Apá 8
Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Wọ Ilẹ̀ Kénáánì
Jóṣúà àtàwọn èèyàn ẹ̀ ṣẹ́gun ilẹ̀ Kénáánì. Jèhófà yan àwọn onídàájọ́ láti gba àwọn èèyàn ẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ ìnilára
NÍ Ọ̀PỌ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún káwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wọ ilẹ̀ Kénáánì, Jèhófà ṣèlérí pé òun máa fún àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù ní ilẹ̀ yẹn. Ní báyìí tí Jóṣúà ti di aṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n ti ṣe tán láti gba Ilẹ̀ Ìlérí náà.
Ọlọ́run ti pinnu láti pa àwọn ará Kénáánì run. Wọ́n ti fi ìwà ìṣekúṣe tó gogò àti ìtàjẹ̀sílẹ̀ kún gbogbo ilẹ̀ náà pátá. Torí náà, báwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ti ṣẹ́gun ìlú èyíkéyìí tó jẹ́ tàwọn ará Kénáánì, ńṣe ni wọ́n gbọ́dọ̀ pa á run yán-án yán-án.
Àmọ́, kó tó di pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ ilẹ̀ Kénáánì, Jóṣúà rán àwọn amí méjì lọ síbẹ̀, àwọn amí náà sì wọ̀ sí ìlú Jẹ́ríkò, nílé obìnrin kan tó ń jẹ́ Ráhábù. Ó gba àwọn amí náà sínú ilé rẹ̀ ó sì dáàbò bò wọ́n bó tilẹ̀ mọ̀ pé ọmọ Ísírẹ́lì ni wọ́n. Ráhábù ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, níwọ̀n bó ti gbọ́ nípa ọ̀nà àgbàyanu tí Jèhófà ń gbà dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀. Ó mú káwọn amí náà búra fóun pé àwọn máa dá òun àti agboolé òun sí.
Lẹ́yìn náà, nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ ilẹ̀ Kénáánì tí wọ́n sì dó ti ìlú Jẹ́ríkò, Jèhófà mú káwọn ògiri ìlú Jẹ́ríkò wó lulẹ̀ lọ́nà ìyanu. Àwọn ọmọ ogun Jóṣúà rọ́ wọnú ìlú náà wọ́n sì pa á run, àmọ́ wọ́n dá Ráhábù àti ìdílé rẹ̀ sí. Lẹ́yìn náà, lọ́dún mẹ́fà tó tẹ̀ lé e, ọ̀kọ̀ọ̀kan, èjèèjì ni Jóṣúà ṣẹ́gun apá tó pọ̀ gan-an lára Ilẹ̀ Ìlérí. Lópin gbogbo ẹ̀, ó pín ilẹ̀ náà fáwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì.
Lápá ìparí àkókò gígùn tí Jóṣúà lò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, ó pe àwọn èèyàn náà jọ. Ó rán wọn létí ọ̀nà tí Jèhófà ti gbà bá àwọn baba ńlá wọn lò, ó sì gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n sin Jèhófà. Àmọ́, lẹ́yìn tí Jóṣúà àtàwọn tí wọ́n jọ sìn ní àkókò kan náà ti kú, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi Jèhófà sílẹ̀ láti lọ máa sin àwọn ọlọ́run èké. Fún nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún [300] ọdún, ségesège lorílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ń ṣe tó bá dọ̀ràn pípa àwọn òfin Jèhófà mọ́. Láàárín àkókò yẹn, Jèhófà jẹ́ káwọn ọ̀tá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pọ́n wọn lójú. Àwọn Filísínì jẹ́ ọ̀kan lára irú àwọn ọ̀tá bẹ́ẹ̀. Àmọ́, nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ké pe Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́, ó yan àwọn onídàájọ́ tí yóò máa ṣe aṣáájú wọn, kí wọ́n lè gbà wọ́n; méjìlá sì ni gbogbo àwọn onídàájọ́ náà.
Inú ìwé Àwọn Onídàájọ́ la ti lè kà nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ lákòókò tí Jèhófà fi lò wọ́n, bẹ̀rẹ̀ látorí Ótíníẹ́lì títí dórí Sámúsìnì, ọkùnrin alágbára jù lọ tó tíì gbé ayé rí. Òtítọ́ kan tí kò ṣeé gbójú fò tá a lè rí kọ́ nínú ìwé Àwọn Onídàájọ́ rèé: Ṣíṣègbọràn sí Jèhófà máa ń yọrí sí ìbùkún, àìgbọràn máa ń yọrí sí ìyọnu.
—A gbé e ka ìwé Jóṣúà; Àwọn Onídàájọ́; Léfítíkù 18:24, 25.