ORÍ KẸFÀ
“Jọ̀wọ́, Ṣègbọràn Sí Ohùn Jèhófà”
1, 2. Kí ló sábà máa ń jẹ́ ìwà àwọn tó ń rọ́ gba “ipa ọ̀nà gbígbajúmọ̀,” kí sì nìdí tó fi yẹ kí tìrẹ yàtọ̀ sí tiwọn?
LÒDE òní, àwọn èèyàn kì í fẹ́ ṣègbọràn. Ṣe ni ọ̀pọ̀ èèyàn kàn máa ń ṣe ohun tó bá ṣáà ti wù wọ́n láìfẹ́ mọ̀ bóyá ó bójú mu tàbí kò bójú mu. Bí wọ́n ṣe máa ń ronú ni pé, ‘Kàn ṣe ohun tó wù ọ́ jàre’ tàbí ‘Ṣe nǹkan tó o fẹ́ ṣe, tí wọn ò bá ṣáà ti ní gbá ọ mú.’ A máa ń rí èyí nínú bí àwọn awakọ̀ ṣe ń rú òfin ìrìnnà, báwọn olùdókòwò ṣe ń tẹ òfin ìṣòwò lójú àti báwọn aláṣẹ ṣe ń rú àwọn òfin táwọn fúnra wọn ṣe. Bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe ń rọ́ gba “ipa ọ̀nà gbígbajúmọ̀” láì bojú wẹ̀yìn náà nìyẹn nígbà ayé Jeremáyà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìyẹn ò dáa, ó sì tún léwu.—Jer. 8:6.
2 O mọ̀ pé àwọn tó bá fẹ́ rí ojú rere Ọlọ́run Olódùmarè kò ní máa ṣe bí àwọn èèyàn ayé ṣe ń ṣe, kó máa bá wọn gba “ipa ọ̀nà gbígbajúmọ̀.” Jeremáyà pàápàá jẹ́ ká rí i pé ìwà àwọn tó ń ṣègbọràn sí Jèhófà máa ń yàtọ̀ sí tàwọn tí “kò ṣègbọràn sí ohùn [rẹ̀].” (Jer. 3:25; 7:28; 26:13; 38:20; 43:4, 7) Ó yẹ kí kálukú wa yẹ ara rẹ̀ wò láti mọ ìhà tóun wà nínú méjèèjì. Kí nìdí tó fi yẹ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé Sátánì ti túbọ̀ gboró gan-an nínú bó ṣe ń dọdẹ àwọn olùṣòtítọ́ lójú méjèèjì. Bí ejò olóró tó ti ba de ohun tó fẹ́ pa ló ṣe máa ń bu ẹni tọ́wọ́ rẹ̀ bá tẹ̀ ṣán lójijì. Tá a bá ti fi ṣe ìpinnu wa láti máa gbọ́ràn sí Jèhófà lẹ́nu, a ò ní kó sẹ́nu eyín oró rẹ̀. Ṣùgbọ́n kí la máa ṣe tí ìpinnu wa láti máa ṣègbọràn sí Jèhófà kò fi ní lè yẹ̀ lábẹ́ ipòkípò? Ọ̀rọ̀ inú àwọn ìwé tí Jeremáyà kọ máa ràn wá lọ́wọ́.
ẸNI TÍ A KÒ GBỌ́DỌ̀ ṢÀÌGBỌRÀN SÍ
3. Kí nìdí tá ò fi gbọ́dọ̀ ṣàìgbọràn sí Jèhófà?
3 Kí nìdí tá ò fi gbọ́dọ̀ ṣàìgbọràn sí Jèhófà lọ́nàkọnà? Jeremáyà jẹ́ ká mọ ìdí kan pàtàkì, ó sọ pé Jèhófà ni “Olùṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé nípasẹ̀ agbára rẹ̀, Ẹni náà tí ó fìdí ilẹ̀ eléso múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in nípasẹ̀ ọgbọ́n rẹ̀.” (Jer. 10:12) Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run. A gbọ́dọ̀ bẹ̀rù rẹ̀ ju ọba èyíkéyìí lọ. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé òun ni Aláṣẹ tó ga jù lọ, ó láṣẹ láti sọ pé dandan ni ká pa àwọn òfin ọlọ́gbọ́n tóun fún wa mọ́, èyí tó jẹ́ pé ó máa ṣe wá níre títí láé tá a bá ń pa wọ́n mọ́.—Jer. 10:6, 7.
4, 5. (a) Kí ni Jèhófà jẹ́ kó hàn kedere sáwọn Júù nígbà tí ọ̀dá ń dá wọn? (b) Báwo ni àwọn ará Júdà ṣe ń fi “omi ààyè” tí Jèhófà ń pèsè fún wọn ṣòfò? (d) Báwo lo ṣe lè máa mu “omi ààyè” tí Ọlọ́run ń pèsè?
