Orí 74
Ìmọ̀ràn fun Mata, ati Ìtọ́ni Lórí Adura
LÀKÒÓKÒ ipa-ọ̀nà iṣẹ́-òjíṣẹ́ Jesu ní Judia, ó wọ abúlé Bẹtani. Nibi yii ni Mata, Maria, ati arakunrin wọn Lasaru ńgbé. Ó ṣeeṣe kí Jesu ti pade awọn mẹta wọnyi ṣaaju ninu iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀ ati nitori naa ó ti jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ pẹlu wọn bayii. Ohun yoowu tí ìbáà jẹ́, Jesu nisinsinyi lọ sí ilé Mata, oun sì tẹ́wọ́gbà á tayọ̀tayọ̀.
Mata háragàgà lati pèsè ohun dídára jùlọ gan-an tí ó ní fun Jesu. Nitootọ, ó jẹ́ ọlá kan tí ó ga kí Mesaya tí a ti ṣèlérí bẹ ilé ẹnikan wò! Nitori naa Mata kowọnu mímúra ohun jíjẹ gígọntíọ kan tí ó sì ńrí sí ọpọlọpọ awọn kúlẹ̀kúlẹ̀ miiran tí ó ṣeto lati mú kí akoko ti Jesu fi wà nibẹ tù ú lára kí ó sì gbádùnmọ́ ọn.
Ní ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀, Maria arabinrin Mata jókòó síbi ẹsẹ̀ Jesu tí ó sì fetisilẹ sí i. Lẹhin àkókò diẹ, Mata sunmọ ọ̀dọ̀ wọn ó sì wi fun Jesu pe: “Oluwa, kò ha jámọ́ nǹkankan fun ọ pe arabinrin mi ti fi emi nikan silẹ lati bójútó awọn nǹkan? Nitori naa, sọ fun un pe kí ó darapọ̀ ní ríràn mi lọwọ.”
Ṣugbọn Jesu kọ̀ lati sọ ohunkohun fun Maria. Kàkà bẹẹ, ó fún Mata ní ìtọ́ni fun dídàníyàn rékọjá ààlà pẹlu awọn nǹkan ti ara. “Mata, Mata,” Jesu fi pẹlu inúrere tọ́ ọ sọ́nà, “iwọ ńṣàníyàn o sì ńdààmú nipa ọ̀pọ̀ nǹkan. Ṣugbọn, awọn ohun diẹ ni a nílò, tabi ohun kanṣoṣo péré.” Jesu ńsọ pe kò pọndandan lati lo ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àkókò ninu pípèsè ọpọlọpọ ounjẹ silẹ fun jíjẹ igba kanṣoṣo. Kìkì iwọnba diẹ tabi ounjẹ ẹyọ kan péré pàápàá ti tó.
Awọn ìpètepèrò Mata dárá; ó ńfẹ́ lati jẹ́ olùgbàlejò ti o ni aajo alejo. Sibẹ, nipa ìfiyèsí alánìíyàn rẹ̀ sí awọn ìpèsè ti ara, oun ńpàdánù àǹfààní naa lati gba ìtọ́ni ti ara-ẹni lati ọ̀dọ̀ Ọmọkunrin Ọlọrun fúnraarẹ̀! Nitori naa Jesu parí èrò sí pe: “Maria ti yàn ìpa daradara naa, a kò sì ní gbà á kuro lọwọ rẹ̀.”
Lẹhin naa, ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ miiran, ọmọ-ẹhin kan beere lọwọ Jesu pe: “Oluwa, kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ bí a ti ṣe ńgbàdúrà, gan-an gẹgẹ bi Johanu ti kọ́ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀.” Ó ṣeeṣe kí ọmọ-ẹhin rẹ̀ yii kí ó má sí nibẹ ní nǹkan bii ọdun kan ati aabọ sẹhin nigba ti Jesu pèsè adura àwòkọ́ṣe ninu Iwaasu rẹ̀ orí Òkè. Nitori naa Jesu tún awọn ìtọ́ni rẹ̀ sọ ṣugbọn ó tún nbaa nìṣó lẹhin naa lati fúnni ní àkàwé kan lati tẹnumọ́ ìdí tí ó fi jẹ́ ọ̀ranyàn lati gbàdúrà láìsinmi.
