Orí 11
Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn Nìwọ̀nyí!
1. Kí ni ìdí tí ó fi dàbí ẹni pé ṣìbáṣìbo máa ń bá ọ̀pọ̀ ènìyàn nígbà tí wọ́n bá ń gbé bí ipò ayé ti rí yẹ̀wò, ṣùgbọ́n níbo ni a ti lè rí àlàyé tí ó ṣeé fọkàntẹ̀ sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ayé?
BAWO ni ayé wa tí kò fararọ ṣe dé ibi tí ó dé yìí? Ibo ni a forílé? Ìwọ ha ti béèrè àwọn ìbéèrè wọ̀nyẹn nígbà kan rí bí? Ṣìbáṣìbo ń bá àwọn kan nígbà tí wọ́n bá wo bí ipò ayé ti rí. Àwọn òtítọ́ gidi bí ogun jíjà, òkùnrùn, àti ìwà-ọ̀daràn mú kí àwọn ènìyàn máa ṣe kàyéfì nípa ohun tí ọjọ́-ọ̀la yóò mú wá. Àwọn aṣáájú nínú àkóso kò fúnni ní ìrètí kankan. Bí ó ti wù kí ó rí, àlàyé tí ó ṣeé fọkàntẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun nípa àwọn àkókò oníwàhálà wa yìí wà lárọ̀ọ́wọ́tó nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Lọ́nà tí ó ṣeé fọkàntẹ̀ Bibeli ràn wá lọ́wọ́ láti rí ibi tí a wà nínú ìṣàn àkókò. Ó fi hàn wá pé a wà ní “awọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí.—2 Timoteu 3:1.
2. Ìbéèrè wo ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, báwo ni ó sì ṣe fèsì?
2 Fún àpẹẹrẹ, gbé ìdáhùn tí Jesu fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sí àwọn ìbéèrè díẹ̀ tí wọ́n gbé dìde yẹ̀wò. Ọjọ́ mẹ́ta ṣáájú ikú Jesu, wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ni yoo sì jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ ati ti ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan?”a (Matteu 24:3) Ní ìfèsìpadà, Jesu sọ ní pàtó nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ayé àti àwọn ipò tí yóò fi hàn ní kedere pé ètò-ìgbékalẹ̀ aláìwà-bí-Ọlọ́run yìí ti wọnú àwọn ọjọ́ ìkẹyìn rẹ̀.
3. Èéṣe tí àwọn ipò nǹkan lórí ilẹ̀-ayé fi burú sí i nígbà tí Jesu bẹ̀rẹ̀ síí ṣàkóso?
3 Bí a ti fi hàn nínú orí tí ó ṣáájú, ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ Bibeli ṣamọ̀nà sí ìparí èrò náà pé Ìjọba Ọlọrun ti bẹ̀rẹ̀ síí ṣàkóso. Ṣùgbọ́n báwo ni ìyẹn ṣe lè rí bẹ́ẹ̀? Àwọn nǹkan ti túbọ̀ burú síi, kò dára síi. Níti gidi, èyí fi hàn lọ́nà tí ó lágbára pé Ìjọba Ọlọrun ti bẹ̀rẹ̀ síí ṣàkóso. Èéṣe tí ó fi rí bẹ́ẹ̀? Ó dára, Orin Dafidi 110:2 fi tó wa létí pé fún àkókò kan Jesu yóò ṣàkóso ‘láàárín àwọn ọ̀tá rẹ̀.’ Nítòótọ́, ìgbésẹ̀ rẹ̀ àkọ́kọ́ bí Ọba ní ọ̀run ni láti fi Satani àti àwọn áńgẹ́lì ẹ̀mí-èṣù rẹ̀ sọ̀kò sísàlẹ̀ sí sàkáání ilẹ̀-ayé. (Ìṣípayá 12:9) Kí ni ìyọrísí èyí? Gẹ́lẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ìṣípayá 12:12 ṣe sọtẹ́lẹ̀ ni ó rí pé: “Ègbé ni fún ilẹ̀-ayé ati fún òkun, nitori Èṣù ti sọ̀kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ní mímọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni oun ní.” A ń gbé nísinsìnyí nínú “sáà àkókò kúkúrú” yẹn.
