Ìsọ̀rí 4
Kristẹndọm Ti Da Ọlọrun Ati Bibeli
1, 2. Eeṣe ti awọn kan kò fi ni ọ̀wọ̀ fun Bibeli, ṣugbọn ki ni Bibeli sọ?
1 Awọn eniyan ní ọpọlọpọ ilẹ̀ ni wọn ti yẹra fun Bibeli ti wọn kò si ni ọ̀wọ̀ fun un nitori ìwà buburu awọn ti wọn sọ pe awọn ń tẹle e. Ni awọn ilẹ̀ kan a ti sọ pe Bibeli jẹ ìwé tí ń ṣamọna sí ogun, pe o jẹ ìwé awọn aláwọ̀ funfun, ati pe o jẹ ìwé ti o ṣetilẹhin fun ètò ijọba amúnisìn. Ṣugbọn iwọnyi jẹ oju-woye alaṣiṣe.
2 Bibeli, ti a kọ ni Àárín-Gbùngbùn Ìlà-Oòrùn Ayé, kò fọwọsi awọn ogun ijọba amúnisìn ati fifi ìwà wọ̀bìà finiṣèjẹ ti a ti ń ṣe lorukọ isin Kristian lati igba pipẹ bẹẹ wá. Ni odikeji eyi, nipa kika Bibeli ati kíkọ́ awọn ẹ̀kọ́ isin Kristian tootọ eyi ti Jesu fi kọni, iwọ yoo rí i pe Bibeli dẹbi gidigidi fun ogun jíjà, ìwàpálapàla, ati fifi awọn ẹlomiran ṣèjẹ. Àbùkù naa jẹ ti awọn wọ̀bìà eniyan, kii ṣe ti Bibeli. (1 Korinti 13:1-6; Jakọbu 4:1-3; 5:1-6; 1 Johannu 4:7, 8) Nitori naa maṣe jẹ ki ìwàkíwà awọn eniyan onimọtara-ẹni-nikan ti wọn ń gbe ní ilodisi imọran rere Bibeli di ọ lọwọ lati janfaani lati inu awọn ìṣúra inu rẹ̀.
3. Ki ni otitọ iṣẹlẹ itan fihan nipa Kristẹndọm?
3 Lara awọn ti wọn kò gbé ni ibamu pẹlu Bibeli ni awọn eniyan ati orilẹ-ede Kristẹndọm wà. “Kristẹndọm” ni a tumọ gẹgẹ bi apakan ayé nibi ti isin Kristian ti jẹ eyi ti ó borí. Ni eyi ti o pọ julọ o jẹ ìhà Ìwọ̀-Oòrùn Ayé ati awọn eto-igbekalẹ ṣọọṣi rẹ̀, eyi ti o gbajúmọ̀ lati ọ̀rúndún kẹrin C.E. Bibeli ti wà lọwọ Kristẹndọm lati ọpọ ọ̀rúndún, awọn ẹgbẹ alufaa rẹ̀ si ti sọ pe wọn fi ń kọni ati pe awọn jẹ aṣoju Ọlọrun. Ṣugbọn awọn ẹgbẹ alufaa Kristẹndọm ati awọn ojihin-iṣẹ Ọlọrun wọn ha kọni ní otitọ bi? Awọn iṣe wọn ha ṣoju fun Ọlọrun ati Bibeli bi? Isin Kristian ha bori niti gidi ni Kristẹndọm bi? Rara. Lati igba ti isin rẹ̀ ti gba iwaju ni ọ̀rúndún kẹrin, Kristẹndọm ti jẹ ọta Ọlọrun ati Bibeli. Bẹẹni, otitọ iṣẹlẹ inu itan fihan pe Kristẹndọm ti da Ọlọrun ati Bibeli.
Awọn Ẹ̀kọ́ Aláìbá Bibeli Mu
4, 5. Awọn ẹ̀kọ́ alaiba Bibeli mu wo ni a fi ń kọni ni awọn ṣọọṣi?
