Orí 20
Ogunlọ́gọ̀ Ńlá
1. Lẹ́yìn ti Jòhánù ti ṣàpèjúwe fífi èdìdì di àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì, àwùjọ mìíràn wo ló rí?
BÍ JÒHÁNÙ ṣe ṣàpèjúwe fífi èdìdì di ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tán, ó ń bá a lọ láti ròyìn ọ̀kan nínú àwọn ìṣípayá tó wọni lọ́kàn jù lọ nínú gbogbo Ìwé Mímọ́. Ayọ̀ ti ní láti gbà á lọ́kàn bó ti ń ròyìn rẹ̀ pé: “Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí mo rí, sì wò ó! ogunlọ́gọ̀ ńlá, tí ẹnì kankan kò lè kà, láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n, wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, wọ́n wọ aṣọ funfun; imọ̀ ọ̀pẹ sì ń bẹ ní ọwọ́ wọn.” (Ìṣípayá 7:9) Bẹ́ẹ̀ ni, dídá ẹ̀fúùfù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọ̀nyẹn dúró mú kó ṣeé ṣe fún àwùjọ àwọn èèyàn mìíràn yàtọ̀ sí ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tó jẹ́ Ísírẹ́lì tẹ̀mí láti lè rí ìgbàlà. Àwọn wọ̀nyí sì ni ogunlọ́gọ̀ ńlá èèyàn tí ń sọ èdè púpọ̀, tí wọ́n ti onírúurú orílẹ̀-èdè wá.a—Ìṣípayá 7:1.
2. Àlàyé wo làwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ayé ṣe nípa ogunlọ́gọ̀ ńlá, ojú wo sì làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà yẹn lọ́hùn-ún pàápàá fi wo àwùjọ yìí?
2 Àwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ayé sọ pé ogunlọ́gọ̀ yìí túmọ̀ sí àwọn tí kì í ṣe Júù nípa tara tá a yí lọ́kàn padà sí ìsìn Kristẹni tàbí àwọn Kristẹni ajẹ́rìíkú tí wọ́n ń re ọ̀run. Kódà ìgbà kan tiẹ̀ wà táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kà wọ́n sí ẹgbẹ́ ti ọ̀run onípò kejì, gẹ́gẹ́ bá a ti sọ lọ́dún 1886 nínú Ìdìpọ̀ Kìíní ìwé Studies in the Scriptures, The Divine Plan of the Ages: “Wọ́n pàdánù ẹ̀bùn ìtẹ́ náà àti wíwà bí Ọlọ́run, àmọ́ níkẹyìn a óò bí wọn gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹni ẹ̀mí nínú ẹgbẹ́ kan tó rẹlẹ̀ sí wíwà bíi ti Ọlọ́run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn wọ̀nyí la yà sí mímọ́ ní tòótọ́, ẹ̀mí ayé ti ṣẹ́pá wọn débi pé wọ́n kùnà láti fi ìwàláàyè wọn rúbọ.” Látọdún 1930 la sì tún ti sọ ọ̀rọ̀ tó jọ èyí nínú Light, Ìwé Kìíní: “Àwọn tó para pọ̀ di ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí kùnà láti di ẹlẹ́rìí onítara fún Olúwa.” A ṣàpèjúwe wọn gẹ́gẹ́ bí àwùjọ olódodo lójú ara ẹni, tó ní ìmọ̀ òtítọ́ àmọ́ tí wọn ò wàásù rẹ̀ dà bí alárà. Àwọn náà máa dọ́run gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ onípò kejì tí kò ní bá Kristi ṣàkóso.
3. (a) Ìrètí wo ló wà fáwọn ọlọ́kàn títọ́ tí wọ́n wá di onítara lẹ́yìn náà nínú iṣẹ́ ìwàásù? (b) Báwo ni Ilé Ìṣọ́ (Gẹ̀ẹ́sì) tó jáde lọ́dún 1923 ṣe ṣàlàyé àkàwé àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́?
3 Àmọ́ ṣá o, a rí àwọn míì lára àwọn alábàákẹ́gbẹ́ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọn ò fọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ mú iṣẹ́ ìwàásù. Kò sí lọ́kàn wọn pé wọ́n á lọ sọ́run. Àní ṣe ní ìrètí wọn ṣe wẹ́kú pẹ̀lú àkòrí àsọyé fún gbogbo ènìyàn táwọn èèyàn Jèhófà sọ lọ́pọ̀ ibi látọdún 1918 sí ọdún 1922. Ohun tí àkòrí rẹ̀ pilẹ̀ jẹ́ ni “Ayé Ti Dópin—Ọ̀kẹ́ àìmọye Tí Wọ́n Wàláàyè Nísinsìnyí Kì Yóò Kú Láé.”b Kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí Ilé Ìṣọ́ (Gẹ̀ẹ́sì) ti October 15, 1923, fi ṣàlàyé àkàwé Jésù nípa àwọn àgùntàn àti àwọn ewúrẹ́, (Mátíù 25:31-46) ó sọ pé: “Àgùntàn dúró fún gbogbo èèyàn orílẹ̀-èdè, kì í ṣe àwọn tá a fẹ̀mí bí bí kò ṣe àwọn tó fẹ́ láti máa hùwà òdodo, àwọn tó jẹ́ pé lérò ọkàn tiwọn, wọ́n gba Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bí Olúwa, wọ́n ń retí àkókò tó sàn jù lábẹ́ ìjọba rẹ̀, wọ́n sì ń wọ̀nà fún un.”
4. Báwo ni òye wa nípa ẹgbẹ́ orí ilẹ̀ ayé ṣe wá ń pọ̀ sí i bí ìmọ́lẹ̀ tí ń tàn yòò lọ́dún 1931? lọ́dún 1932? lọ́dún 1934?
4 Láwọn ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, ìyẹn lọ́dún 1931, Vindication, Ìwé Kìíní, jíròrò Ìsíkíẹ́lì orí 9, ó sì fi hàn pé àwọn èèyàn tá a sàmì sí níwájú orí pé wọ́n á la òpin ayé yìí já làwọn àgùntàn inú àkàwé òkè yí. Vindication, Ìwé Kẹta, tó jáde lọ́dún 1932, ṣàpèjúwe ẹ̀mí rere tó wà lọ́kàn Jèhónádábù, ọkùnrin kan tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì, tó wọlé sínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin Ọba Jéhù ẹni àmì òróró Ísírẹ́lì, tó sì bá a lọ láti rí bó ṣe ń fi ìtara pa àwọn onísìn èké. (2 Àwọn Ọba 10:15-17) Ìwé náà ṣàlàyé pé: “Jèhónádábù dúró fún ẹgbẹ́ àwọn èèyàn náà tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé nísinsìnyí ní àkókò tí iṣẹ́ Jéhù [ti pípolongo àwọn ìdájọ́ Jèhófà] ń tẹ̀ síwájú tí wọ́n jẹ́ onífẹ̀ẹ́ inú rere, tí wọn kò sí ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ètò Sátánì, tí wọ́n fara mọ́ òdodo, àwọn sì ni Olúwa yóò pa mọ́ nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì, tí yóò mú wọn la ìjàngbọ̀n yẹn já, tí yóò sì fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé. Àwọn wọ̀nyí ló wá para pọ̀ di ẹgbẹ́ ‘àwọn àgùntàn.’” Lọ́dún 1934 Ilé Ìṣọ́ (Gẹ̀ẹ́sì) mú kó ṣe kedere pé àwọn Kristẹni tí wọ́n ní ìrètí ti orí ilẹ̀ ayé yìí gbọ́dọ̀ ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà kí wọ́n sì ṣe ìrìbọmi. Òye wa nípa ẹgbẹ́ orí ilẹ̀ ayé yìí ń pọ̀ síwájú àti síwájú bí ìmọ́lẹ̀ tí ń tàn yòò.—Òwe 4:18.
