ORÍ KẸTÀLÁ
Ó Kẹ́kọ̀ọ́ Nínú Àwọn Àṣìṣe Rẹ̀
1, 2. (a) Irú ìjàngbọ̀n wo ni Jónà kó ara rẹ̀ àtàwọn atukọ̀ òkun sí? (b) Ẹ̀kọ́ wo ni ìtàn Jónà lè kọ́ wa?
JÓNÀ ń gbọ́ ariwo kíkankíkan àti ìbòòsí nínú ọkọ̀ òkun tó wà, ó sì ń ṣe é bíi pé kó rí nǹkan bo etí rẹ̀ kó má bàa gbọ́ ariwo náà mọ́. Ariwo tó ń gbọ́ ju ariwo tí àwọn okùn ìgbòkun ọkọ̀ náà ń pa kíkankíkan torí atẹ́gùn líle tó ń fẹ́ lù wọ́n. Ariwo yìí sì ju ti àwọn ìgbì òkun tó ga bí òkè tó ń rọ́ lu ọkọ̀ náà ṣáá lọ́tùn-ún lósì, tí àwọn igi rẹ̀ fi ń rọ́ kẹ̀kẹ̀ bíi pé wọ́n máa fọ́. Igbe ọ̀gákọ̀ náà àti àwọn ọmọ iṣẹ́ rẹ̀ tó ń ṣe kìràkìtà kí ọkọ̀ wọn má rì ló ká Jónà lára jù. Jónà mọ̀ pé gbogbo wọn ò ní pẹ́ bómi lọ, òun lóun sì kó bá wọn.
2 Báwo ni Jónà ṣe kó sínú ìjàngbọ̀n yìí? Ṣe ló ṣàìgbọràn sí Jèhófà Ọlọ́run. Kí ló ṣe? Ṣé ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ti wá kọjá àtúnṣe ni? A máa rí ẹ̀kọ́ kọ́ gan-an nínú ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí. Bí àpẹẹrẹ, ìtàn Jónà jẹ́ ká rí i pé àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn fẹsẹ̀ múlẹ̀ pàápàá lè ṣàṣìṣe, wọ́n sì lè ṣàtúnṣe.
Wòlíì Tó Wá Láti Gálílì
3-5. (a) Kí ló sábà máa ń wá sí àwọn èèyàn lọ́kàn tí wọ́n bá rántí Jónà? (b) Kí la mọ̀ nípa irú ẹni tí Jónà jẹ́ látilẹ̀wá? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.) (d) Kí nìdí tí iṣẹ́ wòlíì tí Jónà ń ṣe kò fi rọrùn rárá?
3 Tí àwọn èèyàn bá rántí Jónà, àwọn àṣìṣe rẹ̀ ló sábà máa ń wá sí wọn lọ́kàn. Irú bó ṣe ṣàìgbọràn tàbí bó ṣe ṣe orí kunkun. Àmọ́, ó ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan rere míì tó yẹ ká mọ̀ nípa rẹ̀. Rántí pé Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló yàn án ṣe wòlíì rẹ̀. Jèhófà ò ní yàn án pé kó ṣe irú iṣẹ́ pàtàkì bẹ́ẹ̀ ká ní kì í ṣe olóòótọ́ àti olódodo.
