ORÍ 18
‘Ẹ Wá Ọlọ́run, Kẹ́ Ẹ sì Rí I Ní Ti Gidi’
Pọ́ọ̀lù wá ibi tí ọ̀rọ̀ òun àti tàwọn tó wàásù fún ti jọra, ó sì mú ọ̀rọ̀ ẹ̀ bá ipò wọn mu
Ó dá lórí Ìṣe 17:16-34
1-3. (a) Kí ló ba àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lọ́kàn jẹ́ nígbà tó dé Áténì? (b) Kí la lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù?
PỌ́Ọ̀LÙ rí ohun tó bà á lọ́kàn jẹ́ gan-an nígbà tó dé Áténì, nílùú Gíríìsì. Ojúkò ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ni Áténì, ibẹ̀ ni Socrates, Plato àti Aristotle ti fìgbà kan rí kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́. Ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn jẹ àwọn ará ìlú yìí lógún. Kò síbi tí Pọ́ọ̀lù yíjú sí tí ò ti rí ère rẹpẹtẹ, ì báà jẹ́ inú tẹ́ńpìlì, inú ìlú, tàbí lójú ọ̀nà. Ìdí tó sì fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé oríṣiríṣi òrìṣà làwọn ará Áténì ń bọ. Pọ́ọ̀lù mọ ojú tí Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́ fi ń wo ìbọ̀rìṣà. (Ẹ́kís. 20:4, 5) Bí Jèhófà ṣe kórìíra ìbọ̀rìṣà náà ni àpọ́sítélì olóòótọ́ yìí ṣe kórìíra rẹ̀!
2 Ohun tí Pọ́ọ̀lù rí bó ṣe wọ ibi ọjà ìlú yẹn bà á lọ́kàn jẹ́ gan-an ni. Wọ́n to àwọn ère tó ní ìrísí ẹ̀yà ìbímọ, tí wọ́n fi ń jọ́sìn òrìṣà Hẹ́mísì sí apá àríwá ìwọ̀ oòrùn ìlú náà, nítòsí ọ̀nà àbáwọlé. Ńṣe ni ojúbọ kún ibi ọjà náà fọ́fọ́. Báwo ni àpọ́sítélì onítara yìí ṣe wá máa wàásù nílùú táwọn èèyàn ti ń bọ̀rìṣà yìí? Ṣé ó máa fara balẹ̀ ronú ohun tó máa sọ, kó lè wá ibi tí ọ̀rọ̀ òun àti tàwọn tó fẹ́ wàásù fún ti jọra? Ṣé ó máa lè ran àwọn èèyàn yẹn lọ́wọ́ láti wá Ọlọ́run tòótọ́, kí wọ́n sì rí I?
3 Nínú Ìṣe 17:22-31, a rí bí Pọ́ọ̀lù ṣe bá àwọn ọ̀mọ̀wé ìlú Áténì sọ̀rọ̀. Àpẹẹrẹ rere lohun tó ṣe yìí jẹ́ tó bá kan ti pé ká bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lọ́nà tó máa wọ̀ wọ́n lọ́kàn, tá ò sì ní múnú bí wọn. Tá a bá ronú lórí ohun tí Pọ́ọ̀lù ṣe yìí, ó máa jẹ́ ká mọ ibi tọ́rọ̀ wa àti tàwọn tá à ń wàásù fún ti jọra, ká sì bá wọn fèròwérò.
Ó Ń Kọ́ Wọn “ní Ibi Ọjà” (Ìṣe 17:16-21)
4, 5. Ibo ni Pọ́ọ̀lù ti wàásù nílùú Áténì, irú àwọn èèyàn wo ló sì bá níbẹ̀?
4 Nígbà ìrìn àjò míṣọ́nnárì ẹlẹ́ẹ̀kejì tí Pọ́ọ̀lù rìn ní nǹkan bí ọdún 50 Sànmánì Kristẹni, ó lọ sí ìlú Áténì.a Nígbà tó ń dúró kí Sílà àti Tímótì dé láti Bèróà, bí àṣà rẹ̀, “ó bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn Júù fèròwérò nínú sínágọ́gù.” Ó tún lọ síbi tí wọ́n ń pè ní agora tàbí “ibi ọjà,” tó ti lè rí àwọn tí kì í ṣe Júù tó ń gbé nílùú Áténì. (Ìṣe 17:17) Ọjà tó wà nílùú Áténì tóbi gan-an, ó sì wà nítòsí òkè kan tí wọ́n ń pè ní Acropolis. Ọjà nìkan kọ́ ni wọ́n ń ná níbẹ̀; wọ́n tún máa ń lo ibẹ̀ bíi gbọ̀ngàn táwọn èèyàn ti lè kóra jọ. Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé, “wọ́n máa ń ṣòwò níbẹ̀, àwọn olóṣèlú náà máa ń lo ibẹ̀, ó tún jẹ́ ojúkò àṣà ìṣẹ̀ǹbáyé ìlú náà.” Àwọn ọ̀mọ̀wé ará Áténì nífẹ̀ẹ́ láti máa wá síbẹ̀ kí wọ́n lè máa jíròrò àwọn nǹkan tuntun.
