Ẹ̀kọ́ 8
Jòsáyà Ní Àwọn Ọ̀rẹ́ Rere
Ǹjẹ́ o mọ̀ pé kò rọrùn láti ṣe ohun tó dára?— Ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọ̀ bẹ́ẹ̀. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé kò rọrùn rárá fún ọmọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jòsáyà láti ṣe ohun tí ó dára. Àmọ́, ó ní àwọn ọ̀rẹ́ rere tí wọ́n ràn án lọ́wọ́. Ní báyìí, jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa Jòsáyà àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.
Ámọ́nì ni bàbá Jòsáyà, òun sì ni ọba Júdà. Èèyàn burúkú ni Ámọ́nì, òrìṣà sì ni ó ń jọ́sìn. Nígbà tí Ámọ́nì kú, Jòsáyà di ọba Júdà. Àmọ́, ọmọ ọdún mẹ́jọ péré ni nígbà yẹn! Ǹjẹ́ o rò pé irú ìwà burúkú tí bàbá rẹ̀ hù ni òun náà hù?— Rárá o, ìwà tiẹ̀ yàtọ̀ pátápátá!
Kódà, láti kékeré ló ti wu Jòsáyà kó máa ṣègbọràn sí Jèhófà. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà nìkan ló ń bá ṣe ọ̀rẹ́. Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sì ràn án lọ́wọ́ láti ṣe ohun tí ó dára. Àwọn wo ni àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ yìí?
Ọ̀kan nínú wọn ni Sefanáyà. Òun ni wòlíì tó kìlọ̀ fún àwọn èèyàn Júdà pé tí wọ́n bá ń jọ́sìn òrìṣà, nǹkan burúkú máa ṣẹlẹ̀ sí wọn. Jòsáyà fetí sí Sefanáyà, kò jọ́sìn òrìṣà, Jèhófà ló jọ́sìn.
Jòsáyà tún bá Jeremáyà ṣe ọ̀rẹ́. Ọjọ́ orí wọn sún mọ́ra, ibì kan náà làwọn méjèèjì sì ti dàgbà. Ọ̀rẹ́ àtàtà ni wọ́n, wọ́n sì fẹ́ràn ara wọn débi pé nígbà tí Jòsáyà kú, Jeremáyà kọ orin nípa bí ikú Jòsáyà ṣe dùn òun tó. Àwọn méjèèjì ran ara wọn lọ́wọ́ láti ṣe ohun tí ó dára, wọ́n sì ṣègbọràn sí Jèhófà.
Jòsáyà àti Jeremáyà ran ara wọn lọ́wọ́ láti ṣe ohun tí ó dára
Kí lo rí kọ́ lára Jòsáyà?— Láti kékeré ló ti wu Jòsáyà kó máa ṣègbọràn sí Jèhófà. Ó mọ̀ pé àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ló yẹ kí òun bá ṣe ọ̀rẹ́. Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ló yẹ kí ìwọ náà bá ṣe ọ̀rẹ́, torí wọ́n máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe ohun tí ó dára!