ORÍ KẸRÌNDÍNLÓGÚN
“Jésù . . . Nífẹ̀ẹ́ Wọn Dé Òpin”
1, 2. Báwo ni Jésù ṣe lo alẹ́ tó kẹ́yìn pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, kí sì nìdí tó fi ka wákàtí mélòó kan tó kù yìí sí pàtàkì tó bẹ́ẹ̀?
BÍ JÉSÙ ṣe kó gbogbo àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ jọ sí yàrá òkè ní Jerúsálẹ́mù, ó mọ̀ pé alẹ́ yẹn lòun máa fi wà pẹ̀lú wọn kẹ́yìn. Àkókò tó máa padà sọ́dọ̀ Bàbá rẹ̀ ti sún mọ́lé. Tó bá fi máa tó wákàtí mélòó kan sí àkókò yẹn, wọ́n máa fi àṣẹ ọba mú un, èyí sì máa jẹ́ ìdánwò ìgbàgbọ́ tí kò rí irú rẹ̀ rí. Síbẹ̀ pẹ̀lú bí ikú rẹ̀ ṣe rọ̀ dẹ̀dẹ̀ tó yẹn, ọkàn rẹ̀ ò kúrò lára àwọn àpọ́sítélì rẹ̀.
2 Jésù ti sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé òun máa tó fi wọ́n sílẹ̀, àmọ́ ní báyìí, ó ṣì ní àwọn nǹkan míì tó fẹ́ bá wọn sọ láti lè fún wọn lókun kí wọ́n bàa lè dúró gbọin lójú àdánwò tí ń bẹ níwájú. Nítorí náà, ńṣe ló lo àkókò ráńpẹ́ tó kù yìí láti kọ́ wọn láwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tó máa jẹ́ kí wọ́n lè dúró bí olùṣòtítọ́. Àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ lálẹ́ ọjọ́ yẹn wà lára àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó wọ̀ wọ́n lọ́kàn jù tó sì túbọ̀ mú kí àárín wọn gún régé sí i. Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ fi jẹ ẹ́ lógún ju ọ̀rọ̀ ara rẹ̀ lọ? Kí nìdí tó fi ka wákàtí mélòó kan tó kù yìí sí pàtàkì tó bẹ́ẹ̀? Ìfẹ́ ni. Ìfẹ́ tó ní sí wọn jinlẹ̀ gan-an.
3. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jésù ò dúró di alẹ́ ọjọ́ tó lò kẹ́yìn kó tó máa fìfẹ́ hàn sáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀?
3 Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà nígbà tí àpọ́sítélì Jòhánù ń sọ̀rọ̀, lábẹ́ ìmísí Ọlọ́run nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ yẹn, ó ní: “Nítorí ó mọ̀ ṣáájú àjọyọ̀ ìrékọjá náà pé wákàtí òun ti dé fún òun láti lọ kúrò ní ayé yìí sọ́dọ̀ Baba, bí Jésù ti nífẹ̀ẹ́ àwọn tirẹ̀ tí wọ́n wà ní ayé, ó nífẹ̀ẹ́ wọn dé òpin.” (Jòhánù 13:1) Kì í ṣe pé Jésù dúró di alẹ́ ọjọ́ yẹn kó tó fi han “àwọn tirẹ̀” pé òun nífẹ̀ẹ́ wọn. Jálẹ̀ gbogbo ìgbà tó fi ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, kódà nínú ohun kékeré pàápàá, ó jẹ́ ká rí ẹ̀rí pé òun nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun. Ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà pé ká gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára àwọn ọ̀nà tó gbà fi ìfẹ́ hàn, nítorí pé nípa títẹ̀lé àpẹẹrẹ rẹ̀ la fi lè fira wa hàn ní ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tòótọ́.
Bó Ṣe Ń Mú Sùúrù
4, 5. (a) Kí nìdí tí Jésù fi ní láti mú sùúrù fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀? (b) Kí ni Jésù ṣe nígbà táwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mẹ́ta tó mú dání lọ sí ọgbà Gẹtisémánì ò lè máa bá a ṣọ́nà?