5 Kò rọrùn láti yí àwọn tí Pọ́ọ̀lù rí níbi ọjà náà lérò pa dà. Lára àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ ni àwọn Epikúríà àtàwọn Sítọ́íkì, wọ́n jẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ onímọ̀ ọgbọ́n orí, ohun tí wọ́n sì gbà gbọ́ yàtọ̀ síra.b Bí àpẹẹrẹ, àwọn Epikúríà gbà gbọ́ pé ṣe làwọn ohun alààyè kàn ṣàdédé wà. Èrò wọn ni pé: “Kò sídìí láti bẹ̀rù Ọlọ́run; Òkú ò mọ nǹkan kan; Ohun rere lè tẹ̀ wá lọ́wọ́ láì làágùn jìnnà; Èèyàn lè fara da ìṣòro láìsí ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run.” Ní tàwọn Sítọ́íkì, èrò wọn ni pé Ọlọ́run kan ṣoṣo ló wà. Bákan náà, wọ́n gbà pé ọgbọ́n àti làákàyè àwa èèyàn ti tó fún wa láti ṣàṣeyọrí. Àwùjọ méjèèjì ò nígbàgbọ́ nínú àjíǹde táwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi fi ń kọ́ni. Ó ṣe kedere pé èrò wọn ò bá òtítọ́ tí ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́ fi ń kọ́ni mu, òtítọ́ yìí ni Pọ́ọ̀lù sì ń wàásù rẹ̀.
6, 7. Kí làwọn Gíríìkì tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù, kí làwa náà máa ń bá pàdé lónìí?
6 Kí làwọn Gíríìkì tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé yìí ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ ohun tí Pọ́ọ̀lù fi ń kọ́ni? Àwọn kan lára wọn sọ pé “onírèégbè” ni Pọ́ọ̀lù, ìyẹn sì lè túmọ̀ sí ‘ẹni tó ń ṣa èso kiri’ lédè Gíríìkì. (Ìṣe 17:18) Nígbà tí ọ̀mọ̀wé kan ń sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n lò yìí, ó sọ pé: “Ẹyẹ kékeré kan tó máa ń ṣa èso kiri ni wọ́n kọ́kọ́ ń fi orúkọ yìí pè, àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n wá ń fi orúkọ náà pe ẹni tó bá ń ṣa ilẹ̀ jẹ nínú ọjà. Bákan náà, wọ́n tún máa ń lo orúkọ yìí fún ẹnikẹ́ni tó bá ń kó onírúurú ìsọfúnni jọ, tàbí tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ò yé èèyàn dáadáa, tí ò sì lè ṣàlàyé ọ̀rọ̀ náà lọ́nà tó yéni.” Lọ́rọ̀ kan ṣá, ohun táwọn ọ̀mọ̀wé yìí ń sọ ni pé Pọ́ọ̀lù ò mọ nǹkan tó ń ṣe, pé àgbọ́sọ lásán ló ń sọ. Àmọ́, bá a ṣe máa rí i, Pọ́ọ̀lù ò jẹ́ kí orúkọ tí ò dáa tí wọ́n ń pè é yìí mú kó rẹ̀wẹ̀sì.
7 Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ rí lónìí. Àwọn èèyàn máa ń pe àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láwọn orúkọ tí ò dáa torí pé ohun tá a gbà gbọ́ bá Bíbélì mu. Bí àpẹẹrẹ, àwọn olùkọ́ kan ń kọ́ àwọn èèyàn pé òtítọ́ ni ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n tó sọ pé ara ẹranko lèèyàn ti jáde wá, wọ́n sì ń sọ pé tí orí éèyàn bá pé, ó yẹ kó gbà á gbọ́. Ohun tí wọ́n ń sọ ni pé aláìmọ̀kan lẹni tó bá kọ̀ láti gbà pé ara ẹranko lèèyàn ti jáde wá. Àwọn ọ̀mọ̀wé yìí fẹ́ káwọn èèyàn máa wò wá bí aláìríkan-ṣèkan tá a bá ń ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ nípa ìṣẹ̀dá, tá a sì ń fi ohun tí Ẹlẹ́dàá dá ti ọ̀rọ̀ wa lẹ́yìn. Àmọ́ ìyẹn ò bà wá lẹ́rù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe la máa ń fìgboyà sọ̀rọ̀ nígbà tá a bá ń sọ ohun tá a gbà gbọ́ pé Jèhófà Ọlọ́run, Ẹlẹ́dàá tí ọgbọ́n rẹ̀ ò láàlà, ló dá ayé.—Ìfi. 4:11.
