Orin 34
Jíjẹ́ Kí Orúkọ Wa Máa Rò Wá
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Jèhófà ológo, Olódùmarè,
Pípé nínú òdodo àtìfẹ́.
Orísun òtítọ́, ọlọ́gbọ́n gbogbo,
Ìwọ l’Ọba Aláṣẹ ní ọ̀run.
Àwa èèyàn rẹ ńyọ̀ nínú ìsìn rẹ;
Òótọ́ Ìjọba rẹ là ńsọ fáyé.
(ÈGBÈ)
Àǹfààní ńlá ni jíjẹ́ Ẹlẹ́rìí rẹ.
Jẹ́ kí orúkọ wa lè máa rò wá!
2. Iṣẹ́ ìsìn mímọ́ rẹ táa jùmọ̀ ńṣe
Mú kífẹ̀ẹ́ òun àlàáfíà so wá pọ̀.
A ńkọ́ni ní òótọ́ a ńgbógo rẹ yọ
Inú wa ńdùn bíyìn rẹ ti ńpọ̀ síi.
Báa ti ńjẹ́ oókọ Baba wa, Jèhófà,
Ọlá ló jẹ́ láti gbógo rẹ ga.
(ÈGBÈ)
Àǹfààní ńlá ni jíjẹ́ Ẹlẹ́rìí rẹ.
Jẹ́ kí orúkọ wa lè máa rò wá!
(Tún wo Diu. 32:4; Sm. 43:3; Dán. 2:20, 21.)