Ìgbà Ayé Àwọn Baba Ńlá
ORÚKỌ àwọn ìlú kan ni Sítéfánù dá láti fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹní mowó, ó sọ pé: “[Jèhófà] fara han Ábúráhámù baba ńlá wa nígbà tí ó wà ní Mesopotámíà, kí ó tó bẹ̀rẹ̀ sí gbé ní Háránì, ó sì wí fún un pé, ‘Lọ . . . sí ilẹ̀ tí èmi yóò fi hàn ọ́.’” (Ìṣe 7:1-4) Èyí ló fi nasẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì-pàtàkì tó kan Ábúráhámù, Ísákì, àti Jékọ́bù ní Ilẹ̀ Ìlérí, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún sì wé mọ́ ète Ọlọ́run láti bù kún ìran ènìyàn.—Jẹ 12:1-3; Joṣ 24:3.
Ọlọ́run pe Ábúráhámù (tàbí Ábúrámù) jáde láti Úrì, ìyẹn ìlú kan tó láásìkí púpọ̀ ní ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà. Apá ìlà oòrùn etí Odò Yúfírétì ni ìlú náà wà láyé àtijọ́. Ojú ọ̀nà wo ni Ábúráhámù ti ní láti gbà? Bí a bá wò ó láti Kálídíà, ìyẹn àgbègbè kan tí a tún ń pè ní Súmà tàbí Ṣínárì, ó jọ bíi pé ńṣe ni ì bá kàn lọ tààrà láti ibẹ̀ sápá ìwọ̀ oòrùn. Kí ló dé tó fi wá forí lé iyànníyàn Háránì lókè lọ́hùn ún?
Itòsí ẹkùn ìlà oòrùn Àgbègbè Ilẹ̀ Ọlọ́ràá ni ilẹ̀ Úrì wà, èyí tó bẹ̀rẹ̀ láti Palẹ́sìnì títí lọ dé gbogbo ilẹ̀ irà tó wà láàárín odò Tígírísì àti Yúfírétì. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ojú ọjọ́ kì í fi bẹ́ẹ̀ gbóná níbẹ̀ láyé ìgbà kan, tí ilẹ̀ ibẹ̀ kì í sì í sábàá gbẹ. Ilẹ̀ aṣálẹ̀ àwọn ará Síríà àti Arébíà, tó kún fún òkè olókùúta ẹfun, ló wà lápá ìsàlẹ̀ àgbègbè ọlọ́ràá yìí, ilẹ̀ ibẹ̀ sì jẹ́ pẹ̀tẹ́lẹ̀ oníyanrìn. Ìwé Encyclopædia Britannica sọ pé ilẹ̀ àárín etíkun Mẹditaréníà àti Mesopotámíà yìí “fẹ́rẹ̀ẹ́ má ṣeé gbà kọjá.” Ó ṣeé ṣe kí àwọn tó jẹ́ arìnrìn-àjò nínú aṣálẹ̀ máa ti ibi odò Yúfírétì kọjá sí Tádímórì, kí wọ́n sì gba ibẹ̀ lọ sí Damásíkù, àmọ́ Ábúráhámù ò kó ìdílé rẹ̀ àtàwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀ gba irú aginjù yìí ní tiẹ̀.
Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Ábúráhámù gba apá òkè àfonífojì Odò Yúfírétì lọ sí Háránì. Ó lè wá tibẹ̀ gba ojú ọ̀nà tí àwọn oníṣòwò máa ń gbà dé ibi odò aláfẹsẹ̀sọdá kan ní Kákémíṣì, lẹ́yìn náà kó wá forí lé apá ìhà gúúsù nítòsí Damásíkù títí tó máa fi dé ibi tá a wá ń pè ní Òkun Gálílì. Ojú Ọ̀nà Òkun tàbí “Via Maris,” wà láti Mẹ́gídò títí dé Íjíbítì. Àmọ́, àárín àwọn òkè ńlá tó wà ní Samáríà ni Ábúráhámù gbà lọ ní tiẹ̀, kí ó tó wá pàgọ́ sí Ṣékémù. Láìpẹ́ láìjìnnà, ó tún mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n lójú ọ̀nà ilẹ̀ olókè yẹn. Máa fọkàn bá a rìnrìn àjò yìí lọ bí o ṣe ń ka Jẹ́nẹ́sísì 12:8 sí 13:4. Kíyè sí àwọn àgbègbè tó wà lára ibi tó rìn dé, irú bíi: Dánì, Damásíkù, Hóbà, Mámúrè, Sódómù, Gérárì, Bíá-ṣébà, àti Móráyà (ìyẹn ní Jerúsálẹ́mù).—Jẹ 14:14-16; 18:1-16; 20:1-18; 21:25-34; 22:1-19.