8. (a) Kí làwọn kan lára àwọn tó gbọ́ ìwàásù Pọ́ọ̀lù ṣe? (b) Kí ló ṣeé ṣe kí Áréópágù tí wọ́n mú Pọ́ọ̀lù lọ túmọ̀ sí? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
8 Èrò àwọn míì tó gbọ́ ìwàásù Pọ́ọ̀lù níbi ọjà náà yàtọ̀. Lójú wọn, “ó jọ ẹni tó ń kéde àwọn ọlọ́run àjèjì.” (Ìṣe 17:18) Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni Pọ́ọ̀lù ń ṣàlàyé ọlọ́run míì fáwọn ará Áténì, a jẹ́ pé kékeré kọ́ lọ̀rọ̀ yìí, torí pé ó jọ ọ̀kan lára ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan onímọ̀ ọgbọ́n orí náà Socrates tí wọ́n sì pa á ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn. Abájọ tí wọ́n fi mú Pọ́ọ̀lù lọ sí Áréópágù, tí wọ́n sì sọ pé kó ṣàlàyé ẹ̀kọ́ àjèjì yìí fáwọn ará Áténì.c Tóò, báwo wá ni Pọ́ọ̀lù á ṣe ṣàlàyé ọ̀rọ̀ ẹ̀ fáwọn èèyàn tí ò mọ Ìwé Mímọ́ yìí?
“Ẹ̀yin Èèyàn Áténì, Mo Kíyè Sí Pé” (Ìṣe 17:22, 23)
9-11. (a) Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀ pẹ̀lú àwọn èèyàn náà láti ibi térò wọn ti jọra? (b) Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa?
9 Ká má gbàgbé pé ìbọ̀rìṣà tó gbilẹ̀ ní ìlú náà ba Pọ́ọ̀lù nínú jẹ́ gan-an. Àmọ́ dípò tí á fi sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ sí àwọn abọ̀rìṣà yẹn, ṣe ló kó ara ẹ̀ níjàánu. Pọ́ọ̀lù lo ọgbọ́n láti bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀ níbi térò wọn ti jọra. Ó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀ báyìí: “Ẹ̀yin èèyàn Áténì, mo kíyè sí pé nínú ohun gbogbo, ó jọ pé ẹ bẹ̀rù àwọn ọlọ́run ju bí àwọn yòókù ṣe bẹ̀rù wọn lọ.” (Ìṣe 17:22) Ohun tí Pọ́ọ̀lù ń dọ́gbọ́n sọ ni pé, ‘Mo rí i pé ọ̀rọ̀ ìjọsìn jẹ yín lógún gan-an.’ Ó bọ́gbọ́n mu pé Pọ́ọ̀lù yìn wọ́n fún bí wọ́n ṣe nítara fún ẹ̀sìn. Ó gbà pé ó ṣeé ṣe káwọn kan lára àwọn tí ẹ̀kọ́ èké ti fọ́ lójú ṣe tán láti gbọ́ ohun tó fẹ́ sọ. Ó ṣe tán, Pọ́ọ̀lù rántí pé òun náà ti fìgbà kan rí jẹ́ ‘aláìmọ̀kan, tí ò sì ní ìgbàgbọ́.’—1 Tím. 1:13.
