Ìrìn Àjò Láti Íjíbítì Sí Ilẹ̀ Ìlérí
KÒ SÍ ibi táwọn èèyàn ò ti mọ̀ nípa ìṣíkúrò àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ilẹ̀ Íjíbítì. Àmọ́ kí ni Mósè àtàwọn èèyàn Ọlọ́run wá bá pàdé lẹ́yìn tí wọ́n la Òkun Pupa já tán? Ibo ni wọ́n dorí kọ, báwo ni wọ́n sì ṣe dé Odò Jọ́dánì tí wọ́n máa gbà dé Ilẹ̀ Ìlérí?
Ilẹ̀ Kénáánì gan-an níbi tí wọ́n ń lọ, àmọ́ Mósè kò mú wọn gba ọ̀nà tó yá, ìyẹn èyí tó jẹ́ nǹkan bí irínwó [400] kìlómítà tí wọ́n bá gba etíkun oníyanrìn, tí ì bá sì mú wọn já sí Filísíà tààràtà, tí í ṣe agbègbè àwọn ọ̀tá. Bẹ́ẹ̀ ni kò gba àgbègbè Sínáì tí omi yí ká, níbi tí oòrùn ganrínganrín ti máa ń mú káwọn òkúta wẹ́wẹ́ àti òkúta ẹfun ilẹ̀ náà gbóná janjan. Mósè ò kó wọn gbabẹ̀ o, apá ìhà gúúsù ló kó àwọn èèyàn náà gbà, lápá ọ̀nà etíkun tó ṣe tóóró. Márà ni ibi àkọ́kọ́ pàá tí wọ́n pàgọ́ sí, níbi tí Jèhófà ti sọ omi kíkorò di omi tó ṣeé mu.a Lẹ́yìn táwọn èèyàn náà kúrò ní Élímù, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ráhùn nítorí oúnjẹ; Ọlọ́run wá dárí àwọn àparò sọ́dọ̀ wọn ó sì tún rọ̀jò mánà fún wọn. Ní Réfídímù, omi tún dá ìjàngbọ̀n sílẹ̀, ibẹ̀ ni wọ́n wà tí wọ́n ti ṣẹ́gun àwọn ará Ámálékì tó wá kọ lù wọ́n, ibẹ̀ ni bàbá ìyàwó Mósè sì ti gba Mósè nímọ̀ràn pé kó jẹ́ kí àwọn ọkùnrin tó kúnjú òṣùwọ̀n máa ràn án lọ́wọ́.—Ẹk, orí 15 sí 18.
Lẹ́yìn èyí, Mósè kó Ísírẹ́lì gba ibi tí àwọn òkè ńláńlá wà níhà gúúsù lọ́hùn-ún, wọ́n sì pàgọ́ sí Òkè Sínáì. Ibẹ̀ làwọn èèyàn Ọlọ́run ti gba Òfin, tí wọ́n kọ́ àgọ́ ìjọsìn, tí wọ́n sì rú àwọn ẹbọ. Ní ọdún kejì, wọ́n kọrí sí ìhà àríwá wọ́n sì la “aginjù ńlá àti amúnikún-fún-ẹ̀rù” kọjá, ìrìn àjò wọn sí àgbègbè Kádéṣì (Kadeṣi-báníà) yóò sì gbà tó ọjọ́ mọ́kànlá gbáko. (Di 1:1, 2, 19; 8:15) Nítorí pé àwọn èèyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀rù nítorí ìròyìn burúkú tí àwọn amí mẹ́wàá mú wá, wọ́n dẹni tó ń rìn káàkiri fún odindi ọdún méjìdínlógójì. (Nu 13:1-14:34) Lára àwọn ibi tí wọ́n ti dúró ni Ábúrónà àti Esioni-gébérì, lẹ́yìn náà ni wọ́n tún ṣẹ́rí padà sí Kádéṣì.—Nu 33:33-36.
Nígbà tí àkókò jàjà tó fún Ísírẹ́lì láti wọ Ilẹ̀ Ìlérí, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò gba ọ̀nà àríwá ní tààràtà. Ọ̀nà tí wọ́n gbà mú kí wọ́n já sí ọ̀gangan ilẹ̀ Édómù wọ́n sì kọjú síhà àríwá ní ojú “ọ̀nà ọba,” ìyẹn ọ̀nà tí wọ́n ń pè ní Òpópónà Ọba. (Nu 21:22; Di 2:1-8) Kò rọrùn rárá fún odindi orílẹ̀-èdè kan, tó ní àwọn ọmọ wẹ́wẹ́, ẹran ọ̀sìn, àtàwọn àgọ́, láti gba ojú ọ̀nà yìí. Wọ́n ní láti rìn kọ́lọkọ̀lọ lọ sísàlẹ̀ kí wọ́n sì tún gòkè padà wá jáde lójú ọ̀nà tó ṣòro láti rìn náà, ìyẹn àwọn ọ̀nà Séréédì àti Áánónì (tó jìnnà sísàlẹ̀ tó okòó lé lẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta mítà [520 m]).—Di 2:13, 14, 24.
