Orin 152
Agbára Wa, Ìrètí Wa, Ìgbẹ́kẹ̀lé Wa
Bíi Ti Orí Ìwé
Jèhófà, o fún wa nírètí
èyí tí à ńṣìkẹ́.
Ìrètí yìí ńmúnú wa dùn
a fẹ́ sọ fáyé gbọ́.
Nígbà míì, ìṣòro ayé yìí
máa ńmú kí ẹ̀rù bà wá,
Ìrètí tó ńmú ọkàn yọ̀
kò wá lágbára mọ́.
(ÈGBÈ)
Agbára, Ìrètí
Ìgbẹ́kẹ̀lé wa.
O máa ńbá wa gbé ‘ṣòro wa.
À ńwàásù, à ńkọ́ni,
ọkàn wa balẹ̀
torí ìwọ la gbẹ́kẹ̀ lé.
Jọ̀ọ́ Jèhófà, jẹ́ ká máa rántí
pé o wà lẹ́yìn wa,
’Gbà gbogbo lò ńtù wá nínú
tí ìṣòro bá dé.
Àwọn ìrònú tó ńmókun wá
lè mú k’írètí sọjí,
Wọ́n ńjẹ́ ká lè fi ìgboyà
kéde orúkọ rẹ.
(Ègbè)
Agbára, Ìrètí
Ìgbẹ́kẹ̀lé wa.
O máa ńbá wa gbé ‘ṣòro wa.
À ńwàásù, à ńkọ́ni,
ọkàn wa balẹ̀
torí ìwọ la gbẹ́kẹ̀ lé.
(Tún wo Sm. 72:13, 14; Òwe 3:5, 6, 26; Jer 17:7.)