Ọ̀pọ̀ nǹkan rere míì wà tó yẹ ká mọ̀ nípa Jónà yàtọ̀ sí àwọn àṣìṣe rẹ̀
4 Bíbélì ò fi bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa irú ẹni tí Jónà jẹ́ látilẹ̀wá. (Ka 2 Àwọn Ọba 14:25.) Ṣùgbọ́n ó ní ọmọ ìlú Gati-héférì ni. Ìlú yìí wà ní kìlómítà mẹ́rin péré sí ìlú Násárétì tí wọ́n ti tọ́ Jésù dàgbà ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rin [800] ọdún lẹ́yìn ìgbà náà.a Ìgbà tí Jèróbóámù Ọba Kejì ń ṣàkóso ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì ni Jónà jẹ́ wòlíì. Èlíjà ti kú tipẹ́tipẹ́ nígbà yẹn, Èlíṣà tó gbapò rẹ̀ náà sì ti kú nígbà tí bàbá Jèróbóámù yìí jẹ́ ọba. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà lo Èlíjà àti Èlíṣà láti fòpin sí ìjọsìn Báálì, àwọn èèyàn Ísírẹ́lì tún ti ń mọ̀ọ́mọ̀ fi Jèhófà sílẹ̀. Àpẹẹrẹ burúkú ọba kan tó “ń bá a lọ ní ṣíṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà” ni àwọn èèyàn Ísírẹ́lì wá ń tẹ̀ lé báyìí. (2 Ọba 14:24) Nítorí náà, iṣẹ́ wòlíì tí Jónà ń ṣe nígbà yẹn kò rọrùn rárá. Síbẹ̀, ó ń bá iṣẹ́ rẹ̀ lọ láìjáwọ́.
5 Lọ́jọ́ kan, nǹkan kan ṣẹlẹ̀ tó yí ìgbésí ayé Jónà pa dà. Jèhófà rán an ní iṣẹ́ kan tó gbà pé ó nira gan-an láti jẹ́. Iṣẹ́ wo ló rán an?
“Dìde, Lọ sí Nínéfè”
6. Iṣẹ́ wo ni Jèhófà rán Jónà? Kí nìdí tí iṣẹ́ yìí fi lè bà á lẹ́rù?
6 Jèhófà sọ fún Jónà pé: “Dìde, lọ sí Nínéfè ìlú ńlá títóbi náà, kí o sì pòkìkí lòdì sí i pé ìwà búburú wọn ti gòkè wá síwájú mi.” (Jónà 1:2) Kò ṣòro láti mọ ìdí tí iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán Jónà yìí fi lè bà á lẹ́rù. Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ [800] kìlómítà ni ìlú Nínéfè wà sí apá ìlà oòrùn. Téèyàn bá sì máa fẹsẹ̀ rìn ín, ó lè gba onítọ̀hún ní oṣù kan gbáko. Àmọ́, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé kékeré ni ìnira ìrìn ọ̀nà jíjìn yẹn jẹ́ lára iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán Jónà. Torí tó bá dé ìlú Nínéfè yóò jíṣẹ́ ìdájọ́ Jèhófà fún àwọn ará Ásíríà tí wọ́n rorò tí wọ́n sì jẹ́ òṣónú ẹ̀dá. Nígbà tí àwọn tó jẹ́ èèyàn Ọlọ́run ò fi gbogbo ara gbọ́rọ̀ Jónà, ǹjẹ́ tàwọn abọ̀rìṣà yẹn kò wá ní burú jù bẹ́ẹ̀ lọ? Ṣé ojú òun ìránṣẹ́ Jèhófà, tó fẹ́ dá lọ jíṣẹ́ yìí, kò wá ní rí màbo ní ìlú Nínéfè tó fẹ̀ gan-an, tí Ọlọ́run wá pè ní “ìlú ńlá ìtàjẹ̀sílẹ̀” nígbà tó yá?—Náh. 3:1, 7.
7, 8. (a) Kí ni Jónà ṣe tó fi hàn pé kò tiẹ̀ fẹ́ jíṣẹ́ tí Jèhófà rán an rárá? (b) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká kàn gbà pé ojo èèyàn ni Jónà?
