APÁ 5
Láti Ìgbà Ìkólẹ́rúlọ-sí-Bábílónì Títí Di Àkókò Títún Odi Jerúsálẹ́mù Kọ́
Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà ní ìgbèkùn, ọ̀pọ̀ nǹkan ló dán ìgbàgbọ́ wọn wò. Ọba Bábílónì pàṣẹ pé kí wọ́n ju Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò sínú iná ìléru, àmọ́ Ọlọ́run mú wọn jáde láàyè. Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn ará Mídíà àti Páṣíà ṣẹ́gun Bábílónì, wọ́n sì ju Dáníẹ́lì sínú ihò kìnnìún, àmọ́ Ọlọ́run tún dáàbò bò ó nípa pípa àwọn kìnnìún lẹ́nu mọ́.
Níkẹyìn, Kírúsì ọba Páṣíà dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè. Wọ́n padà sí ìlú wọn lẹ́yìn àádọ́rin [70] ọdún géérégé táwọn ará Bábílónì ti kó wọn nígbèkùn. Ọ̀kan lára ohun tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe nígbà tí wọ́n padà sí Jerúsálẹ́mù ni pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà. Àmọ́, kò pẹ́ káwọn ọ̀tá tó dá wọn dúró lẹ́nu iṣẹ́. Nítorí náà, ní nǹkan bí ọdún méjìlélógún [22] lẹ́yìn tí wọ́n dé Jerúsálẹ́mù ni wọ́n tó kọ́ tẹ́ńpìlì náà parí pátápátá.
Síwájú sí i, a kọ́ nípa ìrìn àjò Ẹ́sírà lọ sí ìlú Jerúsálẹ́mù láti ṣe tẹ́ńpìlì náà lọ́ṣọ̀ọ́. Èyí jẹ́ ní nǹkan bí ọdún mẹ́tàdínláàádọ́ta [47] lẹ́yìn tí wọ́n ti kọ́ tẹ́ńpìlì náà parí. Nígbà tó sì di ọdún mẹ́tàlá lẹ́yìn ìrìn àjò Ẹ́sírà, Nehemáyà ṣèrànwọ́ láti tún odi Jerúsálẹ́mù tó ti wó lulẹ̀ kọ́. Apá KARÙN-ÚN yìí kárí ìtàn ohun tó wáyé láàárín ọdún méjìléláàádọ́jọ [152] títí di àkókó tá a wà yìí.