5. (a) Kí la sọ nípa àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá lọ́dún 1935? (b) Nígbà tí J. F. Rutherford ní káwọn tó wà ní àpéjọ ti ọdún 1935 tí wọ́n ní ìrètí wíwà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé dìde dúró, kí ló ṣẹlẹ̀?
5 Kí òye wa nípa Ìṣípayá 7:9-17 wá máa pọ̀ yanturu sí i ló kù báyìí! (Sáàmù 97:11) Léraléra ni ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ (Gẹ̀ẹ́sì) ti ń sọ pé àpéjọ àgbègbè kan tó máa wáyé ní May 30 sí June 3, ọdún 1935, nílùú Washington, D.C., lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, yóò jẹ́ “ìtùnú àti àǹfààní ní ti tòótọ́” fún àwọn tí Jèhónádábù ṣàpẹẹrẹ. Bó sì ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn! Nínú àsọyé kan tó wọni lára tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Ògìdìgbó Ńlá Náà,” tí nǹkan bí ọ̀kẹ́ kan èèyàn tó wà níbi àpéjọ náà tẹ́tí sí, J. F. Rutherford, tó ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé nígbà yẹn, fi Ìwé Mímọ́ ṣàlàyé pé ọ̀kan náà làwọn àgùntàn mìíràn òde òní àtàwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá inú Ìṣípayá 7:9. Nígbà tí àsọyé yìí wọra tán, ó béèrè pé: “Ǹjẹ́ kí gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìrètí wíwà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé jọ̀wọ́ dìde?” Bí ọ̀pọ̀ lára àwùjọ náà ti dìde dúró báyìí, ó polongo pé: “Wò ó! Ògìdìgbó ńlá náà!” Kẹ́kẹ́ kọ́kọ́ pa, lẹ́yìn náà wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í pàtẹ́wọ́ kíkankíkan. Ìdùnnú ṣubú layọ̀ fún ẹgbẹ́ Jòhánù, àti àwùjọ Jèhónádábù! Lọ́jọ́ tó tẹ̀ lé e, òjìlélẹ́gbẹ̀rin [840] Ẹlẹ́rìí tuntun ló ṣèrìbọmi, èyí tó pọ̀ jù lọ lára wọn sì jẹ́ ara ogunlọ́gọ̀ ńlá.
Bí Ẹni Tí Ogunlọ́gọ̀ Ńlá Náà Jẹ́ Ṣe Dá Wa Lójú
6. (a) Kí ló mú ká lóye ní kedere pé àwùjọ àwọn Kristẹni òde òní, tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́, tí wọ́n ní ìrètí láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé ni ogunlọ́gọ̀ ńlá? (b) Kí ni aṣọ funfun ogunlọ́gọ̀ ńlá náà ṣàpẹẹrẹ?
6 Báwo ló ṣe lè dá wa lójú tó bẹ́ẹ̀ pé àwùjọ àwọn Kristẹni òde òní yìí, tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ tí wọ́n sì nírètí láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé tí Ọlọ́run dá yìí ni ogunlọ́gọ̀ ńlá? Tẹ́lẹ̀, nínú ìran, Jòhánù ti rí àwùjọ ti ọ̀run tí a “rà . . . fún Ọlọ́run láti inú gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àti àwọn ènìyàn àti orílẹ̀-èdè.” (Ìṣípayá 5:9, 10) Látinú gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àtàwọn èèyàn àti orílẹ̀-èdè náà ni ogunlọ́gọ̀ ńlá ti wá, àmọ́ ìpín tiwọ́n yàtọ̀. Òté kankan ò sí lórí iye tí wọ́n máa jẹ́ bó ṣe rí nínú ọ̀ràn ti Ísírẹ́lì Ọlọ́run. Kò sẹ́ni tó lè sọ tẹ́lẹ̀ pé iye pàtó tí wọ́n máa jẹ́ rèé. Wọ́n fọ aṣọ wọn di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn, èyí tó jẹ́ àpẹẹrẹ pé ojú olódodo ni Ọlọ́run fi ń wò wọ́n lọ́lá ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú ẹbọ Jésù. (Ìṣípayá 7:14) Wọ́n ń ju imọ̀ ọ̀pẹ, wọ́n sì ń yin Mèsáyà náà gẹ́gẹ́ bí Ọba wọn.
7, 8. (a) Jíju imọ̀ ọ̀pẹ láìsí iyè méjì rán àpọ́sítélì Jòhánù létí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo? (b) Kí ni jíjù tí ogunlọ́gọ̀ ńlá ń ju imọ̀ ọ̀pẹ fi hàn?
7 Bí Jòhánù ṣe ń wo ìran náà nìṣó, ó ti ní láti máa rántí àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ léyìí tó ju ọgọ́ta [60] ọdún lọ, ní ọ̀sẹ̀ tí Jésù gbé kẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé. Ní Nísàn 9, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, nígbà tí ogunlọ́gọ̀ rọ́ wá láti kí Jésù káàbọ̀ sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n “mú àwọn imọ̀ ọ̀pẹ, wọ́n sì jáde lọ láti pàdé rẹ̀. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kígbe pé: ‘Gbà là, àwa bẹ̀ ọ́! Alábùkún ni ẹni tí ń bọ̀ ní orúkọ Jèhófà, àní ọba Ísírẹ́lì!’” (Jòhánù 12:12, 13) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, jíjù tí ogunlọ́gọ̀ ńlá náà ń ju imọ̀ ọ̀pẹ tí wọ́n sì ń kígbe ń fi hàn pé wọn láyọ̀ gidigidi nítorí pé wọ́n tẹ́wọ́ gba Jésù gẹ́gẹ́ bí Ọba tí Jèhófà yàn sípò.
8 Láìsí iyè méjì, imọ̀ ọ̀pẹ àti igbe ayọ̀ náà tún rán Jòhánù létí Àjọyọ̀ Àtíbàbà tí wọ́n máa ń ṣe ní Ísírẹ́lì láyé ọjọ́un. Jèhófà pàṣẹ nípa àjọyọ̀ yìí pé: “Ní ọjọ́ kìíní kí ẹ̀yin fúnra yín sì mú èso igi dáradára, àwọn imọ̀ ọ̀pẹ àti àwọn ẹ̀tun ẹlẹ́ka púpọ̀ àti igi pọ́pílà àfonífojì olójú ọ̀gbàrá, kí ẹ sì yọ̀ níwájú Jèhófà Ọlọ́run yín fún ọjọ́ méje.” Imọ̀ ọ̀pẹ tí wọ́n lò yìí ló dúró fún ayọ̀ yíyọ̀. Àwọn àgọ́ tó wà fún ìgbà díẹ̀ ránni létí pé Jèhófà ti gba àwọn èèyàn rẹ̀ là kúrò ní Íjíbítì, kí wọ́n bàa lè máa gbé nínú àwọn àgọ́ nínú aginjù. “Àtìpó àti ọmọdékùnrin aláìníbaba àti opó” ń ṣe nínú àríyá yìí. Gbogbo Ísírẹ́lì sì ní láti “kún fún ìdùnnú.”—Léfítíkù 23:40; Diutarónómì 16:13-15.