7 Bóyá irú àwọn nǹkan tí Jónà ń rò nìyí, a ò lè sọ. Ohun tá a mọ̀ ni pé ó sá gba ọ̀nà ibòmíì lọ. Ṣé ẹ rí i, Jèhófà sọ pé kí Jónà lọ sápá ìlà oòrùn, ìwọ̀ oòrùn ló forí lé, ó fẹ́ sá lọ sọ́nà jíjìn réré. Ó wá lọ sí etíkun ìlú Jópà níbi tó ti rí ọkọ̀ òkun kan tó ń lọ sí ìlú Táṣíṣì. Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé orílẹ̀-èdè Sípéènì ni ìlú Táṣíṣì wà. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé ibi tí Jónà forí lé fi ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàájọ [3,500] kìlómítà jìnnà sí Nínéfè. Tí wọ́n bá máa rin ìrìn àjò orí omi lọ sí irú ìpẹ̀kun Òkun Ńlá bẹ́ẹ̀, ìyẹn Òkun Mẹditaréníà, ó lè gbà tó ìrìn àjò ọdún kan gbáko! Ẹ ò rí i pé ṣe ni Jónà fẹ́ sá lọ ráúráú, kó má bàa jíṣẹ́ tí Jèhófà rán an!—Ka Jónà 1:3.
8 Ṣé èyí wá fi hàn pé ojo ẹ̀dá ni Jónà? Kò rí bẹ́ẹ̀ o. Torí a ṣì máa rí i níwájú pé ó ṣe àwọn ohun tó fi hàn pé ó nígboyà. Àmọ́ ṣá o, aláìpé èèyàn tó máa ń ṣe ọ̀pọ̀ àṣìṣe bíi ti gbogbo wa náà ni Jónà. (Sm. 51:5) Àbí, èwo nínú wa ló lè fọwọ́ sọ̀yà pé ẹ̀rù ò ba òun rí?
9. Èrò wo ló lè máa wá sí wa lọ́kàn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nípa iṣẹ́ tí Jèhófà ní ká ṣe? Òótọ́ ọ̀rọ̀ wo ló yẹ ká máa rántí nírú àkókò yẹn?
9 Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó lè máa ṣe wá bíi pé ohun tí Ọlọ́run ní ká ṣe ti le jù tàbí pé ó jẹ́ ohun tí ò lè ṣeé ṣe. Iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tí Ọlọ́run ní kí gbogbo Kristẹni máa ṣe tiẹ̀ lè kà wá láyà. (Mát. 24:14) Ohun tó ń fà á ni pé, a sábà máa ń gbàgbé òótọ́ ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ, pé: “Ohun gbogbo ṣeé ṣe fún Ọlọ́run.” (Máàkù 10:27) Nítorí pé irú nǹkan báyìí máa ń ṣẹlẹ̀ sí wa, ìyẹn jẹ́ ká rí i pé ó lè ṣẹlẹ̀ sí Jónà náà. Àmọ́, kí ló wá ṣẹlẹ̀ sí Jónà bó ṣe ń sá lọ?
Jèhófà Bá Wòlíì Rẹ̀ Tó Ṣàìgbọràn Wí
10, 11. (a) Kí ni Jónà á máa rò bí ọkọ̀ òkun náà ṣe gbéra ní etíkun? (b) Ewu wo ló dé bá ọkọ̀ òkun náà àti àwọn atukọ̀ rẹ̀?
10 Ẹ jẹ́ ká fojú inú wo Jónà bó ṣe jókòó pẹ̀sẹ̀ sínú ọkọ̀ òkun náà, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọkọ̀ akẹ́rù ti àwọn ará Fòníṣíà. Jónà ń wo bí ọ̀gá atukọ̀ àtàwọn ọmọọṣẹ́ rẹ̀ ṣe ń múra àtigbéra, kí wọ́n lè kúrò ní etíkun. Bí ọkọ̀ náà ṣe ń lọ tí wọ́n sì ń jìnnà sí etíkun díẹ̀díẹ̀, Jónà á ti máa rò pé òun ti bọ́ lọ́wọ́ iṣẹ́ ńlá tó ń já òun láyà. Ni ojú ọjọ́ bá yí pa dà lójijì.