4 Ìfẹ́ àti sùúrù tan mọ́ra. Ìwé 1 Kọ́ríńtì 13:4 sọ pé “Ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra,” àti pé ìpamọ́ra túmọ̀ sí fífi sùúrù fara dà á fún àwọn ẹlòmíì. Ǹjẹ́ Jésù ní láti mú sùúrù fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni o, ọ̀rọ̀ wọn gba sùúrù! Bá a ṣe rí i ní Orí 3 ìwé yìí, ó pẹ́ káwọn àpọ́sítélì rẹ̀ tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Àní ó ju ẹ̀ẹ̀kan lọ tí wọ́n ṣe awuyewuye nípa ẹni tó máa jẹ́ ọ̀gá láàárín wọn. Kí ni Jésù ṣe sí i? Ṣó bínú tutọ́ sókè fojú gbà á, bóyá kó bú wọn tàbí kó sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ sí wọn? Ó tì o. Sùúrù ló tún fi ṣàlàyé fún wọn, kódà nígbà tí “awuyewuye gbígbónájanjan kan” tún dìde lórí ìṣòro yìí kan náà lálẹ́ tó lò kẹ́yìn pẹ̀lú wọn!—Lúùkù 22:24-30; Mátíù 20:20-28; Máàkù 9:33-37.
5 Nígbà tó ṣe díẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ yẹn kan náà, Jésù lọ sí ọgbà Gẹtisémánì tòun ti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mọ́kànlá tí wọ́n dúró tì í, ohun kan tó sì dán sùúrù rẹ̀ wò tún ṣẹlẹ̀. Ó ní káwọn mẹ́jọ tó kù dúró, ó sì ní kí Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù tẹ̀ lé òun lọ sáàárín ọgbà lọ́hùn-ún. Jésù wá sọ fún wọn pé: “Mo ní ẹ̀dùn-ọkàn gidigidi, àní títí dé ikú. Ẹ dúró síhìn-ín, kí ẹ sì máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà pẹ̀lú mi.” Ó rìn síwájú díẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà kíkankíkan. Lẹ́yìn àkókò gígùn tó ti ń gbàdúrà, ó padà sọ́dọ̀ àwọn àpọ́sítélì mẹ́ta yìí. Báwo ló ṣe bá wọn? Lákòókò tó ń dójú kọ àdánwò ńlá bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ ẹ jẹ́ mọ̀ pé oorun làwọn wọ̀nyẹn ń sùn ràì! Ǹjẹ́ ó fìbínú sọ̀rọ̀ sí wọn pé wọn ò wà lójúfò? Ó tì o, pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ló tún fi gbà wọ́n níyànjú. Ohùn jẹ́jẹ́ tó fi bá wọn sọ̀rọ̀ fi hàn pé ó mọ ìnira tó bá wọn àti bó ṣe rẹ̀ wọ́n tó.a Ó ní: “Ní tòótọ́, ẹ̀mí ń háragàgà, ṣùgbọ́n ẹran ara ṣe aláìlera.” Ní gbogbo alẹ́ ọjọ́ yẹn, ńṣe ni Jésù ní sùúrù, kódà lẹ́yìn tó padà lẹ́ẹ̀méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó jẹ́ pé ojú oorun yẹn náà ni wọ́n ṣì wà!—Mátíù 26:36-46.
