ORÍ 10
‘Ẹ Ó Di Alààyè’
OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ: Ìran nípa àwọn “egungun gbígbẹ” tó wá sí ìyè àti bó ṣe ṣẹ lọ́nà tó gbòòrò
1-3. Kí ló mú kí ìbànújẹ́ dorí àwọn Júù tó wà nígbèkùn kodò? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ orí yìí.)
ÀWỌN Júù tó wà nígbèkùn Bábílónì ò gbà pé Jèhófà lè jẹ́ kí Jerúsálẹ́mù pa run. Nǹkan bí ọdún márùn-ún ni Ìsíkíẹ́lì fi kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe tan ara wọn jẹ, síbẹ̀ wọn ò gbọ́ ìkìlọ̀. Kí ni Ìsíkíẹ́lì ò ṣe tán? Ó ṣàpèjúwe, ó fojú sọ, ó fara sọ, bẹ́ẹ̀ sì ni kò dákẹ́, kí wọ́n lè mọ̀ pé ibi tí wọ́n fojú sí, ọ̀nà ò gbabẹ̀! Kódà, nígbà táwọn tó wà nígbèkùn náà gbọ́ pé àwọn ọmọ ogun Bábílónì ti yí Jerúsálẹ́mù ká, wọ́n ṣì gbà pé mìmì kan ò lè mi ìlú àwọn. Àmọ́ nígbà tí ọ̀rọ̀ bẹ́yìn yọ, ìbànújẹ́ dorí wọn kodò!
2 Lẹ́yìn ọdún méjì táwọn ọ̀tá ti yí Jerúsálẹ́mù ká, ẹnì kan tó ráyè jáde nílùú náà sá wá sí Bábílónì, ó sì ròyìn fún wọn pé: “Wọ́n ti pa ìlú náà run!” Ṣe lọkàn àwọn èèyàn náà gbọgbẹ́. Ó kọ́kọ́ dà bí àlá lójú wọn pé ìlú ìbílẹ̀ wọn, ibi àmúyangàn wọn, níbi tí tẹ́ńpìlì Ọlọ́run tòótọ́ wà ti pa run! Ó ṣe kedere pé ìrètí wọn ti já sófo.—Ìsík. 21:7; 33:21.
3 Lásìkò tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn Júù yìí ni wòlíì Ìsíkíẹ́lì rí ìran táá mú kí ìrètí àwọn èèyàn náà sọ jí. Báwo lohun tí Ìsíkíẹ́lì rí ṣe kan àwọn tó wà nígbèkùn? Báwo ló ṣe kan àwa èèyàn Ọlọ́run lóde òní, àǹfààní wo ló sì máa ṣe ẹnì kọ̀ọ̀kan wa? Ká lè rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká jọ wo ohun tí Jèhófà fi han Ìsíkíẹ́lì.
“Sọ Tẹ́lẹ̀ Sórí Àwọn Egungun Yìí,” Kó O sì ‘Sọ Tẹ́lẹ̀ fún Afẹ́fẹ́’
4. Kí ló gbàfiyèsí nínú ìran tí wòlíì Ìsíkíẹ́lì rí?
4 Ka Ìsíkíẹ́lì 37:1-10. Nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí, ó bá ara rẹ̀ ní àárín pẹ̀tẹ́lẹ̀ kan tí egungun òkú kún inú rẹ̀. Kí ohun tó rí lè dá a lójú, Jèhófà ní kí wòlíì náà lọ ‘yí ká’ gbogbo ibi tí àwọn egungun náà wà. Bí Ìsíkíẹ́lì ṣe ń rìn yí ká pẹ̀tẹ́lẹ̀ náà, ó kíyè sí bí àwọn egungun náà ṣe pọ̀ bí ilẹ̀ bí ẹní, tí wọ́n sì gbẹ gan-an. Wòlíì náà sọ pé egungun náà “pọ̀ gan-an” wọ́n sì “gbẹ gidigidi.”