11 Ìjì lílé bẹ̀rẹ̀ sí í jà, ó ń ru òkun gùdù lọ́tùn-ún lósì. Àwọn ìgbì òkun náà ga bí òkè, débi pé àwọn ọkọ̀ òkun ńláńlá òde òní pàápàá lè rí bíńtín láàárín wọn. Ǹjẹ́ ó máa wá pẹ́ rárá kí ìjì líle yìí tó fọ́ ọ̀kọ̀ òkun onígi lásánlàsàn náà dà nù bó ṣe ń taari rẹ̀ síwá sẹ́yìn? Àbí ìgbà yẹn tiẹ̀ ni Jónà ti róye pé Jèhófà ló fà á, gẹ́gẹ́ bó ṣe kọ ọ́ lẹ́yìn náà pé, “Jèhófà fúnra rẹ̀ sì rán ẹ̀fúùfù ńláǹlà jáde sí òkun”? A ò lè sọ. Àmọ́, ó rí i pé àwọn atukọ̀ náà bẹ̀rẹ̀ sí í ké pe àwọn òrìṣà wọn, ó sì mọ̀ pé àwọn òrìṣà yẹn ò lè gbà wọ́n. (Léf. 19:4) Jónà sọ nínú ìwé rẹ̀ pé: “Àti ní ti ọkọ̀ òkun náà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ fọ́.” (Jónà 1:4) Wàyí o, ẹnu wo ni Jónà máa wá fi gbàdúrà sí Ọlọ́run tó ń sá fún?
12. (a) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká kàn gbà pé ṣe ni Jónà ò bìkítà bó ṣe sùn nígbà tí ìjì ń jà? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.) (b) Báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ kí wọ́n mọ ẹni tó fa ìyọnu tó bá wọn?
12 Bó ṣe wá rí i pé kò sí nǹkan kan tóun lè ṣe sí ọ̀ràn náà, ó lọ wá ibì kan sùn sí nínú ọkọ̀ náà. Ó sì sùn lọ fọnfọn.b Ọ̀gá atukọ̀ náà rí i níbi tó sùn sí, ló bá jí i pé kí òun náà ké pe ọlọ́run rẹ̀. Bí àwọn atukọ̀ náà ṣe rí i pé ìjì tó ń jà kì í ṣe ojú lásán, wọ́n ṣẹ́ kèké kí wọ́n lè mọ ẹni tó fa ìyọnu náà láàárín àwọn tí wọ́n jọ wà nínú ọkọ̀. Ó dájú pé àyà Jónà á ti máa já bí kèké náà ṣe ń fò wọ́n lọ́kọ̀ọ̀kan. Nígbà tó yá, àṣírí tú. Àṣé torí Jónà ni Jèhófà ṣe jẹ́ kí ìjì náà jà, òun náà sì ni Jèhófà jẹ́ kí kèké mú.—Ka Jónà 1:5-7.
13. (a) Kí ni Jónà jẹ́wọ́ fún àwọn atukọ̀? (b) Kí ni Jónà sọ pé kí àwọn atukọ̀ ṣe sí òun, kí sì nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀?