10 Pọ́ọ̀lù wá ń bọ́rọ̀ ẹ̀ lọ láti ibi térò wọn ti jọra, ó sọ ohun tó mú kó gbà pé lóòótọ́ lọ̀rọ̀ ẹ̀sìn jẹ àwọn ará Áténì lógún, nígbà tó mẹ́nu kan pẹpẹ kan tí wọ́n yà sí mímọ́ “Sí Ọlọ́run Àìmọ̀.” Ìwé kan sọ pé, “àṣà àwọn Gíríìkì àtàwọn míì ni láti máa ya àwọn pẹpẹ sí mímọ́ fún ‘àwọn ọlọ́run àìmọ̀,’ torí wọ́n máa ń bẹ̀rù pé àwọn lè ti yọ àwọn ọlọ́run kan sílẹ̀ nínú ìjọsìn àwọn, tó sì ṣeé ṣe kí wọ́n bínú.” Pẹpẹ táwọn ará Áténì ṣe yìí fi hàn pé wọ́n gbà pé Ọlọ́run kan wà táwọn ò mọ̀. Pọ́ọ̀lù wá lo pẹpẹ yìí láti fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀ nígbà tó ń wàásù ìhìn rere fún wọn. Ó ṣàlàyé pé: “Ohun tí ẹ̀ ń sìn láìmọ̀ ni mo wá kéde fún yín.” (Ìṣe 17:23) Ẹ ò rí i pé ọ̀nà tó dáa jù ni Pọ́ọ̀lù gbà báwọn èèyàn yìí fèròwérò! Kò sọ̀rọ̀ nípa ọlọ́run ilẹ̀ òkèèrè bí ẹ̀sùn táwọn kan lára wọn fi kàn án. Àmọ́, ṣe ló ń ṣàlàyé fún wọn nípa Ọlọ́run tòótọ́ tí wọn ò mọ̀.
11 Báwo la ṣe lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa? Tá a bá lákìíyèsí, a lè rí àwọn nǹkan tó máa fi hàn pé ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn jẹ ẹnì kan lógún, bí ohun tẹ́ni náà fi sọ́rùn tàbí tó gbé kọ́ sínú ilé rẹ̀ tàbí ohun kan tó gbé sínú ọgbà ẹ̀. A lè sọ pé: ‘Mo rí i pé ẹ ní ẹ̀sìn tẹ́ ẹ̀ ń ṣe. Ó wù mí kí n bá èèyàn bíi tiyín, tó ní ẹ̀sìn tiẹ̀ sọ̀rọ̀.’ Lẹ́yìn tá a bá ti fọgbọ́n sọ fẹ́ni náà pé a mọyì bó ṣe ní ẹ̀sìn tiẹ̀, a lè wá bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ wa níbi térò wa ti jọra. Ẹ má gbàgbé pé a ò lè pinnu bóyá ẹnì kan máa tẹ́tí sí wa tàbí kò ní tẹ́tí sí wa torí ohun tó gbà gbọ́. Ó ṣe tán, ọ̀pọ̀ lára àwọn ará wa náà ti fìgbà kan rí gba ẹ̀kọ́ èké gbọ́.
Ọlọ́run “Kò Jìnnà sí Ẹnì Kọ̀ọ̀kan Wa” (Ìṣe 17:24-28)
12. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe mú kọ́rọ̀ ẹ̀ bá ipò àwọn tó ń tẹ́tí sí i mu?
12 Pọ́ọ̀lù ti bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀ níbi tí èrò ẹ̀ ti jọ tàwọn tó ń wàásù fún, àmọ́ ṣé kò ní gbé ọ̀rọ̀ gba ibòmíì bó ṣe ń bá ọ̀rọ̀ ẹ̀ lọ? Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ òun ní ìmọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì, àmọ́ wọn ò mọ Ìwé Mímọ́, torí náà ó bá wọn sọ̀rọ̀ lóríṣiríṣi ọ̀nà. Lákọ̀ọ́kọ́, ó ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínú Bíbélì fún wọn láìkà á ní tààràtà. Ìkejì, ó jẹ́ káwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀ mọ̀ pé òun mọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn, àti pé èèyàn bíi tiwọn lòun náà. Ẹ̀kẹta, ó fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ìwé lítíréṣọ̀ èdè Gíríìkì kí wọ́n lè mọ̀ pé ohun tó fi ń kọ́ni wà nínú ìwé táwọn òǹkọ̀wé Gíríìkì kọ. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká gbé gbankọgbì ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yẹ̀ wò. Òótọ́ pàtàkì wo ló sọ nípa Ọlọ́run táwọn ará Áténì ò mọ̀ nípa ẹ̀?
13. Àlàyé wo ni Pọ́ọ̀lù ṣe nípa ẹni tó dá ọ̀run àti ayé, kí ló sì fẹ́ káwọn èèyàn náà mọ̀?
13 Ọlọ́run ló dá ọ̀run àti ayé. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ọlọ́run tó dá ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òun fúnra rẹ̀ ṣe jẹ́ Olúwa ọ̀run àti ayé, kì í gbé inú àwọn tẹ́ńpìlì tí a fi ọwọ́ kọ́.”d (Ìṣe 17:24) Ọ̀run àti ayé ò ṣèèṣì wà. Ọlọ́run tòótọ́ ni Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo. (Sm. 146:6) Jèhófà ò dà bí Átẹ́nà àtàwọn òrìṣà yòókù tó jẹ́ pé inú tẹ́ńpìlì, ojúbọ àtàwọn pẹpẹ ló ń pinnu ògo wọn, torí pé tẹ́ńpìlì téèyàn kọ́ ò lè gba Olúwa Ọba Aláṣẹ ọ̀run àti ayé. (1 Ọba 8:27) Ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù ò lọ́jú pọ̀ rárá, ohun tó ń sọ ni pé, Ọlọ́run tòótọ́ lágbára ju àwọn òrìṣà táwọn èèyàn ṣe tí wọ́n sì gbé sínú tẹ́ńpìlì.—Àìsá. 40:18-26.
14. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé Ọlọ́run ò gbára lé àwa èèyàn fún ohunkóhun?
14 Ọlọ́run ò retí pé káwọn èèyàn ran òun lọ́wọ́. Àwọn abọ̀rìṣà sábà máa ń wọṣọ olówó ńlá fáwọn ère wọn, wọ́n máa ń fún wọn lẹ́bùn olówó iyebíye, tàbí kí wọ́n fi oúnjẹ àti àwọn ohun mímu rúbọ sí wọn, bí ẹni pé àwọn ère yẹn nílò àwọn nǹkan wọ̀nyẹn. Ó ṣeé ṣe káwọn kan lára àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí ọmọ ilẹ̀ Gíríìkì tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé ọlọ́run ò retí ìrànlọ́wọ́ kankan látọ̀dọ̀ èèyàn. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kí wọ́n gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù pé “Ọlọ́run kì í retí pé kí èèyàn ran òun lọ́wọ́ bíi pé ó nílò ohunkóhun.” Torí náà, Ẹlẹ́dàá ò retí ohunkóhun látọ̀dọ̀ àwa èèyàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, òun ló ń pèsè gbogbo ohun tá a nílò, bí “ìyè àti èémí àti ohun gbogbo,” tó fi mọ́ oòrùn, òjò àti ilẹ̀ tó ń so éso. (Ìṣe 17:25; Jẹ́n. 2:7) Torí náà, Ọlọ́run tó jẹ́ Olùpèsè kò retí ohunkóhun látọ̀dọ̀ àwa èèyàn.
15. Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn ará Áténì tí wọ́n gbà pé àwọn dáa ju àwọn tí kì í ṣe Gíríìkì lọ, ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la sì lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ rẹ̀?
15 Ọlọ́run ló dá èèyàn. Èrò àwọn ará Áténì ni pé àwọn dáa ju àwọn tí kì í ṣe Gíríìkì lọ. Àmọ́, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé kò yẹ ká máa fi orílẹ̀-èdè wa yangàn tàbí ká máa rò pé ẹ̀yà tiwa ló dáa jù. (Diu. 10:17) Pọ́ọ̀lù wá fọgbọ́n tún òye wọn ṣe lórí ọ̀rọ̀ tó gbẹgẹ́ yìí, ó sọ pé: ‘Láti ara ọkùnrin kan ni Ọlọ́run ti dá gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn èèyàn,’ ó dájú pé ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí mú káwọn tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ronú jinlẹ̀. (Ìṣe 17:26) Ohun tí Jẹ́nẹ́sísì sọ nípa Ádámù, tó jẹ́ baba ńlá gbogbo èèyàn ló ń tọ́ka sí. (Jẹ́n. 1:26-28) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀dọ̀ ẹnì kan náà ni gbogbo èèyàn ti wá, kò sí ẹ̀yà tàbí orílẹ̀-èdè tó dáa ju òmíì lọ. Torí náà, ó dájú pé àwọn tí Pọ́ọ̀lù ń bá sọ̀rọ̀ á lóye ohun tó ń sọ. Àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan pé, bá a ṣe ń sapá láti lo ọgbọ́n àti òye lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe, a ò gbọ́dọ̀ bomi la òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì torí káwọn èèyàn lè gbọ́rọ̀ wa.