5. Kí lohun méjì tí Jèhófà pa láṣẹ pé kí Ìsíkíẹ́lì ṣe, kí ló sì ṣẹlẹ̀ nígbà tí wòlíì náà ṣe bẹ́ẹ̀?
5 Ẹ̀yìn ìyẹn ni Jèhófà ní kí Ìsíkíẹ́lì ṣe ohun méjì kan tó máa mú káwọn egungun náà sọjí díẹ̀díẹ̀. Jèhófà kọ́kọ́ pàṣẹ fún wòlíì náà pé kó “sọ tẹ́lẹ̀ sórí àwọn egungun yìí” kí wọ́n lè “di alààyè.” (Ìsík. 37:4-6) Gbàrà tí Ìsíkíẹ́lì sọ àsọtẹ́lẹ̀ náà, “ariwo kan dún, ó dún bí ìgbà tí nǹkan ń rọ́ gììrì, àwọn egungun náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í tò pọ̀,” lẹ́yìn náà ni “iṣan àti ẹran” bo àwọn egungun náà, “awọ sì bò wọ́n.” (Ìsík. 37:7, 8) Jèhófà tún pàṣẹ fún Ìsíkíẹ́lì pé kó ‘sọ tẹ́lẹ̀ fún afẹ́fẹ́’ pé kó “fẹ́ lu” àwọn òkú náà. Nígbà tí wòlíì náà ṣe bẹ́ẹ̀, ‘èémí wọnú wọn, wọ́n wá di alààyè, wọ́n sì dìde dúró, ọmọ ogun tó pọ̀ gan-an ni wọ́n.’—Ìsík. 37:9, 10.
“Egungun Wa Ti Gbẹ, A Ò sì Ní Ìrètí Mọ́”
6. Kí ni Jèhófà sọ tó jẹ́ kí Ìsíkíẹ́lì lóye ìran tó rí?
6 Jèhófà wá mú kí Ìsíkíẹ́lì lóye ohun tí ìran náà túmọ̀ sí, ó sọ pé: “Gbogbo ilé Ísírẹ́lì ni àwọn egungun yìí.” Nígbà táwọn Júù tó wà nígbèkùn gbọ́ pé wọ́n ti pa Jerúsálẹ́mù run, ṣe ni wọ́n ronú pé tàwọn ti tán. Wọ́n kérora pé: “Egungun wa ti gbẹ, a ò sì ní ìrètí mọ́. Wọ́n ti pa wá run pátápátá.” (Ìsík. 37:11; Jer. 34:20) Àmọ́, Jèhófà gbọ́ ìdárò wọn, ó sì fi han Ìsíkíẹ́lì nínú ìran pé ìyípadà máa bá àwọn egungun yẹn, èyí jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ̀ pé ìrètí ṣì wà fún àwọn.
7. Bó ṣe wà nínú Ìsíkíẹ́lì 37:12-14, kí ni Jèhófà mú kó yé Ìsíkíẹ́lì? Báwo nìyẹn ṣe fi àwọn èèyàn Ọlọ́run tó wà nígbèkùn lọ́kàn balẹ̀?
7 Ka Ìsíkíẹ́lì 37:12-14. Jèhófà lo ìran yẹn láti mú kó dá àwọn tó wà nígbèkùn náà lójú pé wọ́n máa pa dà wà láàyè, òun á mú wọn pa dà sílùú ìbílẹ̀ wọn, wọ́n á sì gbèrú níbẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà tún pè wọ́n ní “ẹ̀yin èèyàn mi.” Ẹ wo bí ọ̀rọ̀ yẹn ṣe máa múnú àwọn tó wà nígbèkùn náà dùn tó, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti sọ̀rètí nù! Kí ló mú kó dá wọn lójú pé lóòótọ́ ni wọ́n máa pa dà sílùú ìbílẹ̀ wọn? Ó dá wọn lójú torí pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ló ṣèlérí náà. Ó sọ pé: “Èmi Jèhófà ti sọ̀rọ̀, mo sì ti ṣe é.”
8. (a) Báwo ni “gbogbo ilé Ísírẹ́lì” ṣe dà bí òkú fún ọ̀pọ̀ ọdún? (b) Báwo ni Ìsíkíẹ́lì 37:9 ṣe jẹ́ ká mọ ohun tó fà á tí Ísírẹ́lì fi kú lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
8 Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn egungun òkú tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran ṣe ṣẹ sí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ lára? Ọdún 740 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni àsọtẹ́lẹ̀ yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ sí Ísírẹ́lì lára, wọ́n kú lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ nígbà tí wọ́n pa ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì run, tí wọ́n sì kó àwọn tó ṣẹ́ kù lọ sí ìgbèkùn. Ní nǹkan bí àádóje (130) ọdún lẹ́yìn náà, wọ́n kó àwọn ọmọ Júdà náà lọ sígbèkùn. Èyí wá túmọ̀ sí pé “gbogbo ilé Ísírẹ́lì” ló wà nígbèkùn. (Ìsík. 37:11) Àwọn egungun òkú tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran yẹn ṣàpẹẹrẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n wà nígbèkùn.a Àmọ́ ẹ má gbàgbé pé kì í ṣe pé àwọn egungun yẹn kàn gbẹ nìkan ni, Bíbélì sọ pé wọ́n “gbẹ gidigidi,” èyí tó túmọ̀ sí pé ọjọ́ pẹ́ tí wọ́n ti wà nínú ipò yẹn. Téèyàn bá ṣírò ẹ̀ lóòótọ́, ó lé ní igba (200) ọdún tí Ísírẹ́lì àti Júdà lò nígbèkùn, ìyẹn látọdún 740 sí 537 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni.—Jer. 50:33.