9. Igbe ayọ̀ wo ni ogunlọ́gọ̀ ńlá náà jùmọ̀ ń kọ?
9 Bí ogunlọ́gọ̀ ńlá náà kì í tilẹ̀ í ṣe apá kan Ísírẹ́lì tẹ̀mí, ó bá a mú pé wọ́n ń ju imọ̀ ọ̀pẹ, níwọ̀n bí wọ́n ti ń fi ayọ̀ àti ìmoore gbé ògo ìjagunmólú àti ìgbàlà fún Ọlọ́run àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, gẹ́gẹ́ bí Jòhánù ṣe ṣàlàyé níbí yìí pé: “Wọ́n sì ń bá a nìṣó ní kíké pẹ̀lú ohùn rara, pé: ‘Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa, ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ni ìgbàlà wa ti wá.’” (Ìṣípayá 7:10) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé látinú gbogbo àwùjọ ẹ̀yà ìran ni ogunlọ́gọ̀ ńlá náà ti jáde wá, kìkì “ohùn rara” kan ṣoṣo ni wọ́n ń ké jáde. Báwo ni wọ́n ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tó jẹ́ pé ọ̀kankòjọ̀kan orílẹ̀-èdè ni wọ́n ti wá, tí èdè wọn sì yàtọ̀ síra?
10. Báwo ni ogunlọ́gọ̀ ńlá náà ṣe lè máa fi “ohùn rara” kan ṣoṣo ké jáde ní ìṣọ̀kan bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀kankòjọ̀kan orílẹ̀-èdè ni wọ́n ti wá, tí èdè wọn sí yàtọ̀ síra?
10 Ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí jẹ́ apá kan ètò kan ṣoṣo tó wà lórí ilẹ̀ ayé lónìí, táwọn èèyàn láti ọ̀kankòjọ̀kan orílẹ̀-èdè kóra jọ sí, tó sì wà ní ìṣọ̀kan ní tòótọ́. Wọn ò ní ìlànà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n ń tẹ̀ lé, àmọ́ níbi yòówù tí wọ́n bá ń gbé ìlànà títọ́ tó wà nínú Bíbélì ló ń darí gbogbo nǹkan tí wọ́n bá ń ṣe. Wọn kì í dara pọ̀ mọ́ àwọn tó gbà pé orílẹ̀-èdè tàwọn lọ̀gá, tí wọ́n ń fọ̀tẹ̀ yí bí nǹkan ṣe ń lọ sí pa dà, nítorí pé lóòótọ́ ni wọ́n ti “fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀.” (Aísáyà 2:4) Wọn ò pín sí ẹgbẹẹgbẹ́ tàbí ẹ̀kẹ̀ẹ̀ka ìsìn, débi tí ìdàrúdàpọ̀ á fi wà nínú ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́ni tí ohùn wọn ò sì ní ṣọ̀kan bíi tàwọn oníṣọ́ọ̀ṣì; wọn ò sì jókòó gẹlẹtẹ kí wọ́n wá ní kí ẹgbẹ́ àlùfáà aṣiṣẹ́-gbowó-oṣù wá máa bá àwọn yin Ọlọ́run lórúkọ ẹ̀sìn. Wọn kì í sọ pé ìgbàlà àwọn dọwọ́ ẹ̀mí mímọ́, nítorí pé wọn kì í ṣe ìránṣẹ́ ọlọ́run mẹ́talọ́kan. Délé dóko, ní nǹkan bí ọgbọ̀n-lénígba [230] ilẹ̀ lórígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé, ni wọ́n ti ń fi èdè òtítọ́ mímọ́ gaara kan ṣoṣo tí wọ́n jùmọ̀ ń sọ ké pe orúkọ Jèhófà. (Sefanáyà 3:9) Bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, wọn kì í fi bò pé ìgbàlà àwọn dọwọ́ Jèhófà, Ọlọ́run ìgbàlà, nípasẹ̀ Jésù Kristi, Olórí Aṣojú Rẹ̀ fún ìgbàlà.—Sáàmù 3:8; Hébérù 2:10.
11. Báwo ni ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ òde òní ṣe ń ran àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá lọ́wọ́ láti mú kí ohùn rara wọn ròkè sí i?
11 Ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ òde òní ti ṣèrànwọ́ láti mú kí ohùn rara ogunlọ́gọ̀ ńlá tó wà ní ìṣọ̀kan túbọ̀ máa ròkè. Kò sí àwùjọ ìsìn míì lórí ilẹ̀ ayé tó pọn dandan fún láti máa tẹ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jáde lédè tó ju irínwó [400] lọ, níwọ̀n bí kò ti sí àwùjọ míì tó fẹ́ láti máa mú irú ìhìn rere kan náà tọ gbogbo olùgbé ilẹ̀ ayé lọ. Láti lè ràn wá lọ́wọ́ sí i lórí èyí, àwọn ẹni àmì òróró kan tí wọ́n para pọ̀ jẹ́ Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, fọwọ́ sí i pé ká ṣe ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà kan tó ṣe é tẹ èdè púpọ̀ tó ń jẹ́ Multilanguage Electronic Phototypesetting System, tàbí ní ìkékúrú MEPS. Ní àkókò tí wọ́n tẹ ìwé yìí, onírúurú ẹ̀rọ MEPS ni wọ́n lò jákèjádò ayé láwọn ẹ̀ka ilé iṣẹ́ Watch Tower Society tó ju márùnlélọ́gọ́fà [125] lọ, èyí sì ti mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti máa tẹ ìwé ìròyìn ẹlẹ́ẹ̀mejì lóṣù náà, ìyẹn Ilé Ìṣọ́, nígbà kan náà, lédè tó ju àádóje [130] lọ. Àwọn èèyàn Jèhófà tún máa ń tẹ àwọn ìwé ńlá, bí irú èyí tó ò ń kà yìí jáde nígbà kan náà, láwọn èdè mélòó kan. Èyí sì ti mú kó ṣeé ṣe fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ nínú wọn jẹ́ ara ogunlọ́gọ̀ ńlá náà láti máa pín ọ̀kẹ́ àìmọye lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìtẹ̀jáde kiri lọ́dọọdún ní gbogbo èdè táwọn èèyàn ń sọ jù lọ, tí ìyẹn sì ń mú káwọn èèyàn púpọ̀ sí i láti inú gbogbo ẹ̀yà àti èdè lè kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí wọ́n sì pa ohùn wọn pọ̀ mọ́ ohùn rara ti ogunlọ́gọ̀ ńlá náà.—Aísáyà 42:10, 12.
Ní Ọ̀run Tàbí Lórí Ilẹ̀ Ayé?
12, 13. Lọ́nà wo ni ogunlọ́gọ̀ ńlá náà gbà “dúró níwájú ìtẹ́ àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn”?