6. Báwo la ṣe lè ní sùúrù bíi ti Jésù nínú ọ̀nà tá a gbà ń bá àwọn èèyàn lò?
6 Ẹ̀kọ́ ńlá ló jẹ́ fún wa láti mọ̀ pé Jésù ò ro àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pin. Sùúrù tó ní ò já sásán torí pé àwọn ọkùnrin olóòótọ́ yìí wá mọ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn bó ṣe ṣe pàtàkì tó láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni tó wà lójúfò. (1 Pétérù 3:8; 4:7) Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nínú bá a ṣe ń ṣe sáwọn ẹlòmíì? A ní láti máa mú sùúrù, pàápàá jù lọ, àwọn alàgbà. Ó lè jẹ́ pé ìgbà tí ìṣòro ka alàgbà kan láyà tàbí tí àníyàn kan ti gbà á lọ́kàn làwọn Kristẹni kan á tún gbé ìṣòro tiwọn lọ bá a. Ìgbà míì sì wà táwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́ ò tiẹ̀ ní fẹ́ gba ìmọ̀ràn bọ̀rọ̀. Bó ṣe wù kó rí, ńṣe làwọn alàgbà tó bá ní sùúrù máa ń fúnni ní ìtọ́ni “pẹ̀lú ìwà tútù” wọn a sì máa “fi ọwọ́ pẹ̀lẹ́tù mú agbo.” (2 Tímótì 2:24, 25; Ìṣe 20:28, 29) Ó yẹ káwọn òbí náà máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nípa jíjẹ́ onísùúrù torí pé àwọn ìgbà míì lè wà táwọn ọmọ ò ní tètè gba ìbáwí. Ìfẹ́ àti sùúrù ló máa ran àwọn òbí lọ́wọ́ tí wọn ò fi ní jẹ́ kó sú wọn láti máa kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Kékeré kọ́ lèrè òbí tó bá ṣe sùúrù fáwọn ọmọ rẹ̀.—Sáàmù 127:3.
Bó Ṣe Ń Bójú Tó Wọn
7. Àwọn ọ̀nà wo ni Jésù gbà ṣe ohun táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nílò fún wọn?
7 Ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ kì í jẹ́ kí ọ̀ràn tiẹ̀ nìkan gbà á lọ́kàn. (1 Jòhánù 3:17, 18) Ìfẹ́ “kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan.” (1 Kọ́ríńtì 13:5) Ìfẹ́ ló mú kí Jésù ṣe ohun táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nílò fún wọn. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń ṣe ohun tí wọ́n nílò kí wọ́n tiẹ̀ tó sọ ọ́. Nígbà tó kíyè sí i pé ó ti rẹ̀ wọ́n, ó ní kí wọ́n tẹ̀ lé òun ní àwọn “nìkan sí ibi tí ó dá,” kí wọ́n “sì sinmi díẹ̀.” (Máàkù 6:31) Nígbà tó sì róye pé ebi ti ń pa wọ́n, ẹnì kan ò sọ fún un kó tó bọ́ wọn, pẹ̀lú ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn tó wá láti gbọ́rọ̀ rẹ̀.—Mátíù 14:19, 20; 15:35-37.
8, 9. (a) Kí ló jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù mọ ohun táwọn ọmọ ẹ̀yìn nílò nípa tẹ̀mí àti pé ó ṣe é fún wọn? (b) Nígbà tí Jésù wà lórí òpó igi oró, báwo ló ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀rọ̀ àbójútó ìyá òun jẹ òun lógún?
8 Jésù mọ ohun táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nílò láti lè túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run, ó sì ṣeé fún wọn. (Mátíù 4:4; 5:3) Ó sábà máa ń fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní àfiyèsí àrà ọ̀tọ̀ nígbà tó bá ń kọ́ gbogbo èèyàn lẹ́kọ̀ọ́. Ká kúkú sọ pé torí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ló ṣe ṣe Ìwàásù Lórí Òkè. (Mátíù 5:1, 2, 13-16) Nígbà tó bá fi àpèjúwe kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, “ní ìdákọ́ńkọ́, yóò ṣàlàyé ohun gbogbo fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀.” (Máàkù 4:34) Jésù yan “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” láti lè rí i pé ebi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ò pa àwọn ọmọlẹ́yìn òun lẹ́yìn tóun bá ti padà sí ọ̀run. Ẹgbẹ́ ẹrú yìí, tó jẹ́ kìkì àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Jésù lórí ilẹ̀ ayé kò tíì yéé fi ìṣòtítọ́ fúnni ní oúnjẹ tẹ̀mí “ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu” láti ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni títí dòní olónìí.—Mátíù 24:45.