4 Yàtọ̀ sí pé Jèhófà jẹ́ Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run, òun ni Ẹlẹ́mìí tó ni ẹ̀mí wa. Ọlọ́run jẹ́ kí èyí hàn kedere sáwọn Júù ìgbà ayé Jeremáyà. Ṣẹ́ ẹ rí i, omi Odò Náílì làwọn ará Íjíbítì gbára lé nínú jíjẹ àti mímu wọn, àmọ́ tàwọn èèyàn Ọlọ́run tó ń gbé ní Ilẹ̀ Ìlérí yàtọ̀. Tí òjò ò bá rọ̀ lásìkò rẹ̀, ó máa ń ṣòro gan-an fún wọn láti rí omi, nítorí omi òjò tí wọ́n ń tọ́jú sínú ìkùdu abẹ́ ilẹ̀ ni wọ́n sábà máa ń lò. (Diu. 11:13-17) Jèhófà nìkan ló sì lè mú kí òjò rọ̀, kí ohun ọ̀gbìn lè hù. Ṣùgbọ́n tó bá fẹ́, ó lè máà jẹ́ kí òjò yìí rọ̀ rárá. Ìdí nìyẹn tí ọ̀dá burúkú fi dá léraléra nílẹ̀ àwọn Júù aláìgbọràn tìgbà ayé Jeremáyà, àní débi tí oko àti ọgbà àjàrà wọn fi gbẹ táútáú, táwọn kànga àti ìkùdu wọn sì gbẹ pátápátá.—Jer. 3:3; 5:24; 12:4; 14:1-4, 22; 23:10.
5 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Júù kì í fọ̀rọ̀ omi ṣeré, síbẹ̀ wọ́n kọ “omi ààyè” tí Jèhófà ń fún wọn fàlàlà sílẹ̀. Ńṣe ni wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ń tẹ Òfin Ọlọ́run lójú, wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ lé ìmùlẹ̀ wọn pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká. Ọ̀rọ̀ wọn wá dà bíi tẹni tó lọ ń pọn omi sínú ìkùdu fífọ́, tí kò lè gba omi dúró, nígbà ọ̀wọ́n omi. Wọ́n jẹ palaba ìyà. (Ka Jeremáyà 2:13; 17:13.) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn yìí jẹ́ ẹ̀kọ́ ńlá fún wa pé ká ṣọ́ra ká má lọ forí jálé agbọ́n bíi tiwọn. Ìgbà gbogbo ni Jèhófà ń pèsè ìtọ́ni lọ́kan-ò-jọ̀kan fún wa látinú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n ìgbà tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, “omi ààyè” yìí déédéé, tá a sì ń sapá láti fi ẹ̀kọ́ rẹ̀ sílò ló máa ṣe wá láǹfààní.
6. (a) Ìhà wo ni Sedekáyà Ọba kọ sí ṣíṣègbọràn sí Jèhófà? (b) Kí nìdí tí ohun tí ọba yìí ṣe kò fi bọ́gbọ́n mu lójú tìrẹ?
6 Bí ọjọ́ ìdájọ́ Ọlọ́run lórí àwọn ará Júdà ṣe ń sún mọ́lé, ló túbọ̀ ń ṣe pàtàkì pé kí ẹni tó bá fẹ́ mórí bọ́ lára wọn ṣègbọràn sí Ọlọ́run. Tí èyíkéyìí lára àwọn Júù bá fẹ́ rójú rere Jèhófà, tó sì fẹ́ kó dáàbò bo òun, ó gbọ́dọ̀ ronú pìwà dà kó bẹ̀rẹ̀ sí í pa òfin rẹ̀ mọ́. Ohun tó sì yẹ kí Sedekáyà Ọba ṣe nìyẹn. Àmọ́, ṣe ló gba ìgbàkugbà láyè. Nígbà táwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ sọ fún un pé àwọn fẹ́ pa Jeremáyà, ìbẹ̀rùbojo kò jẹ́ kó lè lanu sọ fún wọn pé kí wọ́n má pa á. Ṣùgbọ́n, bá a ṣe rí i nínú orí kárùn-ún ìwé yìí, Ebedi-mélékì kò jẹ́ kí wòlíì Jeremáyà kú sínú ìkùdu tí wọ́n jù ú sí láti lè pa á. Ẹ̀yìn ìyẹn ni Jeremáyà tún rọ Sedekáyà pé: “Jọ̀wọ́, ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà.” (Ka Jeremáyà 38:4-6, 20.) Èyí tó fi hàn pé tí ọba yìí bá fẹ́ràn ara rẹ̀, ńṣe ni kó yéé ṣiyè méjì, kó yáa ṣègbọràn sí Ọlọ́run.
