APÁ 7
Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìsìn Tòótọ́?
1. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe láti mú inú Ọlọ́run dùn?
LÁTI ní àjọṣe alárinrin tó dán mọ́rán pẹ̀lú Ọlọ́run, a kò gbọ́dọ̀ kópa nínú ìsìn èké rárá. A gbọ́dọ̀ máa ṣe ìsìn tòótọ́. Lónìí, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn jákèjádò ayé ló ń ṣe bẹ́ẹ̀.
2. Ibo la ti lè rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kí sì ni iṣẹ́ wọn?
2 Bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, àwọn olùjọsìn tòótọ́ ló para pọ̀ di “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí wọ́n jáde wá “láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n.” (Ìṣípayá 7:9) Ní òjìlérúgba ó dín márùn-ún [235] orílẹ̀-èdè ni àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń fi taratara ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ọ̀nà onífẹ̀ẹ́ ti Jèhófà àti àwọn ohun tó fẹ́ ká ṣe.
Dídá Àwọn Olùjọsìn Tòótọ́ Mọ̀
3. Ta ni àwọn Ẹlẹ́rìí ń darí ìjọsìn wọn sí, irú ìjọsìn wo ni wọn kì í sì í lọ́wọ́ nínú rẹ̀?
3 Àwọn Ẹlẹ́rìí mọ̀ pé Jèhófà nìkan ṣoṣo ló yẹ ká máa jọ́sìn. Wọn kì í tẹrí ba fún àwọn òrìṣà tàbí ère ìsìn. (1 Jòhánù 5:21) Wọn kì í júbà òkú nípa ṣíṣe àìsùn òkú tàbí àwọn ayẹyẹ mìíràn tó ń gbé àwọn ohun tí wọ́n gbà gbọ́ nínú ìsìn èké àti “àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀mí èṣù” lárugẹ. (1 Tímótì 4:1) Ṣùgbọ́n, wọ́n ń tu àwọn tí èèyàn wọn kú nínú nípa ṣíṣàlàyé ìlérí Ọlọ́run pé àjíǹde àwọn òkú sínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé yóò wà.—Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 24:15.
4. Bó bá dọ̀ràn iṣẹ́ òkùnkùn, ojú wo làwọn èèyàn Ọlọ́run fi ń wò ó?
4 Àwọn Ẹlẹ́rìí kì í ṣiṣẹ́ òkùnkùn, wọ́n kì í tọ adáhunṣe lọ, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í wọ ẹgbẹ́ àjẹ́ nítorí wọ́n mọ̀ pé ọ̀dọ̀ Èṣù ni àwọn nǹkan wọ̀nyí ti wá. Wọn kì í gbẹ́kẹ̀ lé iṣẹ́ òkùnkùn láti fi dáàbò bo ara wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà ni wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé.—Òwe 18:10.
5. Ọ̀nà wo ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ‘kò fi jẹ́ apá kan ayé’?
5 Jésù sọ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ‘kò ní jẹ́ apá kan ayé.’ (Jòhánù 17:16) Jésù alára kọ̀ láti lọ́wọ́ nínú ìṣèlú ìgbà ayé rẹ̀. (Jòhánù 6:15) Bákan náà, àwọn Ẹlẹ́rìí kì í lọ́wọ́ nínú ìṣèlú, wọn kì í lọ́wọ́ nínú ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kópa nínú ìdíje bó-o-bá-a-o-pa-á bó-ò-bá-a-o-bù-ú-lẹ́sẹ̀ ayé yìí. Ṣùgbọ́n, wọ́n máa ń san owó orí, wọ́n sì máa ń ṣègbọràn sí òfin orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń gbé.—Jòhánù 15:19; Róòmù 13:1, 7.
6. Ìlànà wo làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa ń tẹ̀ lé nípa ìgbéyàwó àti ìkọ̀sílẹ̀?
6 Nítorí pé àwọn Ẹlẹ́rìí máa ń ṣègbọràn sí àṣẹ ìjọba, wọ́n máa ń rí i dájú pé wọ́n fìdí ìgbéyàwó wọn múlẹ̀ lábẹ́ òfin. (Títù 3:1) Wọ́n ń ṣègbọràn sí ìtọ́ni Ọlọ́run, ìdí sì nìyẹn tí wọ́n fi ń yàgò fún ìkóbìnrinjọ. (1 Tímótì 3:2) Síwájú sí i, níwọ̀n bí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nínú ìgbésí ayé wọn, ìgbéyàwó wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ bá a débi ìkọ̀sílẹ̀.
