Orí 16
Itara fun Ijọsin Jehofa
AWỌN iyèkan Jesu—awọn ọmọkunrin Maria miiran—ni Jakọbu, Josẹfu, Simoni, ati Judasi. Ṣaaju ki gbogbo awọn wọnyi to rin irin ajo pẹlu Jesu ati awọn ọmọ ẹhin rẹ̀ lọ sí Kapanaomu, ilu kan nitosi Òkun Galili, boya wọn duro ni ile wọn ni Nasarẹti ki idile naa baa lè di awọn ẹrù ti wọn yoo nilo.
Ṣugbọn eeṣe ti Jesu fi lọ sí Kapanaomu dipo ti iba fi maa ba iṣẹ ojiṣẹ rẹ̀ niṣo ni Kana, ni Nasarẹti, tabi ni awọn ibomiran ni awọn òkè kéékèèké ti Galili? Fun ohun kan, ibi ti a tẹ Kapanaomu dó sí gbajumọ pupọ, dajudaju ó sì jẹ ilu kan ti o tubọ tobi. Pẹlupẹlu, pupọ julọ ninu awọn ọmọ ẹhin tí Jesu ṣẹ̀ṣẹ̀ ní ngbe ninu tabi nitosi Kapanaomu, ki o ma baa jẹ ọranyan fun wọn lati fi ibugbe wọn silẹ lati gba idanilẹkọọ lati ọ̀dọ̀ rẹ̀.
Lakooko iduro rẹ̀ ni Kapanaomu, Jesu ṣe awọn iṣẹ agbayanu, gẹgẹ bi ẹ̀rí oun funraarẹ̀ ti fihan ní awọn oṣu diẹ lẹhn naa. Ṣugbọn laipẹ Jesu ati awọn ẹlẹgbẹ rẹ̀ ti wà loju ọna lẹẹkan sii. O jẹ́ ìgbà ìrúwé, wọn sì mú ọna wọn pọ̀n lọ si Jerusalẹmu lati lọ si Irekọja 30 C.E. Nigba ti wọn wà nibẹ, awọn ọmọ ẹhin rí ohun kan nipa Jesu ti o ṣeeṣe kí wọn má tii rí rí.
Ni ibamu pẹlu Òfin Ọlọrun, a beere lọwọ awọn ọmọ Isirẹli lati ṣe awọn irubọ ẹran. Nitori naa, fun ìrọrùn wọn, awọn oniṣowo ni Jerusalẹmu nta awọn ẹran tabi awọn ẹyẹ fun ète yii. Ṣugbọn wọn nta a ninu tẹmpili gan-an, wọn sì ńrẹ́ awọn eniyan naa jẹ nipa ṣíṣá owó gọbọi lé wọn.
Bi o ti kun fun ikannu, Jesu fi okùn ṣe pàṣán ó sì lé awọn olutaja naa jade. Oun da awọn owó ẹyọ awọn onípàṣípààrọ̀ owó dànù ó sì bi awọn tabili wọn ṣubú. “Ẹ gbe nǹkan wọnyi kuro nihin-in,” ni oun kígbe lé awọn ti nta àdàbà. “Ẹ maṣe sọ ile baba mi di ile ọjà títà.”
Nigba ti awọn ọmọ ẹhin Jesu rí eyi, wọn ranti asọtẹlẹ naa nipa Ọmọkunrin Ọlọrun: “Ìtara ile rẹ jẹ mi run.” Ṣugbọn awọn Juu beere pe: “Àmì wo ni iwọ fihan wa, ti iwọ fi nṣe nǹkan wọnyi?” Jesu dahun pe: “Ẹ wó tẹmpili yii palẹ, ni ọjọ mẹta emi yoo sì gbé e ró.”
Awọn Juu ro pe tẹmpili gidi ni Jesu nsọrọ nipa rẹ̀, nitori naa wọn beere pe: “Ọdun mẹrindinlaadọta ni a fi kọ tẹmpili yii, iwọ yoo ha sì gbé e ró ni ọjọ mẹta?” Bi o ti wu ki o ri, Jesu nsọrọ nipa tẹmpili ara rẹ̀. Ni ọdun mẹta lẹhin naa, awọn ọmọ ẹhin rẹ̀ ranti ọrọ rẹ̀ yii nigba ti a jí i dide kuro ninu òkú. Johanu 2:12-22; Matiu 13:55; Luuku 4:23.
▪ Lẹhin ayẹyẹ igbeyawo ni Kana, awọn ibi wo ni Jesu rinrin ajo lọ?
▪ Eeṣe ti Jesu fi kún fun ikannu, ki ni oun sì ṣe?
▪ Ki ni awọn ọmọ ẹhin Jesu ranti nigba ti wọn rí awọn igbesẹ rẹ̀?
▪ Ki ni Jesu sọ nipa “tẹmpili yii,” ki ni oun sì ni lọkan?