Kí nìdí tó fi dára bí Jeremáyà ṣe ń rọ àwọn Júù lemọ́lemọ́ pé kí wọ́n ṣègbọràn sí Ọlọ́run?
MÁ ṢE FI ṢÍṢÈGBỌRÀN SÍ JÈHÓFÀ FALẸ̀
7. Irú àwọn ipò wo ló ti máa gba pé kéèyàn jẹ́ onígbọràn?
7 Bó ti ṣe pàtàkì pé káwọn èèyàn jẹ́ onígbọràn nígbà ayé Jeremáyà náà ló ṣe ṣe pàtàkì lóde òní. Báwo ni ìpinnu rẹ láti máa ṣègbọràn sí Jèhófà ṣe lágbára tó? Tó o bá ṣèèṣì já sí ibi tí àwòrán oníhòhò wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ṣé wàá máa wò ó ni àbí wàá gbójú kúrò kíá kó o sì tètè kúrò ní ìkànnì yẹn? Tí ẹnì kan níbi iṣẹ́ rẹ tàbí níléèwé rẹ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí bá sọ pé kẹ́ ẹ jọ máa fẹ́ra yín ńkọ́? Ṣé wàá nígboyà láti kọ̀? Ǹjẹ́ wàá jẹ́ kí ìwé àwọn apẹ̀yìndà wù ọ́ kà, ṣé wàá sì fẹ́ wo ìkànnì wọn lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí wàá kà wọ́n sóhun ìríra? Yálà àwọn ohun tá a sọ yìí ṣẹlẹ̀ tàbí àwọn ipò míì lo ti bára rẹ, má gbàgbé ọ̀rọ̀ inú Jeremáyà 38:20.
8, 9. (a) Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu láti máa gbọ́rọ̀ sáwọn alàgbà lẹ́nu nígbà tí wọ́n bá ń gbìyànjú láti ràn ọ́ lọ́wọ́? (b) Táwọn alàgbà bá ń fún ọ nímọ̀ràn lemọ́lemọ́, irú ojú wo ló yẹ kó o máa fi wò ó?
8 Jèhófà rán Jeremáyà lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn rẹ̀ léraléra kó lọ rọ̀ wọ́n pé: “Kí olúkúlùkù jọ̀wọ́ yí padà kúrò ní ọ̀nà búburú rẹ̀, kí ẹ sì ṣe ọ̀nà yín àti ìbálò yín ní rere.” (Jer. 7:3; 18:11; 25:5; ka Jeremáyà 35:15.) Lóde òní bákan náà, àwọn alàgbà máa ń sa gbogbo ipá wọn láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ará tó bá wà nínú ewu nípa tẹ̀mí. Tó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn alàgbà fún ọ nímọ̀ràn pé kó o yàgò fún nǹkan kan tí kò bọ́gbọ́n mu tàbí ohun kan tí kò dáa, gbọ́rọ̀ sí wọn lẹ́nu. Bó ṣe jẹ́ pé ire àwọn Júù ni Jeremáyà ń wá náà làwọn alàgbà ṣe ń wá ire rẹ.
9 Àwọn alàgbà lè rán ọ létí àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ kan tí wọ́n ti sọ fún ọ rí. Mọ̀ dájú pé kì í rọrùn láti máa tún ìmọ̀ràn kan náà sọ fún ẹnì kan nítorí pé kò tẹ̀ lé e, tẹ́ni tó nílò ìrànlọ́wọ́ bá sì tún wá lọ ń ṣorí kunkun bíi ti ọ̀pọ̀ àwọn Júù tí Jeremáyà bá sọ̀rọ̀ nígbà ayé rẹ̀, ó máa ń nira gan-an ni. Wo ìsapá táwọn alàgbà ń ṣe léraléra láti ràn ọ́ lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ. Má sì tún gbàgbé pé, ká ní gbàrà tí Jeremáyà kìlọ̀ fún wọn ni wọ́n ti kọbi ara sí i ni, kò ní ṣẹ̀ṣẹ̀ máa tún un sọ fún wọn léraléra. Ní tòdodo, téèyàn ò bá fẹ́ kí wọ́n máa tún ìmọ̀ràn sọ fóun lemọ́lemọ́, ṣe láá tètè máa ṣiṣẹ́ lórí ìmọ̀ràn tí wọ́n fún un.