12 Báwo la ṣe mọ̀ pé dídúró táwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá náà “dúró níwájú ìtẹ́” kò túmọ̀ sí pé wọ́n wà ní ọ̀run? Ọ̀pọ̀ ẹ̀rí tó ṣe kedere wà tá a lè fi ti kókó yìí lẹ́yìn. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “níwájú” níbí yìí ni e·noʹpi·on. Ní tààràtà, ohun tó túmọ̀ sí ní “ní ọ̀kánkán iwájú,” a sì lò ó láwọn ìgbà mélòó kan fáwọn èèyàn lórí ilẹ̀ ayé tí wọ́n wà “níwájú” tàbí “ní ọ̀kánkán iwájú” Jèhófà. (1 Tímótì 5:21; 2 Tímótì 2:14; Róòmù 14:22; Gálátíà 1:20) Nígbà kan báyìí táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà ní aginjù, Mósè sọ fún Áárónì pé: “Sọ fún gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pátá pé, ‘Ẹ wá síwájú Jèhófà, nítorí pé ó ti gbọ́ ìkùnsínú yín.’” (Ẹ́kísódù 16:9) Kò di dandan kí Mósè kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ sọ́run kí wọ́n tó lè wà níwájú Jèhófà nígbà tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí. (Fi wé Léfítíkù 24:8.) Kàkà bẹ́ẹ̀, nínú aginjù níbẹ̀ gan-an ni wọ́n ti dúró ní ọ̀kánkán ojú Jèhófà, tí Jèhófà sì darí àfiyèsí rẹ̀ sára wọn.
13 Bíbélì tún kà síwájú sí i pé: “Nígbà tí Ọmọ ènìyàn bá dé nínú ògo rẹ̀ . . . Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni a ó sì kó jọ níwájú rẹ̀.”c Gbogbo ìran èèyàn ò ní sí lọ́run nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí bá ní ìmúṣẹ. Dájúdájú, àwọn tí yóò “lọ sínú ìkékúrò àìnípẹ̀kun” ò ní sí lọ́run. (Mátíù 25:31-33, 41, 46) Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni aráyé á dúró lórí ilẹ̀ ayé ní ọ̀kánkán ojú Jésù, tí Jésù á sì wá darí àfiyèsí rẹ̀ sí wọn láti ṣe ìdájọ́. Bó ṣe jẹ́ náà nìyẹn ní ti ogunlọ́gọ̀ náà, wọ́n wà “níwájú ìtẹ́ àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà” ní ti pé wọ́n dúró ní ọ̀kánkán ojú Jèhófà àti Ọba rẹ̀, Kristi Jésù, tí wọ́n sì dá wọn láre.
14. (a) Àwọn wo ni Bíbélì sọ pé wọ́n wà “yí ká ìtẹ́” náà tí wọ́n sì tún wà “lórí Òkè Ńlá Síónì [ti ọ̀run]”? (b) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ogunlọ́gọ̀ ńlá náà ń sin Ọlọ́run “nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀,” kí nìdí tíyẹn ò fi sọ wọ́n di ẹgbẹ́ agbo àlùfáà?
14 Ìwé Mímọ́ sọ pé àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún [24] náà àti àwùjọ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ẹni àmì òróró wà “yí ká ìtẹ́” Jèhófà, wọ́n sì wà “lórí Òkè Ńlá Síónì [ti ọ̀run].” (Ìṣípayá 4:4; 14:1) Ogunlọ́gọ̀ ńlá náà kì í ṣe ẹgbẹ́ àlùfáà wọn ò sì dé ipò gíga yẹn. Òótọ́ ni pé Ìṣípayá 7:15 wá sọ lẹ́yìn náà pé ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí ń sin Ọlọ́run “nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀,” àmọ́, kì í ṣe ibi ìjọsìn inú lọ́hùn-ún, tó jẹ́ ibi Mímọ́ Jù Lọ ni tẹ́ńpìlì yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ àgbàlá orí ilẹ̀ ayé ti tẹ́ńpìlì tẹ̀mí Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà na·osʹ, tó túmọ̀ sí “tẹ́ńpìlì” níbí sábà máa ń túmọ̀ ní gbogbo gbòò sí odidi ilé tá a kọ́ kalẹ̀ nítorí àtimáa lò ó fún ìjọsìn Jèhófà. Lónìí, èyí jẹ́ ìgbékalẹ̀ tẹ̀mí tí ọ̀run àti ilẹ̀ ayé jẹ́ ara rẹ̀.—Fi wé Mátíù 26:61; 27:5, 39, 40; Máàkù 15:29, 30; Jòhánù 2:19-21, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW.
Igbe Ìyìn Láyé àti Lọ́run
15, 16. (a) Kí làwọn ẹ̀dá olùṣòtítọ́ tó wà lókè ọ̀run ṣe nígbà tí ogunlọ́gọ̀ ńlá jáde wá? (b) Bí Jèhófà ṣe ń ṣí àwọn ohun kọ̀ọ̀kan tó ní lọ́kàn láti ṣe payá, kí làwọn ẹ̀dá ẹ̀mí rẹ̀ ń ṣe? (d) Báwo làwa tá a wà lórí ilẹ̀ ayé ṣe lè bá wọn kọ nínú orin ìyìn náà?
15 Ogunlọ́gọ̀ ńlá ń yin Jèhófà, ṣùgbọ́n àwọn mìíràn pẹ̀lú ń kọrin ìyìn rẹ̀. Jòhánù ròyìn pé: “Gbogbo àwọn áńgẹ́lì sì dúró yí ká ìtẹ́ náà àti àwọn alàgbà àti ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, wọ́n sì dojú bolẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà, wọ́n sì jọ́sìn Ọlọ́run, wí pé: ‘Àmín! Ìbùkún àti ògo àti ọgbọ́n àti ìdúpẹ́ àti ọlá àti agbára àti okun ni fún Ọlọ́run wa títí láé àti láéláé. Àmín.’”—Ìṣípayá 7:11, 12.
16 Nígbà tí Jèhófà dá ilẹ̀ ayé, gbogbo àwọn áńgẹ́lì mímọ́ rẹ̀ “jùmọ̀ ń fi ìdùnnú ké jáde, tí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí hó yèè nínú ìyìn.” (Jóòbù 38:7) Bí Jèhófà ṣe ń ṣí àwọn ohun tuntun kọ̀ọ̀kan tó ní lọ́kàn láti ṣe payá, ó dájú pé ṣe làwọn áńgẹ́lì á máa hó ìhó ayọ̀. Nígbà tí àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún [24] náà, ìyẹn àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] nínú ògo wọn ti ọ̀run, ké jáde láti fi ìmọrírì hàn fún Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, gbogbo ẹ̀dá Ọlọ́run yòókù tó kù lọ́run fi ohùn kan ṣoṣo dara pọ̀ mọ́ wọn láti fìyìn fún Jésù àti Jèhófà Ọlọ́run. (Ìṣípayá 5:9-14) Ayọ̀ àwọn ẹ̀dá wọ̀nyí ti kọ́kọ́ kún àkúnwọ́sílẹ̀ nígbà tí wọ́n rí i pé Jèhófà ti ṣe ohun tó ní lọ́kàn nípa jíjí àwọn olùṣòtítọ́ ẹni àmì òróró dìde síbi ògo níbi táwọn áńgẹ́lì ń gbé. Àmọ́ ní báyìí táwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá náà ti jáde wá, ńṣe làwọn ẹ̀dá olùṣòtítọ́ ti Jèhófà lọ́run yìí ń hó ìhó ayọ̀ tí wọ́n sì ń yin Ọlọ́run. Ní tòótọ́, àkókò tó wúni lórí láti máa gbé ni ọjọ́ Olúwa jẹ́ fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà. (Ìṣípayá 1:10) Àǹfààní ńláǹlà ló sì jẹ́ fún wa lórí ilẹ̀ ayé ńbí láti máa bá wọn kọrin ìyìn yìí bá a ṣe ń jẹ́rìí nípa Ìjọba Jèhófà!
