Orin 54
A Ní Láti Nígbàgbọ́
1. Láyé àtijọ́, Ọlọ́run ńtipa
Àwọn wòlíì bá wa sọ̀rọ̀.
Lónìí, ‘Ẹ ronú pìwà dà’ ló sọ,
Láti ẹnu Ọmọ rẹ̀.
(ÈGBÈ)
Ǹjẹ́ a nígbàgbọ́ tó dájú?
Dandan nìgbàgbọ́ láti yè.
Ǹjẹ́ a nígbàgbọ́ tó níṣẹ́?
Ìgbàgbọ́ yìí ló ńpa wá mọ́ láàyè.
2. A ńfayọ̀ pàṣẹ Kristi Jésù mọ́
Pé ká máa wàásù ’jọba yìí.
A ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ;
Aò jẹ́ bòótọ́ mọ́lẹ̀ láé.
(ÈGBÈ)
Ǹjẹ́ a nígbàgbọ́ tó dájú?
Dandan nìgbàgbọ́ láti yè.
Ǹjẹ́ a nígbàgbọ́ tó níṣẹ́?
Ìgbàgbọ́ yìí ló ńpa wá mọ́ láàyè.
3. Ìdákọ̀ró ńlá ni ìgbàgbọ́ wa;
Kíbẹ̀rù má fà wá sẹ́yìn.
Bí ọ̀pọ̀ ọ̀tá tiẹ̀ dojú kọ wá,
Ìgbàlà wa ti dé tán.
(ÈGBÈ)
Ǹjẹ́ a nígbàgbọ́ tó dájú?
Dandan nìgbàgbọ́ láti yè.
Ǹjẹ́ a nígbàgbọ́ tó níṣẹ́?
Ìgbàgbọ́ yìí ló ńpa wá mọ́ láàyè.
(Tún wo Róòmù 10:10; Éfé. 3:12; Héb. 11:6; 1 Jòh. 5:4.)