4 Awọn ẹ̀kọ́ ipilẹ ti Kristẹndọm ni a kò gbékarí Bibeli ṣugbọn lori awọn itan àròsọ ìgbà laelae—ti Griki, Egipti, Babiloni, ati awọn miiran. Awọn ẹ̀kọ́ iru bi aileku ọkàn ti a dá mọ́ni, idaloro ayeraye inu ina ọrun apaadi, pọgatori, ati Mẹtalọkan (ẹni mẹta ninu Ọlọrun kanṣoṣo) kò si ninu Bibeli.
5 Fun apẹẹrẹ, gbé ẹ̀kọ́ naa pe awọn eniyan buburu ni a o daloro titilae ninu ina ọrun apaadi yẹwo. Ki ni imọlara rẹ nipa èròǹgbà yii? Eyi ṣaibarade fun ọpọlọpọ. Wọn rii pe kò bọgbọnmu pe ki Ọlọrun dá eniyan lóró titilae, ni fifi wọn sinu irora aroni-dé-góńgó. Iru èrò òkúrorò bẹẹ lòdì sí Ọlọrun Bibeli, nitori “ifẹ ni Ọlọrun.” (1 Johannu 4:8) Bibeli mu ki o ṣekedere pe iru ẹ̀kọ́ bẹẹ ‘kò wá sinu ọkàn’ Ọlọrun Olodumare.—Jeremiah 7:31; 19:5; 32:35.
6. Bawo ni Bibeli ṣe já ẹ̀kọ́ aileku ọkàn níkoro?
6 Lonii ọpọlọpọ isin, papọ pẹlu awọn ṣọọṣi Kristẹndọm, kọni pe awọn eniyan ní aileku ọkàn, eyi ti o ń lọ si ọrun tabi ọrun apaadi lẹhin iku. Eyi kii ṣe ẹ̀kọ́ Bibeli. Kaka bẹẹ, Bibeli sọ kedere pe: “Alaaye mọ̀ pe awọn o kú; ṣugbọn awọn òku kò mọ ohun kan, . . . nitori ti kò si ète, bẹẹ ni kò si imọ, tabi ọgbọn, ni isa-oku nibi ti iwọ ń rè.” (Oniwasu 9:5, 10) Olorin naa si sọ pe nigba iku “ó pada si erupẹ rẹ̀; ni ọjọ naa gan-an, ìrò inu rẹ̀ run.”—Orin Dafidi 146:4.
7. Ki ni iya ẹṣẹ Adamu ati Efa fun rírú ofin Ọlọrun?
7 Ranti, pẹlu, pe nigba ti Adamu ati Efa ru ofin Ọlọrun, iya ẹ̀ṣẹ̀ wọn kii ṣe aileku. Èrè ni iyẹn yoo jẹ, kii ṣe ijiya! Kàkà bẹẹ, a sọ fun wọn pe wọn yoo “pada si ilẹ̀, nitori inu rẹ̀ ni a ti mu [wọn] wá.” Ọlọrun tẹnumọ ọn fun Adamu pe: “Erupẹ sa ni iwọ, iwọ o si pada di erupẹ.” (Genesisi 3:19) Nipa bẹẹ, ẹ̀kọ́ aileku ọkàn ti a dá mọ́ni kò si ninu Bibeli ṣugbọn ń ṣe ni Kristẹndọm yá a lati ọdọ awọn eniyan ti kii ṣe Kristian tí wọn ti wà ṣaaju wọn.