13 Jónà wá jẹ́wọ́ gbogbo bọ́rọ̀ ṣe jẹ́ fáwọn atukọ̀ náà. Ó ní ìránṣẹ́ Jèhófà, Ọlọ́run Olódùmarè ni òun. Pé ṣe ni òun fẹ́ sá fún Ọlọ́run yìí, òun sì ti ṣẹ̀ ẹ́, ìyẹn ló sì kó gbogbo wọn sínú ewu ńlá yìí. Ni ìdí àwọn ọkùnrin náà bá domi, Jónà sì rí i lójú wọn. Wọ́n wá bi Jónà pé kí ni kí àwọn ṣe sí i kí ọkọ̀ àwọn má bàa dà nù, kí àwọn sì bómi lọ. Kí ló sọ? Ara Jónà lè sẹ́gìíìrì tó bá ń ro bóun á ṣe máa pòfóló nígbà tóun bá rì sínú òkun tútù nini tó ń ru gùdù yẹn. Àmọ́, kò fẹ́ fẹ̀mí àwọn ẹni ẹlẹ́ni wọ̀nyí ṣòfò dà nù nígbà tó lè kó wọn yọ. Torí náà, ó ní: “Ẹ gbé mi, kí ẹ sì jù mí sínú òkun, òkun yóò sì pa rọ́rọ́ fún yín; nítorí mo mọ̀ pé èmi ni ó fà á tí ìjì líle ńláǹlà yìí fi dé bá yín.”—Jónà 1:12.
14, 15. (a) Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Jónà tó lágbára gan-an? (b) Kí ni àwọn atukọ̀ yìí ṣe nípa ohun tí Jónà ní kí wọ́n ṣe sí òun?
14 Ó dájú pé ojo èèyàn ò lè sọ̀rọ̀ báyìí, àbí? Inú Jèhófà máa dùn gan-an láti rí ìwà akọni tí Jónà hù bó ṣe gbà láti kú dípò àwọn yòókù ní àkókò ewu yẹn. Èyí jẹ́ ká rí i pé ìgbàgbọ́ Jónà lágbára gidigidi. Àwa náà lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ lóde òní, ká máa fi ire àwọn ẹlòmíì ṣáájú tiwa. (Jòh. 13:34, 35) Tá a bá rí ẹni tó nílò ìrànlọ́wọ́ nípa tara, tàbí ẹni tó ní ẹ̀dùn ọkàn, tàbí ẹni tó nílò ìrànlọ́wọ́ kí àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà lè dán mọ́rán, ǹjẹ́ a máa ń sa gbogbo ipá wa láti ran onítọ̀hún lọ́wọ́? Inú Jèhófà máa ń dùn gan-an ni tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀!
15 Bóyá ohun tí Jónà ní kí àwọn atukọ̀ yìí ṣe ká àwọn náà lára gan-an, torí wọn ò kọ́kọ́ gbà láti jù ú sómi. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n sa gbogbo ipá wọn láti tukọ̀ la ìjì líle náà kọjá, àmọ́ pàbó ni gbogbo rẹ̀ já sí. Ṣe ni ìjì náà túbọ̀ ń le sí i. Níkẹyìn, wọ́n rí i pé kò sí ṣíṣe kò sí àìṣe. Lẹ́yìn tí wọ́n ti ké pe Jèhófà Ọlọ́run Jónà, pé kó ṣàánú àwọn, wọ́n gbé Jónà, wọ́n sì jù ú sínú òkun.—Jónà 1:13-15.
Ọlọ́run Ṣàánú Jónà Ó sì Gba Ẹ̀mí Rẹ̀ Là
16, 17. Ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jónà nígbà tí wọ́n jù ú sínú òkun. (Tún wo àwọn àwòrán.)
16 Jónà balẹ̀ sínú ìgbì òkun tó ń ru gùdù yẹn. Bóyá ó tiẹ̀ jà raburabu díẹ̀ kó lè léfòó láàárín ìfófòó òkun tó balẹ̀ sí, kó sì wá najú rí ọkọ̀ náà pé ó ti ń sáré lọ. Ni ìgbì òkun ńlá bá bò ó mọ́lẹ̀, ó sì rì sínú ibú. Bó ṣe ń rì lọ dòò sí ìsàlẹ̀ òkun lọ́hùn-ún, ó lè máa rò pé ó ti parí fóun nìyẹn.