4. Kí ni díẹ̀ lára àwọn apá-ẹ̀ka àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, kí ni wọ́n sì fi hàn? (Wo àpótí.)
4 Kò yani lẹ́nu nígbà náà, nígbà tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ Jesu ohun tí àmì wíwàníhìn-ín rẹ̀ àti ti ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yóò jẹ́, èsì rẹ̀ ń múni ṣe wọ̀ọ̀. Onírúurú apá-ẹ̀ka àmì náà ni a rí nínú àpótí tí ó wà ní ojú-ìwé 102. Bí o ti lè ríi, Kristian aposteli Paulu, Peteru, ati Johannu pèsè àfikún kúlẹ̀kúlẹ̀ fún wa nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Lóòótọ́, èyí tí ó pọ̀ jùlọ lára apá-ẹ̀ka àmì náà àti ti àwọn ọjọ́ ìkẹyìn mú àwọn ipò oníwàhálà lọ́wọ́. Síbẹ̀, ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí níláti mú wa gbàgbọ́ dájú pé ètò-ìgbékalẹ̀ búburú yìí ti súnmọ́ òpin rẹ̀. Ẹ jẹ́ kí a túbọ̀ ṣàyẹ̀wò kínníkínní lórí díẹ̀ síi lára lájorí apá-ẹ̀ka àwọn ọjọ́ ìkẹyìn náà.
ÀWỌN APÁ-Ẹ̀KA ÀWỌN ỌJỌ́ ÌKẸYÌN
5, 6. Báwo ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìjà ogun àti ìyàn ṣe ń ní ìmúṣẹ?
5 “Orílẹ̀-èdè yoo dìde sí orílẹ̀-èdè ati ìjọba sí ìjọba.” (Matteu 24:7; Ìṣípayá 6:4) Òǹkọ̀wé Ernest Hemingway pe Ogun Àgbáyé I ní “ìpànìyàn láìnídìí tí ó jẹ́ àrágbabú, oníṣìkàpànìyàn, tí a sì bójútó lọ́nà burúkú jùlọ tí ó tíì wáyé rí lórí ilẹ̀-ayé.” Ní ìbámu pẹ̀lú ìwé náà The World in the Crucible—1914-1919, èyí jẹ́ “ọ̀nà ìgbàṣe titun kan nínú ogun jíjà, ogun àkọ́kọ́ tí ó kan tilé-toko nínú ìrírí aráyé. Gígùn àkókò rẹ̀, ìgbónájanjan rẹ̀, àti ìgbòòrò rẹ̀ rékọjá ohunkóhun mìíràn tí a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ tàbí tí a fojú sọ́nà fún ní gbogbogbòò.” Lẹ́yìn náà ni Ogun Àgbáyé II, tí ó tún wá túbọ̀ mú ìparun wá ju Ogun Àgbáyé I lọ. Ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìtàn náà Hugh Thomas sọ pé: “Ọ̀rúndún ogún ni ìbọn arọ̀jò ọta, àgbá asọ̀kò ọta, ọkọ̀ òfúúrufú arọ̀jò ọta B-52, bọ́m̀bù runlé rùnnà àti, níkẹyìn, àgbá ọta ti darí. Àwọn ogun tí wọ́n túbọ̀ kún fún ìtàjẹ̀sílẹ̀ tí wọ́n sì jẹ́ aṣèparunbàjẹ́ ju ti àwọn sànmánì mìíràn lọ ti sàmì síi.” Nítòótọ́, púpọ̀ ni a sọ nípa ìbọ́ra ogun sílẹ̀ lẹ́yìn tí Ogun Tútù parí. Síbẹ̀, ìròyìn kan díwọ̀n pé lẹ́yìn ìlọsílẹ̀ tí a wéwèé nǹkan bí 10,000 sí 20,000 ṣóńṣó orí àfọ̀njá alágbára átọ́míìkì ni yóò ṣì wà—tí ó fi 900 ìgbà ju ìdáńgájíá ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí a lò nígbà Ogun Àgbáyé II lọ.