Níkẹyìn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dé Òkè Nébò. Míríámù ti kú ní Kádéṣì, Áárónì sì ti kú ní Òkè Hóórì. Ibi tí wọ́n dé yìí ni Mósè kú sí, ìyẹn Òkè Nébò níbi tí Mósè ti lè rí ilẹ̀ tó ń wù ú láti wọ̀ náà lọ́ọ̀ọ́kán. (Di 32:48-52; 34:1-5) Lẹ́yìn rẹ̀, Jóṣúà ni ẹrù iṣẹ́ mímú Ísírẹ́lì wọ ilẹ̀ ìlérí jálé léjìká. Èyí sì ni òpin ìrìn àjò tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ láti ogójì ọdún sẹ́yìn.—Joṣ 1:1-4.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Kò sẹ́ni tó mọ ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọ̀gangan ibòmíràn tí wọ́n tún pàgọ́ sí.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 9]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Ojú Ọ̀nà Ìjádelọ
Ojú Ọ̀nà Tí Orílẹ̀-Èdè Ísírẹ́lì Gbà
A7 ÍJÍBÍTÌ
A5 Rámésésì?
B5 Súkótù?
D5 Étámù?
D5 Píháhírótì
E6 Máráhì
E6 Élímù
Ẹ6 AGINJÙ SÍNÌ
Ẹ7 Dófíkà
F8 Réfídímù
F8 Òkè Sínáì (Hórébù)
F8 AGINJÙ SÍNÁÌ
F7 Kiburoti- hátááfà
G7 Hásérótì
G6 Rimoni-pérésì
G5 Rísà
G3 Kádéṣì
G3 Bẹne-jáákánì
G5 Hoori-hágígádì
GB5 Jótíbátà
GB5 Ábúrónà
GB6 Esioni-gébérì
G3 Kádéṣì
G3 AGINJÙ SÍÍNÌ
GB3 Òkè Hóórì
GB3 Sálímónà
I3 Púnónì
I3 Iye-ábárímù
I2 MÓÁBÙ
I1 Díbónì
I1 Alimoni-díbílátáímù
GB1 Jẹ́ríkò
[Àwọn ìbòmíì]
A3 GÓṢÉNÌ
A4 Ónì
A5 Mémúfísì (Nófì)
B3 Sóánì
B3 Tápánẹ́sì
D5 Mígídólì
E3 ṢÚRÌ
E5 AGINJÙ ÉTÁMÙ
F5 AGINJÙ PÁRÁNÌ
G1 FILÍSÍÀ
G1 Áṣídódì
G2 Gásà
G2 Bíá-ṣébà
G3 Ásímónì
G3 NÉGÉBÙ
GB1 Jerúsálẹ́mù
GB1 Hébúrónì (Kiriati-ábà)
GB2 Árádì (Ọmọ Kénáánì)
GB4 SÉÍRÌ
GB4 ÉDÓMÙ
I7 MÍDÍÁNÌ
Ojú Ọ̀nà Pàtàkì
Ọ̀nà Tó Lọ sí Ilẹ̀ Àwọn Fílísínì
Ọ̀nà Tó Lọ sí Ṣúrì
Ojú Ọ̀nà Ọba
Ojú Ọ̀nà Tí Wọ́n Ń Gbà Nínú Aṣálẹ̀
Ojú Ọ̀nà Ẹli Hájì
[Àwọn Òkè]
F8 Òkè Sínáì (Hórébù)
GB3 Òkè Hóórì
I1 Òkè Nébò
[Omi]
Ẹ2 Òkun Mẹditaréníà (Òkun Ńlá)
E7/G7 Òkun Pupa
I1 Òkun Iyọ̀
[Àwọn Odò]
A6 Odò Náílì
F3 A.O. Íjíbítì
I2 Áánónì
I3 Séréédì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Àwọn arìnrìn-àjò nínú aṣálẹ̀ ń kọjá ní àgbègbè Sínáì tí omi yí ká
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Ísírẹ́lì pàgọ́ síwájú Òkè Sínáì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Wọ́n rí omi lò nínú àwọn ìsun omi tó wà ní Kádéṣì tàbí àwọn tó wà nítòsí ibẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Gbogbo Ísírẹ́lì ní láti kọjá ní àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Áánónì