“Ta ni ninu yin tí yoo ní ọ̀rẹ́ kan,” ni Jesu bẹ̀rẹ̀, “tí yoo sì tọ̀ ọ́ lọ ní ọ̀gànjọ́ òru tí yoo sì wí fun un pe, ‘Ọ̀rẹ́, yá mi ní awọn ìṣù burẹdi mẹta nitori ọ̀rẹ́ mi kan ṣẹ̀ṣẹ̀ dé sí ọ̀dọ̀ mi lati ìrìn àjò kan emi kò sì ní ohunkohun lati gbé síwájú rẹ̀’? Onítọ̀hún lati inú ilé sì wí ní ìfèsìpadà, ‘Jáwọ́ ninu dídààmú mi. A ti ti ilẹ̀kùn nisinsinyi, awọn ọmọ mi kéékèèké sì nbẹ pẹlu mi lórí ibùsùn; emi kò lè dìde kí emi sì fun ọ ní ohunkohun.’ Mo sọ fun yin, bí ó tilẹ jẹ́ pe oun kò ní dìde kí ó sì fun un ní ohunkohun nitori jíjẹ́ tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀, dajudaju nitori ìtẹpẹlẹmọ́ aláìṣojo rẹ̀ oun yoo dìde yoo sì fun un ní awọn ohun tí ó nílò.”
Nipa ìfiwéra yii Jesu kò ní in lọ́kàn lati pẹ́ ẹ sọ pe Jehofa Ọlọrun kò múratán lati dáhùnpadà sí awọn ibeere, gẹgẹ bi ó ti rí pẹlu ọ̀rẹ́ tí ó wà ninu ìtàn rẹ̀. Bẹẹkọ, ṣugbọn oun ńṣàkàwé pe bí ọ̀rẹ́ kan tí kò ní ìfẹ́ ìmúratán yoo bá dáhùn sí awọn ibeere aláìsinmi, meloomeloo ni Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́! Nitori naa Jesu nbaa lọ pe: “Bẹẹ gẹ́gẹ́ ni mo wí fun yin, Ẹ maa baa nìṣó ní bibèèrè, a o sì fifún yin; ẹ maa baa nìṣó ní wíwákiri, ẹyin yoo sì rí; ẹ maa baa nìṣó ní kíkànkùn, a o sì ṣí i fun yin.”
Lẹhin naa Jesu ṣe ìtọ́kasí kan sí awọn baba ẹ̀dá-ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀, aláìpé, nipa wiwi pe: “Nitootọ, baba wo ni ó wà láàárín yin, tí ọmọkunrin rẹ̀ bá beere ẹja, boya tí yoo fi ejò lé e lọ́wọ́ dípò ẹja? Tabi bí ó bá beere ẹyin pẹlu ti yoo fi àkèéke lé e lọwọ? Nitori naa, bí ẹyin, bí ẹ tilẹ jẹ́ eniyan burúkú, bá mọ bí a ti ńfi awọn ẹ̀bùn daradara fun awọn ọmọ yin, meloomeloo ni Baba ní ọ̀run yoo fi ẹ̀mí mímọ́ fun awọn wọnni tí nbeere lọwọ rẹ̀!” Nitootọ, ó jẹ́ ìṣírí asúnniṣiṣẹ́ tí Jesu pèsè lati maa gbàdúrà láìsinmi. Luuku 10:38–11:13, NW.
▪ Eeṣe tí Mata fi lọ jìnnà sínú irúfẹ́ awọn ìmúrasílẹ̀ gbígbòòrò rékọjá ààlà tobẹẹ fun Jesu?
▪ Ki ni Maria ṣe, eesitiṣe tí Jesu fi gbóríyìn fun un dípò Mata?
▪ Ki ni ó sún Jesu lati tún awọn ìtọ́ni rẹ̀ lórí adura sọ?
▪ Bawo ni Jesu ṣe ṣàkàwé ìdí tí ó fi jẹ́ ọ̀ranyàn lati maa gbadura láìsinmi?