ORIN 35
Máa Ṣe “Àwọn Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Jù”
1. A nílò ìfòyemọ̀ gan-an lónìí
Ká lè mọ ohun tó tọ́;
Àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù
Tí a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣe.
(ÈGBÈ)
Nífẹ̀ẹ́ ire; Sá fún ibi.
Múnú Jáà dùn.
Yóò bù kún wa bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́, tá a sì
Nífòyemọ̀,
Tá à ń ṣohun tó ṣe pàtàkì jù!
2. Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé
Ká wàásù ìhìn rere.
Ká kọ́ àwọn tó fẹ́ràn òtítọ́
Kí wọ́n ṣèfẹ́ Ọlọ́run.
(ÈGBÈ)
Nífẹ̀ẹ́ ire; Sá fún ibi.
Múnú Jáà dùn.
Yóò bù kún wa bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́, tá a sì
Nífòyemọ̀,
Tá à ń ṣohun tó ṣe pàtàkì jù!
3. Tá a bá ń ṣohun tó ṣe pàtàkì jù,
Ọkàn wa máa balẹ̀ gan-an.
Àlàáfíà Ọlọ́run wa yóò máa ṣọ́
Ọkàn àti èrò wa.
(ÈGBÈ)
Nífẹ̀ẹ́ ire; Sá fún ibi.
Múnú Jáà dùn.
Yóò bù kún wa báa ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́, tá a sì
Nífòyemọ̀,
Tá à ń ṣohun tó ṣe pàtàkì jù!
(Tún wo Sm. 97:10; Jòh. 21:15-17; Fílí. 4:7.)