9. Báwo làwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí Ísírẹ́lì àtijọ́ ṣe jọra pẹ̀lú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí “Ísírẹ́lì Ọlọ́run”?
9 Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Ìsíkíẹ́lì àtàwọn wòlíì míì sọ nípa bí nǹkan ṣe máa pa dà bọ̀ sípò fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún ṣẹ sáwọn míì lára. (Ìṣe 3:21) Báwọn ọ̀tá ṣe “pa” orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, tí wọ́n sì wà bí òkú fún ọ̀pọ̀ ọdún, bẹ́ẹ̀ náà làwọn ọ̀tá pa “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” ìyẹn ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, àwọn náà sì wà bí òkú nígbèkùn tẹ̀mí fún ọ̀pọ̀ ọdún. (Gál. 6:16) Kódà, ọdún tí ìjọ àwọn ẹni àmì òróró fi wà nígbèkùn kọjá kèrémí, ṣe ni ipò tẹ̀mí wọn dà bíi ti egungun tó ti “gbẹ gidigidi.” (Ìsík. 37:2) Bá a ṣe ṣàlàyé nínú orí tó ṣáájú èyí, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún kejì Sànmánì Kristẹni ni ìjọ Kristẹni lọ sígbèkùn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ni wọ́n sì lò nígbèkùn yẹn bí Jésù ṣe sọ nínú àkàwé àlìkámà àti èpò.—Mát. 13:24-30.
‘Àwọn Egungun Bẹ̀rẹ̀ sí Í Tò Pọ̀’
10. (a) Àwọn nǹkan wo ni Ìsíkíẹ́lì 37:7, 8 sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn Ọlọ́run? (b) Àwọn nǹkan wo ló mú kí ìgbàgbọ́ àwọn tó wà nígbèkùn bẹ̀rẹ̀ sí í sọ jí díẹ̀díẹ̀?
10 Ọjọ́ pẹ́ tí Jèhófà ti gbẹnu àwọn wòlíì sọ tẹ́lẹ̀ pé kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ni nǹkan máa yí pa dà sí rere fún àwọn èèyàn òun. (Ìsík. 37:7, 8) Àwọn nǹkan wo ló mú kí ìgbàgbọ́ àwọn Júù tó wà nígbèkùn yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í sọ jí díẹ̀díẹ̀, tó sì mú kí wọ́n máa fojú sọ́nà fún ìgbà tí wọ́n á pa dà sílùú ìbílẹ̀ wọn? Lára ẹ̀ ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ táwọn wòlíì kan ti sọ ṣáájú ìgbà yẹn. Bí àpẹẹrẹ, Àìsáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn àṣẹ́kù tó pè ní “irúgbìn mímọ́,” máa pa dà sí ilẹ̀ wọn. (Àìsá. 6:13; Jóòbù 14:7-9) Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ ni wòlíì Ìsíkíẹ́lì sọ nípa bí wọ́n ṣe máa pa dà sílé, tí wọ́n á sì tún pa dà máa jọ́sìn Jèhófà. Kò sí àní-àní pé ìyẹn fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀. Ohun míì tó fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ ní Bábílónì ni bí wọ́n ṣe ń rí àwọn olóòótọ́ bíi Dáníẹ́lì àtàwọn míì láàárín wọn. Ó sì dájú pé ìrètí wọn á túbọ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀ nígbà táwọn ọ̀tá ṣẹ́gun Bábílónì lọ́nà ìyanu lọ́dún 539 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni.
11, 12. (a) Báwo ni nǹkan ṣe yí pa dà ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ fún “Ísírẹ́lì Ọlọ́run”? (Tún wo àpótí náà, “Ìjọsìn Mímọ́ Pa Dà Bọ̀ Sípò Díẹ̀díẹ̀.”) (b) Ìbéèrè wo ló jẹ yọ látinú ohun tó wà nínú Ìsíkíẹ́lì 37:10?