Ogunlọ́gọ̀ Ńlá Náà Jáde Wá
17. (a) Kí ni ìbéèrè tí ọ̀kan nínú àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún [24] náà béèrè, kí nìyẹn sì fi hàn pé ó ṣeé ṣe? (b) Ìgbà wo la dáhùn ìbéèrè alàgbà náà?
17 Láti àkókò àpọ́sítélì Jòhánù títí lọ dé ọjọ́ Olúwa, ẹni tí ogunlọ́gọ̀ ńlá náà jẹ́ rú àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lójú. Ó bá a mu rẹ́gí, nígbà náà, pé ọ̀kan nínú àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún [24], tó ń ṣojú fún àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n wà lọ́run báyìí, béèrè ìbéèrè kan tó ṣí Jòhánù níyè. “Ní ìdáhùnpadà, ọ̀kan nínú àwọn alàgbà náà wí fún mi pé: ‘Àwọn wọ̀nyí tí wọ́n wọ aṣọ funfun, ta ni wọ́n, ibo ni wọ́n sì ti wá?’ Nítorí náà, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ mo wí fún un pé: ‘Olúwa mi, ìwọ ni ẹni tí ó mọ̀.’” (Ìṣípayá 7:13, 14a) Bẹ́ẹ̀ ni, alàgbà yẹn lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè náà kó sì fi fún Jòhánù. Èyí fi hàn pé ó ṣeé ṣe káwọn tá a ti jí dìde lára àwùjọ àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún [24] náà máa lọ́wọ́ nínú fífi àwọn òtítọ́ àtọ̀runwá ránṣẹ́ lónìí. Àmọ́ bí ẹgbẹ́ Jòhánù lórí ilẹ̀ ayé ṣe ń fara balẹ̀ kíyè sí àwọn nǹkan tí Jèhófà ń ṣe láàárín wọn ló mú kí wọ́n mọ ẹni tí ogunlọ́gọ̀ ńlá náà jẹ́. Ó tètè yé wọn yékéyéké pé àkókò ló tó lọ́dún 1935 tí Jèhófà fi fi ẹ̀kún rẹ́rẹ́ òye nípa àwọn nǹkan tó ní í ṣe pẹ̀lú ìṣàkóso Ìjọba Rẹ̀ dá àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́lá.
18, 19. (a) Ìrètí wo ni ẹgbẹ́ Jòhánù tẹnu mọ́ lọ́dún 1920 sí ọdún 1929 àti ní ọdún 1930 sí ọdún 1934, ṣùgbọ́n àwọn tí iye wọn túbọ̀ ń pọ̀ sí i wo ni wọ́n tẹ́tí sí iṣẹ́ ìwàásù? (b) Kí ni dídá tá a dá ogunlọ́gọ̀ ńlá mọ̀ lọ́dún 1935 jẹ́ ká mọ̀ nípa ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000]? (d) Kí ni àkọsílẹ̀ ìṣirò nípa Ìrántí Ikú Kristi jẹ́ ká mọ̀?
18 Láàárín ọdún 1920 sí ọdún 1929 àti lọ́dún 1930 sí 1934, gbọnmọgbọnmọ ni ẹgbẹ́ Jòhánù ń tẹnu mọ́ ìrètí ti ọ̀run, nínú àwọn ìwé àti lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ìyẹn sì lè jẹ́ nítorí pé ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ò tíì pé nígbà náà. Ṣùgbọ́n, ńṣe ni iye èèyàn tó ń pọ̀ sí i tí wọ́n ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ìwàásù náà tí wọ́n sì ń fi ìtara lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìjẹ́rìí ń fojú sọ́nà fún gbígbé títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Wọn ò ní ìrètí àtilọ sókè ọ̀run. Ìyẹn kọ́ ni ìpè tiwọn. Wọn kì í ṣe ara agbo kékeré, ara àwọn àgùntàn mìíràn ni wọ́n wà. (Lúùkù 12:32; Jòhánù 10:16) Dídá tá a dá wọn mọ̀ lọ́dún 1935 gẹ́gẹ́ bí ogunlọ́gọ̀ ńlá ti àwọn àgùntàn mìíràn ni ẹ̀rí tó fi hàn pé yíyàn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí nígbà yẹn.
19 Ṣé àkọsílẹ̀ ìṣirò tó wà lọ́wọ́ ti èrò yìí lẹ́yìn? Bẹ́ẹ̀ ni. Lọ́dún 1938, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù náà kárí ayé jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárùn-ún àti mẹ́tàdínláàádọ́ta [59,047]. Nínú iye yìí, ẹgbàá méjìdínlógún, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin àti méjìlélọ́gbọ̀n [36,732] ló jẹ nínú àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ níbi Ìrántí Ikú Jésù tó máa ń wáyé lọ́dọọdún, èyí tó fi hàn pé wọ́n nírètí àtilọ sọ́run. Látìgbà yẹn wá, iye àwọn tó ń jẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa yìí ti ń dín kù síwájú àti síwájú sí i, ìdí pàtàkì tó sì fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé àwọn olùṣòtítọ́ ẹlẹ́rìí fún Jèhófà wọ̀nyí ń parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn lórí ilẹ̀ ayé. Lọ́dún 2005, ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ, ọgọ́rùn márùn-ún ó lé mẹ́rìnlélógún [8,524] èèyàn péré ló jẹ ohun ìṣàpẹẹrẹ Ìrántí Ikú Kristi, èyí sì kéré jọjọ sí àròpọ̀ iye àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi kárí ayé, èyí tó jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́rìndínlógún àti ẹgbàá márùndínnígba ó lé mẹ́rìndínlọ́gọ́fà [16,390,116].
20. (a) Láwọn ọdún làásìgbò ti ìgbà Ogun Àgbáyé Kejì, kí la gbọ́ ti J. F. Rutherford sọ nípa ogunlọ́gọ̀ ńlá? (b) Kí wá la fi mọ̀ báyìí pé ògìdìgbó èèyàn ni ogunlọ́gọ̀ ńlá náà jẹ́?
20 Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀, Sátánì sapá kíkankíkan láti dá iṣẹ́ kíkó ogunlọ́gọ̀ ńlá náà jọ dúró. Àwọn aláṣẹ ká iṣẹ́ ìwàásù lọ́wọ́ kò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè. Láwọn ọdún làásìgbò wọ̀nyẹn, àti ní kété ṣáájú kí J. F. Rutherford tó kú lọ́dún 1942, a gbọ́ tó sọ pé: “Tóò . . . ó jọ bíi pé ògìdìgbó ńlá náà kì yóò fi bẹ́ẹ̀ tó bá a ṣe rò pó máa tó tẹ́lẹ̀ mọ́ o.” Ṣùgbọ́n ìbùkún Ọlọ́run ti mú ká ronú gba ibi tó yàtọ̀! Nígbà tó fi máa di ọdún 1946 iye àwọn Ẹlẹ́rìí tó ń lọ́wọ́ sí iṣẹ́ ìwàásù náà kárí ayé ti ròkè, ó ti di ẹgbàá méjìdínláàádọ́rùn-ún, ọ̀tàlénírínwó ó dín mẹ́rin [176,456], èyí tó pọ̀ jù nínú wọn ló sì jẹ́ ara ogunlọ́gọ̀ ńlá. Lọ́dún 2005, ọ̀ọ́dúnrún ọ̀kẹ́, ẹgbàá márùndínnígba àti méjìlélógún [6,390,022] làwọn Ẹlẹ́rìí tó ń fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà ní òjìlénígba ó dín márùn-ún [235] ilẹ̀, OGUNLỌ́GỌ̀ ŃLÁ gbáà mà nìyẹn o! Ńṣe ni iye náà sì túbọ̀ ń pọ̀ sí i.
