Orí 44
Mímú Ìjì Apaniláyà Kan Dákẹ́
ỌJỌ́ naa ti kún fun ìgbòkègbodò fun Jesu, títí kan kíkọ́ ogunlọgọ lẹ́kọ̀ọ́ ní etíkun ati lẹhin naa ṣíṣàlàyé awọn àkàwé naa fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ níkọ̀kọ̀. Nigba ti ilẹ̀ ṣú, ó wipe: “Ẹ jẹ́ kí a rékọjá lọ sí apá keji.”
Lọ́hùn-ún ní èbúté ìlà-oòrùn Òkun Galili ni ẹ̀kún-ilẹ̀ tí a ńpè ni Dekapolisi wà, lati inú ọ̀rọ̀ Giriiki naa deʹka, tí ó tumọsi “mẹ́wàá,” ati poʹlis, tí ó tumọsi “ìlú.” Awọn ìlú Dekapolisi jẹ́ àárín gbùngbùn àṣà ìbílẹ̀ Giriiki, bí ó tilẹ jẹ́ pe kò sí iyèméjì pe wọn tún jẹ́ ibùgbé ọpọlọpọ awọn Juu pẹlu. Ìgbòkègbodò Jesu ní ẹ̀kún-ilẹ̀ yii, bí ó ti wù kí ó rí, mọníwọ̀n gidigidi. Àní nigba ìbẹ̀wò yii pàápàá, gẹgẹ bi a o ti ríi niwaju, a ṣèdíwọ́ fun un lati dúró pẹ́ nibẹ.
Nigba ti Jesu beere pe kí wọn fi ibẹ̀ silẹ lọ sí òdìkejì èbúté naa, awọn ọmọ-ẹhin fi ọkọ oju omi gbé e. Ìlọkúrò wọn, bí ó ti wù kí ó rí, kò ṣàìgba àfiyèsí. Láìpẹ́ awọn miiran kó sínú awọn ọkọ̀ oju omi wọn lati bá wọn rìn. Òdìkejì naa kò jìnnà pupọ. Niti tootọ, Òkun Galili wulẹ jẹ́ adágún omi títóbi kan tí ó jẹ́ nǹkan bii ibùsọ̀ 13 ní gígùn ati ibùsọ̀ 7 1/2 níbùú níbi tí ó ti fẹ̀ julọ.
Gẹgẹ bi ó ti lè yéni àárẹ̀ ti mú Jesu. Nitori naa, kété tí wọn ti lọ kúrò, ó dùbúlẹ̀ sí ẹ̀hìn ọkọ̀ naa, ó gbé orí rẹ̀ lé ìrọ̀rí kan, ó sì sùnlọ fọnfọn. Pupọ awọn apọsiteli naa jẹ́ awakọ̀ ojú-omi ti o ni iriri, niwọn bi wọn ti pẹ́ ninu iṣẹ́ ẹja pípa lórí Òkun Galili. Nitori naa wọn bójútó iṣẹ́ wíwa ọkọ̀ oju omi naa.
Ṣugbọn eyi kì yoo jẹ́ ìrìn àjò kan tí ó rọrùn. Nitori ìdíwọ̀n ooru tí ó pọ̀ sí i ní orí omi adágún naa, tí ó jẹ́ nǹkan bii 700 ẹsẹ̀-bàtà rẹlẹ̀ sí ìtẹ́bẹẹrẹ omi òkun, ati atẹ́gùn tí ó tutù jù lórí awọn òkè ti o wà ni ìtòsí, nigba miiran awọn ẹ̀fúùfù líle maa ńfẹ́ wálẹ̀ tí wọn sì maa ńdá ìjì ẹ̀fúùfù líle òjijì silẹ lórí adágún naa. Eyi ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nisinsinyi. Láìpẹ́ awọn ìgbì bẹrẹsii rọ́lu ara ọkọ̀ naa tí wọn sì ńṣẹ́wọ inú rẹ̀, tí ó fi jẹ́ pe omi fẹrẹẹ bò ó. Sibẹ Jesu ṣì sùn!
Awọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀ òkun onírìírí naa ńṣiṣẹ́ kìtàkìtà lati tu ọkọ̀ naa. Láìsí iyèmejì wọn ti fi ìjáfáfá darí ọkọ̀ rékọjá awọn ìjì tẹlẹ. Ṣugbọn lọ́tẹ̀ yii wọn ti dé òpin awọn ohun àmúṣagbára wọn. Ní bíbẹ̀rù ohun ti o lè ṣẹlẹ si ẹ̀mí wọn, wọn jí Jesu. ‘Ọ̀gá, iwọ kò ha bìkítà? Awa ńrì lọ!’ ni wọn ṣe sáàfúlà. ‘Gbà wá là, awa ti fẹ́ rì sinu omi!’
Ní títají lójú oorun, Jesu pàṣẹ fun ẹ̀fúùfù ati òkun pe: “Káì! Dákẹ́ jẹ́ẹ́!” Ẹ̀fúùfù tí ńrugùdù naa sì dẹ́kun òkun sì parọ́rọ́. Ní yíyíjú sí awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ó beere pe: ‘Eeṣe tí ẹyin fi kún fun ẹ̀rù tobẹẹ? Ṣe ẹyin kò ní ìgbàgbọ́ kankan sibẹsibẹ ni?’
Nitori eyi, ìbẹ̀rù kan tí ó ṣàjèjì gbá awọn ọmọ-ẹhin naa mú. ‘Ta ni ọkunrin yii niti gidi?’ ni wọn beere lọwọ araawọn ẹnikinni ẹnikeji, ‘nitori ó ńpàṣẹ fun ẹ̀fúùfù ati omi pàápàá, tí wọn sì ńgbọ́ tirẹ̀.’
Ẹ wo irú agbára tí Jesu fihan! Bawo ni ó ti fi wa lọ́kàn balẹ̀ tó lati mọ̀ pe Ọba wa ní agbára lórí awọn ohun ìpìlẹ̀ àdánidá ati pe nigba ti ó bá darí àfiyèsí rẹ̀ ní kíkún sí ìhà ilẹ̀-ayé wa lákòókò ìṣàkóso Ijọba rẹ̀, gbogbo eniyan ni yoo maa gbé ninu àìléwu kuro lọwọ awọn àjálù ibi àdánidá apaniláyà!
Laipẹ lẹhin naa nigba ti ìjì naa ti rọlẹ̀, Jesu ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ dé láìséwu sí èbúté ìlà-oòrùn. Boya awọn ọkọ̀ yooku ni a dásí kuro lọwọ ìjì lile naa tí wọn sì ti padà sílé láìséwu. Maaku 4:35–5:1; Matiu 8:18, 23-27; Luuku 8:22-26.
▪ Ki ni Dekapolisi, nibo ni ó sì wà?
▪ Ki ni awọn ipò àyíká tí ó fa awọn ìjì líle lórí Òkun Galili?
▪ Nigba ti òye iṣẹ́ ọkọ̀ wíwà wọn kò lè gbà wọn là, ki ni ohun tí awọn ọmọ-ẹhin ṣe?