Máa Tẹ̀ Síwájú
NÍGBÀ tí o bẹ̀rẹ̀ sí mọ bí a ṣe ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, àwọn èròkérò, ọ̀rọ̀kọ́rọ̀, àti ìwàkíwà tó ti mọ́ ọ lára bẹ̀rẹ̀ sí yí padà díẹ̀díẹ̀. Ọ̀pọ̀ jù lọ àyípadà yìí ló wáyé kó o tiẹ̀ tó forúkọ sílẹ̀ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Ní báyìí, ó ṣeé ṣe kó o ti tẹ̀ síwájú débi pé o ya ìgbésí ayé rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà. Ṣé ó túmọ̀ sí pé o lè wá ṣíwọ́ ìtẹ̀síwájú rẹ báyìí? Rárá o. Ìbẹ̀rẹ̀ lásán ni ìrìbọmi tó o ṣe jẹ́.
Ọmọ ẹ̀yìn náà Tímótì ti di Kristẹni alàgbà nígbà tí Pọ́ọ̀lù sọ fún un pé kí ó “máa fẹ̀sọ̀ ronú lórí” ìmọ̀ràn tí òun fún un àti àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n gbé lé e lọ́wọ́, kí ó “fi ara rẹ̀ fún” nǹkan wọ̀nyẹn, kí ‘ìlọsíwájú rẹ̀ lè fara hàn kedere fún gbogbo ènìyàn.’ (1 Tím. 4:12-15) Yálà o ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí tọ ọ̀nà òtítọ́ ni o tàbí o ti ní ọ̀pọ̀ ìrírí nínú ìgbé ayé Kristẹni, ó yẹ kí o fẹ́ láti tẹ̀ síwájú.
Ìmọ̀ àti Àyípadà
A kà á nínú Éfésù 3:14-19 pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbàdúrà pé kí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ dẹni tó “lè fi èrò orí mòye ní kíkún ohun tí ìbú àti gígùn àti gíga àti jíjìn” òtítọ́ jẹ́. Ìyẹn ni Jésù fi fúnni ní àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn kí wọ́n máa kọ́ni, kí wọ́n máa tọ́ni sọ́nà, kí wọ́n sì máa gbé ìjọ ró. Ṣíṣe àṣàrò déédéé nínú Ọ̀rọ̀ onímìísí ti Ọlọ́run, pẹ̀lú ìtọ́sọ́nà láti ọ̀dọ̀ àwọn olùkọ́ tó nírìírí, lè ràn wá lọ́wọ́ láti “dàgbà sókè” nípa tẹ̀mí.—Éfé. 4:11-15.
Ìdàgbàsókè yẹn kan pé kí o di ẹni tí a sọ “di tuntun nínú ipá tí ń mú èrò inú [rẹ] ṣiṣẹ́.” Ìyẹn ni pé kí o dẹni tí èrò inú rẹ̀ kì í yẹ̀ kúrò lórí ohun tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run àti ti Kristi mu nínú gbogbo ohun tó o bá ń ṣe. Èyí sì gba pé kí o máa kọ́ nípa èrò inú wọn déédéé, kí o lè “gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀.” (Éfé. 4:23, 24) Nígbà tó o bá ń ka àkọsílẹ̀ inú àwọn ìwé Ìhìn Rere, ǹjẹ́ o máa ń ka ìtàn ìgbésí ayé Kristi yìí sí àwòṣe kan tó yẹ kí o tẹ̀ lé? Ǹjẹ́ o máa ń wá bí wàá ṣe mọ àwọn ìwà tí Jésù hù kí o sì wá sapá gidigidi láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ nínú ìgbésí ayé rẹ?—1 Pét. 2:21.
Irú ọ̀rọ̀ tó máa ń jáde lẹ́nu rẹ lè fi hàn bí o ṣe tẹ̀ síwájú nínú ṣíṣe bẹ́ẹ̀ tó. Àwọn tó bá ti gbé ànímọ́ tuntun wọ̀ kì í tẹnu bọ ọ̀rọ̀ àbòsí, èébú, ọ̀rọ̀ rírùn, tàbí sísọ ọ̀rọ̀ àìdáa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe lọ̀rọ̀ ẹnu wọn máa ń “dára fún gbígbéniró . . . kí ó lè fi ohun tí ó ṣeni lóore fún àwọn olùgbọ́.” (Éfé. 4:25, 26, 29, 31; 5:3, 4; Júúdà 16) Ohun tí wọ́n ń sọ lẹ́nu tí wọ́n bá wà láyè ara wọn àti nínú àwọn ìpàdé ìjọ máa ń fi hàn pé òtítọ́ ń yí ìgbésí ayé wọn padà sí rere.