JÈHÓFÀ MÁA Ń DÁRÍ JINI FÀLÀLÀ, ÀMỌ́ KÌ Í ṢÉ E NÍ WỌ̀ǸDÙRÙKÙ
10. Kí nìdí tí Jèhófà kì í fi í dédé dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini?
10 Nínú ayé búburú yìí, kò sí bá a ṣe lè máa gbìyànjú láti ṣègbọràn sí Jèhófà tó tá ò ní máa ṣàṣìṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, torí a kì í rìn kí orí má mì. Nítorí náà, a dúpẹ́ pé Jèhófà máa ń fẹ́ láti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá. Àmọ́, kì í kàn-án dédé dárí jini. Kí nìdí rẹ̀? Ìdí ni pé ohun ìríra ni ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ sí Jèhófà. (Aísá. 59:2) Nítorí náà, kó tó dárí jì wá, ó máa ń fẹ́ rí i dájú pé a yẹ lẹ́ni tóun lè dárí jì.
11. Kí nìdí téèyàn ò fi lè dẹ́ṣẹ̀ ìkọ̀kọ̀ kó sì mú un jẹ?
11 Gẹ́gẹ́ bá a ṣe rí i níṣàájú, ńṣe lọ̀pọ̀ àwọn Júù ìgbà ayé Jeremáyà kúkú ń mu ẹ̀ṣẹ̀ bí ẹní mu omi, wọ́n wá tipa bẹ́ẹ̀ ṣi àǹfààní sùúrù àti àánú Ọlọ́run lò. Lóde òní, ǹjẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run lè dẹni tó ń hu irú ìwà bẹ́ẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni o, tónítọ̀hún bá ń ṣàìka àwọn ìránnilétí Jèhófà sí, tó wá ń dẹ́ṣẹ̀ lé ẹ̀ṣẹ̀. Àwọn ẹlòmíì sì ti ṣerú nǹkan bẹ́ẹ̀ lọ́nà tó hàn sójú táyé, irú bíi kí wọ́n kó wọ ìgbéyàwó onípanṣágà. Àmọ́, ká tiẹ̀ wá sọ pé ẹ̀ṣẹ̀ kan fara sin fáwọn èèyàn, inú ewu gidi lẹni tó ṣàìgbọràn sí Jèhófà yẹn wà. Ẹnì kan tó ń yọ́ ẹ̀ṣẹ̀ dá lábẹ́lẹ̀ lè máa rò pé, ‘Kò kúkú sẹ́ni tó máa mọ̀.’ Ṣùgbọ́n, ohun tó pa mọ́ lójú èèyàn, ó hàn gbangba lójú Ọlọ́run. Kódà, òun tó jẹ́ Ọba Arínúróde mọ èrò ọkàn wa pàápàá. (Ka Jeremáyà 32:19.) Kí wá ni ṣíṣe bí ẹnì kan bá ṣẹ̀ sí Ọlọ́run?
12. Kí làwọn alàgbà ní láti ṣe nígbà míì láti dáàbò bo ìjọ?
12 Ọ̀pọ̀ àwọn Júù ló tẹ́ńbẹ́lú ìrànlọ́wọ́ tí Jèhófà ń gbìyànjú léraléra láti ṣe fún wọn nípasẹ̀ Jeremáyà. Lónìí bákan náà, ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì lè má ronú pìwà dà, kó wá kọ ìrànlọ́wọ́ táwọn alàgbà fẹ́ ṣe fún un. Nírú ipò bẹ́ẹ̀, àwọn alàgbà ní láti ṣe ohun tí Bíbélì sọ, kí wọ́n yọ ẹlẹ́ṣẹ̀ náà lẹ́gbẹ́ láti dáàbò bo ìjọ. (1 Kọ́r. 5:11-13; wo àpótí tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Wọ́n Wà Láìsí Òfin,” lójú ìwé 73.) Àmọ́ ṣé ó wá túmọ̀ sí pé kò sírètí fún onítọ̀hún mọ́ ni, pé kò lè rí ojú rere Jèhófà mọ́ láéláé? Rárá o. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ya ọlọ̀tẹ̀ fún ìgbà pípẹ́; síbẹ̀ Ọlọ́run sọ fún wọn pé: “Ẹ padà, ẹ̀yin ọ̀dàlẹ̀ ọmọ. Èmi yóò mú ipò ìwà ọ̀dàlẹ̀ yín lára dá.” (Jer. 3:22)a Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà ní kí àwọn oníwà àìtọ́ pa dà sọ́dọ̀ òun. Ńṣe ló tiẹ̀ dìídì fún wọn nítọ̀ọ́ni pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀.
Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé ká tọrọ ìdáríjì lọ́dọ̀ Ọlọ́run nígbà tá a bá dẹ́ṣẹ̀?