8. Bawo ni Bibeli ṣe já ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan Kristẹndọm níkoro?
8 Bakan naa, ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan Kristẹndọm mu ki o dabi ẹni pe Ọlọrun jẹ ohun ijinlẹ Ọlọrun ẹni-mẹta-ninu-ọkanṣoṣo kan. Ṣugbọn kò si ẹ̀kọ́ yẹn ninu Bibeli. Fun apẹẹrẹ, ni Isaiah 40:25, Ọlọrun sọ kedere pe: “Njẹ ta ni ẹyin o ha fi mi wé, tabi ta ni emi o ba dọgba?” Idahun naa daju: Kò si ẹnikẹni ti o le ba a dọgba. Bakan naa, Orin Dafidi 83:18 sọ lọna rirọrun pe: “Iwọ orukọ ẹni-kanṣoṣo ti ijẹ Jehofa, iwọ ni Ọga-ogo lori ayé gbogbo.”—Tun wo Isaiah 45:5; 46:9; Johannu 5:19; 6:38; 7:16 pẹlu.
9. Ki ni a le sọ nipa ẹ̀kọ́ Bibeli ati nipa ẹ̀kọ́ awọn ṣọọṣi Kristẹndọm?
9 Awọn ẹ̀kọ́ Bibeli nipa Ọlọrun ati awọn ète rẹ̀ ṣekedere, wọn rọrùn lati loye, wọn sì mọgbọndani. Ṣugbọn awọn ẹ̀kọ́ ṣọọṣi Kristẹndọm kò rí bẹẹ. Eyi ti o tun buru ju, wọn tako Bibeli.
Awọn Iṣe Alaiwa-bi-Ọlọrun
10, 11. Ni awọn ọ̀nà wo ni awọn ẹ̀kọ́ Bibeli fi beere fun ohun ti o jẹ odikeji si eyi ti awọn ṣọọṣi Kristẹndọm ti ń ṣe?
10 Ni afikun si kikọni ní awọn ẹ̀kọ́ èké, Kristẹndọm ti da Ọlọrun ati Bibeli nipa awọn iṣe rẹ̀. Ohun tí awọn ẹgbẹ alufaa ati ṣọọṣi ti ṣe lati awọn ọ̀rúndún ti o ti kọja wá, ti wọn sì ń baa lọ lati ṣe ni akoko wa, jẹ odikeji ohun ti Ọlọrun Bibeli beere fun, ati odikeji ohun ti Oludasilẹ isin Kristian, Jesu Kristi, kọni ti o si ṣe.
11 Fun apẹẹrẹ, Jesu kọ awọn ọmọ-lẹhin rẹ̀ lati maṣe dá si ọran iṣelu ayé yii tabi ki wọn lọwọ ninu awọn ogun rẹ̀. Ó tun kọ wọn lati jẹ olufẹ alaafia, lati jẹ olupa ofin mọ́, lati ni ifẹ fun eniyan ẹlẹgbẹ wọn laisi ojusaaju, koda ki wọn ṣetan lati fi iwalaaye ti awọn funraawọn rubọ dipo gbigba iwalaaye awọn ẹlomiran.—Johannu 15:13; Iṣe 10:34, 35; 1 Johannu 4:20, 21.
12. Ki ni Jesu sọ pe yoo fi awọn Kristian tootọ han?
12 Niti tootọ, Jesu kọni pe ifẹ fun awọn eniyan yooku ni yoo jẹ àmì ti yoo fi awọn Kristian tootọ han yatọ sí awọn èké Kristian, afàwọ̀rajà. Ó sọ fun awọn ti yoo tẹle e pe: “Ofin titun kan ni mo fifun yin, ki ẹyin ki o fẹ ọmọnikeji yin; gẹgẹ bi emi ti fẹran yin, ki ẹyin ki o si le fẹran ọmọnikeji yin. Nipa eyi ni gbogbo eniyan yoo fi mọ̀ pe, ọmọ-ẹhin mi ni ẹyin iṣe, nigba ti ẹyin ba ni ifẹ si ọmọnikeji yin.”—Johannu 13:34, 35; 15:12.
13, 14. Ki ni fihan pe awọn ṣọọṣi Kristẹndọm kò ṣojú fun Ọlọrun?