11 Báwo ni nǹkan ṣe yí pa dà ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ fún “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” ìyẹn ìjọ Kristẹni àwọn ẹni àmì òróró? Lẹ́yìn tí wọ́n ti wà nígbèkùn tẹ̀mí fún ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún, “ariwo kan dún, ó dún bí ìgbà tí nǹkan ń rọ́ gììrì,” ìyẹn ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í wá bí ìjọsìn tòótọ́ ṣe máa pa dà fìdí múlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrìndínlógún, William Tyndale túmọ̀ Bíbélì sí èdè Gẹ̀ẹ́sì. Làwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì bá gbaná jẹ torí wọn ò fẹ́ kí Bíbélì dé ọwọ́ àwọn èèyàn. Wọ́n bá mú Tyndale, wọ́n sì pa á. Láìfi ìyẹn pè, àwọn míì lo ìgboyà, wọ́n sì túmọ̀ Bíbélì sí onírúurú èdè. Bí ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í tàn yanran nínú ayé òkùnkùn nìyẹn.
12 Nígbà tó yá, Charles T. Russell àtàwọn míì tí wọ́n jọ ṣiṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í fìtara polongo òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó wá dà bí ìgbà tí “iṣan àti ẹran” bo àwọn egungun náà. Wọ́n lo ìwé ìròyìn Zion’s Watch Tower àtàwọn ìtẹ̀jáde míì láti mú káwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ lóye ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì, kí wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹni àmì òróró Ọlọ́run. Lápá ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1900, Ọlọ́run tún fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó fòróró yàn lágbára kí wọ́n lè fi kún ìtara wọn. Lára ohun tó lò ni Photo-Drama of Creation [ìyẹn, Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá] àti ìwé The Finished Mystery. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni àkókò tó fáwọn èèyàn Ọlọ́run láti “dìde dúró.” (Ìsík. 37:10) Ìgbà wo nìyẹn ṣẹlẹ̀, báwo ló sì ṣe ṣẹlẹ̀? Àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ nílùú Bábílónì àtijọ́ máa jẹ́ ká rí ìdáhùn ìbéèrè yìí.
‘Wọ́n Di Alààyè, Wọ́n sì Dìde Dúró’
13. (a) Báwo lọ̀rọ̀ tó wà nínú Ìsíkíẹ́lì 37:10, 14 ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìmúṣẹ látọdún 537 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni? (b) Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ló jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn kan láti ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá pa dà sí Ísírẹ́lì?
13 Bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 537 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn Júù tó wà ní Bábílónì bẹ̀rẹ̀ sí í rí ìmúṣẹ ìran Ìsíkíẹ́lì. Lọ́nà wo? Jèhófà mú kí wọ́n pa dà wà láàyè, ó sì mú kí wọ́n “dìde dúró” ní ti pé ó dá wọn nídè kúrò nígbèkùn, ó sì mú kí wọ́n pa dà sílùú ìbílẹ̀ wọn. Ẹgbẹ̀rún méjìlélógójì, ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé ọgọ́ta (42,360) àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje (7,000) àwọn tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì ló fi Bábílónì sílẹ̀ kí wọ́n lè lọ tún Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ kọ́, kí wọ́n sì lè máa gbé nílẹ̀ Ísírẹ́lì. (Ẹ́sírà 1:1-4; 2:64, 65; Ìsík. 37:14) Ní nǹkan bí àádọ́rin (70) ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn, Ẹ́sírà àtàwọn bí ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún méje àti àádọ́ta (1,750) tí wọ́n wà ní Bábílónì pa dà sí Jerúsálẹ́mù. (Ẹ́sírà 8:1-20) Lápapọ̀, àwọn Júù tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógójì (44,000) ló pa dà sílùú ìbílẹ̀ wọn, ká sòótọ́, “ọmọ ogun tó pọ̀ gan-an” ni wọ́n. (Ìsík. 37:10) Bákan náà, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn kan láti ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọmọ àwọn tí Ásíríà kó lẹ́rú ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹjọ wà lára àwọn Júù tó pa dà sí Ísírẹ́lì, kí wọ́n lè jọ tún tẹ́ńpìlì kọ́.—1 Kíró. 9:3; Ẹ́sírà 6:17; Jer. 33:7; Ìsík. 36:10.
14. (a) Báwo lọ̀rọ̀ tó wà nínú Ìsíkíẹ́lì 37:24 ṣe jẹ́ ká mọ ìgbà tí àsọtẹ́lẹ̀ náà máa ṣẹ lọ́nà tó gbòòrò? (b) Kí ló ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1919? (Wo àpótí náà, “‘Àwọn Egungun Gbígbẹ’ Àtàwọn ‘Ẹlẹ́rìí Méjì’—Báwo Ni Wọ́n Ṣe Jọra?”)
