ORÍ 1
Ohun Tó Mú Kí Jésù Jẹ́ Olùkọ́ Ńlá
NÍ OHUN tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì ọdún sẹ́yìn, ẹnì kan bí ọmọ kan tó yàtọ̀ gan-an. Ọmọ yìí dàgbà ó dẹni ńlá tó lókìkí ju gbogbo èèyàn tó ti ń gbé lórí ilẹ̀ ayé yìí lọ. Ọkọ̀ òfuurufú tàbí ọkọ̀ ilẹ̀ kò sí láyé ìgbà yẹn. Kò sí tẹlifíṣọ̀n, kò sí rédíò, bẹ́ẹ̀ ni kò sí tẹlifóònù nígbà tá à ń wí yìí.
Jésù lorúkọ ọmọ náà. Ó di ẹni tó gbọ́n jù lọ lórí ilẹ̀ ayé. Ó sì tún wá di olùkọ́ tó mọ èèyàn kọ́ jù lọ. Ó máa ń ṣàlàyé ohun tó bá ń sọ lọ́nà tó máa tètè yéni.
Gbogbo ibi tí Jésù bá ti rí àwọn èèyàn ló ti máa ń kọ́ wọn. Ó kọ́ àwọn èèyàn létí òkun àti nínú ọkọ̀ ojú omi. Ó ń kọ́ wọn nínú ilé wọn ó sì tún ń kọ́ wọn lójú ọ̀nà nígbà tó bá ń rìnrìn àjò. Jésù kò ní mọ́tò, bẹ́ẹ̀ ni kò sì tíì sí ọkọ̀ èrò tàbí ọkọ̀ ojú irin nígbà yẹn tó lè máa wọ̀ lọ sí ibi tó bá fẹ́ lọ. Ẹsẹ̀ ni Jésù fi ń rìn káàkiri láti kọ́ àwọn èèyàn.
Ọ̀pọ̀ nǹkan tá a mọ̀ ló jẹ́ pé ẹnì kan ló kọ́ wa. Àmọ́ ọ̀dọ̀ Jésù Olùkọ́ Ńlá náà la ti lè kọ́ àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ. Inú Bíbélì ni àwọn ọ̀rọ̀ Jésù wà. Nígbà tá a bá ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù tàbí tá à ń kà á nínú Bíbélì, bí ẹni pé Jésù gan-an ló ń bá wa sọ̀rọ̀ ni.
Kí nìdí tí Jésù fi jẹ́ Olùkọ́ Ńlá bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ẹnì kan ti kọ́ Jésù lẹ́kọ̀ọ́. Jésù sì mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì láti máa fetí sílẹ̀. Ta ni Jésù wá fetí sílẹ̀ sí? Ta ló kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́?— Bàbá rẹ̀ ni. Ọlọ́run sì ni Bàbá Jésù.
Kí Jésù tó wá sí ayé bí èèyàn, ọ̀run ló ń gbé lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Nítorí náà, Jésù yàtọ̀ sí àwọn èèyàn yòókù láyé torí pé kò sí èèyàn mìíràn tó ti gbé lọ́run kí wọ́n tó wá bí i sí ayé. Ọmọ tó máa ń gbọ́ràn sí Bàbá rẹ̀ lẹ́nu ni Jésù nígbà tó wà lọ́run, ó máa ń fetí sílẹ̀ dáadáa. Ìyẹn ló jẹ́ kí Jésù lè kọ́ àwọn èèyàn ní ohun tó ti gbọ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Ìwọ náà lè dà bí Jésù tó o bá ń fetí sí bàbá rẹ àti ìyá rẹ.
Ohun tó tún mú Jésù jẹ́ Olùkọ́ Ńlá ni pé ó fẹ́ràn àwọn èèyàn. Ó fẹ́ láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè kọ́ nípa Ọlọ́run. Jésù fẹ́ràn àwọn àgbàlagbà, ó sì tún fẹ́ràn àwọn ọmọdé pẹ̀lú. Àwọn ọmọdé sì máa ń fẹ́ láti lọ sọ́dọ̀ Jésù torí pé ó máa ń bá wọn sọ̀rọ̀ ó sì máa ń fetí sí ohun táwọn ọmọdé bá ń sọ.