9 Lọ́jọ́ tí Jésù máa kú, ó jẹ́ ká rí i lọ́nà tó ṣeni láàánú pé ipò tẹ̀mí àwọn tí òun fẹ́ràn jẹ òun lógún gan-an. Fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀. Jésù wà lórí òpó igi níbi tó ti ń jẹ̀rora burúkú burúkú. Kó tó lè mí sínú, ó ti ní láti kọ́kọ́ fi ẹsẹ̀ ti ara rẹ̀ sókè. Kò sì síyè méjì pé ìrora ńlá gbáà nìyẹn á jẹ́ fún un bí ara rẹ̀ ṣe ń fà ya níbi ojú ìṣó tí wọ́n fi kàn án lẹ́sẹ̀ tí ẹ̀yìn rẹ̀ tí wọ́n ti fi ẹgba bà jẹ́ sì ń ha òpó náà. Kó tó lè sọ̀rọ̀, ó ní láti mí sínú, èyí sì ti ní láti fa ìnira àti ìrora fún un gan-an ni. Síbẹ̀ náà, pẹ̀lú bí àtisọ̀rọ̀ ṣe nira fún Jésù tó yìí, kó tó gbẹ́mìí mì, ó kúkú tiraka sọ̀rọ̀ kan tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ Màríà ìyá rẹ̀ púpọ̀. Nígbà tó rí Màríà ìyá rẹ̀ àti àpọ́sítélì Jòhánù tí wọ́n dúró sítòsí rẹ̀, ó gbóhùn sókè débi táwọn tó dúró nítòsí fi lè gbọ́, ó sọ fún ìyá rẹ̀ pé: “Obìnrin, wò ó! Ọmọkùnrin rẹ!” Ó sì sọ fún Jòhánù pé: “Wò ó! Ìyá rẹ!” (Jòhánù 19:26, 27) Jésù mọ̀ pé yàtọ̀ sí pé àpọ́sítélì náà tó jẹ́ olóòótọ́ á ṣe ohun tó máa dín ẹ̀dùn ọkàn Màríà kù, ó tún máa pèsè nípa tara àti nípa tẹ̀mí fún un.b
10. Báwo làwọn òbí ṣe lè ṣe bíi ti Jésù nínú bíbójú tó àwọn ọmọ wọn?
10 Àwọn òbí tí wọ́n bá mọ ojúṣe wọn á rí i pé ó yẹ kéèyàn máa ṣàṣàrò lórí àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀. Bàbá tó fẹ́ràn ìdílé rẹ̀ á máa ṣe ohun tí ìdílé rẹ̀ ń fẹ́ fún wọn. (1 Tímótì 5:8) Olórí ìdílé tó mọ ohun tó tọ́ á rí i pé òun àti ìdílé òun ń ní àkókò ìsinmi àti eré ìnàjú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ní pàtàkì jù lọ, àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni ní láti rí i pé àwọn ọmọ wọn ò rẹ̀yìn nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Lọ́nà wo? Irú àwọn òbí bẹ́ẹ̀ máa ń ṣètò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé, wọ́n á máa ṣe é déédéé, wọ́n á sì máa rí i pé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ń dùn mọ́ àwọn ọmọ tó sì ń fún wọn níṣìírí. (Diutarónómì 6:6, 7) Nínú ọ̀rọ̀ àti nínú àpẹẹrẹ táwọn òbí ń fi lélẹ̀, wọ́n ní láti máa jẹ́ káwọn ọmọ wọn mọ̀ pé iṣẹ́ ìwàásù ṣe pàtàkì púpọ̀ àti pé mímúra sílẹ̀ ká tó lọ sípàdé àti wíwà ní gbogbo ìpàdé jẹ́ ara ìjọsìn tí a ò gbọ́dọ̀ pa jẹ.—Hébérù 10:24, 25.
