ORIN 150
Wá Ọlọ́run Kó O Lè Rí Ìgbàlà
1. Gbogbo ọba ayé,
Wọ́n ń tako Jésù Ọba.
Ìṣàkóso àwọn èèyàn
Máa tó dópin láìpẹ́.
Jáà tí ṣèdájọ́ wọn,
Ìjọba Ọlọ́run dé.
Kò ní pẹ́ mọ́ rárá tí Jésù
Máa pa àwọn ọ̀tá run.
(ÈGBÈ)
Jèhófà ló lè gbani là,
Fọkàn balẹ̀, kó o gbẹ́kẹ̀ lé e.
Wá òdodo rẹ̀,
Jẹ́ olótìítọ́,
Fara mọ́ ìṣàkóso rẹ̀.
Wàá fojú rí bí Jèhófà
Á ṣe gbà ọ́ là.
2. Bá a ṣe ń wàásù òótọ́,
Àwọn kan ń fetí sí wa.
Àwọn mìíràn kò sì fẹ́ gbọ́,
Wọ́n sì tún ń gbéjà kò wá.
Àdánwò wa lè pọ̀,
A ó máa sin Jèhófà lọ.
Jèhófà ń bójú tó èèyàn rẹ̀;
Á gbọ́ wa tá a bá ké pè é.
(ÈGBÈ)
Jèhófà ló lè gbani là,
Fọkàn balẹ̀, kó o gbẹ́kẹ̀ lé e.
Wá òdodo rẹ̀,
Jẹ́ olótìítọ́,
Fara mọ́ ìṣàkóso rẹ̀.
Wàá fojú rí bí Jèhófà
Á ṣe gbà ọ́ là.
(Tún wo 1 Sám. 2:9; Sm. 2:2, 3, 9; Òwe 2:8; Mát. 6:33.)