13 Sibẹ, ni ọ̀rúndún kan tẹle omiran, awọn ẹgbẹ alufaa Kristẹndọm ti dá si oṣelu ti wọn si ti ṣetilẹhin fun awọn ogun orilẹ-ede tiwọn. Wọn tilẹ ti ṣetilẹhin fun awọn ìhà ti o kọju si araawọn ninu awọn ogun laaarin Kristẹndọm, iru bii awọn ogun agbaye meji ti ọ̀rúndún yii. Ninu awọn ija ogun wọnyẹn awọn ẹgbẹ alufaa ni ìhà mejeeji ti gbadura iṣẹgun fun ìhà tiwọn, ti awọn mẹmba isin kan lati orilẹ-ede kan ń pa mẹmba isin kan naa ni orilẹ-ede miiran. Ṣugbọn bi Bibeli ṣe sọ pe awọn ọmọ Satani ń ṣe niyẹn, kii ṣe awọn ọmọ Ọlọrun. (1 Johannu 3:10-12, 15) Nipa bẹẹ, nigba ti awọn ẹgbẹ alufaa ati awọn ọmọlẹhin wọn sọ pe awọn jẹ Kristian, wọn tako awọn ẹ̀kọ́ Jesu Kristi, ẹni ti o sọ fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀ pe ki wọn ‘mu idà kuro.’—Matteu 26:51, 52.
14 Fun ọpọ ọ̀rúndún awọn ṣọọṣi ti lẹ ìdí àpò pọ̀ mọ́ awọn alagbara oṣelu ti Kristẹndọm nigba ti awọn orilẹ-ede wọnyẹn ṣẹgun, ṣe ìkólẹ́rú, ti wọn sì tẹ awọn eniyan miiran lóríba lakooko ijọba agbokeere ṣakoso. Bi ọran ti rí niyẹn fun ọpọ ọ̀rúndún ni Africa. China pẹlu ni iriri eyi, nigba ti awọn orilẹ-ede Ìwọ̀-Oòrùn Ayé ń yan awọn agbegbe ti wọn yoo maa dari tipátipá, bii lakooko awọn Ogun Opium ati ti Ìdìtẹ̀ Ẹgbẹ Imulẹ Agbógunti Àlejò ati isin Kristian ni China ni 1900.
15. Awọn ìwà-ibi wo ni Kristẹndọm ti hù?
15 Awọn isin Kristẹndọm bakan naa ti léwájú ninu ṣiṣe inunibini, idaloro, ati koda pipa awọn wọnni ti wọn kò fohunṣọkan pẹlu wọn ni awọn ọ̀rúndún wọnyẹn ti a pe ni Sanmani Ojú Dúdú. Nigba Iwadii Lati Gbogunti Àdámọ̀, eyi ti o wà fun ọgọrọọrun ọdun, awọn iṣe òkúrorò, iru bii idaloro ati ìṣìkàpani, ni a faṣẹ sí ti a sì ń ṣe fun awọn eniyan oniwa yíyẹ, aláìmọwọ́mẹsẹ̀. Awọn olubi naa ni awọn ẹgbẹ alufaa ati awọn ọmọlẹhin wọn, ti gbogbo wọn jẹwọ jijẹ Kristian. Wọn tilẹ gbiyanju lati pa Bibeli rẹ́ ki awọn gbáàtúù eniyan má baa rí i kà.
Wọn Kii Ṣe Kristian
16, 17. Eeṣe ti a fi le sọ pe awọn ṣọọṣi kii ṣe Kristian?
16 Rara o, awọn orilẹ-ede ati ṣọọṣi Kristẹndọm kii ṣe Kristian latẹhinwa, ati nisinsinyi. Wọn kii ṣe iranṣẹ Ọlọrun. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ti a mísí sọ nipa wọn pe: “Wọn jẹwọ pe wọn mọ Ọlọrun; ṣugbọn nipa iṣẹ wọn ń sẹ́ ẹ, wọn jẹ ẹni irira, ati alaigbọran, ati niti iṣẹ rere gbogbo alainilaari.” —Titu 1:16.