Bó Ṣe Máa Ń Wù Ú Láti Dárí Jini
11. Kí ni Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nípa ìdáríjì?
11 Dídáríjini wà lára ọ̀nà tá a lè gbà fi ìfẹ́ hàn. (Kólósè 3:13, 14) Ìwé 1 Kọ́ríńtì 13:5 sọ pé ìfẹ́ “kì í kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe.” Lọ́pọ̀ ìgbà, Jésù jẹ́ káwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mọ bí ìdáríjì ṣe ṣe pàtàkì tó. Ó rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n máa dárí ji àwọn ẹlòmíì “kì í ṣe, Títí dé ìgbà méje, bí kò ṣe, Títí dé ìgbà àádọ́rin lé méje.” (Mátíù 18:21, 22) Ó kọ́ wọn pé kí wọ́n darí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ kan lẹ́yìn tí wọ́n bá ti fún un ní ìbáwí tó sì ronú pìwà dà. (Lúùkù 17:3, 4) Jésù máa ń fi àpẹẹrẹ tiẹ̀ kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ni, ìyẹn ló fi yàtọ̀ sáwọn alágàbàgebè Farisí tó jẹ́ pé wọn kì í ṣe ohun tí wọ́n bá sọ. (Mátíù 23:2-4) Ẹ jẹ́ ká wá wo bí Jésù ṣe fi hàn pé tinútinú lòun fi ń dárí ji àwọn èèyàn nígbà tí ẹnì kan tó fọkàn tán já a kulẹ̀.
12, 13. (a) Lọ́nà wo ni Pétérù gbà padà lẹ́yìn Jésù lálẹ́ ọjọ́ tí wọ́n mú Un? (b) Báwo ni ohun tí Jésù ṣe lẹ́yìn tó jíǹde ṣe fi hàn pé kó fọ̀rọ̀ mọ sórí kó kàn máa wàásù ìdáríjì?
12 Jésù àti àpọ́sítélì Pétérù sún mọ́ ara wọn dáadáa. Ọlọ́yàyà èèyàn ni Pétérù, àmọ́ nígbà míì kì í fara balẹ̀. Jésù mọrírì àwọn ànímọ́ rere tí Pétérù ní, ó sì gbé àwọn iṣẹ́ pàtàkì lé e lọ́wọ́. Pétérù pẹ̀lú Jákọ́bù àti Jòhánù fójú ara wọn rí àwọn iṣẹ́ ìyanu kan táwọn àpọ́sítélì mẹ́sàn-án yòókù ò rí. (Mátíù 17:1, 2; Lúùkù 8:49-55) Bá a ṣe sọ lẹ́ẹ̀kan, Pétérù wà lára àwọn àpọ́sítélì tí Jésù mú lọ sínú ọgbà Gẹtisémánì lóru ọjọ́ tí wọ́n mú Un. Síbẹ̀ lóru ọjọ́ yẹn kan náà, lẹ́yìn tí Júdásì fi Jésù hàn tí wọ́n sì lọ fi sí àhámọ́, Pétérù àtàwọn àpọ́sítélì tó kù pa Jésù tì, wọ́n sì sá lọ. Lẹ́yìn náà, Pétérù ṣe ọkàn akin, ó dúró níta ibi tí wọ́n ti ń fèrú gbẹ́jọ́ Jésù. Síbẹ̀, ìbẹ̀rù mú Pétérù, ó sì ṣe àṣìṣe kan tó burú jáì, ó parọ́ lẹ́ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ pé òun ò mọ Jésù rí! (Mátíù 26:69-75) Kí ni Jésù ṣe? Ká ní ìwọ ni ọ̀rẹ́ tó o fọkàn tán ṣe ohun tó dùn ọ́ tó báyìí sí, kí lò bá ṣe?