17 Jónà pa dà wá ṣàlàyé bó ṣe rí lára rẹ̀ nígbà yẹn. Láàárín àkókò náà, ó rántí àwọn nǹkan kan fìrí. Bí àpẹẹrẹ, ọkàn rẹ̀ bà jẹ́ bó ṣe ronú pé òun ò ní rí tẹ́ńpìlì ẹlẹ́wà Jèhófà tó wà ní Jerúsálẹ́mù mọ́. Ó mọ̀ ọ́n lára pé òun ń rì lọ sábẹ́ omi lọ́hùn-ún, nítòsí ibi tí àwọn òkè ńlá ti pilẹ̀ nínú ibú, tí àwọn koríko inú òkun sì lọ́ mọ́ òun lára. Bóyá ó wá gbà pé inú kòtò, tàbí sàréè òun nìyẹn.—Ka Jónà 2:2-6.
18, 19. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Jónà nínú ibú òkun lọ́hùn-ún? Irú ẹ̀dá inú omi wo ló gbé e mì, ta ló sì jẹ́ kí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ṣẹlẹ̀? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
18 Àmọ́ o, nǹkan kan ń da omi rú bọ̀! Nǹkan dúdú ni, ó tóbi fàkìàfakia, nǹkan abẹ̀mí sì ni. Ó sún mọ́ ọ̀dọ̀ Jónà, ó sì pa kuuru mọ́ ọn. Ó wá lanu wàà, ó sì gbé e mì.
19 Jónà yóò ti rò pé ikú dé nìyẹn! Àmọ́, ó rí i pé ohun àrà kan ṣẹlẹ̀. Òun ṣì ń mí! Ẹja tó gbé e mì kò pa á lára, kò jẹ ẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ooru inú ẹja náà ò sì pa á. Àní Jónà ṣì wà láàyè, bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú ibi tá a lè pè ní sàréè rẹ̀ ló wà! Ẹnu bẹ̀rẹ̀ sí í yà á gidigidi. Ó dájú pé Jèhófà Ọlọ́run Jónà ló “ṣètò ẹja ńlá kan láti gbé Jónà mì.”c—Jónà 1:17.
20. Kí la lè rí kọ́ nípa Jónà látinú àdúrà tó gbà nínú ikùn ẹja ńlá náà?
20 Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ìṣẹ́jú ń gorí ìṣẹ́jú, wákàtí sì ń gorí wákàtí. Nínú òkùnkùn biribiri tí Jónà wà, ó ronú, ó sì gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run. Orí kejì ìwé Jónà ni àdúrà tó gbà yìí wà, ó sì jẹ́ ká rí ọ̀pọ̀ nǹkan kọ́ nípa Jónà. Àdúrà yẹn jẹ́ ká mọ̀ pé Jónà mọ Ìwé Mímọ́ gan-an, torí pé léraléra ló ń lo ọ̀rọ̀ inú ìwé Sáàmù. Ó tún jẹ́ ká mọ̀ pé ó ní ẹ̀mí ìmoore, ìwà tó sì dáa ni. Jónà wá sọ níparí àdúrà rẹ̀ pé: “Ní tèmi, èmi yóò fi ohùn ìdúpẹ́ rúbọ sí ọ. Èmi yóò san ohun ti mo jẹ́jẹ̀ẹ́. Ti Jèhófà ni ìgbàlà.”—Jónà 2:9.
21. Ẹ̀kọ́ wo ni Jónà kọ́ nípa ìgbàlà? Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo ló yẹ ká máa rántí?
21 Inú ibi téèyàn ò tiẹ̀ lè ronú kàn rárá yìí, ìyẹn ní “ìhà inú ẹja,” ni Jónà ti wá rí i pé Jèhófà lè gba ẹnikẹ́ni là níbikíbi àti nígbàkigbà. Àní sẹ́, Jèhófà rí ìránṣẹ́ rẹ̀ tó níṣòro yìí nínú ẹja tó wà lọ́hùn-ún, ó sì gbà á là. (Jónà 1:17) Jèhófà nìkan ló lè dá ẹ̀mí ẹnì kan sí nínú ẹja ńlá fún ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta kí nǹkan kan má sì ṣe onítọ̀hún. Lóde òní, ó yẹ kí àwa náà máa rántí pé Jèhófà ni “Ọlọ́run, ẹni tí èémí [wa] wà lọ́wọ́ rẹ̀.” (Dán. 5:23) Òun ni ẹlẹ́mìí tó ni ẹ̀mí wa, àti èémí tá à ń mí sínú. Ǹjẹ́ a moore Ọlọ́run? Ṣé kò wá yẹ ká máa pa àṣẹ Jèhófà mọ́?
