámù pé: ‘Jáde kúrò ní Úrì kó o sì fi àwọn ẹbí rẹ sílẹ̀, kó o lọ sí orílẹ̀-èdè kan tí èmi óò fi hàn ọ́.’ Ǹjẹ́ Ábúráhámù ṣe bí Ọlọ́run ṣe wí yìí, pé kó fi gbogbo ìgbádùn ìlú Úrì sílẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣe bẹ́ẹ̀. Torí pé Ábúráhámù máa ń gbọ́ràn sí Ọlọ́run lẹ́nu nígbà gbogbo ló ṣe di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.
Díẹ̀ lára àwọn èèyàn Ábúráhámù bá a lọ nígbà tó fi Úrì sílẹ̀. Térà, bàbá rẹ̀ tẹ̀ lé e lọ. Lọ́ọ̀tì ọmọ arákùnrin rẹ̀ bá a lọ. Sárà, aya Ábúráhámù sì tẹ̀ lé e lọ pẹ̀lú. Nígbà tó ṣe, gbogbo wọn dé Háránì, ibẹ̀ ni Térà kú sí. Ní báyìí wọ́n ti rìn jìnnà sí Úrì.
Nígbà tó yá Ábúráhámù àti ìdílé rẹ̀ kúrò ní Háránì wọ́n sì wá sí ilẹ̀ kan tá à ń pè ní Kénáánì. Jèhófà sọ fún un níbẹ̀ pé: ‘Ilẹ̀ tí èmi yóò fi fún àwọn ọmọ rẹ nìyí.’ Ábúráhámù dúró sí Kénáánì ó sì ń gbé inú àgọ́.
Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í ran Ábúráhámù lọ́wọ́ tó bẹ́ẹ̀ tó fi ní agbo àgùntàn ńlá àtàwọn ẹranko mìíràn àti ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ìránṣẹ́. Ṣùgbọ́n òun àti Sárà kò bí ọmọ kankan.
Nígbà tí Ábúráhámù di ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún [99], Jèhófà wí pé: ‘Mo ṣèlérí pé ìwọ yóò di bàbá àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè púpọ̀.’ Ṣùgbọ́n báwo ni èyí ṣe lè ṣẹlẹ̀, níwọ̀n bí Ábúráhámù àti Sárà ti dàgbà kọjá ẹni tó lè bímọ?