ṢÈGBỌRÀN SÍ JÈHÓFÀ KÓ O PA DÀ SỌ́DỌ̀ RẸ̀
13. Kí ni ẹni tó fẹ́ pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà gbọ́dọ̀ mọ̀?
13 Kẹ́nì kan tó lè pa dà sọ́dọ̀ Ọlọ́run bí Jeremáyà ṣe sọ, ó ní láti kọ́kọ́ bi ara rẹ̀ ní ìbéèrè táá jẹ́ kó ronú nípa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, irú bíi, ‘Kí ni mo lọ dán wò yìí?’ Kó wá fi ìlànà Bíbélì yẹ ara rẹ̀ wò, kó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàtúnṣe tó bá yẹ. Àwọn Júù aláìlẹ́mìí ìrònúpìwàdà ti ìgbà ayé Jeremáyà kọ̀ láti bi ara wọn nírú ìbéèrè bẹ́ẹ̀. Wọn kò gba ẹ̀ṣẹ̀ wọn lẹ́ṣẹ̀ rárá. Jèhófà kò sì dárí jì wọ́n torí irú wọn kọ́ ló máa ń dárí jì. (Ka Jeremáyà 8:6.) Àmọ́, ní ti ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tó lẹ́mìí ìrònúpìwàdà, yóò mọ̀ pé bóun ṣe ṣàìgbọràn sí Jèhófà, òun ti kó ẹ̀gàn bá orúkọ rẹ̀ àti ìjọ Kristẹni. Ẹnì kan tó ronú pìwà dà tọkàntọkàn tún máa ń kẹ́dùn gan-an lórí ìpalára tóun ti lè ṣe fáwọn ẹni ẹlẹ́ni. Ó gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ìgbà tóun bá gbà pé òun lòun jẹ̀bi gbogbo àkóbá tí ìwà àìtọ́ òun fà ni Jèhófà tó máa tẹ́tí sí ẹ̀bẹ̀ ìdáríjì òun. Ṣùgbọ́n, ó ṣì ku nǹkan míì tó máa ṣe kó tó lè pa dà rí ojú rere Ọlọ́run.
14. Báwo lèèyàn ṣe lè “padà tààrà sọ́dọ̀ Jèhófà”? (Tún wo àpótí náà “WKí Ni Ìrònúpìwàdà?”)
14 Ẹni tó ronú pìwà dà tọkàntọkàn yóò yẹ ara rẹ̀ wò láti mọ ohun tó sún òun dédìí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ náà, àwọn ohun tóun nífẹ̀ẹ́ sí àti irú ìgbésí ayé tóun ti ń gbé. (Ka Ìdárò 3:40, 41.) Ó máa wá ibi tí ọ̀rọ̀ òun ti wọ́ wá, bóyá láti ibi bíbá ẹ̀yà òdìkejì kẹ́gbẹ́ ni, ọtí mímu ni, sìgá ni, ìdí Íńtánẹ́ẹ̀tì ni tàbí ibi iṣẹ́ òun. Bí ìyàwó ilé kan ṣe máa ń gbá ilé rẹ̀ mọ́ táá tún fi nǹkan họ gbogbo kọ̀rọ̀ ilé ìdáná kí ilé rẹ̀ lè wà ní mímọ́ tónítóní, bẹ́ẹ̀ ló ṣe yẹ kí ẹnì kan tó ronú pìwà dà sa gbogbo ipá rẹ̀ láti mú kí èrò ọkàn rẹ̀ àti ohun tó ń ṣe ní ìkọ̀kọ̀ wà ní mímọ́ tónítóní. Ó gbọ́dọ̀ “padà tààrà sọ́dọ̀ Jèhófà” nípa rírí i dájú pé òun ṣe gbogbo ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ kóun ṣe, òun sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbé ayé tó bá àwọn ìlànà Ọlọ́run mu. Nígbà ayé Jeremáyà, ńṣe làwọn Júù míì pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà “lọ́nà èké.” Wọ́n ṣe bí ẹní kábàámọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, àmọ́ ojú ayé lásán ni wọ́n ń ṣe, wọn ò yíwà pa dà rárá. (Jer. 3:10) Ṣùgbọ́n ẹni tó ń fi tọkàntọkàn bẹ̀bẹ̀ fún ìdáríjì kì í ṣe bíi tiwọn, kò ní máa gbìyànjú láti tan Jèhófà àti ìjọ Ọlọ́run jẹ. Kò ní jẹ́ pé torí kó kàn lè bọ́ lọ́wọ́ ìtìjú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tàbí torí kó lè tún máa ní àjọṣe pẹ̀lú àwọn ẹbí àtàwọn míì nínú ètò Ọlọ́run láá fi máa bẹ̀bẹ̀ fún ìdáríjì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe láá kọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ pátápátá kó lè rí ojú rere Ọlọ́run, kó sì gba ìdáríjì.