16. Kí ni Ẹlẹ́dàá fẹ́ káwọn èèyàn ṣe?
16 Ọlọ́run ò fẹ́ káwọn èèyàn jìnnà sóun. Táwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù bá tiẹ̀ ti ń sọ̀rọ̀ nípa ìdí téèyàn fi wà láàyè fún ọ̀pọ̀ ọdún, wọn ò lè ṣàlàyé lọ́nà tó fi máa yéni. Àmọ́, Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé tó yéni yékéyéké nípa ìdí tí Ẹlẹ́dàá fi dá èèyàn, ìyẹn ni pé kí wọ́n “máa wá Ọlọ́run, tí wọ́n bá lè táràrà fún un, kí wọ́n sì rí i ní ti gidi, bó tilẹ̀ jẹ́ pé, ní tòótọ́, kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.” (Ìṣe 17:27) Ó dájú pé Ọlọ́run táwọn ará Áténì ò mọ̀ yẹn, ṣeé mọ̀ ní ti gidi. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé, kò jìnnà sáwọn tó fẹ́ mọ̀ ọ́n, tí wọ́n sì fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀. (Sm. 145:18) Ẹ kíyè sí i pé Pọ́ọ̀lù lo ọ̀rọ̀ náà “wa,” ó ṣe bẹ́ẹ̀ kó lè fi hàn pé òun náà wà lára àwọn tó yẹ kí wọ́n “máa wá” Ọlọ́run, kí wọ́n sì máa “táràrà fún un.”
17, 18. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn èèyàn fẹ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run, kí la sì lè rí kọ́ látinú bí Pọ́ọ̀lù ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ wọ àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ lọ́kàn?
17 Ó yẹ káwọn èèyàn fẹ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run. Pọ́ọ̀lù sọ pé, nípasẹ̀ Ọlọ́run ni “a fi ní ìyè, tí à ń rìn, tí a sì wà.” Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé ọ̀rọ̀ Epimenides, ìyẹn akéwì ọmọ ilẹ̀ Kírétè tó gbáyé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹfà ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí, “àwọn ará Áténì ò sì kóyán rẹ̀ kéré nínú ààtò ẹ̀sìn wọn.” Pọ́ọ̀lù tún sọ ìdí míì tó fi yẹ kéèyàn fẹ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run, ó sọ pé: “Bí ọ̀rọ̀ àwọn kan lára àwọn akéwì yín tó sọ pé, ‘Nítorí àwa náà jẹ́ ọmọ rẹ̀.’ ” (Ìṣe 17:28) Àwa èèyàn gbọ́dọ̀ máa wo ara wa bí ẹni tó ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, torí pé òun ló dá baba ńlá wa. Kí ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù lè wọ àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ lọ́kàn, ó fa ọ̀rọ̀ yọ ní tààràtà látinú ìwé Gíríìkì tí kò sí àní-àní pé àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ náà mọ̀ nípa ẹ̀.e Bíi ti Pọ́ọ̀lù, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwa náà lè fa ọ̀rọ̀ yọ látinú àwọn ìwé ìtàn, ìwé gbédègbẹ́yọ̀, tàbí àwọn ìwé míì téèyàn lè ṣèwádìí nínú ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá mú ọ̀rọ̀ tó bá ohun tá à ń jíròrò mu látinú ìwé kan táwọn èèyàn fojú pàtàkì wò, ó lè mú kí àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà yí èrò wọn pa dà nípa àwọn àṣà ẹ̀sìn èké kan tí wọ́n ń lọ́wọ́ sí.
18 Níbi tí Pọ́ọ̀lù bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ dé yìí, ó ti sọ àwọn ohun tó jẹ́ òótọ́ nípa Ọlọ́run, ó sì tún ń fọgbọ́n jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ bá àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ mu. Kí ni àpọ́sítélì yìí fẹ́ káwọn ará Áténì ṣe nípa ìsọfúnni pàtàkì yìí? Láìfọ̀rọ̀ falẹ̀, ó sọ fún wọ́n bó ṣe ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ.
“Kí Gbogbo Èèyàn Níbi Gbogbo . . . Ronú Pìwà Dà” (Ìṣe 17:29-31)
19, 20. (a) Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe lo ọgbọ́n láti fi hàn pé ìwà òmùgọ̀ ni kéèyàn máa jọ́sìn àwọn ère? (b) Kí ló yẹ káwọn tí Pọ́ọ̀lù ń bá sọ̀rọ̀ ṣe?
19 Pọ́ọ̀lù ti ṣe tán láti mú káwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣiṣẹ́ lórí ohun tí wọ́n gbọ́. Ó rán wọn létí ọ̀rọ̀ tó fà yọ nínú ìwé àwọn Gíríìkì, ó sọ pé: “Nítorí náà, bí a ṣe jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, kò yẹ kí a rò pé Olú Ọ̀run rí bíi wúrà tàbí fàdákà tàbí òkúta, bí ohun tí a fi ọgbọ́n àti iṣẹ́ ọnà èèyàn gbẹ́ lére.” (Ìṣe 17:29) Tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run ló dá àwọn èèyàn lóòótọ́, báwo ló tún ṣe máa wá jẹ́ pé, òun náà ni ère téèyàn fọwọ́ ara rẹ̀ gbẹ́? Pọ́ọ̀lù lo ọgbọ́n láti fi hàn pé ìwà òmùgọ̀ ló jẹ́ láti máa jọ́sìn àwọn ère táwọn èèyàn ṣe. (Sm. 115:4-8; Àìsá. 44:9-20) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sọ pé “kò yẹ kí a,” ó kó ara ẹ̀ mọ́ àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀, ìyẹn ni ò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà gbòdì lára wọn.
