Orin 12
Ọlọ́run Ṣèlérí Ìyè Àìnípẹ̀kun
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Ọlọ́run ṣèlérí ìyè.
Ayé yìí yóò wà títí.
Inú olóòótọ́ yóò máa dùn.
Ìlérí yìí dájú.
(Ègbè)
Aó wà láàyè láéláé.
Ó yẹ ká sapá fúnun.
Òótọ́ nìlérí Jáà.
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóò ṣẹ
2. Nínú Párádísè láyé;
Àwa ọmọ Jáà yóò pé.
Lábẹ́ ìdarí Ọlọ́run,
Àlàáfíà yóò gbilẹ̀.
(Ègbè)
Aó wà láàyè láéláé.
Ó yẹ ká sapá fúnun.
Òótọ́ nìlérí Jáà.
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóò ṣẹ
3. Láìpẹ́ lájíǹde ológo,
Ìbànújẹ́ yóò pòórá.
Jáà yóò rọ̀jò ìfẹ́ lù wá,
Yóò nu omijé wa.
(ÈGBÈ)
Aó wà láàyè láéláé.
Ó yẹ ká sapá fúnun.
Òótọ́ nìlérí Jáà.
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóò ṣẹ.
(Tún wo Aísá. 25:8; Lúùkù 23:43; Jòh. 11:25; Ìṣí. 21:4.)