21. (a) Báwo ni kíkó àwọn èèyàn Ọlọ́run jọ ní ọjọ́ Olúwa ṣe bá ìran Jòhánù mu wẹ́kú? (b) Báwo ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ pàtàkì kan ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìmúṣẹ?
21 Bọ́rọ̀ ṣe rí yìí ti wá mú kí kíkó àwọn èèyàn Ọlọ́run jọ ní ọjọ́ Olúwa bá ìran tí Jòhánù rí mu wẹ́kú: lákọ̀ọ́kọ́ kíkó àwọn tó ṣẹ́ kù lára ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] jọ; lẹ́yìn náà, kíkó ogunlọ́gọ̀ ńlá jọ. Gẹ́gẹ́ bí Aísáyà ti sọ tẹ́lẹ̀, nísinsìnyí “ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́,” àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè ń wọ́ tìrítìrí lọ kí wọ́n bàa lè lọ́wọ́ sí ìjọsìn mímọ́ gaara ti Jèhófà. Ayọ̀ wa sì kún nítorí a mọ̀ pé Jèhófà ń dá “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun.” (Aísáyà 2:2-4; 65:17, 18) Ọlọ́run ń kó “ohun gbogbo jọpọ̀ nínú Kristi, àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run àti àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé.” (Éfésù 1:10) Àwọn ẹni àmì òróró ajogún Ìjọba ọ̀run, tá a ti ń fi ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún kó jọ látìgbà tí Jésù ti wà láyé, ni “àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run.” Ogunlọ́gọ̀ ńlá ti àwọn àgùntàn mìíràn sì tún ti wá jáde wá báyìí gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹni àkọ́kọ́ lára “àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé.” Bó o bá ń bá a nìṣó láti máa sin Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú ètò tó ṣe yìí, ó lè já sí ayọ̀ ayérayé fún ọ.
Ìbùkún Tí Ogunlọ́gọ̀ Ńlá Máa Gbádùn
22. Ìsọfúnni síwájú sí i wo ni Jòhánù rí gbà nípa ogunlọ́gọ̀ ńlá?
22 Ọlọ́run lo ọ̀nà tó ń gbà fi ìran han Jòhánù láti fún un ní ìsọfúnni síwájú sí i nípa ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí: “Ó [ìyẹn alàgbà náà] sì wí fún mi pé: ‘Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí ó jáde wá láti inú ìpọ́njú ńlá náà, wọ́n sì ti fọ aṣọ wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi wà níwájú ìtẹ́ Ọlọ́run; wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún un tọ̀sán-tòru nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀; Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ yóò sì na àgọ́ rẹ̀ bò wọ́n.’”—Ìṣípayá 7:14b, 15.
23. Kí ni ìpọ́njú ńlá láti inú èyí tí ogunlọ́gọ̀ ńlá ti “jáde wá”?
23 Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ́ rí, Jésù ti sọ pé ní ìparí wíwàníhìn-ín òun nínú ògo Ìjọba ni “ìpọ́njú ńlá” máa bẹ̀rẹ̀, “irúfẹ́ èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyí, rárá o, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò tún ṣẹlẹ̀ mọ́.” (Mátíù 24:21, 22) Nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn bá máa nímùúṣẹ, àwọn áńgẹ́lì á tú ẹ̀fúùfù mẹ́rin ilẹ̀ ayé náà dà sílẹ̀ láti pa ayé Sátánì run. Bábílónì Ńlá, ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé láá kọ́kọ́ pa run. Lẹ́yìn náà, nígbà tí ìpọ́njú náà bá ti rinlẹ̀ dáadáa, Jésù á dá àwọn tí wọ́n ṣẹ́ kù lára ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] lórí ilẹ̀ ayé nídè, pa pọ̀ pẹ̀lú ogunlọ́gọ̀ ńlá.—Ìṣípayá 7:1; 18:2.
24. Báwo ni ẹnì kọ̀ọ̀kan lára ogunlọ́gọ̀ ńlá ṣe ń dẹni tó yẹ fún lílà á já?
24 Kí ló máa mú kí ẹnì kọ̀ọ̀kan lára ogunlọ́gọ̀ ńlá yẹ lẹ́ni tí yóò là á já? Alàgbà náà sọ fún Jòhánù pé wọ́n ti “fọ aṣọ wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” Lédè mìíràn, wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù gẹ́gẹ́ bí Olùràpadà wọn, wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, wọ́n ti ṣàpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ wọn nípasẹ̀ ìrìbọmi, wọ́n sì ní “ẹ̀rí-ọkàn rere” nítorí pé wọ́n ń hùwà àìlábòsí. (1 Pétérù 3:16, 21; Mátíù 20:28) Nítorí náà, wọ́n mọ́ tónítóní wọ́n sì jẹ́ olódodo lójú Jèhófà. Wọ́n sì ń pa ara wọn mọ́ “láìní èérí kúrò nínú ayé.”—Jákọ́bù 1:27.
25. (a) Báwo ni ogunlọ́gọ̀ ńlá náà ṣe ń ṣe “iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀” fún Jèhófà “tọ̀sán-tòru nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀”? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe “na àgọ́ rẹ̀” bo ogunlọ́gọ̀ ńlá náà?
25 Síwájú sí i, wọ́n ti di ẹlẹ́rìí onítara fún Jèhófà, “wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún un tọ̀sán-tòru nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀.” Ṣé ọ̀kan lára àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá tó ti ya ara wọn sí mímọ́ yìí ni ìwọ náà? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún ọ láti máa sin Jèhófà nìṣó nínú àgbàlá tẹ́ńpìlì ńlá rẹ̀ tẹ̀mí lórí ilẹ̀ ayé. Lónìí, ogunlọ́gọ̀ ńlá ló ń ṣe èyí tó pọ̀ jù lọ nínú iṣẹ́ ìjẹ́rìí náà lábẹ́ ìdarí àwọn ẹni àmì òróró. Láìka wíwá àtijẹ àtimu sí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún lára wọn ń ya àkókò sọ́tọ̀ láti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún nípa sísìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà. Àmọ́, yálà o wà lára wọn tàbí o kò sí níbẹ̀, yíyà tó o ti ya ara ẹ sí mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ara ogunlọ́gọ̀ ńlá, tó ohun tó lè mú kó o máa yọ̀ pé nítorí ìgbàgbọ́ àti àwọn iṣẹ́ rẹ, a polongo rẹ ní olódodo gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ Ọlọ́run a sì fi inú dídùn tẹ́wọ́ gbà ọ́ gẹ́gẹ́ bí àlejò nínú àgọ́ rẹ̀. (Sáàmù 15:1-5; Jákọ́bù 2:21-26) Ìdí ẹ̀ nìyẹn tí Jèhófà fi “na àgọ́ rẹ̀” bo àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti pé, gẹ́gẹ́ bí olùgbàlejò rere, ó ń dáàbò bò wọ́n.—Òwe 18:10.