6 “Àìtó oúnjẹ . . . yoo sì wà.” (Matteu 24:7; Ìṣípayá 6:5, 6, 8) Láti 1914 ìyàn tí ó pọ̀ jọjọ tí ó tó nǹkan bíi 20 ti wà. Àwọn agbègbè tí ọ̀ràn kan ní nínú Bangladesh, Burundi, Cambodia, China, Etiopia, ilẹ̀ Griki, India, Nigeria, Russia, Rwanda, Somalia, àti Sudan. Ṣùgbọ́n kì í ṣe àìtó oúnjẹ ni ó sábà máa ń fa ìyàn. Àwùjọ àwọn onímọ̀ lórí iṣẹ́ àgbẹ̀ àti ìṣúnná owó parí èrò pé: “Ìpèsè oúnjẹ lágbàáyé ní àwọn ẹ̀wádún àìpẹ́ ti ga sókè síi ju iye ènìyàn rẹ̀ lọ. . . . Ṣùgbọ́n nítorí pé ó kéré tán 800 million àwọn ènìyàn ṣì wà nínú ipò òṣì paraku, . . . wọn kò lè ra èyí tí ó tó láti fi gba ara wọn sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àìjẹunrekánú tí ó lékenkà.” Ṣíṣe àtojúbọ̀ sínú ọ̀ràn ìṣèlú ti dákún àwọn ọ̀ràn mìíràn. Ọ̀mọ̀wé Abdelgalil Elmekki ti University of Toronto fúnni ní àpẹẹrẹ méjì nínú èyí tí ebi ti ń pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún nígbà tí orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń gbé ń fi ọ̀pọ̀ tabua oúnjẹ ránṣẹ́ sí òkè òkun. Ó dàbí ẹni pé ìdàníyàn àwọn alákòóso wọ̀nyí ni láti jèrè owó ilẹ̀ òkèèrè láti pèsè fún àwọn ogun wọn jù láti fi oúnjẹ bọ́ àwọn aráàlú wọn. Kí ni ìparí èrò Ọ̀mọ̀wé Elmekki? Ìyàn sábà máa ń jẹ́ “ọ̀ràn ìpínkiri àti ìlànà ètò ìjọba.”
7. Kí ni àwọn òtítọ́-ìṣẹ̀lẹ̀ nípa àjàkálẹ̀ àrùn lónìí?
7 “Awọn àjàkálẹ̀ àrùn.” (Luku 21:11; Ìṣípayá 6:8) Àrùn gágá ti 1918 sí 1919 gba ẹ̀mí 21 million ènìyàn ó kérétán. A. A. Hoehling kọ nínú ìwé náà The Great Epidemic pé: “Kò sí ìgbà kankan rí nínú ìtàn tí ayé ti rí ìrunbàjẹ́ láti ọwọ́ panipani kan tí ó pa ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn pẹ̀lú ìyárakánkán bẹ́ẹ̀.” Lónìí, àjàkálẹ̀ àrùn ṣì ń jà rànyìn. Lọ́dọọdún, jẹjẹrẹ ń pa àádọ́talérúgba ọ̀kẹ́ ènìyàn, àwọn àrùn àrunṣu ń gba ẹ̀mí iye tí ó ju àádọ́jọ ọ̀kẹ́ àwọn ọmọ-ọwọ́ àti àwọn ọmọdé, tí ikọ́ ẹ̀gbẹ́ sì ń pa àádọ́jọ ọ̀kẹ́. Àwọn àkóràn tí ó ní ìsopọ̀ pẹ̀lú èémí, ní pàtàkì òtútù àyà, ń pa million 3.5 àwọn ọ̀dọ́mọdé tí wọn kò tíì pé ọmọ ọdún márùn-ún lọ́dọọdún. Iye tí ń mú háà ṣeni ti billion 2.5—ìlàjì iye àwọn olùgbé ayé—ń jìyà lọ́wọ́ àwọn àìsàn tí àìtó omi tàbí omi tí a sọ dẹ̀gbin àti àṣà ìmọ́tótó tí kò dára tó ń ṣokùnfà rẹ̀. Àrùn AIDS rọ̀dẹ̀dẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìránnilétí kan síwájú síi pé ènìyàn, láìka àṣeyọrí pàtàkì tí ó ti ṣe nínú ìmọ̀ ìṣègùn sí, kò lágbára láti mú àjàkálẹ̀ àrùn kúrò.