15. Irú àdúrà wo ni ẹni tó ronú pìwà dà tọkàntọkàn máa ń gbà sí Ọlọ́run?
15 Ipa pàtàkì ni àdúrà ń kó nínú ìrònúpìwàdà. Láyé àtijọ́, àwọn èèyàn sábà máa ń gbọ́wọ́ sókè tí wọ́n bá ń gbàdúrà. Lónìí, tí ẹni tó ronú pìwà dà bá ń gbàdúrà, ṣe ni yóò ṣe bí Jeremáyà ṣe sọ, yóò ‘gbé ọkàn-àyà rẹ̀ pẹ̀lú àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ sókè sí Ọlọ́run.’ (Ìdárò 3:41, 42) Tẹ́ni tó ronú pìwà dà náà bá kábàámọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, á máa ṣe ohun tó bá àdúrà ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ tó ń gbà mu. Àdúrà rẹ̀ yóò sì jẹ́ àtọkànwá.
16. Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mú pé kí ẹlẹ́ṣẹ̀ pa dà sọ́dọ̀ Ọlọ́run?
16 Láìsí àní-àní, ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tó mọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ lẹ́ṣẹ̀ máa ní láti rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀. Àmọ́ òótọ́ ọ̀rọ̀ kan rèé: Jèhófà fẹ́ káwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pa dà wá sọ́dọ̀ òun. Tí Ọlọ́run bá rí i pé ẹnì kan ń kẹ́dùn látọkàn wá nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ọkàn tirẹ̀ náà máa ń yọ́ sí i. Ẹ̀mí ìyọ́nú á wá bẹ̀rẹ̀ sí í “ru gùdù” nínú rẹ̀ torí ó máa ń fẹ́ dárí ji gbogbo ẹni tó bá ronú pìwà dà, àní bó ṣe ṣe fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó pa dà dé láti ìgbèkùn. (Jer. 31:20) Ọlọ́run ṣèlérí àlàáfíà àti ìrètí fún àwọn tó bá ṣègbọràn, tí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀, èyí sì fini lọ́kàn balẹ̀ gan-an ni! (Jer. 29:11-14) Ara yóò tún pa dà máa tu irú àwọn bẹ́ẹ̀ pẹ̀sẹ̀ láàárín àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run.
ÌGBỌRÀN YÓÒ DÁÀBÒ BÒ Ọ́
17, 18. (a) Àwọn wo làwọn ọmọ Rékábù? (b) Kí la mọ̀ wọ́n mọ̀, gẹ́gẹ́ bá a ṣe rí i nínú àwòrán ojú ìwé 77?
17 Kéèyàn máa ṣègbọràn sí Jèhófà ní gbogbo ọ̀nà lohun tó ti pé jù. A lè rí èyí látinú àpẹẹrẹ tàwọn ọmọ Rékábù nígbà ayé Jeremáyà. Ní èyí tó ju igba ọdún ṣáájú ìgbà yẹn ni ọmọ Kénì náà, Jèhónádábù baba ńlá wọn, tó bá Jéhù lọ ṣiṣẹ́ Ọlọ́run, ti ka àwọn nǹkan kan léèwọ̀ fún wọn. Ọtí wáìnì wà lára ohun tó kà léèwọ̀ fún wọn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhónádábù ti kú tipẹ́, àwọn ọmọ Rékábù ò yà kúrò nínú àṣẹ tó pa fún wọn. Jeremáyà wá dán wọn wò, ó mú wọn lọ síbi yàrá ìjẹun nínú tẹ́ńpìlì, ó wá gbé ọtí wáìnì ka iwájú wọn pé kí wọ́n fi gbádùn ara wọn. Àmọ́, wọ́n sọ fún un pé: “Àwa kì yóò mu wáìnì.”—Jer. 35:1-10.
18 Àwọn ọmọ Rékábù gbà pé àwọn gbọ́dọ̀ pa àṣẹ baba ńlá wọn tó ti kú tipẹ́ mọ́. Ẹ ò rí i pé ó yẹ kí àwa olùjọsìn tòótọ́ tiẹ̀ tún fọwọ́ pàtàkì mú pípa àṣẹ Ọlọ́run alààyè mọ́ jùyẹn lọ! Báwọn ọmọ Rékábù ṣe kọ̀ tí wọn kò ṣàìgbọràn sí àṣẹ baba ńlá wọn dùn mọ́ Jèhófà nínú gan-an, èyí tó fi hàn pé tiwọn yàtọ̀ pátápátá sí tàwọn Júù tó ya aláìgbọràn. Ọlọ́run wá ṣèlérí fáwọn ọmọ Rékábù pé òun yóò pa wọ́n mọ́ nígbà àjálù tó ń bọ̀. Ẹ ò rí i pé ó dájú lóde òní náà pé Jèhófà máa pa àwọn tó ń ṣègbọràn sí i ní gbogbo ọ̀nà mọ́ la ìpọ́njú ńlá já!—Ka Jeremáyà 35:19.
Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ ronú pìwà dà kó tó lè hàn pé ó jẹ́ onígbọràn? Báwo ni jíjẹ́ onígbọràn kò ṣe ní jẹ́ kéèyàn tiẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ rárá débi táá fi di pé èèyàn ń wọ́nà láti ronú pìwà dà?
JÈHÓFÀ KÌ Í FI ÀWỌN ONÍGBỌRÀN SÍLẸ̀
19. Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa dáàbò bò ọ́ tó o bá ń ṣègbọràn sí i?
19 Ayé ìgbàanì nìkan kọ́ ni Ọlọ́run máa ń fi ìṣọ́ ṣọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ o. Kódà láyé òde òní náà, Jèhófà ń gba àwọn onígbọràn lọ́wọ́ ohun tó lè ṣàkóbá fún wọn nípa tẹ̀mí. Bí odi gíga ṣe ń dáàbò bo ìlú ńlá kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá láyé àtijọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni òfin Ọlọ́run ṣe ń dáàbò bo àwọn tó ń ṣàyẹ̀wò rẹ̀, tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé e ní gbogbo ìgbà. Nítorí náà, ṣé wàá máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run lórí ọ̀rọ̀ ìwà híhù, èyí tó dà bí odi ààbò fún wa? Ó dájú pé nǹkan yóò máa lọ dáadáa fún ọ tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀. (Jer. 7:23) Ìrírí ọ̀pọ̀ èèyàn sì fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí.—Wo àpótí náà “Tá A Bá Ń Ṣègbọràn sí Jèhófà Ààbò Ló Jẹ́.”
20, 21. (a) Kí ló yẹ kó dá ọ lójú bó o ṣe ń sin Jèhófà? (b) Kí ni Jèhóákímù Ọba ṣe nígbà tó gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run gbẹnu Jeremáyà sọ?
20 Àwọn alátakò máa ń jẹ́ kó nira gan-an láti sin Ọlọ́run. Wọ́n lè jẹ́ ará ilé rẹ, àwọn ará ibi iṣẹ́ rẹ, ọmọ iléèwé rẹ tàbí kí wọ́n jẹ́ ara àwọn aláṣẹ níbi tó ò ń gbé. Àmọ́, jẹ́ kó dá ọ lójú pé tó o bá ń ṣègbọràn sí Jèhófà déédéé nínú gbogbo nǹkan, yóò tì ọ́ lẹ́yìn kódà nínú ipò tó le koko jù lọ. Rántí pé Ọlọ́run ṣèlérí fún Jeremáyà pé òun máa pa ẹ̀mí rẹ̀ mọ́ lójú àtakò lílekoko tó máa bá pàdé, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. (Ka Jeremáyà 1:17-19.) Lára àwọn ìgbà tó hàn kedere pé Ọlọ́run ń ti Jeremáyà lẹ́yìn ni ìgbà ìjọba Jèhóákímù.
21 Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí alákòóso ilẹ̀ Ísírẹ́lì tó tún fìbínú gbógun ti àwọn agbọ̀rọ̀sọ Ọlọ́run bíi ti Jèhóákímù. Àpẹẹrẹ kan ni ti ohun tó ṣe sí wòlíì Úríjà nígbà ayé wòlíì Jeremáyà. Ọba burúkú yìí tiẹ̀ ṣe é débi pé ó ní kí wọ́n lọ mú wòlíì Jèhófà yìí wá ní orílẹ̀-èdè míì tó sá lọ. Nígbà tí wọ́n mú un dé, ọba yìí ní kí wọ́n pa á. (Jer. 26:20-23) Ó tún ṣẹlẹ̀ pé ní ọdún kẹrin ìjọba Jèhóákímù, Jèhófà ní kí Jeremáyà ṣàkọsílẹ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ tóun ti ń sọ fún un pátá, kó sì lọ kà á sétígbọ̀ọ́ àwọn èèyàn ní tẹ́ńpìlì. Nígbà tí àkájọ ìwé tí Jeremáyà kọ ọ̀rọ̀ náà sí wá tẹ Jèhóákímù lọ́wọ́, ó ní kí ọ̀kan lára òṣìṣẹ́ ààfin òun kà á sóun létí. Bó ṣe ń kà á lọ́wọ́, ọba yìí gbà á, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ya á sínú iná, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ aládé kan bẹ̀ ẹ́ pé kó má ṣe bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó rán àwọn èèyàn pé kí wọ́n lọ mú Jeremáyà àti Bárúkù wá. Àmọ́ kí ló ṣẹlẹ̀? Ṣe ni “Jèhófà fi wọ́n pa mọ́.” (Jer. 36:1-6; ka Jeremáyà 36:21-26.) Jèhófà ò jẹ́ kí ọwọ́ Jèhóákímù tẹ ọkùnrin olóòótọ́ méjèèjì náà.