Lọ́jọ́ kan, àwọn òbí kan mú ọmọ wọn kéékèèké wá sọ́dọ̀ Jésù. Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rẹ́ Jésù ronú pé Olùkọ́ Ńlá náà ò lè ráyè gbọ́ ti àwọn ọmọ kéékèèké. Ni wọ́n bá sọ pé kí wọ́n máa lọ. Ṣùgbọ́n kí ni Jésù sọ?— Ó sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ mi; ẹ má gbìyànjú láti dá wọn lẹ́kun.” Bẹ́ẹ̀ ni, Jésù fẹ́ kí àwọn ọmọdé wá sọ́dọ̀ òun. Bí Jésù ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n tó, tó sì tún jẹ́ èèyàn pàtàkì, ó ṣì máa ń wá àyè láti kọ́ àwọn ọmọdé.—Máàkù 10:13, 14.
Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí Jésù fi máa ń kọ́ àwọn ọmọdé tó sì máa ń fetí sí wọn? Ìdí kan ni pé ó ń fẹ́ kí wọ́n láyọ̀. Ohun tó ń sọ fún wọn nípa Ọlọ́run tó jẹ́ Bàbá rẹ̀ tó wà ní ọ̀run ni yóò mú kí wọ́n láyọ̀. Báwo ni ìwọ náà ṣe lè mú àwọn èèyàn láyọ̀?— O lè mú wọn láyọ̀ tó o bá ń sọ àwọn ohun tó o ti kọ́ nípa Ọlọ́run fún wọn.
Nígbà kan, Jésù lo ọmọ kékeré láti fi kọ́ àwọn ọ̀rẹ́ Rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan. Ohun tó ṣe ni pé, ó mú ọmọ kékeré kan dìde dúró sáàárín àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ̀. Jésù wá sọ fún àwọn àgbàlagbà náà pé wọ́n gbọ́dọ̀ yí ìwà wọn padà kí wọ́n dà bí ọmọ kékeré náà.
Kí ni Jésù ń fẹ́ kí wọ́n máa ṣe tó fi sọ ọ̀rọ̀ tó sọ yìí? Ǹjẹ́ o mọ bí àgbàlagbà kan tàbí ọmọ kan tó dàgbà jù ọ́ lọ ṣe lè sọ ara rẹ̀ di ọmọ kékeré?— Ó dára, ọmọ kékeré mọ̀ pé àgbàlagbà mọ nǹkan púpọ̀ ju òun lọ, nítorí náà á fẹ́ fara balẹ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, ohun tí Jésù ń sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ni pé wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ bíi tàwọn ọmọdé. Bẹ́ẹ̀ ni o, gbogbo wa pátá la lè rí ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ kọ́ lọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Ó yẹ kí gbogbo wa tún fi sọ́kàn pé àwọn ẹ̀kọ́ tí Jésù ń kọ́ni ṣe pàtàkì ju àwọn èrò tiwa fúnra wa lọ.—Mátíù 18:1-5.
Ìdí mìíràn tí Jésù tún fi jẹ́ Olùkọ́ Ńlá ni pé ó mọ bí a ti ń mú kí ẹ̀kọ́ dùn mọ́ni. Ó máa ń ṣàlàyé ọ̀rọ̀ lọ́nà tó rọrùn, tó sì ṣe kedere. Ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹyẹ, òdòdó àtàwọn nǹkan tá a sábà máa ń rí láti mú kó rọrùn fún àwọn èèyàn láti lóye àwọn ohun kan nípa Ọlọ́run.
Lọ́jọ́ kan, Jésù wà ní ẹ̀gbẹ́ òkè kan, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Jésù jókòó ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wàásù fún wọn, gẹ́gẹ́ bó o ṣe rí i nínú àwòrán yìí. Ìwàásù rẹ̀ yìí là ń pè ní Ìwàásù Lórí Òkè. Ó sọ pé: ‘Ẹ wo àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run. Wọn kì í gbin irúgbìn. Wọn kì í kó oúnjẹ pa mọ́ sínú ilé. Ọlọ́run tí ń bẹ lọ́run ló ń bọ́ wọn. Ṣé ẹ̀yin ò ṣe pàtàkì jù wọ́n lọ ni?’
Jésù tún sọ pé: ‘Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ lára àwọn òdòdó lílì inú pápá. Bí wọ́n ṣe ń dàgbà, wọn kì í ṣe iṣẹ́. Ẹ sì wo bí wọ́n ṣe lẹ́wà tó! A kò ṣe Sólómọ́nì Ọba pàápàá ní ọ̀ṣọ́ tó àwọn òdòdó lílì inú pápá. Torí náà, bí Ọlọ́run bá ń tọ́jú àwọn òdòdó tó ń dàgbà, ǹjẹ́ kò ní tọ́jú ẹ̀yin náà?’—Mátíù 6:25-33.