8. Báwo ni àwọn ènìyàn ṣe ń fi hàn pé wọ́n jẹ́ “olùfẹ́ owó”?
8 “Awọn ènìyàn yoo jẹ́ . . . olùfẹ́ owó.” (2 Timoteu 3:2) Ní àwọn ilẹ̀ yíká ayé, ó dàbí ẹni pé àwọn ènìyàn ní ìfẹ́ ọkàn tí kò ṣeé tẹ́lọ́rùn fún ọrọ̀ púpọ̀ síi. “Àṣeyọrísírere” ni a sábà máa ń fi bí owó oṣù ti pọ̀ tó díwọ̀n rẹ̀, “àṣeparí” ni a sì ń fi bí ohun tí ẹnì kan ní ṣe pọ̀ tó díwọ̀n. Igbákejì ààrẹ ikọ̀ tí ń polówó ọjà kan polongo pé: “Ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì yóò máa báa lọ láti jẹ́ ipá tí ń súnniṣiṣẹ́ ní àwùjọ àwọn ará America . . . àti ipá tí ó ṣe pàtàkì tí ó túbọ̀ ń pọ̀ síi ní àwọn ọjà kàǹkà-kàǹkà mìíràn bákan náà.” Èyí ha ń ṣẹlẹ̀ níbi tí o ń gbé bí?
9. Kí ni a lè sọ nípa àsọtẹ́lẹ̀ àìgbọràn sí òbí?
9 “Aṣàìgbọràn sí òbí.” (2 Timoteu 3:2) Àwọn òbí, olùkọ́, àti àwọn mìíràn lónìí ní ẹ̀rí ojúkojú pé ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ jẹ́ aláìlọ́wọ̀ àti aláìgbọràn. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọ̀dọ́mọdé wọ̀nyí ń hùwà padà sí àìmọ̀wàáhù àwọn òbí wọn tàbí wọ́n ń ṣàfarawé wọn. Iye àwọn ọmọ tí ń pọ̀ sí i ń pàdánù ìgbẹ́kẹ̀lé nínú—tí wọ́n sì ń ṣọ̀tẹ̀ lòdì sí—ilé ẹ̀kọ́, òfin, ìsìn, àti àwọn òbí wọn. Olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga kan tí ó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí ìtẹ̀sí, ó dàbí ẹni pé wọ́n ní ọ̀wọ̀ tí kò tó nǹkan fún ohun gbogbo.” Bí ó ti wù kí ó rí, ó múni láyọ̀ pé ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ tí ó bẹ̀rù Ọlọrun jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ nínú ìwà.
10, 11. Ẹ̀rí-àmì wo ni ó wà pé àwọn ènìyàn jẹ́ òǹrorò tí wọ́n sì jẹ́ aláìní ìfẹ́ni àdánidá?
10 “Òǹrorò.” (2 Timoteu 3:3) Ọ̀rọ̀ Griki náà tí a tú sí “òǹrorò” túmọ̀ sí ‘aláìṣeé tùlójú, ẹhànnà, aláìní ìbánikẹ́dùn àti ìmọ̀lára.’ Ẹ wo bí èyí ti bá ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dádá ìwà ipá òde-òní mu tó! Ọ̀rọ̀ olóòtú kan sọ pé: “Ìgbésí-ayé kún fún ìkìmọ́lẹ̀ ìpakúpa lọ́nà tí ń daniláàmú, tí ó sì lẹ́rùjẹ̀jẹ̀ tí ó fi béèrè pé kí ẹnì kan pa àwọn ìmọ̀lára rẹ̀ kú kí ó tó lè ka àwọn ìwéìròyìn ojoojúmọ́.” Ẹ̀ṣọ́ ilé kan ṣàkíyèsí pé ó dàbí ẹni pé ọ̀pọ̀ àwọn èwe ń di ojú wọn sí àbájáde àwọn ìgbésẹ̀ wọn. Ó sọ pé: “Ìmọ̀lára náà ni pé, ‘N kò mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́la. Èmi yóò gba gbogbo ohun tí mo bá lè gbà lónìí.’”
