ÌTÀN 41
Ejò Bàbà
ǸJẸ́ ejò yìí ò jọ ejò gidi tó lọ́ mọ́ ara òpó? Kì í ṣe èjò gidi rárá. Bàbà ni wọ́n fi ṣe é. Jèhófà ló sọ fún Mósè pé kó gbé e kọ́ sára òpó káwọn èèyàn lè máa wò ó kí wọ́n má bàa kú. Ṣùgbọ́n ejò gidi làwọn ejò yòókù tó ò ń wò nílẹ̀ yẹn. Wọ́n ti bu àwọn èèyàn náà jẹ èyí sì ti dá àìsàn sáwọn èèyàn náà lára. Ǹjẹ́ o mọ ìdí rẹ̀?
Ìdí ni pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run àti Mósè. Wọ́n ráhùn pé: ‘Kí ló dé tó o fi mú wa jáde kúrò ní Íjíbítì láti wá kú sínú aginjù yìí? Kò sí oúnjẹ tàbí omi níhìn-ín. Mánà yìí sì ti sú wa ní jíjẹ.’
Oúnjẹ tó dára sì ni mánà o. Ọ̀nà àrà ni Jèhófà gbà pèsè oúnjẹ yìí fún wọn. Ọ̀nà àrà ló sì gbà pèsè omi fún wọn pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n àwọn èèyàn náà ya aláìmoore fún gbogbo bí Ọlọ́run ṣe ń tọ́jú wọn. Nítorí náà, Jèhófà rán àwọn ejò olóró wọ̀nyí láti fi ìyà jẹ wọ́n. Ejò náà bù wọ́n jẹ, ọ̀pọ̀ nínú wọn sì kú.
Níkẹyìn, àwọn èèyàn náà wá bá Mósè wọ́n sì wí pé: ‘A ti dẹ́ṣẹ̀, nítorí a ti sọ̀rọ̀ òdì sí Jèhófà àti sí ọ. Wàyí o, bá wa gbàdúrà sí Jèhófà pé kó mú àwọn ejò wọ̀nyí kúrò.’
Nítorí náà Mósè gbàdúrà nítorí àwọn èèyàn náà. Jèhófà wá sọ fún Mósè pé kó ṣe ejò bàbà yìí. Ó ní kó gbé e kọ́ sára òpó kan, pé kí ẹnikẹ́ni tí ejò bá ti bù jẹ gbé ojú sókè, kó wo ejò bàbà ara òpó náà. Mósè ṣe ohun tí Ọlọ́run wí. Àwọn èèyàn tí ejò sì bù jẹ gbé ojú sókè wo ejò bàbà náà, ara wọn sì dá.
Ẹ̀kọ́ wà tá a lè rí kọ́ nínú èyí. Lọ́nà kan, gbogbo wa la dà bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ejò bù jẹ wọ̀nyẹn. Gbogbo wa ló wà ní ipò ẹni tó lè kú. Tó o bá wò yí ká, wàá rí i pé àwọn èèyàn ń darúgbó, wọ́n ń ṣàìsàn, wọ́n sì ń kú. Èyí jẹ́ nítorí pé Ádámù àti Éfà, ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́, yí padà kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà, ọmọ wọn sì ni gbogbo wa. Ṣùgbọ́n Jèhófà ti ṣe ọ̀nà kan tá a máa gbà wà láàyè títí láé.
Jèhófà rán Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi, wá sí ilẹ̀ ayé. Wọ́n gbé Jésù kọ́ sórí igi, nítorí ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé ẹni búburú ni. Ṣùgbọ́n kí Jésù bàa lè gbà wá là ni Jèhófà fi fi í fún wa. Bá a bá wo Jésù, bá a bá tẹ̀ lé e, ó máa ṣeé ṣe fún wa láti ní ìyè àìnípẹ̀kun. A ṣì máa mọ púpọ̀ sí i nípa èyí níwájú.