Bí o kò bá jẹ́ ẹni tí “a ń bì kiri gẹ́gẹ́ bíi nípasẹ̀ àwọn ìgbì òkun, tí a sì ń gbé síhìn-ín sọ́hùn-ún nípasẹ̀ gbogbo ẹ̀fúùfù ẹ̀kọ́” mọ́, ìyẹn náà jẹ́ ẹ̀rí pé o ń ní ìlọsíwájú. (Éfé. 4:14) Bí àpẹẹrẹ, bí àwọn èèyàn ayé bá gbé ọ̀rọ̀ nípa onírúurú èrò tuntun, jíjà fẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn, tàbí oríṣi àwọn eré ìnàjú tó lòde wá bá ọ, kí lo máa ń ṣe? Ṣé ó máa ń ṣe ọ́ bíi pé kó o pa ojúṣe rẹ nípa tẹ̀mí tì, kí o wá lo àkókò rẹ̀ láti fi lépa irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀? Bí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn lè ṣèdíwọ́ fún ìtẹ̀síwájú rẹ nípa tẹ̀mí. Ohun tó ti bọ́gbọ́n mu jù ni pé kí o máa ra àkókò padà láti ṣe àwọn nǹkan tẹ̀mí!—Éfé. 5:15, 16.
Ọwọ́ tó o fi ń mú àwọn ẹlòmíràn tún lè fi hàn bí o ṣe ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí tó. Ǹjẹ́ o ti dẹni tó máa ń ‘fi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn,’ tó sì máa ń ‘dárí ji àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ̀ fàlàlà’?—Éfé. 4:32.
Nínú ìjọ àti nílé ló yẹ kó ti máa hàn pé o ń tẹ̀ síwájú nínú ṣíṣe gbogbo nǹkan lọ́nà tí Jèhófà ń fẹ́. Ó yẹ kó sì tún hàn nílé ẹ̀kọ́, nígboro, àti níbi iṣẹ́ rẹ. (Éfé. 5:21–6:9) Bí àwọn ànímọ́ Ọlọ́run bá ń hàn lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nínú ìwà rẹ ní irú àwọn ipò wọ̀nyẹn, a jẹ́ pé ìlọsíwájú rẹ ń fara hàn kedere nìyẹn.
Lo Ẹ̀bùn Rẹ
Olúkúlùkù wa ni Jèhófà pín òye àti ẹ̀bùn fún. Ńṣe ló ń fẹ́ ká máa fi nǹkan wọ̀nyí ṣe àwọn èèyàn lóore lọ́nà tí yóò fi jẹ́ pé òun ń tipa wa fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ hàn. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé nípa èyí pé: “Níwọ̀n yíyẹ gẹ́gẹ́ bí olúkúlùkù ti rí ẹ̀bùn kan gbà, ẹ lò ó fún ṣíṣe ìránṣẹ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì gẹ́gẹ́ bí ìríjú àtàtà fún inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run.” (1 Pét. 4:10) Báwo lo ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìríjú tìrẹ?
Pétérù tẹ̀ síwájú pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá ń sọ̀rọ̀, kí ó sọ̀rọ̀ bí pé àwọn ọ̀rọ̀ ìkéde ọlọ́wọ̀ Ọlọ́run ni.” (1 Pét. 4:11) Ẹsẹ yìí tẹnu mọ́ ohun tó jẹ́ ojúṣe wa, pé ká máa sọ̀rọ̀ lọ́nà tó bá Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu pátápátá, kí ògo lè jẹ́ ti Ọlọ́run. Ọ̀nà tí a sì ń gbà sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ ní láti yin Jèhófà lógo pẹ̀lú. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí ò ń gbà ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lè mú kí o lo ẹ̀bùn rẹ lọ́nà bẹ́ẹ̀, pé kí o tipa ọ̀nà tí o gbà ń ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ yin Ọlọ́run lógo. Bí ìyẹn bá jẹ́ ohun tó o fẹ́ ṣe, báwo ni wàá ṣe wá díwọ̀n ìtẹ̀síwájú rẹ nílé ẹ̀kọ́?