22, 23. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ tó jẹ́ kó hàn bóyá Jónà ní ẹ̀mí ìmoore lóòótọ́? (b) Kí la rí kọ́ lára Jónà tó máa ràn wá lọ́wọ́ nígbà tá a bá ṣe àṣìṣe?
22 Jónà wá ńkọ́? Ṣé ó pa àṣẹ Jèhófà mọ́ láti fi hàn pé òun moore? Bẹ́ẹ̀ ni o. Lẹ́yìn ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta, ẹja náà gbé Jónà wá sí etíkun, ó sì “pọ Jónà sórí ilẹ̀ gbígbẹ.” (Jónà 2:10) Àbẹ́ ò rí nǹkan, kò sí pé Jónà ṣẹ̀ṣẹ̀ ń lúwẹ̀ẹ́ lọ sí etíkun! Àmọ́ ṣá, òun ló bẹ̀rẹ̀ sí í wọ́nà ara rẹ̀ lọ láti etíkun ibi tí ẹja yẹn pọ̀ ọ́ sí. Kò pẹ́ kò jìnnà, ohun kan ṣẹlẹ̀ tó jẹ́ kó hàn bóyá Jónà ní ẹ̀mí ìmoore lóòótọ́. Ìwé Jónà 3:1, 2 sọ pé: “Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ Jónà wá nígbà kejì, pé: ‘Dìde, lọ sí Nínéfè ìlú ńlá títóbi náà, kí o sì pòkìkí fún un nípa ìpòkìkí tí èmi yóò sọ fún ọ.’” Kí ni Jónà wá ṣe?
23 Jónà ò jáfara. Bíbélì sọ pé: “Látàrí ìyẹn, Jónà dìde, ó sì lọ sí Nínéfè ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Jèhófà.” (Jónà 3:3) Jónà ṣe bí Jèhófà ṣe sọ. Ó ti kẹ́kọ̀ọ́ nínú àwọn àṣìṣe rẹ̀ lóòótọ́. Ó yẹ ká kẹ́kọ̀ọ́ nínú ohun tí Jónà ṣe yìí, ká sì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ rẹ̀. Kò sẹ́ni tí kì í dẹ́ṣẹ̀, gbogbo wa la sì máa ń ṣe àṣìṣe. (Róòmù 3:23) Àmọ́, ṣé a máa ń jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa, àbí ṣe la máa ń kẹ́kọ̀ọ́ nínú àṣìṣe wa tí a ó sì ṣègbọràn, ká sì máa bá iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run nìṣó?
24, 25. (a) Ẹ̀san wo ni Jèhófà san Jónà nígbà tó ṣì wà láyé? (b) Ẹ̀san wo ni Jónà tún máa rí gbà lọ́jọ́ iwájú?
24 Ṣé Jèhófà san Jónà lẹ́san torí pé ó ṣègbọràn? Bẹ́ẹ̀ ni o. Torí ó jọ pé Jónà wá mọ̀ nígbà tó yá pé àwọn atukọ̀ tó wà nínú ọkọ̀ náà yè bọ́. Ó ṣẹlẹ̀ pé gbàrà tí wọ́n ṣe bí Jónà ṣe wí, tí wọ́n jù ú sínú òkun nítorí àwọn tó wà nínú ọkọ̀, ni ìjì náà dáwọ́ dúró. Làwọn atukọ̀ yẹn bá “bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀rù Jèhófà gidigidi,” wọ́n sì rúbọ sí Jèhófà dípò àwọn òrìṣà wọn.—Jónà 1:15, 16.
