Orí 82
Jesu Lẹẹkan Sii Forile Jerusalẹmu
LÁÌPẸ́ Jesu ti wà lójú ọ̀nà lẹẹkan sí i, ní kíkọ́ni lati ìlú dé ìlú ati lati abúlé dé abúlé. Lọna tí ó hàn gbangba oun wà ní àgbègbè Peria, ní ìkọjá Odò Jọdani lati Judia. Ṣugbọn ibi tí ó ńrè ní Jerusalẹmu.
Ọgbọ́n ìmọ̀-ọ̀ràn awọn Juu naa pe kìkì iwọnba diẹ ni ìgbàlà yoo tọ́sí ni ohun tí ó ṣeeṣe ki ó sún ọkunrin kan lati beere pe: “Oluwa, awọn wọnni tí a ńgbàlà ha kéré?” Pẹlu ìdáhùn rẹ̀, Jesu fi ipá mú awọn ènìyàn naa lati ronú nipa ohun tí wọn nílò fun ìgbàlà: “Ẹ fi tokuntokun lo araayin dé góńgó [iyẹn ni pe, jìjàkadì, tabi jẹ̀rora] lati gba ẹnu ilẹ̀kùn tóóró wọlé.”
Irù ìsapá olókunra bẹẹ jẹ́ kánjúkánjú “nitori ọpọlọpọ,” ni Jesu nbaa lọ, “ni yoo wá ọ̀nà lati wọlé ṣugbọn wọn kò ní lè wọlé.” Eeṣe tí wọn kò fi ní lè wọlé? Oun ṣàlàyé pe ‘nigba tí baale ilé bá sì ti dìde tí ó sì ti ti ilẹ̀kùn pa tí awọn ènìyàn sì bẹrẹsii dúró ní òde tí wọn ńkan ilẹ̀kùn, wipe, “Ọ̀gbẹ́ni, ṣílẹ̀kùn fun wa,” oun yoo wipe: “Emi kò mọ ibi tí ẹ ti wá. Ẹ kuro lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹyin òṣìṣẹ́ àìṣòdodo!”’
Awọn ẹni tí a tìmọ́ ẹ̀hìn òde naa lọna ti o han gbangba wá ní àkókò kan tí ó rọgbọ fun kìkì awọn fúnraawọn. Ṣugbọn nigba yẹn ilẹ̀kùn àǹfààní ni a ti tìpa tí a sì fi àgádágodo há. Lati wọ ilé, o yẹ ki wọn ti wá ṣaaju àkókò naa, bí ó tilẹ jẹ́ pe ó lè ti jẹ́ aláìrọgbọ lati ṣe bẹẹ ní àkókò naa. Nitootọ, àbárèbábọ̀ onibanujẹ kan ńdúró dè awọn wọnni tí ńrọ́ fífi ìjọsìn Jehofa ṣe olórí ète wọn ninu igbesi-aye tì sapakan!
Awọn Juu tí a rán Jesu lati lọ ṣe iranṣẹ fun, ní apá tí ó pọ̀ jùlọ, ti kùnà lati gbá àǹfààní yíyanilẹ́nu wọn mú lati tẹ́wọ́gbà ìpèsè Ọlọrun fun ìgbàlà. Nitori naa Jesu sọ pe wọn yoo sọkún wọn yoo sì pa awọn ehín wọn keke nigba ti a bá jù wọn sita. Ní ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀, awọn ènìyàn lati “awọn apá ìlà-oòrùn ati ìwọ̀-oòrùn, ati lati àríwá ati guusu,” bẹẹni, lati orílẹ̀-èdè gbogbo, “yoo sì rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì ninu ijọba Ọlọrun.”
Jesu nbaa lọ: “Awọn wọnni tí wọn kẹhin nbẹ [awọn ti kii ṣe Juu tí a tẹ́ḿbẹ́lú, pẹlu awọn Juu tí a nnilara] tí yoo ṣaaju, awọn wọnni tí wọn ṣaaju sì nbẹ [awọn Juu tí wọn lọ́rọ̀ nipa ti ara ati nipa ti ìsìn] ti wọn yoo kẹhin.” Jíjẹ́ tí wọn jẹ́ ẹni ikẹhin tumọsi pe irú awọn ọlẹ, aláìmoore, bẹẹ kì yoo wà ninu Ijọba Ọlọrun rárá.