Dípò kó o máa fi iye kókó ìmọ̀ràn tó o ti ṣiṣẹ́ lé nínú ìwé ìmọ̀ràn ọ̀rọ̀ sísọ tàbí irú iṣẹ́ tí wọ́n ń yàn fún ọ díwọ̀n ara rẹ, máa ronú nípa bí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yẹn ṣe túbọ̀ ń mú kí ẹbọ ìyìn rẹ dára sí i. Ilé ẹ̀kọ́ yẹn ń kọ́ wa ni bí a ṣe lè túbọ̀ já fáfá sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Nípa bẹ́ẹ̀, bi ara rẹ léèrè pé: ‘Ǹjẹ́ mo tiẹ̀ máa ń múra ohun tí mo máa sọ lóde ẹ̀rí sílẹ̀ ní ti gidi? Ǹjẹ́ mo tíì mọ bí mo ṣe lè fi hàn pé mo kanlẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí àwọn tí mo ń wàásù fún? Ǹjẹ́ mo máa ń lànà sílẹ̀ fún ìpadàbẹ̀wò nípa bíbi àwọn èèyàn ní ìbéèrè tí a óò lè sọ̀rọ̀ lé lórí nígbà tí mo bá tún padà lọ? Bí mo bá ń bá ẹnì kan ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ǹjẹ́ mo máa ń ṣakitiyan láti túbọ̀ jẹ́ olùkọ́ tó ń kọ́ni lọ́nà tó wọni lọ́kàn ṣinṣin?’
Má fi ojú ìwọ̀n àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó o bá ń rí gbà nìkan díwọ̀n ìtẹ̀síwájú rẹ. Kì í ṣe iṣẹ́ tí o rí gbà ló ń pinnu ìlọsíwájú rẹ bí kò ṣe ohun tó o bá fi iṣẹ́ yẹn ṣe. Bí iṣẹ́ yẹn bá jẹ mọ́ kíkọ́ni, bi ara rẹ léèrè pé: ‘Ǹjẹ́ mo lo ọ̀nà tí a gbà ń kọ́ni ní ti gidi? Ǹjẹ́ mo ṣe iṣẹ́ yẹn lọ́nà tí yóò fi lè mú kí àwọn tó gbọ́ ọ ṣe àyípadà nínú ìgbésí ayé wọn?’
Bí a ṣe ń gbà ọ́ níyànjú pé kí o lo ẹ̀bùn rẹ, yóò gba pé kí o lo ìdánúṣe. Ǹjẹ́ o máa ń lo ìdánúṣe láti bá àwọn ará ṣiṣẹ́ pọ̀ lóde ẹ̀rí? Ǹjẹ́ o máa ń wá ọ̀nà láti ran àwọn ará ìjọ rẹ tó jẹ́ ẹni tuntun, ọ̀dọ́, tàbí ẹni tó ń ṣàìsàn lọ́wọ́? Ǹjẹ́ o máa ń yọ̀ǹda ara rẹ láti mú kí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà ní mímọ́, tàbí kó o ṣèrànwọ́ ní onírúurú ọ̀nà ní àpéjọ àgbègbè, àpéjọ àyíká àti ti àkànṣe? Ṣé o lè máa ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ látìgbàdégbà? Ṣé o lè di aṣáájú ọ̀nà déédéé tàbí kí o lọ ṣèrànwọ́ nínú ìjọ tí wọ́n ti nílò ìrànlọ́wọ́ gidigidi? Bí o bá jẹ́ arákùnrin, ṣé ò ń nàgà láti dójú ìlà ohun tí Ìwé Mímọ́ là sílẹ̀ fún ẹni tí yóò bá di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà? Bí o ṣe ń yọ̀ǹda ara rẹ láti ṣèrànwọ́ àti láti tẹ́wọ́ gba ẹrù iṣẹ́ sí, jẹ́ àmì tó ń fi ìlọsíwájú rẹ hàn.—Sm. 110:3.