11 “Aláìní ìfẹ́ni àdánidá.” (2 Timoteu 3:3) A túmọ̀ àpólà ọ̀rọ̀ yìí láti inú ọ̀rọ̀ Griki kan tí ó túmọ̀ sí “ìkà, aláìlójú àánú” tí ó sì túmọ̀ ní ìpìlẹ̀ sí “aláìní ìfẹ́ni àdánidá, ti ìdílé.” (The New International Dictionary of New Testament Theology) Bẹ́ẹ̀ni, kìí sábà sí ìfẹ́ni ní àyíká náà gan-an tí ó yẹ kí ó ti gbalẹ̀—inú ilé. Àwọn ìròyìn nípa híhùwà ìkà sí ẹnìkejì ẹni nínú ìgbéyàwó, àwọn ọmọ, àní àwọn arúgbó òbí pàápàá, ti wọ́pọ̀ lọ́nà tí ń kó ìdààmú báni. Ìgbìmọ̀ aṣèwádìí kan sọ pé: “Ìwà-ipá ẹ̀dá ènìyàn—yálà ìgbátí kan tàbí títini, ìgúnnilọ́bẹ tàbí ìyìnbọnluni—túbọ̀ ń ṣẹlẹ̀ lemọ́lemọ́ sí i nínú agbo ìdílé ju ní ibikíbi mìíràn lọ nínú ẹgbẹ́ àwùjọ wa.”
12. Èéṣe tí a fi le sọ pé àwọn ènìyàn ní àwòrán-ìrísí ìfọkànsìn Ọlọrun?
12 “Ní àwòrán-ìrísí ìfọkànsin Ọlọrun ṣugbọn tí wọ́n jásí èké níti agbára rẹ̀.” (2 Timoteu 3:5) Bibeli ní agbára láti yí ìgbésí-ayé padà sí èyí tí ó sàn jù. (Efesu 4:22-24) Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn lónìí ń lo ìsìn wọn bí ìbòjú lẹ́yìn èyí tí wọ́n ti ń lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò àìṣòdodo tí kò wu Ọlọrun. Irọ́ pípa, olè jíjà, àti híhu ìwàkiwà ìbálòpọ̀ ni àwọn aṣáájú ìsìn sábà máa ń gbà láyè. Ọ̀pọ̀ ìsìn ń wàásù ìfẹ́ ṣùgbọ́n wọ́n ń ṣètìlẹyìn fún ogun jíjà. Ọ̀rọ̀ olóòtú kan nínú ìwé ìròyìn India Today ṣàkíyèsí pé: “Àwọn ẹ̀dá-ènìyàn ti hu àwọn ìwà ìkà ẹlẹ́gbin lòdì sí àwọn ẹ̀dá ẹlẹgbẹ́ wọn . . . ní orúkọ Ẹlẹ́dàá Onípò Àjùlọ.” Níti tòótọ́, ìforígbárí méjì tí ó ní ìtàjẹ̀sílẹ̀ nínú jùlọ ti ẹnu àìpẹ́ yìí—Ogun Àgbáyé I àti II—bẹ́ sílẹ̀ ní àárín gbùngbùn Kristẹndọm.
13. Ẹ̀rí wo ni ó wà pé a ń run ilẹ̀-ayé bàjẹ́?