13 Jésù ti múra tán láti darí ji Pétérù. Ó mọ̀ pé ẹ̀rí ọkàn Pétérù ti ń nà án ní pàṣán torí ẹ̀ṣẹ̀ tó dá yẹn. Ó ṣe tán, àpọ́sítélì yẹn kábàámọ̀ ohun tó ṣe “ó sì bara jẹ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sunkún.” (Máàkù 14:72) Lọ́jọ́ tí Jésù jíǹde, ó fara han Pétérù, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé torí kó lè tù ú nínú, kó sì jẹ́ kó mọ̀ pé òun ṣì gbọ́kàn lé e ló ṣe fara hàn án. (Lúùkù 24:34; 1 Kọ́ríńtì 15:5) Kò pé oṣù méjì lẹ́yìn náà tí Jésù fi pọ́n Pétérù lé nípa jíjẹ́ kó mú ipò iwájú láti jẹ́rìí fún ogunlọ́gọ̀ tó wà ní Jerúsálẹ́mù lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì. (Ìṣe 2:14-40) Ká má sì gbàgbé pé Jésù ò tìtorí pé àwọn àpọ́sítélì pa á tì kó wá di gbogbo wọn sínú o. Dípò ìyẹn, lẹ́yìn tó jíǹde, ó ṣì pè wọ́n ní “arákùnrin mi.” (Mátíù 28:10) Ǹjẹ́ kó ṣe kedere pé Jésù ò fi mọ sórí kó máa kọ́ni láti dárí jini, òun fúnra rẹ̀ dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ ẹ́?
14. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ fi kọ́ra láti máa darí ji ẹni tó bá ṣẹ̀ wá, báwo la sì ṣe lè fi hàn pé a fẹ́ láti darí ji ẹni tó bá ṣẹ̀ wá tọkàntọkàn?
14 Gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀yìn Kristi, a gbọ́dọ̀ kọ́ bá a ṣe lè máa darí ji àwọn ẹlòmíì. Kí nìdí? Bí Jésù ṣe jẹ́ ẹni pípé, kò sẹ́ni pípé nínú àwa àtàwọn tó lè ṣẹ̀ wá. Lóòrèkóòrè là máa ń kọsẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ tàbí nínú ìṣe. (Róòmù 3:23; Jákọ́bù 3:2) Nígbà tó bá yẹ ká dárí ji ẹni tó ṣẹ̀ wá, ó tọ́ ká ṣe bẹ́ẹ̀ kí Ọlọ́run bàa lè dárí ji àwa náà. (Máàkù 11:25) Báwo la ṣe lè máa darí ji àwọn tó bá ṣẹ̀ wá tọkàntọkàn? Ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé ìfẹ́ máa jẹ́ ká lè gbójú fo ẹ̀ṣẹ̀ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ àti kùdìẹ̀ kudiẹ àwọn ẹlòmíì. (1 Pétérù 4:8) Nígbà táwọn tó ṣẹ̀ wá bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn bíi ti Pétérù, ó dájú pé àwa náà máa fẹ́ darí ji ẹni náà tọkàntọkàn bíi ti Jésù. Dípò tí a ó fi dì wọ́n sínú, ohun tó dáa ni pé ká jẹ́ kó tán nínú wa, ká sì gbàgbé ẹ̀. (Éfésù 4:32) Bá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe là ń mú kí àlàáfíà rídìí jókòó nínú ìjọ, bákan náà, àwa fúnra wa á ní àlàáfíà àti ìbàlẹ̀ ọkàn.—1 Pétérù 3:11.
Bó Ṣe Fi Hàn Pé Òun Gbọ́kàn Lé Wọn
15. Kí nìdí tí Jésù fi gbọ́kàn lé àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láìfi ti àwọn kùdìẹ̀ kudiẹ wọn ṣe?