22, 23. Kí ni ìrírí arábìnrin kan ní àárín gbùngbùn ilẹ̀ Éṣíà jẹ́ kó o mọ̀ nípa ìtìlẹ́yìn Ọlọ́run?
22 Jèhófà lè pa àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ òde òní náà mọ́ kúrò nínú ewu tó bá rí i pé ó yẹ bẹ́ẹ̀. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ńṣe ló máa ń fún wọn ní ìgboyà àti ọgbọ́n tí wọ́n máa fi pa àṣẹ rẹ̀ mọ́, kí wọ́n sì máa wàásù ìhìn rere lọ. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà ṣe bẹ́ẹ̀ fún obìnrin kan tá a máa pe orúkọ rẹ̀ ní Gulistan, tó ń dá tọ́ ọmọ mẹ́rin. Nígbà kan, òun nìkan ni Ẹlẹ́rìí tó wà ní àgbègbè ńlá kan ní àárín gbùngbùn ilẹ̀ Éṣíà táwọn aláṣẹ ti lòdì sí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. Ìjọ tó sún mọ́ Gulistan jù lọ lé ní irínwó [400] kìlómítà, torí náà ẹ̀ẹ̀kan lọ́gbọ̀n ló máa ń rí àwọn Kristẹni tó dàgbà nípa tẹ̀mí. Síbẹ̀, ó ń wàásù láti ilé dé ilé láìfi àtakò àtàwọn ìṣòro míì pè, ó sì ń rí ọ̀pọ̀ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́. Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan tá a gbà lẹ́nu àìpẹ́ yìí ṣe sọ, ó tó ogún èèyàn tó ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ń bójú tó àwùjọ àwọn àgùntàn Jèhófà kan tó ń pọ̀ sí i.
23 Ọlọ́run ṣe tán láti ran ìwọ àtàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ onígbọràn lọ́wọ́ bó ṣe ran Jeremáyà àtàwọn Ẹlẹ́rìí bíi Gulistan náà lọ́wọ́. Nítorí náà, fi ṣe ìpinnu rẹ̀ pé òun ni wàá máa ṣègbọràn sí gẹ́gẹ́ bí Olùṣàkóso dípò èèyàn. Ìyẹn ò ní jẹ́ kí àtakò tàbí àwọn ohun ìdíwọ́ míì lè dá ọ dúró kó o má ṣe máa yin Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà lógo létígbọ̀ọ́ àwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù rẹ.—Jer. 15:20, 21.
24. Àwọn àǹfààní wo lo máa jẹ nísinsìnyí tó o bá jẹ́ onígbọràn?
24 Ìgbà tá a bá fi ti Ẹlẹ́dàá wa ṣe nìkan ni ọwọ́ wa lè tẹ ojúlówó ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn nígbèésí ayé. (Jer. 10:23) Lẹ́yìn tó o sì ti ka ọ̀rọ̀ Jeremáyà nípa bó ṣe yẹ kéèyàn jẹ́ onígbọràn, ǹjẹ́ o rí àwọn ibi tó ti yẹ kó o ṣe àwọn àtúnṣe kan kí Jèhófà lè túbọ̀ máa darí ìṣísẹ̀ rẹ? Àwọn òfin rẹ̀ nìkan ló lè mú ká máa gbé ìgbé ayé tá a ó fi ní ojúlówó ayọ̀ àti àṣeyọrí. Jèhófà rọ̀ wá pé: “Ẹ ṣègbọràn sí ohùn mi, . . . kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún yín.”—Jer. 7:23.
Báwo lo ṣe lè máa fi àwọn ẹ̀kọ́ nípa jíjẹ́ onígbọràn tó o ti kọ́ nínú ìwé Jeremáyà sílò nínú àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run?
a Ìjọba Ísírẹ́lì tó wà níhà àríwá ni Jèhófà ń bá wí níbí. Àwọn èèyàn ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá yìí ti wà nígbèkùn fún odindi ọgọ́rùn-ún ọdún nígbà tí Jeremáyà jíṣẹ́ yìí fún wọn. Jeremáyà sì sọ pé títí di bóun ṣe ń jíṣẹ́ yẹn, orílẹ̀-èdè yẹn lápapọ̀ ò tíì ronú pìwà dà. (2 Ọba 17:16-18, 24, 34, 35) Àmọ́, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn lè pa dà sọ́dọ̀ Ọlọ́run, kí wọ́n sì rí ojú rere rẹ̀ bóyá kí wọ́n tiẹ̀ kúrò nígbèkùn pàápàá.