14 Báwo ni apá yìí nínú àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì ṣe ṣẹ lóde òní? Jèhófà fi han Ìsíkíẹ́lì nínú ìran míì pé àsọtẹ́lẹ̀ náà máa ṣẹ lọ́nà tó gbòòrò lẹ́yìn tí Jésù Kristi tó jẹ́ Dáfídì Tó Tóbi Jù bá di Ọba.b(Ìsík. 37:24) Ọ̀rọ̀ sì rí bẹ́ẹ̀ lóòótọ́ torí pé lọ́dún 1919, Jèhófà fún àwọn èèyàn rẹ̀ ní ẹ̀mí rẹ̀. Èyí mú kí wọ́n “di alààyè,” Jèhófà sì gbà wọ́n kúrò nínú ìgbèkùn Bábílónì Ńlá. (Àìsá. 66:8) Lẹ́yìn náà, Jèhófà mú kí wọ́n pa dà máa gbé lórí “ilẹ̀” wọn, tàbí lédè míì, nínú párádísè tẹ̀mí. Àmọ́, báwo làwọn èèyàn Jèhófà lásìkò tiwa yìí ṣe di “ọmọ ogun tó pọ̀ gan-an”?
15, 16. (a) Báwo làwa èèyàn Jèhófà òde òní ṣe di “ọmọ ogun tó pọ̀ gan-an”? (b) Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Ísíkíẹ́lì ṣe lè mú ká máa fara da àwọn ìṣòro wa? (Wo àpótí náà, “Ó Ń Mú Ká Pa Dà Dìde Dúró.”)
15 Kò pẹ́ lẹ́yìn ọdún 1919 tí Kristi yan ẹrú olóòótọ́ ni àsọtẹ́lẹ̀ kan tí wòlíì Sekaráyà sọ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ sáwọn èèyàn Jèhófà lára. Àárín àwọn tó pa dà dé láti ìgbèkùn ni wòlíì yìí wà nígbà tó sọ tẹ́lẹ̀ pé: ‘Ọ̀pọ̀ èèyàn àti orílẹ̀-èdè alágbára yóò wá kí wọ́n lè wá Jèhófà.’ Wòlíì náà fi àwọn tó ń wá Jèhófà wé “ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè.” Àwọn ọkùnrin yìí máa di “Júù kan,” ìyẹn Ísírẹ́lì tẹ̀mí mú, wọ́n á sì máa sọ pé: “A fẹ́ bá yín lọ, torí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.”—Sek. 8:20-23.
16 Lọ́jọ́ tiwa, àwọn tó jẹ́ ara Ísírẹ́lì tẹ̀mí (ìyẹn àwọn tó ṣì wà láyé lára àwọn ẹni àmì òróró) àtàwọn “ọkùnrin mẹ́wàá” (tó ṣàpẹẹrẹ àwọn àgùntàn mìíràn) ti para pọ̀ di “ọmọ ogun tó pọ̀ gan-an.” Kódà, a ti lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ. (Ìsík. 37:10) Torí pé ọmọ ogun Kristi ni wá, à ń tẹ̀ lé Jésù Ọba wa pẹ́kípẹ́kí, ó sì dá wa lójú pé a máa gbádùn ọ̀pọ̀ ìbùkún lọ́jọ́ iwájú.—Sm. 37:29; Ìsík. 37:24; Fílí. 2:25; 1 Tẹs. 4:16, 17.
17. Kí la máa jíròrò nínú orí tó kàn?
17 Ojúṣe ńlá ló já lé àwọn èèyàn Jèhófà léjìká lẹ́yìn tí Jèhófà mú ìjọsìn mímọ́ pa dà bọ̀ sípò. Kí ni ojúṣe náà? Ká lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká pa dà sí àsìkò wòlíì Ìsíkíẹ́lì, ká sì wo iṣẹ́ kan tí Jèhófà gbé fún un ṣáájú ìparun Jerúsálẹ́mù. Kókó yìí la máa gbé yẹ̀ wò nínú orí tó kàn.
a Àwọn egungun tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran kì í ṣe tàwọn tí àìsàn tàbí ìjàǹbá pa tàbí tàwọn tó kú tìtorí ọjọ́ ogbó. Kàkà bẹ́ẹ̀, egungun náà jẹ́ ti àwọn ‘èèyàn tí wọ́n pa.’ (Ìsík. 37:9) “Gbogbo ilé Ísírẹ́lì” ni wọ́n pa lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ nígbà táwọn ọmọ ogun Ásíríà kó ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì lọ sígbèkùn, táwọn ará Bábílónì sì kó ẹ̀yà méjì ti ilẹ̀ Júdà lọ sígbèkùn.