7. Báwo làwọn Ẹlẹ́rìí ṣe ń fi ìfẹ́ hàn sí ara wọn?
7 Àwọn Ẹlẹ́rìí nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n jẹ́ onírúurú ẹ̀yà, tí wọ́n sì wá láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, ìfẹ́ yìí, pa pọ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ tí wọ́n ní sí Ọlọ́run ń mú wọn ṣọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ ará tòótọ́. Nígbà tí jàǹbá bá ṣẹlẹ̀ tàbí nígbà tí àwọn kan bá wà ní ipò àìní gidigidi, àwọn Ẹlẹ́rìí tètè máa ń ran ara wọn lọ́wọ́. Àwọn Ẹlẹ́rìí máa ń fi ìfẹ́ hàn nínú ọ̀nà tí wọ́n ń gbà gbé ìgbé ayé wọn.—Jòhánù 13:35.
8. Àwọn àṣà búburú wo ni àwọn èèyàn Ọlọ́run kì í lọ́wọ́ nínú rẹ̀?
8 Àwọn èèyàn Jèhófà máa ń sapá gidigidi láti gbé ìgbé ayé aláìlábòsí àti ti adúróṣinṣin. Wọn kì í jalè, wọn kì í purọ́, wọn kì í ṣe ìṣekúṣe, wọn kì í mutí para, wọn kì í sì í ṣòwò tó lábòsí nínú. Àwọn ọkọ kì í lu aya wọn. Kí àwọn kan tó di Ẹlẹ́rìí, wọ́n ti ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrànwọ́ Jèhófà, wọ́n ti jáwọ́ ńbẹ̀. Wọ́n ti di ẹni tí ‘a wẹ̀ mọ́’ lójú Ọlọ́run.—1 Kọ́ríńtì 6:9-11.
Àwọn Tó Ń Ṣe Ohun Tí Ọlọ́run Fẹ́
9. Kí ni ìwé kan sọ nípa àwọn ṣọ́ọ̀ṣì mẹ́mìí-mẹ́mìí ní ilẹ̀ Áfíríkà?
9 Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ ìsìn ń sọ pé òtítọ́ wà lọ́dọ̀ àwọn. Wọ́n lè tọ́ka sí àwọn nǹkan tó ń wúni lórí láti fi ti ọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn. Bí àpẹẹrẹ, nípa àwọn tí wọ́n ń pè ní ṣọ́ọ̀ṣì mẹ́mìí-mẹ́mìí nílẹ̀ Áfíríkà, ìwé kan sọ pé: “Ní ọ̀pọ̀ ọ̀nà, [àwọn àwùjọ Kristẹni tuntun] ti gba iṣẹ́ táwọn aláwo tàbí àwọn adáhunṣe máa ń ṣe. . . . Wọ́n sọ pé àwọn máa ń sọ àsọtẹ́lẹ̀, àwọn sì máa ń ṣe iṣẹ́ ìyanu. Àwọn tó jẹ́ wòlíì láàárín wọn máa ń ríran, wọ́n sì máa ń túmọ̀ àlá. Wọ́n máa ń lo omi mímọ́, òróró mímọ́, eérú, àbẹ́là àti tùràrí láti ṣèwòsàn àti láti dènà àrùn.”
10, 11. Kí nìdí tí ohun táwọn èèyàn ń pè ní iṣẹ́ ìyanu lónìí kò ṣe jẹ́ ẹ̀rí pé ìsìn kan ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá?
10 Àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì wọ̀nyẹn máa ń sọ pé iṣẹ́ ìyanu ibẹ̀ ló ń fi hàn pé Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba ìsìn àwọn. Ṣùgbọ́n ohun tí wọ́n ń pè ní iṣẹ́ ìyanu yẹn kì í ṣe ẹ̀rí pé Jèhófà tẹ́wọ́ gba ìsìn kan. Sátánì máa ń fún àwọn onísìn èké kan lágbára láti ṣe ‘àwọn iṣẹ́ agbára.’ (2 Tẹsalóníkà 2:9) Síwájú sí i, Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ẹ̀bùn iṣẹ́ ìyanu látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, irú bíi sísọtẹ́lẹ̀, sísọ̀rọ̀ ní ahọ́n àjèjì àti ìmọ̀ àrà ọ̀tọ̀ ni a óò “mú . . . wá sí òpin.”—1 Kọ́ríńtì 13:8.