20 Àpọ́sítélì náà wá jẹ́ kó yé wọn pé wọ́n ní láti gbé ìgbésẹ̀, ó sọ pé: “Ọlọ́run ti gbójú fo ìgbà àìmọ̀ yìí [téèyàn ti lè máa ronú pé àwọn tó ń bọ òrìṣà lè tu Ọlọ́run lójú], àmọ́ ní báyìí, ó ń sọ fún gbogbo èèyàn níbi gbogbo pé kí wọ́n ronú pìwà dà.” (Ìṣe 17:30) Ó ṣeé ṣe kí àyà àwọn kan lára àwọn tí Pọ́ọ̀lù ń bá sọ̀rọ̀ já nígbà tó sọ pé kí wọ́n ronú pìwà dà. Àmọ́ ọ̀rọ̀ pàtàkì tó bá wọn sọ jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Ọlọ́run ló dá wọn, Òun ni wọ́n sì máa jíhìn fún. Ó pọn dandan pé kí wọ́n wá Ọlọ́run, kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa rẹ̀, kí wọ́n sì máa gbé ìgbé ayé wọn níbàámu pẹ̀lú ohun tí wọ́n kọ́. Ohun tí èyí túmọ̀ sí fáwọn ará Áténì yìí ni pé kí wọ́n mọ̀ pé ohun táwọn ń ṣe ò dáa, kí wọ́n sì jáwọ́ nínú ìbọ̀rìṣà.
21, 22. Ọ̀rọ̀ pàtàkì wo ni Pọ́ọ̀lù fi parí ìwàásù ẹ̀, kí la sì lè kọ́ látinú ohun tó sọ?
21 Ọ̀rọ̀ pàtàkì tí Pọ́ọ̀lù fi parí ìwàásù ẹ̀ ni pé: “[Ọlọ́run] ti dá ọjọ́ kan tó máa fi òdodo ṣèdájọ́ ayé láti ọwọ́ ọkùnrin kan tó ti yàn, ó sì ti pèsè ẹ̀rí tó dájú fún gbogbo èèyàn bó ṣe jí i dìde kúrò nínú ikú.” (Ìṣe 17:31) Ọjọ́ Ìdájọ́ kan ń bọ̀ kẹ̀? Ẹ ò rí i pé ìdí tó ṣe pàtàkì lèyí jẹ́ fún wọn láti wá Ọlọ́run tòótọ́, kí wọ́n sì mọ̀ ọ́n! Pọ́ọ̀lù ò dárúkọ Onídàájọ́ tí Ọlọ́run ti yàn náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ ohun kan tó yà wọ́n lẹ́nu nípa Onídàájọ́ náà pé: Ó ti gbé ayé bí èèyàn, ó kú, Ọlọ́run sì jí i dìde!
22 Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ la lè rí kọ́ nínú ọ̀rọ̀ tó wọni lọ́kàn tí Pọ́ọ̀lù fi parí ìwàásù rẹ̀ yìí. A mọ̀ pé Jésù Kristi tó ti jíǹde ni Onídàájọ́ tí Ọlọ́run yàn. (Jòh. 5:22) A tún mọ̀ pé ẹgbẹ̀rún ọdún ni Ọjọ́ Ìdájọ́ náà máa jẹ́, ó sì ń yára sún mọ́lé. (Ìfi. 20:4, 6) A ò bẹ̀rù Ọjọ́ Ìdájọ́, torí a mọ̀ pé ìbùkún àgbàyanu ló máa mú wá fáwọn olóòótọ́. Àjíǹde Jésù Kristi ni iṣẹ́ ìyanu tó lágbára jù lọ, ó sì jẹ́ ẹ̀rí pé àwọn ohun àgbàyanu tí Ọlọ́run ti ṣèlérí fáwọn olóòótọ́ máa ṣẹlẹ̀ lóòótọ́!