13 ‘Rírun ayé bàjẹ́.’ (Ìṣípayá 11:18) Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tí ó ju 1,600 lọ, tí ó ní àwọn 104 olùgba ẹ̀bùn Nobel nínú, yíká ayé fọwọ́ sí ìkìlọ̀ kan, tí Àjọ-Ẹgbẹ́ Àwọn Onímọ̀ Sáyẹ́ǹsì Tí Ń Dàníyàn (UCS) gbé jáde, tí ó sọ pé: “Ẹ̀dá-ènìyàn àti ayé àgbáyé àdánidá forílé ipa-ọ̀nà ìforígbárí kan. . . . Ṣíṣeéṣe náà pé a lè yẹra fún àjálù tí ó rọ̀dẹ̀dẹ̀ ku kìkì ẹ̀wádún díẹ̀ síi.” Ìròyìn náà sọ pé àwọn àṣà tí ń wu ìwàláàyè léwu “lè yí àgbáyé padà kí ó má sì ṣeé ṣe fún un mọ́ láti gbé ìwàláàyè ró ní ọ̀nà tí a mọ̀.” Ìdínkù ipele ozone, sísọ omi di ẹlẹ́gbin, pípa igbó run, ìpàdánù ìmésojáde ilẹ̀, àti àkúrun ọ̀pọ̀ àwọn ẹran àti irú-ọ̀wọ́ àwọn ewéko ni a tọ́ka sí bí àwọn ìṣòro kánjúkánjú tí a gbọ́dọ̀ bójútó. Àjọ-ẹgbẹ́ UCS sọ pé: “Yíyí ìgbáraléra ìsokọ́ra ìgbésí-ayé padà le ṣokùnfà ìyọrísí tí yóò kárí-ayé, títí kan ìwólulẹ̀ nínú ètò-ìgbékalẹ̀ ohun alààyè èyí tí a kò lóye agbára ìṣiṣẹ́ rẹ̀ dáradára.”
14. Báwo ni o ṣe lè fi hàn pé Matteu 24:14 ń ní ìmúṣẹ ní ọjọ́ wa?
14 “A óò sì wàásù ìhìnrere ìjọba yii ní gbogbo ilẹ̀-ayé.” (Matteu 24:14) Jesu sọtẹ́lẹ̀ pé ìhìnrere Ìjọba yìí ni a óò wàásù kárí ayé, fún ẹ̀rí sí gbogbo orílẹ̀-èdè. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àti ìbùkún àtọ̀runwá, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń yọ̀ọ̀da ọ̀pọ̀ billion wákàtí fún iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ-ẹ̀yìn yìí. (Matteu 28:19, 20) Bẹ́ẹ̀ni, àwọn Ẹlẹ́rìí mọ̀ pé àwọn yóò jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ bí àwọn kò bá polongo ìhìnrere náà. (Esekieli 3:18, 19) Ṣùgbọ́n ó dùn mọ́ wọn nínú pé lọ́dọọdún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ń dáhùnpadà sí ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba náà pẹ̀lú ìmoore wọ́n sì ń mú ìdúró wọn bí Kristian tòótọ́, ìyẹn ni pé, bí àwọn Ẹlẹ́rìí fún Jehofa. Ó jẹ́ àǹfààní tí kò ṣeédíyelé láti ṣiṣẹ́sin Jehofa kí a sì tipa bẹ́ẹ̀ tan ìmọ̀ Ọlọrun kálẹ̀. Lẹ́yìn tí a bá sì ti wàásù ìhìnrere yìí ní gbogbo ilẹ̀-ayé tí a ń gbé, òpin ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí yóò dé.