11 Jésù kìlọ̀ pé: “Kì í ṣe olúkúlùkù ẹni tí ń wí fún mi pé, ‘Olúwa, Olúwa,’ ni yóò wọ ìjọba ọ̀run, bí kò ṣe ẹni tí ń ṣe ìfẹ́ Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run ni yóò wọ̀ ọ́. Ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò wí fún mi ní ọjọ́ yẹn pé, ‘Olúwa, Olúwa, àwa kò ha sọ tẹ́lẹ̀ ní orúkọ rẹ, tí a sì lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde ní orúkọ rẹ, tí a sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ agbára ní orúkọ rẹ?’ Síbẹ̀síbẹ̀, ṣe ni èmi yóò jẹ́wọ́ fún wọn pé: Èmi kò mọ̀ yín rí! Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin oníṣẹ́ ìwà àìlófin.”—Mátíù 7:21-23.
12. Ta ni yóò wọ Ìjọba ọ̀run?
12 Nígbà náà, ta ni yóò wọ Ìjọba ọ̀run? Àwọn tó ń ṣe ìfẹ́ Jèhófà ni.
Àwọn Oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run
13. Iṣẹ́ wo ni Ọlọ́run sọ pé káwọn èèyàn òun máa ṣe lónìí, àwọn wo ló sì ń ṣe é?
13 Kí ni Ọlọ́run ń fẹ́ kí àwọn èèyàn òun máa ṣe lónìí? Jésù sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mátíù 24:14) Iṣẹ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fi ìtara ṣe nìyẹn.
14. Kí ni Ìjọba Ọlọ́run, ta ni yóò sì ṣàkóso nínú Ìjọba náà?
14 Jákèjádò “gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé,” àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń polongo Ìjọba Ọlọ́run pé ó jẹ́ ìjọba ọ̀run kan tí yóò ṣàkóso gbogbo ilẹ̀ ayé ní òdodo. Wọ́n ń kọ́ni pé Jèhófà ti yan Kristi Jésù láti jẹ́ Ọba Ìjọba náà, pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì alájùmọ̀ṣàkóso tí Ọlọ́run yàn nínú aráyé.—Dáníẹ́lì 7:14, 18; Ìṣípayá 14:1, 4.
15. Kí ni Ìjọba náà yóò pa run?
15 Àwọn Ẹlẹ́rìí ń fi han àwọn èèyàn látinú Bíbélì pé Ìjọba Ọlọ́run yóò pa ètò Sátánì run látòkèdélẹ̀. Ìsìn èké àti àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ tí kò bọlá fún Ọlọ́run, tó sì ń fògo fún Èṣù yóò pa run! (Ìṣípayá 18:8) Gbogbo ìjọba èèyàn tí ó ń ta ko Ọlọ́run yóò pa run pẹ̀lú!—Dáníẹ́lì 2:44.
16. Àwọn wo ni yóò jẹ́ ọmọ abẹ́ fún Kristi Jésù, ibo ni wọn yóò sì máa gbé?
16 Ní àfikún sí i, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sọ ọ́ di mímọ̀ pé Kristi Jésù yóò mú àǹfààní àgbàyanu wá bá gbogbo àwọn tó bá ń ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Wọn yóò jẹ́ ọmọ abẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Bíbélì ṣèlérí pé: “Òun yóò dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè, ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ pẹ̀lú, àti ẹnì yòówù tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Òun yóò káàánú ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì, yóò sì gba ọkàn àwọn òtòṣì là.”—Sáàmù 72:12, 13.
17. Kìkì àwọn wo ló ń polongo Ìjọba Ọlọ́run?
17 Kò tún sí àwùjọ èèyàn mìíràn tó ń ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ nípa wíwàásù ìhìn rere Ìjọba náà. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ṣoṣo ló ń polongo Ìjọba Ọlọ́run jákèjádò gbogbo ilẹ̀ ayé.