26. Àwọn ìbùkún mìíràn wo ni ogunlọ́gọ̀ ńlá náà máa gbádùn?
26 Alàgbà náà ń bá a lọ pé: “Ebi kì yóò pa wọ́n mọ́, bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ kì yóò gbẹ wọ́n mọ́, bẹ́ẹ̀ ni oòrùn kì yóò pa wọ́n tàbí ooru èyíkéyìí tí ń jóni gbẹ, nítorí Ọ̀dọ́ Àgùntàn, tí ó wà ní àárín ìtẹ́ náà, yóò máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn, yóò sì máa ṣamọ̀nà wọn lọ sí àwọn ìsun omi ìyè. Ọlọ́run yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn.” (Ìṣípayá 7:16, 17) Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àlejò ní tòótọ́! Ṣùgbọ́n ìtumọ̀ tó jinlẹ̀ wo ní ń bẹ lẹ́yìn ọ̀rọ̀ yìí?
27. (a) Báwo ni Aísáyà ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun kan tó jọ àwọn ọ̀rọ̀ alàgbà náà? (b) Kí ló fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìmúṣẹ sórí ìjọ Kristẹni ní ọjọ́ Pọ́ọ̀lù?
27 Ẹ jẹ́ ká gbé àsọtẹ́lẹ̀ kan tó fara jọ èyí yẹ̀ wò: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: ‘Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà, mo ti dá ọ lóhùn, àti ní ọjọ́ ìgbàlà, mo ti ràn ọ́ lọ́wọ́ . . . Ebi kì yóò pa wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ kì yóò gbẹ wọ́n, tàbí kí ooru amóhungbẹ hán-ún hán-ún mú wọn tàbí kí oòrùn pa wọ́n. Nítorí pé Ẹni tí ń ṣe ojú àánú sí wọn yóò ṣamọ̀nà wọn, ẹ̀bá àwọn ìsun omi sì ni yóò darí wọn lọ.” (Aísáyà 49:8, 10; tún wo Sáàmù 121:5, 6.) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàyọlò apá kan àsọtẹ́lẹ̀ yìí ó sì so ó pọ̀ mọ́ “ọjọ́ ìgbàlà” tó bẹ̀rẹ̀ ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Ó kọ̀wé pé: “Nítorí ó [ìyẹn Jèhófà] wí pé: ‘Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà, mo gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, àti ní ọjọ́ ìgbàlà, mo ràn ọ́ lọ́wọ́.’ Wò ó! Ìsinsìnyí gan-an ni àkókò ìtẹ́wọ́gbà. Wò ó! Ìsinsìnyí ni ọjọ́ ìgbàlà.”—2 Kọ́ríńtì 6:2.
28, 29. (a) Báwo ni àwọn ọ̀rọ̀ Aísáyà ṣe ní ìmúṣẹ ní ọ̀rúndún kìíní? (b) Báwo ni àwọn ọ̀rọ̀ Ìṣípayá 7:16 ṣe ṣẹ mọ́ ogunlọ́gọ̀ ńlá lára? (d) Kí ló máa tìdí títọ́ ogunlọ́gọ̀ ńlá sọ́nà sí “àwọn ìsun omi ìyè” wá? (e) Kí ló máa mú kí ti ogunlọ́gọ̀ ńlá ṣàrà ọ̀tọ̀ láàárín aráyé?
28 Kí ni ìlérí pé ebi ò ní pani mọ́, òùngbẹ ò ní gbẹni mọ́ tàbí pé ooru tó ń mú nǹkan gbẹ́ hán-ún hán-ún ò ní múni mọ́ túmọ̀ sí nígbà náà lọ́hùn-ún? Ó dájú pé àwọn ìgbà míì wà táwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní jìyà ebi tí òùngbẹ gidi sì gbẹ wọ́n. (2 Kọ́ríńtì 11:23-27) Àmọ́, wọ́n ní ọ̀pọ̀ yanturu nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run. Ọlọ́run rí sí i pé wọ́n ní ànító àti àníṣẹ́kù, nítorí náà ebi kì í pa wọ́n, òùngbẹ kì í sì í gbẹ́ wọn bó bá dọ̀ràn àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ náà sì ní Jèhófà ò jẹ́ kí ooru ìbínú rẹ̀ bì lù wọ́n nígbà tó pa ètò àwọn nǹkan Júù run lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni. Bákan náà làwọn ọ̀rọ̀ inú Ìṣípayá 7:16 ní ìmúṣẹ tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run fáwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá lónìí. Àwọn àtàwọn Kristẹni ẹni àmì òróró jùmọ̀ ń gbádùn ọ̀pọ̀ yanturu ìpèsè tó jẹ mọ́ ìjọsìn wọn sí Ọlọ́run.—Aísáyà 65:13; Náhúmù 1:6, 7.
29 Bó o bá jẹ́ ọ̀kan lára ogunlọ́gọ̀ ńlá, ipò rere tí ọkàn rẹ wà á mú kó o “fi ìdùnnú ké jáde,” láìfi ohun tí o ní láti fara dà lábẹ́ ètò Sátánì tó ń kógbá sílé yìí pè, ì báà jẹ́ ìfi-nǹkan-duni tàbí àwọn pákáǹleke mìíràn. (Aísáyà 65:14) Bó o bá sì wá bára ẹ nípò tí wàá fi nílò ìfaradà, Jèhófà lè ‘nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú rẹ.’ Ìdájọ́ mímúná tó dà bí “oòrùn” tí ń jóni lára ò tún ní jẹ́ ewu fún ọ mọ́, àti pé nígbà táwọn áńgẹ́lì náà bá tú ẹ̀fúùfù ìparun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin dà sílẹ̀, Jèhófà lè dá ọ sí kúrò lọ́wọ́ ìbínú Rẹ̀ tó dà bí “ooru . . . tí ń jóni gbẹ.” Lẹ́yìn tí ìparun náà bá ti ṣọṣẹ́ rẹ̀ tán, Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà yóò tọ́ ọ sọ́nà kó o bàa lè jàǹfààní kíkún látinú “àwọn ìsun omi ìyè” tí ń sọ agbára dọ̀tun, àwọn wọ̀nyí dúró fún gbogbo ìpèsè Jèhófà fún ọ láti jèrè ìyè àìnípẹ̀kun. Ìgbàgbọ́ rẹ nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà la óò dá láre ní ti pé kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ni wàá di ẹni pípé. Tẹ̀yin tẹ́ ẹ bá jẹ́ ará ogunlọ́gọ̀ ńlá náà á tún ṣàrà ọ̀tọ̀ láàárín aráyé gẹ́gẹ́ bí “ọ̀kẹ́ àìmọye” tí kò pọn dandan fún pé kí wọ́n kú! Ìgbà yẹn gan-an lọ̀rọ̀ náà á wá ní ìmúṣẹ ní kíkún pé Ọlọ́run á nu gbogbo omijé nù kúrò lójú yín.—Ìṣípayá 21:4.