DÁHÙNPADÀ SÍ Ẹ̀RÍ NÁÀ
15. Báwo ni ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí yóò ṣe dópin?
15 Báwo ni ètò-ìgbékalẹ̀ yìí yóò ṣe dópin? Bibeli sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa “ìpọ́njú ńlá” kan tí yóò bẹ̀rẹ̀ nígbà tí àwọn ètò ìṣèlú ayé yìí bá kọlu “Babiloni Ńlá,” ilẹ̀-ọba ìsìn èké àgbáyé. (Matteu 24:21; Ìṣípayá 17:5, 16) Jesu sọ pé ní sáà yìí “oòrùn yoo ṣókùnkùn, òṣùpá kì yoo sì fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ hàn, awọn ìràwọ̀ yoo sì jábọ́ lati ọ̀run, awọn agbára awọn ọ̀run ni a óò sì mì.” (Matteu 24:29) Èyí lè túmọ̀ lóréfèé sí àwọn àrà mériyìírí ojú-ọ̀run. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ẹni sàràkí tí ń tànmọ́lẹ̀ nínú ayé ìsìn ni a óò túfó tí a óò sì mú kúrò. Lẹ́yìn náà Satani, tí a pè ní “Gogu ilẹ̀ Magogu,” yóò lo àwọn ènìyàn oníwà ìbàjẹ́ láti gbé ìkọlù òjijì pátápátá dìde sí àwọn ènìyàn Jehofa. Ṣùgbọ́n Satani kì yóò kẹ́sẹjárí, nítorí Ọlọrun yóò gbà wọ́n. (Esekieli 38:1, 2, 14-23) “Ìpọ́njú ńlá naa” yóò dé òtéńté rẹ̀ ní Armageddoni, “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọrun Olódùmarè.” Yóò mú gbogbo èyí tí ó kẹ́yìn lára ipasẹ̀ ètò-àjọ Satani lórí ilẹ̀-ayé kúrò, yóò sì ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn ìbùkún aláìlópin láti ṣàn wá fún aráyé tí yóò làájá.—Ìṣípayá 7:9, 14; 11:15; 16:14, 16; 21:3, 4.
16. Báwo ni a ṣe mọ̀ pé àwọn apá-ẹ̀ka tí a sọtẹ́lẹ̀ fún àwọn ọjọ́ ìkẹyìn níí ṣe pẹ̀lú àkókò wa?
16 Ní àwọn nìkan, àwọn apá-ẹ̀ka kan lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí ń ṣàpèjúwe àwọn ọjọ́ ìkẹyìn lè dàbí ẹni pé wọ́n níí ṣe pẹ̀lú àwọn sáà mìíràn nínú ìtàn. Ṣùgbọ́n bí a bá kó wọn papọ̀, àwọn ẹ̀rí tí a sọtẹ́lẹ̀ tọ́ka sí ọjọ́ wa. Bí àkàwé: Àwọn ìlà tí ó parapọ̀ di ìlà-ọwọ́ ìtẹ̀ka ẹnì kan jẹ́ àpẹẹrẹ àmì kan tí ẹnikẹ́ni mìíràn kò lè ní. Lọ́nà kan náà, àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ní àpẹẹrẹ àwọn àmì tiwọn, tàbí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀. Ìwọ̀nyí parapọ̀ jẹ́ “ìlà-ọwọ́” tí kò lè bá sáà àkókò mìíràn mu. Bí a bá gbé e yẹ̀wò pẹ̀lú àwọn ìtọ́ka Bibeli pé Ìjọba ọ̀run ti Ọlọrun ti bẹ̀rẹ̀ síí ṣàkóso, ẹ̀rí náà pèsè ìpìlẹ̀ tí ó fìdímúlẹ̀ fún píparí èrò sí pé ìwọ̀nyí jẹ́ àwọn ọjọ́ ìkẹyìn nítòótọ́. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ̀rí ṣíṣe kedere tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu wà pé ètò ìgbékalẹ̀ búburú tí ó wà nísinsìnyí yóò parun láìpẹ́.