17 Jesu sọ pe isin èké ni a le dámọ̀ pẹlu ohun ti o mu jade, iyẹn ni, awọn eso rẹ̀. Ó sọ pe: “Ẹ maa kiyesi awọn èké wolii ti o ń tọ̀ yin wá ni awọ agutan, ṣugbọn apanijẹ ikooko ni wọn ninu. Eso wọn ni ẹyin o fi mọ̀ wọn. . . . Gbogbo igi rere nii so eso rere; ṣugbọn igi buburu nii so eso buburu. Igi rere kò le so eso buburu, bẹẹ ni igi buburu kò si le so eso rere. Gbogbo igi ti ko bá so eso rere, a ké e lulẹ, a si wọ́ ọ sọ sinu iná. Nitori naa nipa eso wọn ni ẹyin o fi mọ [awọn èké wolii].”—Matteu 7:15-20.
18. Ki ni o ti jẹyọ lati inu awọn ẹ̀kọ́ ati iṣe Kristẹndọm?
18 Nipa bẹẹ, nipasẹ awọn ohun ti wọn ti fi kọni ti wọn si ti ṣe, awọn isin Kristẹndọm ti fihan pe ijẹwọ wọn pe awọn gba Bibeli gbọ́ ati pe wọn jẹ olubẹru Ọlọrun ati Kristian jẹ́ irọ́. Wọn ti da Ọlọrun ati Bibeli. Ni ṣiṣe bẹẹ, wọn ti jẹ ohun irira fun araadọta ọkẹ eniyan wọn si ti mú kí wọn yipada kuro ninu igbagbọ ninu Ẹni Giga Julọ kan.
19. Ìkùnà Kristẹndọm ha tumọsi pe Ọlọrun ati Bibeli ti kùnà bi?
19 Bi o ti wu ki o ri, ìkùnà awọn ẹgbẹ alufaa ati ṣọọṣi Kristẹndọm, ati ìkùnà awọn isin miiran lẹhin òde Kristẹndọm pẹlu, kò tumọsi ìkùnà Bibeli. Bẹẹ ni kò tumọsi pe Ọlọrun ti kùnà. Kàkà bẹẹ, Bibeli sọ fun wa nipa Ẹni Giga Julọ kan ti o wà ti o si bikita nipa wa ati ọjọ-ọla wa. O fihan bi oun yoo ṣe san ẹsan fun awọn eniyan aláìlábòsí ọkàn ti wọn ń fẹ́ lati ṣe ohun títọ́, ti wọn ń fẹ́ rí i ki idajọ òdodo ati alaafia borí kárí ilẹ̀-ayé. O tun fi idi ti Ọlọrun fi fayegba ìwà-ibi ati ijiya lati wà ati bi oun yoo ṣe mu awọn ti ń ṣepalara fun ọmọnikeji wọn kuro ni ayé, papọ pẹlu awọn ti wọn sọ pe wọn ń ṣiṣẹsin in ṣugbọn ti wọn kò si ṣe bẹẹ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
“Iná ìleru” Dante
[Credit Line]
Àkàwé ti Doré nipa awọn Afi Ipò Ṣòwò—Giampolo fun Divine Comedy ti Dante
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Mẹtalọkan Kristẹndọm
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Mẹtalọkan Hindu
[Credit Line]
Iyọọda oninuure ti The British Museum
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Mẹtalọkan Egipti
[Credit Line]
Museo Egizio, Turin
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ní odikeji si awọn ẹ̀kọ́ Jesu, ẹgbẹ awọn alufaa ni ìhà mejeeji ti ṣetilẹhin fun awọn ogun
[Credit Line]
Fọto ti U.S. Army