25 Jèhófà tiẹ̀ tún wá san án lẹ́san tó jùyẹn lọ nígbà tó yá. Jésù fi hàn pé àkókò tí Jónà lò nínú ẹja ńlá náà jẹ́ àpẹẹrẹ àkókò tí òun náà máa lò nínú sàréè tàbí Ṣìọ́ọ̀lù. (Ka Mátíù 12:38-40.) Ẹ wo bí inú Jónà ṣe máa dùn tó nígbà tó bá jíǹde tó sì tún wá rí àǹfààní ìyẹn náà! (Jòh. 5:28, 29) Jèhófà fẹ́ bù kún ìwọ náà. Ṣé wàá ṣe bíi ti Jónà, kó o máa kẹ́kọ̀ọ́ nínú àṣìṣe rẹ, kó o jẹ́ onígbọràn, kó o sì máa fi ire àwọn ẹlòmíì ṣáájú tìrẹ?
a Nǹkan pàtàkì ló jẹ́ pé Jónà wá láti ìlú kan tó wà ní Gálílì. Torí nígbà tí àwọn Farisí ń sọ̀rọ̀ nípa Jésù, wọ́n fi ìgbéraga sọ pé: “Ṣe ìwádìí káàkiri, kí o sì rí i pé kò sí wòlíì kankan tí a óò gbé dìde láti Gálílì.” (Jòh. 7:52) Ọ̀pọ̀ àwọn atúmọ̀ èdè àtàwọn tó ń ṣèwádìí sọ pé ohun táwọn Farisí wọ̀nyẹn ń sọ ni pé kò tíì sí ẹni tó jẹ́ wòlíì rí láti àgbègbè Gálílì tí kò já mọ́ nǹkan kan, kò sì lè sí láé. Tó bá jẹ́ ohun tí àwọn Farisí náà ní lọ́kàn nìyẹn, a jẹ́ pé ṣe ni wọ́n gbójú fo ohun tí ìtàn àti àsọtẹ́lẹ̀ sọ.—Aísá. 9:1, 2.
b Bíbélì Septuagint sọ pé Jónà hanrun láti fi sọ bó ṣe sùn wọra tó. Àmọ́, ká má kàn gbà pé Jónà ò bìkítà nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ló ṣe lọ wábi sùn sí o. Ká rántí pé nígbà míì ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn máa ń jẹ́ kí oorun kunni. Nígbà tí Jésù wà nínú ìrora ní ọ̀gbà Gẹtisémánì, ńṣe ni Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù “ń tòògbé nítorí ẹ̀dùn-ọkàn.”—Lúùkù 22:45.
c Nígbà tí àwọn atúmọ̀ èdè máa tú ọ̀rọ̀ tí àwọn Hébérù pe ẹja níbí sí èdè Gíríìkì, wọ́n túmọ̀ rẹ̀ sí “ẹran abàmì inú òkun” tàbí “ẹja tó tóbi fàkìà-fakia.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí bá a ṣe lè mọ irú ẹ̀dá inú omi tó gbé Jónà mì gan-an, ìwádìí ti fi hàn pé àwọn ẹja àbùùbùtán kan wà nínú Òkun Mẹditaréníà tó tóbi débi pé wọ́n lè gbé odindi èèyàn mì. Àwọn ẹja àbùùbùtán tó tóbi jùyẹn lọ fíìfíì sì tún wà láwọn ibòmíì. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ẹja àbùùbùtán kan wà tó gùn tó ọkọ̀ bọ́ọ̀sì mẹ́ta, ó sì ṣeé ṣe káwọn míì gùn jù bẹ́ẹ̀ lọ.