Awọn Farisi wá sọ́dọ̀ Jesu nisinsinyi wọn sì sọ pe: “Jáde kí o sì mú ọ̀nà rẹ pọ̀n kuro níhìn-ín, nitori pe Hẹrọdu [Antipa] ńfẹ́ lati pa ọ́.” Ó lè jẹ́ pe Hẹrọdu fúnraarẹ̀ ni ó pilẹ ahesọ yii lati mú kí Jesu sá kúrò ní àgbègbè naa. Hẹrọdu lè ti bẹ̀rù lilọwọ ninu ikú wolii Ọlọrun miiran gẹgẹ bi ó ti ṣe ninu pípa Johanu Arinibọmi. Ṣugbọn Jesu sọ fun awọn Farisi naa pe: “Ẹ lọ kí ẹ sì sọ fun kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ yẹn, ‘Wòó! mo ńlé awọn ẹ̀mí-èṣù jáde mo sì ńṣe àṣeparí ìmúláradá ní òní ati ní ọ̀la, ati ní ọ̀túnla emi yoo ti ṣetán.’”
Lẹhin píparí iṣẹ́ rẹ̀ nibẹ, Jesu ńbá ìrìn àjò rẹ̀ lọ síhà Jerusalẹmu nitori, gẹgẹ bi oun ti ṣàlàyé, “a kò gbà kí a pa wolii kan lẹ́hìn-òde Jerusalẹmu.” Eeṣe tí a fi lè fojúsọ́nà pe wọn yoo pa Jesu ní Jerusalẹmu? Nitori pe Jerusalẹmu ni ìlú-ńlá tí ńṣe olú-ìlú, níbi tí a fi ọ̀gangan ilé ẹjọ́ gíga ti Sanhẹdrin sí tí ó ní awọn mẹmba tí iye wọn jẹ́ 71 tí ó sì jẹ́ ibi tí a ti maa ńrú awọn ẹbọ ẹranko. Nitori naa, a kì yoo yọnda kí a pa “Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọrun” nibomiran yatọ si Jerusalẹmu.
“Jerusalẹmu, Jerusalẹmu, olùpa awọn wolii ati olùsọ òkúta lu awọn wọnni tí a rán jáde sí i,” ni Jesu kédàárò, “bawo ni ó ti jẹ́ nígbàkúgbà tó tí emi ti fẹ́ kó awọn ọmọ rẹ jọpọ̀ ní irú-ọ̀nà tí àgbébọ̀ adìẹ kan gbà ńkó awọn òròmọdìẹ rẹ̀ jọpọ̀ lábẹ́ ìyẹ́-apá rẹ̀, ṣugbọn ẹyin ènìyàn yii kò fẹ́ ẹ! Ẹ wòó! a pa ilé yin tì fun yin.” Fun ṣíṣá Ọmọkunrin Ọlọrun tì, orílẹ̀-èdè naa ko le gbe iparun fori!
Bí Jesu ṣe nbaa nìṣó síhà Jerusalẹmu, olùṣàkóso awọn Farisi kan késí i wá sí ilé rẹ̀. Ó jẹ́ Sabaati, awọn ènìyàn naa sì ńṣọ́ ọ tọwọ́tẹsẹ̀, niwọn bi ọkunrin kan ti wà níbẹ̀ tí ó ńjìyà lọwọ ògùdùgbẹ̀, ìkójọ omi boya ní awọn apá ati awọn ẹsẹ̀ rẹ̀. Jesu bá awọn Farisi ati awọn ògbógi ninu Òfin tí wọn wà níbẹ̀ sọ̀rọ̀, ní bibeere pe: “Ó bófinmu tabi kò bófinmu lati ṣe ìwòsàn ní sabaati?”
Kò si ẹni ti o sọ ọ̀rọ̀ kan. Nitori naa Jesu mú ọkunrin naa láradá ó sì ní kí ó maa lọ. Lẹhin naa ó beere pe: “Ta ni ninu yin, tí ọmọkunrin tabi akọmàlúù rẹ̀ bá bọ́ sínú kàǹga, tí kò ní fà á jáde lẹsẹkẹsẹ ní sabaati?” Lẹẹkan sí i, ẹnikẹni kò sọ ọ̀rọ̀ kan ní ìfèsìpadà. Luuku 13:22–14:6; Johanu 1:29, NW.
▪ Ki ni Jesu fihàn pe a nílò fun ìgbàlà, eeṣe tí a sì fi ti ọpọlọpọ mọ́ ẹ̀hìn-òde?
▪ Awọn wo ni wọn “kẹ́hìn” tí wọn di àkọ́kọ́, ati tí wọn “ṣaaju” tí wọn di ikẹhin?
▪ Idi wo ni o ṣeeṣe ki a fi sọ pe Hẹrọdu fẹ́ lati pa Jesu?
▪ Eeṣe tí a kò fi àyè gbà á kí a pa wolii kan lẹ́hìn-òde Jerusalẹmu?