Ipa Tí Ìrírí Ń Kó
Bó bá ṣe ọ́ bíi pé o kò fi bẹ́ẹ̀ ní ìrírí nípa ìgbé ayé Kristẹni, má bọkàn jẹ́ rárá. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè sọ “aláìní ìrírí di ọlọ́gbọ́n.” (Sm. 19:7; 119:130; Òwe 1:1-4) Bí a bá ń fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò, ó máa ń jẹ́ ká jàǹfààní látinú ìmọ̀ pípé tí Jèhófà ní, èyí tó níye lórí púpọ̀púpọ̀ ju ìmọ̀ yòówù kí á tipa ìrírí nìkan ní lọ. Ó sì máa ń ṣẹlẹ̀ pé, bí a ṣe ń tẹ̀ síwájú sí i nínú iṣẹ́ ìsìn wa sí Jèhófà, a máa ń ní ìrírí tó ṣeyebíye. Báwo la ó ṣe wá mú ìyẹn lò lọ́nà tó ṣàǹfààní?
Bójú ẹnì kan bá ti rí ọ̀pọ̀ nǹkan sẹ́yìn láyé yìí, bí nǹkan mìíràn bá sẹlẹ̀, onítọ̀hún lè ronú pé: ‘Irú nǹkan yìí ti ṣẹlẹ̀ sí mi rí. Mo mọ ohun tó yẹ ní ṣíṣe.’ Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀? Òwe 3:7 sọ pé: “Má ṣe di ọlọ́gbọ́n ní ojú ara rẹ.” Lóòótọ́ o, ó yẹ kí ìrírí ayé lè túbọ̀ múni gbé ipò tó bá dójú kọni láyé yẹ̀ wò láti onírúurú ìhà. Àmọ́ tí a bá ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, ó yẹ kí ìrírí wa ní ìgbésí ayé jẹ́ ká mọ̀ lọ́kàn wa pé láìsí ìbùkún Jèhófà, ìsapá ẹni ò lè láṣeyọrí rárá. Ó hàn pé kì í ṣe ìdára-ẹni-lójú àti ìgboyà tá a bá fi kojú àwọn ipò tó bá dojú kọ wá ló ń fi hàn pé a ti ní ìlọsíwájú, bí kò ṣe bí a ṣe tètè máa ń yíjú sí Jèhófà fún ìtọ́sọ́nà ní ìgbésí ayé wa. Ó máa ń hàn nínú dídá tí ó bá dá wa lójú pé kò sóhun tó lè ṣẹlẹ̀ láìjẹ́ pé Ọlọ́run gbà á láyè, àti nínú bí a ṣe ń rí i pé a ní àjọṣe tímọ́tímọ́ tó ṣeé fọkàn tẹ̀ láàárín àwa àti Bàbá wa ọ̀run.
Máa Bá A Lọ Láti Nàgà Sóhun Tí Ń Bẹ Níwájú
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ Kristẹni ẹni àmì òróró tó ti dàgbà dénú nípa tẹ̀mí, síbẹ̀ ó ṣì rí i pé ó ṣe pàtàkì pé kí òun máa bá a lọ ní ‘nínàgà sóhun tí ń bẹ níwájú’ kí ọwọ́ òun lè tẹ ìyè. (Fílí. 3:13-16) Ṣé ìwọ náà rí i pé ó yẹ kó o ṣe bẹ́ẹ̀?
Ibo ni ìtẹ̀síwájú rẹ dé ná? Ohun tó o máa fi díwọ̀n ìtẹ̀síwájú rẹ ni bóyá o ti gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀ pátápátá tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, bí o ṣe ń tẹrí ba fún ipò ọba aláṣẹ Jèhófà tó, àti bí o ṣe ń fi taápọntaápọn lo ẹ̀bùn rẹ láti fi bu ọlá fún Un tó. Bí o ṣe ń jàǹfààní nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ó yẹ kí àwọn ànímọ́ tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń tẹnu mọ́ máa hàn ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé nínú ọ̀nà tó o gbà ń sọ̀rọ̀ àti bí o ṣe ń kọ́ni. Gbájú mọ́ ohun wọ̀nyí nínú ìtẹ̀síwájú rẹ. Fi wọ́n ṣe ìdùnnú rẹ, ó dájú pé ìlọsíwájú rẹ yóò sì hàn kedere.