17. Kí ni ìmọ̀ náà pé ìwọ̀nyí jẹ́ àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yẹ kí ó sún wa láti ṣe?
17 Kí ni yóò jẹ́ ìdáhùnpadà rẹ sí ẹ̀rí pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn nìwọ̀nyí? Gbé èyí yẹ̀wò: Bí runlérùnnà ìjì líléwu kan bá rọ̀dẹ̀dẹ̀, a máa ń gbé àwọn ìgbésẹ̀ ìṣọ́ratẹ́lẹ̀ láìjáfara. Ohun tí Bibeli sọtẹ́lẹ̀ fún ètò-ìgbékalẹ̀ yìí gan-an yẹ kí ó sún wa láti gbégbèésẹ̀. (Matteu 16:1-3) Ní kedere a lè rí i pé a ń gbé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò-ìgbékalẹ̀ ayé yìí. Èyí yẹ kí ó sún wa láti ṣe àwọn ìyípadà èyíkéyìí tí ó bá pọndandan láti lè jèrè ojúrere Ọlọrun. (2 Peteru 3:3, 10-12) Ní títọ́ka sí ara rẹ̀ bí aṣojú ìgbàlà, Jesu pe ìpè kánjúkánjú náà: “Ẹ kíyèsí ara yín kí ọkàn-àyà yín má baà di èyí tí a dẹrùpa pẹlu àjẹjù ati ìmùtíyó kẹ́ri ati awọn àníyàn ìgbésí-ayé, lójijì tí ọjọ́ yẹn yoo sì dé bá yín ní ìṣẹ́jú akàn gẹ́gẹ́ bí ìdẹkùn. Nitori yoo dé bá gbogbo awọn wọnnì tí ń gbé ní ojú gbogbo ilẹ̀-ayé. Ẹ máa wà lójúfò, nígbà naa, ní rírawọ́ ẹ̀bẹ̀ ní gbogbo ìgbà kí ẹ lè kẹ́sẹjárí ní yíyèbọ́ ninu gbogbo nǹkan wọnyi tí a ti yàntẹ́lẹ̀ lati ṣẹlẹ̀, ati ní dídúró níwájú Ọmọkùnrin ènìyàn.”—Luku 21:34-36.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn Bibeli kan lo ọ̀rọ̀ náà “ayé” kàkà kí wọ́n lo “ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan.” Ìwé atúmọ̀ èdè náà Expository Dictionary of New Testament Words láti ọwọ́ W. E. Vine sọ pé ọ̀rọ̀ Griki náà ai·onʹ “dúró fún sáà kan tí kò ní gígùn kan ní pàtó, tàbí àkókò bí a ti wò ó ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní sáà náà.” Ìwé atúmọ̀ èdè náà Greek and English Lexicon to the New Testament (ojú-ìwé 17) ti Parkhurst fi ọ̀rọ̀ náà “ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan” kún un nígbà tí ó ń jíròrò ìlò ai·oʹnes (oníye púpọ̀) ní Heberu 1:2. Nítorí náà ìlò náà “ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan” wà ní ìbámu pẹ̀lú ẹsẹ̀ Griki ìpilẹ̀ṣẹ̀.
DÁN ÌMỌ̀ RẸ WÒ
Kí ni Bibeli sọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ayé ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso Kristi?
Kí ni díẹ̀ lára àwọn apá-ẹ̀ka àwọn ọjọ́ ìkẹyìn?
Kí ni ó mú ọ gbàgbọ́ dájú pé ìwọ̀nyí jẹ́ àwọn ọjọ́ ìkẹyìn?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 102]
DÍẸ̀ LÁRA ÀWỌN APÁ-Ẹ̀KA ÀWỌN ỌJỌ́ ÌKẸYÌN
• Ogun jíjà ní ọ̀nà tí kò ṣẹlẹ̀ rí.—Matteu 24:7; Ìṣípayá 6:4.
• Ìyàn.—Matteu 24:7; Ìṣípayá 6:5, 6, 8.
• Àjàkálẹ̀ àrùn.—Luku 21:11; Ìṣípayá 6:8.
• Ìwà-àìlófin tí ń pọ̀ síi.—Matteu 24:12.
• Pípa ilẹ̀-ayé run.—Ìṣípayá 11:18.
• Ìmìtìtì-ilẹ̀.—Matteu 24:7.
• Àwọn àkókò lílekoko láti bá lò.—2 Timoteu 3:1.
• Ìfẹ́ àìníjàánu fún owó.—2 Timoteu 3:2.
• Àìgbọràn sí àwọn òbí.—2 Timoteu 3:2.
• Àìní ìfẹ́ni àdánidá.—2 Timoteu 3:3.
• Nínífẹ̀ẹ́ adùn dípò Ọlọrun.—2 Timoteu 3:4.
• Àìní ìkóra-ẹni-níjàánu.—2 Timoteu 3:3.
• Àìní ìfẹ́ ohun rere.—2 Timoteu 3:3.
• Àìfiyèsí ewu tí ó rọ̀dẹ̀dẹ̀.—Matteu 24:39.
• Àwọn olùyọṣùtì ṣá ẹ̀rí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn tì.—2 Peteru 3:3, 4.
• Wíwàásù Ìjọba Ọlọrun kárí-ayé.—Matteu 24:14.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 101]