Ǹjẹ́ o mọ ẹ̀kọ́ tí Jésù ń kọ́ wa níbí?— Jésù kò fẹ́ ká máa dààmú nípa ibi tá a ti máa rí oúnjẹ tá a máa jẹ tàbí aṣọ tá a máa wọ̀. Ọlọ́run mọ̀ pé a nílò gbogbo nǹkan wọ̀nyẹn. Jésù kò sọ pé ká má ṣiṣẹ́ láti rí oúnjẹ tàbí aṣọ o. Ohun tó ń sọ ni pé Ọlọ́run ni kí á fi ṣáájú ohun gbogbo. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run á rí i dájú pé a ní oúnjẹ tá a máa jẹ àti aṣọ tá a máa wọ̀. Ǹjẹ́ o gbà bẹ́ẹ̀?—
Kí làwọn èèyàn ṣe lẹ́yìn tí Jésù parí ọ̀rọ̀ rẹ̀?— Bíbélì sọ pé ẹnu yà wọ́n gan-an nípa ọ̀nà tí Jésù gbà ń kọ́ni. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa ń gbádùn mọ́ni gan-an. Àwọn nǹkan tó sọ mú kí àwọn èèyàn ṣe ohun tí ó tọ́.—Mátíù 7:28.
Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Jésù. Ǹjẹ́ o mọ bá a ṣe lè ṣe é?— Ó dára, ọ̀rọ̀ Jésù ti wà lákọọ́lẹ̀ nínú ìwé kan. Ǹjẹ́ o mọ ìwé náà?— Bíbélì Mímọ́ ni. Èyí fi hàn pé a lè máa gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù tá a bá ń fiyè sí àwọn nǹkan tá à ń kà nínú Bíbélì. Ìtàn tó dùn kan tiẹ̀ wà nínú Bíbélì tó fi hàn pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ sọ fún wa pé ká fetí sí Jésù. Ìtàn náà lọ báyìí:
Lọ́jọ́ kan, Jésù mú mẹ́ta lára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, wọ́n sì lọ sórí òkè gíga kan. Orúkọ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ yìí ni Jákọ́bù, Jòhánù àti Pétérù. Tó bá yá, a ṣì máa kọ́ nǹkan púpọ̀ nípa àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí, nítorí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ Jésù tímọ́tímọ́. Àmọ́ bí wọ́n ṣe jọ wà lórí òkè lọ́jọ́ tí à ń wí yìí, ojú Jésù kàn dédé bẹ̀rẹ̀ sí tàn yanranyanran ni. Aṣọ rẹ̀ wá ń tàn yòò, gẹ́gẹ́ bó o ṣe rí i nínú àwòrán yìí.
Lẹ́yìn náà, Jésù àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ wá gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run. Ohùn náà sọ pé: “Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà; ẹ fetí sí i.” (Mátíù 17:1-5) Ǹjẹ́ o mọ ohùn ẹni tó jẹ́?— Ohùn Ọlọ́run ni! Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló sọ pé kí wọ́n máa fetí sí Ọmọ òun.
Àwa náà ńkọ́ lónìí? Ǹjẹ́ a ó ṣègbọràn sí Ọlọ́run ká sì fetí sí Ọmọ rẹ̀ Olùkọ́ Ńlá náà?— Ohun tó yẹ kí gbogbo wa ṣe nìyẹn. Ǹjẹ́ o rántí ọ̀nà tá a lè gbà fetí sí i?—
A lè fetí sí Ọmọ Ọlọ́run nípa kíka àwọn ìtàn tó sọ nípa ìgbésí ayé Jésù nínú Bíbélì. Àwọn nǹkan àtàtà tí Olùkọ́ Ńlá náà fẹ́ sọ fún wa pọ̀ rẹpẹtẹ. Tó o bá ń kà nípa nǹkan wọ̀nyí nínú Bíbélì yóò dùn mọ́ ọ gan-an. Ìwọ yóò sì tún láyọ̀ tó o bá ń sọ àwọn ohun rere tó ò ń kọ́ fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ.
Láti mọ̀ sí i nípa àwọn ohun rere téèyàn lè rí gbà látinú fífetí sí Jésù, ṣí Bíbélì rẹ kó o ka ìwé Jòhánù 3:16; 8:28-30; àti Ìṣe 4:12.