15 Ìfẹ́ àti ìgbọ́kànlé jọ ń rìn pọ̀ ni. Ìfẹ́ “á máa gba ohun gbogbo gbọ́.”c (1 Kọ́ríńtì 13:7) Ìfẹ́ ló sún Jésù láti fi hàn pé tinútinú lòun fi gbọ́kàn lé àwọn ọmọlẹ́yìn òun láìfi ti àìpé wọn ṣe. Ó gbọ́kàn lé wọn ó sì gbà gbọ́ pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà dénú àti pé wọ́n fẹ́ ṣe ìfẹ́ Rẹ̀. Kódà láwọn ìgbà tí wọ́n bá ṣe àṣìṣe, Jésù kì í fura òdì sí wọn, kó wá máa wádìí ohun tó mú wọn ṣe é. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí àpọ́sítélì Jákọ́bù àti Jòhánù lọ sọ fún ìyá wọn pé kí Jésù jẹ́ káwọn jókòó sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ nínú Ìjọba rẹ̀, Jésù ò tìtorí ìyẹn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyè méjì nípa ìdúróṣinṣin wọn tàbí kó yọ wọ́n kúrò lára àwọn àpọ́sítélì.—Mátíù 20:20-28.
16, 17. Àwọn iṣẹ́ wo ni Jésù gbé lé àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ́wọ́?
16 Káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bàa lè mọ̀ pé ó gbọ́kàn lé wọn, ó yan onírúuru iṣẹ́ fún wọn. Lẹ́ẹ̀méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó fi iṣẹ́ ìyanu pèsè oúnjẹ tó sì bọ́ ogunlọ́gọ̀, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ló yàn láti pín oúnjẹ náà. (Mátíù 14:19; 15:36) Nígbà tó ń múra sílẹ̀ fún Ìrékọjá tó ṣe kẹ́yìn, ó rán Pétérù àti Jòhánù pé kí wọ́n lọ sí Jerúsálẹ́mù kí wọ́n sì mú kí gbogbo nǹkan wà ní sẹpẹ́. Àwọn ló rí sí bí wọ́n ṣe rí ọ̀dọ́ àgùntàn, wáìnì, àkàrà aláìwú, ewébẹ̀ kíkorò àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n lò. Iṣẹ́ yìí kì í ṣe iṣẹ́ yẹpẹrẹ rárá, torí ohun pàtàkì ni Ìrékọjá jẹ́ nínú Òfin Mósè, Jésù sì gbọ́dọ̀ rí i pé gbogbo ohun tí Òfin náà là kalẹ̀ lòun tẹ̀ lé. Yàtọ̀ síyẹn, lálẹ́ ọjọ́ yẹn tí Jésù fi Ìrántí Ikú rẹ̀ lọ́lẹ̀, wáìnì àti àkàrà aláìwú yìí kan náà ni Jésù lò gẹ́gẹ́ bí ohun ìṣàpẹẹrẹ.—Mátíù 26:17-19; Lúùkù 22:8, 13.
17 Jésù rí i pé ó bójú mu láti gbé iṣẹ́ tó tiẹ̀ tún ṣe pàtàkì gan-an lé àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ́wọ́. Bá a ṣe sọ lẹ́ẹ̀kan, àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó jẹ́ ẹni àmì òróró tó yàn lórí ilẹ̀ ayé ló gbé iṣẹ́ lé lọ́wọ́ láti máa fi oúnjẹ tẹ̀mí bọ́ àwọn tó máa di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. (Lúùkù 12:42-44) Wàá sì tún rántí pé ìkáwọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ló fi iṣẹ́ wíwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn tó jẹ́ iṣẹ́ bàǹtà banta sí. (Mátíù 28:18-20) Kódà nísinsìnyí tó ti wà lọ́run tó sì ti ń ṣàkóso, abẹ́ àbójútó àwọn ọkùnrin tó rí pé wọ́n tóótun, ìyẹn “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” ló fi ìjọ àwọn èèyàn rẹ̀ tó wà láyé sí.—Éfésù 4:8, 11, 12.