Bí Pípè Náà Ṣe Lè Dájú
30. Báwo ni ìran tí Jòhánù rí ṣe mú ká wo sàkun àwọn ohun títóbilọ́lá tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀, ta ni yóò sì lè “dúró”?
30 Ẹ wo báwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣe jẹ́ ká wo sàkun àwọn ohun títóbilọ́lá tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀! Jèhófà fúnra rẹ̀ wà lórí ìtẹ́ rẹ̀, gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé, ń fi ìyìn fún un ní ìṣọ̀kan. Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé mọrírì bó ṣe jẹ́ àgbàyanu àǹfààní tó fáwọn láti kópa nínú ègbè orin ìyìn tí ń kọ lálá. Láìpẹ́ láìjìnnà, Jèhófà àti Kristi Jésù á mú ìdájọ́ ṣẹ a óò sì gbọ́ igbe pé: “Ọjọ́ ńlá ìrunú wọn ti dé, ta ni ó sì lè dúró?” (Ìṣípayá 6:17) Ta ló lè dúró ná? Ìwọ̀nba kéréje lára àwọn olùgbé ayé, títí kan àwọn tó wà lára ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tá a fi èdìdì dì tó ṣeé ṣe kí wọ́n ṣì wà nínú ẹran ara àti ogunlọ́gọ̀ ńlá àwọn àgùntàn mìíràn ni yóò “dúró,” ìyẹn ni pé àwọn ni yóò, là á já pẹ̀lú wọn.—Jeremáyà 35:19; 1 Kọ́ríńtì 16:13.
31. Báwo ni ìmúṣẹ ìran Jòhánù ṣe yẹ kó nípa lórí àwọn Kristẹni, yálà wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró tàbí ara ogunlọ́gọ̀ ńlá?
31 Bọ́rọ̀ ṣe wá rí yìí, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ẹgbẹ́ Jòhánù ń lo ara wọn tokuntokun láti máa “lépa góńgó náà nìṣó fún ẹ̀bùn eré ìje ti ìpè Ọlọ́run sí òkè nípasẹ̀ Kristi Jésù.” (Fílípì 3:14) Wọ́n mọ̀ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àkókò yìí á gba pé káwọn ní ìfaradà tó pọ̀. (Ìṣípayá 13:10) Lẹ́yìn tí wọ́n ti sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún, wọ́n di ìgbàgbọ́ mú ṣinṣin, wọ́n sì ń yọ̀ pé orúkọ àwọn ti wà ‘lákọọ́lẹ̀ ní ọ̀run.’ (Lúùkù 10:20; Ìṣípayá 3:5) Àwọn tí wọ́n jẹ́ ara ogunlọ́gọ̀ ńlá, pẹ̀lú, mọ̀ pé kìkì “ẹni tí ó bá fara dà á dé òpin ni ẹni tí a ó gbà là.” (Mátíù 24:13) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti sàmì sí ogunlọ́gọ̀ ńlá gẹ́gẹ́ bí àwùjọ tó jáde wá látinú ìpọ́njú ńlá, ẹnì kọ̀ọ̀kan lara wọn gbọ́dọ̀ fi tokuntokun lo ara wọn kí wọ́n bàa lè wà ní mímọ́ kí ọwọ́ wọn sì dí fún iṣẹ́.
32. Kí la rí pé ó jẹ́ kánjúkánjú nínú ọ̀ràn náà pé kìkì àwùjọ méjì ni yóò “dúró” ní ọjọ́ ìkannú Jèhófà?
32 Kò sí ẹ̀rí kankan pé ẹnikẹ́ni yàtọ̀ sí àwùjọ méjì yìí máa “dúró” ní ọjọ́ ìkannú Jèhófà. Kí lèyí túmọ̀ sí fún ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tó ń fọ̀wọ̀ hàn lọ́nà kan fún ẹbọ Jésù lọ́dọọdún nípa wíwá tí wọ́n ń wá síbi Ìrántí Ikú rẹ̀, àmọ́ tí wọn ò tíì máa lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ Jésù débi tí wọ́n á fi di ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti ya ara wọn sí mímọ́, tó ṣe ìrìbọmi, tó sì ń fi taratara ṣiṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run? Láfikún sí ìyẹn, àwọn tí ọwọ́ wọn ti fìgbà kan dí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run àmọ́ tí wọ́n yọ̀ǹda kí ọkàn wọn di èyí tí a “dẹrù pa pẹ̀lú . . . àwọn àníyàn ìgbésí ayé” ńkọ́? Ǹjẹ́ kí gbogbo irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ta jí, kí wọ́n wà lójúfò, kí wọ́n bàa lè “kẹ́sẹ járí ní yíyèbọ́ nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ láti ṣẹlẹ̀, àti ní dídúró níwájú Ọmọ ènìyàn” ìyẹn, Jésù Kristi. Ọjọ́ ti lọ o!—Lúùkù 21:34-36.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW.
b Ilé Ìṣọ́ (Gẹ̀ẹ́sì), April 1, 1918, ojú ìwé 98.
c Ní tààràtà, ó túmọ̀ sí “níwájú rẹ̀,” ní ìbámu pẹ̀lú ìtumọ̀ The Kingdom Interlinear Translation of the Greek Scriptures.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 119]
Ti Ọlọ́run Ni Ìtumọ̀
Fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún ni ẹgbẹ́ Jòhánù fi ṣèwádìí ẹni tí ogunlọ́gọ̀ ńlá náà jẹ́ tí wọn kò sì rí àlàyé tó tẹ́ wọn lọ́rùn. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? A rí ìdáhùn nínú àwọn ọ̀rọ̀ Jósẹ́fù olùṣòtítọ́, nígbà tó wí pé: “Ìtúmọ̀ kò ha jẹ́ ti Ọlọ́run?” (Jẹ́nẹ́sísì 40:8) Ìgbà wo ni Ọlọ́run ń túmọ̀ ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ báwo ló sì ṣe ń túmọ̀ wọn? Ó sábà máa ń jẹ́ nígbà tó bá tó àkókò kí wọ́n nímùúṣẹ tàbí lọ́wọ́lọ́wọ́ tí wọ́n bá ń nímùúṣẹ káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ń ṣèwádìí lè fòye mọ ohun tí wọ́n túmọ̀ sí ní kedere. Òye tí wọ́n bá ní yìí má ń wà “fún ìtọ́ni wa, pé nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí.”—Róòmù 15:4.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 124]
Àwọn tó para pọ̀ di ogunlọ́gọ̀ ńlá
▪ jáde wá láti inú gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti àwọn ènìyàn àti èdè
▪ dúró níwájú ìtẹ́ Jèhófà
▪ ti fọ aṣọ wọn di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà
▪ gbé ògo ìgbàlà wọn fún Jèhófà àti Jésù
▪ jáde wá láti inú ìpọ́njú ńlá
▪ ń sin Jèhófà nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀ tọ̀sán tòru
▪ ń rí ààbò onífẹ̀ẹ́ àti ìtọ́jú Jèhófà gbà
▪ ni Jésù ṣolùṣọ́ àgùntàn wọn lọ síbi ìsun omi ìyè
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 121]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 127]
Ọlọ́run àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn nìkan ló lè gba ogunlọ́gọ̀ ńlá là
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 128]
Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ló máa darí ogunlọ́gọ̀ ńlá lọ síbi ìsun omi ìyè