‘Àwọn Kan Di Onígbàgbọ́’ (Ìṣe 17:32-34)
23. Kí làwọn èèyàn ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù?
23 Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù bá àwọn èèyàn yẹn sọ̀rọ̀, ohun tí wọ́n ṣe yàtọ̀ síra. “Àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe yẹ̀yẹ” nígbà tí wọ́n gbọ́ nípa àjíǹde. Àwọn kan ní tiwọn ò ṣe yẹ̀yẹ́, àmọ́ wọn ò mọ ohun tí wọn máa ṣe, wọ́n ní: “A máa gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí lẹ́nu rẹ nígbà míì.” (Ìṣe 17:32) Àmọ́ àwọn kan gbọ́, wọ́n sì gbà. Bíbélì sọ nípa wọn pé: “Àwọn kan dara pọ̀ mọ́ ọn, wọ́n sì di onígbàgbọ́. Lára wọn ni Díónísíù tó jẹ́ adájọ́ ní kọ́ọ̀tù Áréópágù àti obìnrin kan tó ń jẹ́ Dámárì pẹ̀lú àwọn míì.” (Ìṣe 17:34) Bí wọ́n ṣe máa ń ṣe sáwa náà nìyẹn tá a bá wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Àwọn kan lè fi wá ṣe yẹ̀yẹ́, bẹ́ẹ̀ sì rèé àwọn kan lè má fi wá ṣe yẹ̀yẹ́, àmọ́ wọ́n lè má fẹ́ gbọ́. Àmọ́, inú wa máa ń dùn táwọn kan bá gbọ́ ìwàásù wa, tí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.
24. Kí la lè rí kọ́ nínú ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ ní Áréópágù?
24 Tá a bá ń ronú lórí ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù, ìyẹn á jẹ́ ká lè mọ bá a ṣe lè ṣàlàyé ọ̀rọ̀ fáwọn èèyàn lọ́nà táá fi wọ̀ wọ́n lọ́kàn, táá sì tún jẹ́ kó dá wọn lójú pé òtítọ́ là ń kọ́ wọn. Yàtọ̀ síyẹn, a lè kọ́ bá a ṣe lè ní sùúrù ká sì lo ọgbọ́n pẹ̀lú àwọn tí wọ́n gba ẹ̀kọ́ èké gbọ́. A tún kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì míì pé: A ò gbọ́dọ̀ bomi la ọ̀rọ̀ òtítọ́ Bíbélì torí káwọn èèyàn lè gbọ́ wa. Torí náà, tá a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ìyẹn á jẹ́ ká di olùkọ́ tó mọ̀ọ̀yàn kọ́ dáadáa lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Láfikún sí i, àpẹẹrẹ yìí lè ran àwọn alábòójútó lọ́wọ́ láti di olùkọ́ tó kúnjú ìwọ̀n nínú ìjọ. Ìyẹn á sì jẹ́ ká ṣe tán láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè “wá Ọlọ́run, . . . kí wọ́n sì rí i ní ti gidi.”—Ìṣe 17:27.
a Wo àpótí náà, “Ìlú Áténì—Ojúkò Àṣà Ìṣẹ̀ǹbáyé Láyé Àtijọ́.”
b Wo àpótí náà, “Àwọn Epikúríà Àtàwọn Sítọ́íkì.”
c Téńté ìlú Áténì, lápá àríwá ìwọ̀ oòrùn, ni Áréópágù wà, ibẹ̀ sì ni ìgbìmọ̀ alákòóso ìlú Áténì ti máa ń ṣe àpérò. Ó ṣeé ṣe kí “Áréópágù” túmọ̀ sí ìgbìmọ̀ alákòóso tàbí kó jẹ́ pé òkè tí wọ́n ti ń ṣe àpérò náà ló ń jẹ́ bẹ́ẹ̀. Torí náà, èrò àwọn ọ̀mọ̀wé ò ṣọ̀kan lórí ibi tí wọ́n mú Pọ́ọ̀lù lọ, bóyá ìtòsí òkè kékeré yìí ni o tàbí orí òkè náà gan-an, tàbí ibi táwọn ìgbìmọ̀ alákòóso ti máa ń pàdé lápá ibòmíì níbi ọjà.
d Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “ayé” lédè Yorùbá ni koʹsmos, èèyàn làwọn Gíríìkì sì sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ náà fún. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù lo ọ̀rọ̀ yìí, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn èèyàn ló ní lọ́kàn, kí ìjíròrò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn Gíríìkì lè máa bá a lọ.
e Pọ́ọ̀lù fa ọ̀rọ̀ yọ látinú àwọn ewì nípa ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà, ìyẹn Phaenomena, tí akéwì onímọ̀ ọgbọ́n orí Sítọ́íkì náà Aratus kọ. Lára àwọn ọ̀rọ̀ yìí wà nínú àwọn ìwé míì táwọn Gíríìkì kọ, títí kan ìwé orin tí wọ́n pè ní Hymn to Zeus, tí onímọ̀ ọgbọ́n orí Sítọ́íkì náà Cleanthes kọ.