18-20. (a) Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ní ìgbọ́kànlé nínú àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́? (b) Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nínú bó ṣe máa ń fa iṣẹ́ lé àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́? (d) Kí la máa jíròrò ní orí tó kàn?
18 Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nínú ọ̀nà tá a gbà ń bá àwọn ẹlòmíì lò? Bá a bá ń fi hàn pé a nígbàgbọ́ nínú àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ tá a sì fọkàn tán wọn, ńṣe là ń fi bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn tó hàn. Ẹ jẹ́ ká máa rántí pé ohun tó dáa nípa àwọn èèyàn ni ìfẹ́ máa ń rí kì í rí ohun tó burú nípa wọn. Báwọn ẹlòmíì bá ṣe ohun tó dùn wá, èyí táá máa ṣẹlẹ̀ lóòrèkóòrè, ìfẹ́ ò ní jẹ́ ká tètè rò pé wọ́n dìídì ṣe é ni. (Mátíù 7:1, 2) Bó bá jẹ́ pé ibi táwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ dáa sí là ń wò, ńṣe la óò máa gbé wọn ró dípò tá a ó fi máa fẹnu ya wọ́n lulẹ̀.—1 Tẹsalóníkà 5:11.
19 Ṣé àwa náà lè máa fa iṣẹ́ lé àwọn míì lọ́wọ́ bíi ti Jésù? Ohun tó dáa jù fáwọn tí wọ́n wà nípò àṣẹ nínú ìjọ ni pé kí wọ́n máa fa àwọn iṣẹ́ tó bójú mu tó sì nítumọ̀ lé àwọn ará lọ́wọ́, kí wọ́n ní ìgbọ́kànlé nínú wọn, pé wọ́n á sa gbogbo ipá wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn alàgbà tó ti pẹ́ nínú òtítọ́ á lè dá àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó tóótun tí wọ́n “ń nàgà” láti ṣèrànwọ́ nínú ìjọ lẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tó yẹ kí wọ́n mọ̀ tó sì máa wúlò fún wọn. (1 Tímótì 3:1; 2 Tímótì 2:2) Irú ìdálẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ ṣe kókó. Bí Jèhófà ṣe ń mú kí àwọn tó ń wọlé wá sínú ètò rẹ̀ máa pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ náà ló máa pọn dandan pé ká máa dá àwọn ọkùnrin tó tóótun lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè máa bójú tó àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dé.—Aísáyà 60:22.
20 Àpẹẹrẹ àtàtà ni Jésù fi lélẹ̀ fún wa nípa bó ṣe yẹ ká nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíì. Nínú gbogbo ọ̀nà tó yẹ ká máa gbà tẹ̀ lé e, títẹ̀lé àpẹẹrẹ ìfẹ́ tó fi lélẹ̀ ló ṣe pàtàkì jù. Ní orí tó kàn, a óò jíròrò nípa bó ṣe fìfẹ́ hàn sí wa lọ́nà kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ìyẹn bó ṣe fínnúfíndọ̀ fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí wa.
a Àárẹ̀ ara nìkan kọ́ ló fa oorun táwọn àpọ́sítélì Jésù ń sùn. Àkọsílẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ kan náà yẹn tó wà ní Lúùkù 22:45 sọ pé Jésù “bá wọn tí wọ́n ń tòògbé nítorí ẹ̀dùn-ọkàn.”
b Ó hàn gbangba pé opó ni Màríà nígbà yẹn àti pé àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù ò tíì di ọmọ ẹ̀yìn Jésù.—Jòhánù 7:5.
c Èyí ò túmọ̀ sí pé ìfẹ́ gọ̀ o, pé ẹní bá nífẹ̀ẹ́ dùn-ún tàn jẹ. Ohun tó túmọ̀ sí ni pé ìfẹ́ kì í tọ pinpin láìnídìí, kì í sì í fura òdì. Ìfẹ́ kì í tètè torí ohun tó ṣẹlẹ̀ ka àwọn èèyàn sẹ́ni burúkú láìkọ́kọ́ mọ ohun tó fà á.