Orí 22
A Pe Awọn Ọmọ-ẹhin Mẹrin
LẸHIN igbidanwo lati pa Jesu ni ilu ibilẹ rẹ̀ ni Nasarẹti, oun lọ si ilu Kapanaomu nitosi Òkun Galili. Eyi mu asọtẹlẹ Aisaya miiran ṣẹ. O jẹ́ ọkan ti o sọtẹlẹ pe awọn eniyan Galili ti wọn ngbe lẹbaa okun yoo rí imọlẹ nla.
Bi Jesu ti nba iṣẹ ìtànmọ́lẹ̀ iwaasu Ijọba niṣo nihin-in, oun rí mẹrin ninu awọn ọmọ ẹhin rẹ̀. Awọn wọnyi ti bá a rinrin ajo ṣaaju ṣugbọn wọn pada sidi iṣẹ òwò ẹja pípa wọn nigba ti wọn ba Jesu pada lati Judia. O ṣeeṣe ki Jesu nisinsinyi ti wá wọn rí, niwọn bi o ti tó akoko lati ní awọn oluranlọwọ ti wọn duro sojukan, ti wọn ṣe deedee ti oun lè dá lẹkọọ lati maa ba iṣẹ ojiṣẹ naa niṣo lẹhin ti oun ba ti lọ.
Nitori naa bi Jesu ṣe nrin lọ ni ẹ̀gbẹ́ etikun ti o sì rí Simoni Peteru ati awọn ẹlẹgbẹ rẹ̀ ti wọn nfọ awọn àwọ̀n wọn, oun yà tọ̀ wọn lọ. O gòkè sinu ọkọ Peteru ó sì sọ fun un ki o kuro ni sakaani ilẹ̀. Nigba ti wọn ti lọ siwaju diẹ, Jesu jokoo ninu ọkọ naa ó sì bẹrẹ sii kọ́ awọn ogunlọgọ ni etikun.
Lẹhin naa, Jesu wi fun Peteru pe: “Tì í sí ibú, ki o sì ju àwọ̀n yin si isalẹ fun àkópọ̀.”
“Olukọni,” ni Peteru fèsì, “gbogbo òru àná ni awa fi ṣiṣẹ, awa kò sí mú nǹkan: ṣugbọn nitori ọ̀rọ̀ rẹ emi yoo ju àwọ̀n naa si isalẹ.”
Nigba ti a ju àwọ̀n naa si isalẹ, wọn kó ọpọlọpọ ẹja rẹpẹtẹ tobẹẹ ti àwọ̀n naa sì bẹrẹsii fàya. Ni kiakia, awọn ọkunrin naa wawọ́ sí awọn alabaaṣiṣẹpọ wọn ninu ọkọ kàn ti o wà nitosi lati wá ṣe iranlọwọ. Laipẹ awọn ọkọ mejeeji naa kún fun ọpọlọpọ ẹja ti o fi jẹ pe wọn bẹrẹsii rì. Ni riri eyi, Peteru wólẹ̀ niwaju Jesu ó sì wipe: “Lọ kuro lọdọ mi, nitori ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mi, Oluwa.”
“Ma bẹru,” ni Jesu dahun. “Lati isinsinyi lọ iwọ yoo maa mú eniyan.”
Jesu tún kesi Anderu arakunrin Peteru pẹlu. “Ẹ maa tọ̀ mi lẹhin,” ni oun rọ̀ wọn, “emi yoo sì sọ yin di apẹja eniyan.” Awọn apẹja ẹlẹgbẹ wọn Jakọbu ati Johanu, awọn ọmọkunrin Sebede, ni a nawọ́ ikesini kan naa sí, awọn pẹlu si dahunpada láìlọ́tìkọ̀. Nitori naa awọn mẹrin wọnyi pa òwò ẹja wọn tì wọn sì di awọn ọmọ ẹhin Jesu mẹrin akọkọ, ti wọn duro sojukan, ti wọn ṣedeedee. Luuku 5:1-11; Matiu 4:13-22; Maaku 1:16-20; Aisaya 9:1, 2.
▪ Eeṣe ti Jesu fi pe awọn ọmọ ẹhin rẹ̀ lati tọ̀ ọ́ lẹhin, ta sì ni awọn wọnyi?
▪ Iṣẹ iyanu wo ni o dẹruba Peteru?
▪ Iru iṣẹ ipẹja wo ni Jesu kesi awọn ọmọ ẹhin rẹ̀ lati maa ṣe?