Tí a bá mọ bí àwọn ìlú wọ̀nyẹn ṣe tò tẹ̀ lé ra, á jẹ́ ká lóye àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé Ísákì àti Jékọ́bù. Bí àpẹẹrẹ, lákòókò tí Ábúráhámù wà ní Bíá-ṣébà, ibo ló ní kí ìránṣẹ́ òun ti lọ wá ìyàwó wá fún Ísákì? Ṣebí apá òkè lọ́hùn-ún lójú ọ̀nà Mesopotámíà (tó túmọ̀ sí, “Ilẹ̀ Àárín Omi”) tó lọ sí Padani-árámù ni. Lẹ́yìn náà, wá fojú inú wo ìrìn-àjò gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ tí Rèbékà rìn lórí ràkúnmí láti lọ bá Ísákì ní Négébù, ìyẹn bóyá nítòsí Kádéṣì.—Jẹ 24:10, 62-64.
Nígbà tó yá, Jékọ́bù (Ísírẹ́lì) ọmọ wọn rin irú ìrìn-àjò gígún bẹ́ẹ̀ láti lọ fẹ́ olùjọsìn Jèhófà kan níyàwó. Ojú ọ̀nà mìíràn ni Jékọ́bù gbà padà sí ìlú rẹ̀. Lẹ́yìn tí Jékọ́bù fẹsẹ̀ gba odò Jábókù tó wà nítòsí Pénúélì kọjá, ó bá áńgẹ́lì kan wọ ìwàyá ìjà. (Jẹ 31:21-25; 32:2, 22-30) Àgbègbè yìí ni Ísọ̀ ti pàdé rẹ̀, lẹ́yìn náà àwọn méjèèjì pínyà láti lọ máa gbé lágbègbè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.—Jẹ 33:1, 15-20.
Lẹ́yìn tí wọ́n fipá bá Dínà ọmọ Jékọ́bù lò pọ̀ ní ìlú Ṣékémù, Jékọ́bù ṣí lọ sí Bẹ́tẹ́lì. Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo bí ibi táwọn ọmọ Jékọ́bù ti lọ ń tọ́jú ẹran ọ̀sìn bàbá wọn àti ibi tí Jósẹ́fù ti rí wọn lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn ti jìnnà tó? Àwòrán ilẹ̀ yìí (àti ti ojú ìwé 18 sí 19) lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rí bí Hébúrónì àti Dótánì ti jìnnà síra wọn tó. (Jẹ 35:1-8; 37:12-17) Àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù ta Jósẹ́fù fáwọn oníṣòwò tó ń lọ sí Íjíbítì. Ṣé kì í ṣe ojú ọ̀nà táwọn oníṣòwò yẹn gbà lọ lo rò pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì padà wá gbà nígbà tí wọ́n ń lọ́ sí Íjíbítì lẹ́yìn ìgbà náà, tí wọ́n sì tún gbà á padà bọ̀?—Jẹ 37:25-28.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 7]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Ìrìn àjò Ábúráhámù (wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Ìrìn àjò Ísákì (wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Ìrìn àjò Jékọ́bù (wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Ojú Ọ̀nà Pàtàkì (wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Àwọn Baba Ńlá (àpèjúwe bó ṣe rí)
A4 GÓṢÉNÌ
A5 ÍJÍBÍTÌ
B4 ṢÚRÌ
B5 PÁRÁNÌ
D3 Damásíkù
D3 Dánì (Láíṣì)
D4 Ṣékémù
D4 Bẹ́tẹ́lì
D4 Hébúrónì (Kiriati-ábà)
D4 Gérárì
D4 Bíá-ṣébà
D4 SÉÍRÌ
D4 Kádéṣì
D5 ÉDÓMÙ
E1 Kákémíṣì
E2 Tádímórì
E3 Hóbà
Ẹ1 PADANI-ÁRÁMÙ
Ẹ1 Háránì
F2 MESOPOTÁMÍÀ
G1 Nínéfè
G2 ÀGBÈGBÈ ILẸ̀ ỌLỌ́RÀÁ
G3 Bábílónì
GB4 KÁLÍDÍÀ
GB4 Úrì
[Àwọn Òkè]
D4 Móráyà
[Omi]
B3 Òkun Mẹditaréníà (Òkun Ńlá)
[Odò]
Ẹ2 Yúfírétì
G2 Tígírísì
Àwọn Baba Ńlá (ní Ilẹ̀ Ìlérí)
KÉNÁÁNÌ
Mẹ́gídò
GÍLÍÁDÌ
Dótánì
Ṣékémù
Súkótù
Máhánáímù
Pénúélì
Bẹ́tẹ́lì (Lúsì)
Áì
Jerúsálẹ́mù (Sálẹ́mù)
Bẹ́tílẹ́hẹ́mù (Éfúrátì)
Mámúrè
Hébúrónì (Mákípẹ́là)
Gérárì
Bíá-ṣébà
Sódómù?
NÉGÉBÙ
Réhóbótì?
Bia-laháí-róì
Kádéṣì
Ojú Ọ̀nà Pàtàkì
Ojú Ọ̀nà Òkun
Ojú Ọ̀nà Ọba
[Àwọn Òkè]
Móráyà
[Omi]
Òkun Iyọ̀
[Àwọn Odò]
Jábókù
Jọ́dánì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Odò Yúfírétì nítòsí Bábílónì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Ábúráhámù gbé ní Bíá-ṣébà, ó sì ń tọ́jú àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀ nítòsí ibẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Jábókù